Eko ni soki

Ododo je iwa olola ninu ohun ti o maa npe igbagbo, ti o si maa npe Islam, nigbati Olohun Oba ti ola re ga paa ni ase, O si tun se eyin fun awon ti won ba gba iroyin pelu re, iwa ododo je ola fun awon olododo, o si je oso ati itutu oju fun eniti o ba jere pelu re. Nidamiran, iro je apejuwe ijanba ti o tobi, paapaa julo, o wa ninu awon apere pooki, ki yio si le eru kun ju ijinna si Olohun lo, eru ko ni ye ni eniti yio maa so ododo titi ti won yio fi ko fun lodo Olohun wipe olododo ni, eru ko si ni ye ni imaa pa iro titi ti won yio fi ko lodo Olohun wipe okuro ni.

Awọn erongba lori Khutuba naa:

1.         Ki awọn musulumi le maa tẹle ododo ni ibi ibalopọ wọn;

2.         Ifuni ni ara awọn aburu irọ pipa;

3.         Sise afirinlẹ ifi ọkantan ni ni aarin awọn eniyan.

 

Khutubah Alakọkọ (ogun isẹju):

الحمد لله ربّ العالَمين، القائل في محكم تنزيله: {يا أيها الذين آمنوا اتقوا الله وكونوا مع الصّادقين} [التّوبة: 119]، كونوا مع الصادقين في إيمانهم وأقوالهم وأفعالهم وعهودهم. والصّلاة والسّلام على رسول الله الصّادق المصدوق الأمين، وآله وصحبه ومَن تبعهم بإحسانٍ إلى يوم الدِّين. وبعد؛

 

Dajudaju ipilẹ aburu ti o n sẹlẹ si awọn eniyan ni asiko yi ko sẹyin jijinna ti wọn jinna si ẹsin ododo ti o wa ni ati ọdọ Ọlọhun lọ. Ati fifi ọkan ni inu awọn ipilẹ ẹsin naa silẹ eyi tii se ododo. Dajudaju mi maa duro lori ododo jẹ ọkan ni inu awọn ẹkọ ẹsin Isilaamu ti mumini gbọdọ maa hu ni iwa.

Ni itori naa, ẹyin ẹrusin Ọlọhun ni ododo! ẹbẹru Ọlọhun, ni itoripe ibẹru Ọlọhun ni akojọpọ gbogbo oore, okunfa alubarika ti o si tun jẹ ọkan ni inu awọn iwa dada ti o gbajuma tun ni pẹlu. Pẹlurẹ ni igbagbọ ati Isilaamu musulumi fi n pe.

Nini ododo pẹlu Ọlọhun ni yoo se okunfa sisọ iwọ Rẹ, pipe igbagbọ ododo si I, mmi maa se suru ni asiko inira, mi maa se ọpẹ ni ori awọn oore Rẹ, mi maa se asepọ ni titori Ọlọhun, ati mi maa binu ni itori Rẹ ni igbati awọn eniyan ba tapa si asẹ Ọlọhun. Idiniyi ti Ọlọhun fi pasẹ ibẹru Ọlọhun ati diduro pẹlu awọn olusọ ododo. [At-Taubah: 119].

{يا أيها الذين آمنوا اتقوا الله وكونوا مع الصادقين} [التّوبة: 119]، يعني : الصادقين في إيمانهم وأقوالهم وأفعالهم وعهودهم.

Dajudaju awọn ododo ti o fi ẹsẹ mulẹ nikan soso ni o yẹ ki a maa se amulo, afihan ati igbe ara lee ni ibi gbogbo isesi wa. Ohun ni yoo mu ifi ọkantan ara ẹni wa, ti  apọnle ati ifẹ yoo si jẹ ọba ni aarin awọn oluda owo pọ. Ti alaafia, ifọkanbalẹ ati alubarika yoo si sọkalẹ. Hakim ibn Hizam (رضي الله عنه) gba ẹgbawa pe: Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sọ wipe: "Olutaja ati oluraja si ni ẹtọ ati sa ẹsa ni opin igba ti wọn si wa papọ ti wọn kotii tuka, ti wọn basi sọ ododo ti wọn si se alaye ti o yẹ alubarika yoo wọ inu owo wọn, sugbọn ti wọn ba parọ, ti wọn si se abosi, alubarika yoo kuro ni inu owo naa".

Ododo ni inu Tira Ọlọhun: Ọlọhun (سبحانه وتعالى) darukọ ododo ni awọn ọna ti o pọ ni inu Al-kuran ti O n se wa ni akin lilo ododo, ti O n se alaye ere ododo funwa, ni inu awọn ọna wọnyi ni:

{يا أيها الذين آمنوا اتقوا الله وكونوا مع الصادقين} [التّوبة: 119]. أي: كونوا مع الصادقين في أقوالهم وأفعالهم وأحوالهم، الذين أقوالهم صدق وأعمالهم وأحوالهم لا تكون إلا صدقاً خالية من الكسل والفتور، سالمة من المقاصد السيئة مشتملة على الإخلاص والنية الصالحة.

"Mo pe ẹyin ti ẹ gbagbọ ni ododo, ẹ paya Ọlọhun ki ẹsi wa pẹlu awọn olusọ ododo" [At-Taubah: 119]. Ni ibi ọrọ wọn, isẹ wọn ati gbogbo isesi wọn, eyi ti o duro pẹlu ododo, ti ko si kọlọkọlọ kankan ni ibẹ.

وقوله تعالى: { ليجزي الله الصادقين بصدقهم }[الأحزاب: 24] أي: بسبب صدقهم في أقوالهم وأحوالهم، ومعاملتهم مع الله، واستواء ظاهرهم وباطنهم.

"Ki Ọlọhun le san awọn olusọ ododo ni ẹsan ododo  wọn" [Al-Ahzaab: 24]. Itumọ eleyi nipe: olododo niwọn ni ibi ọrọ wọn, isẹ wọn ati gbogbo isesi wọn.

وقال الله تعالى: { هذا يوم ينفع الصادقين صدقهم لهم جنات تجري من تحتها الأنهار خالدين فيها أبدا} [المائدة: 119]، أي: أن صدقهم في الدنيا ينفعهم يوم القيامة، وأن العبد لا ينفعه يوم القيامة ولا ينجيه من عذابه إلاّ الصدق.

"Eleyi ni ọjọ ti ododo yoo maa wulo fun awọn olododo, tiwọn ni awọn alijannah kan, ti awọn odo n saan lọ ni abẹ wọn, ti wọn yoo si maa wa ni inu rẹ lọ gbere" [Al-Maidah: 119]. Itumọ eleyi nipe: ododo wọn ni aye yoo se wọn ni anfaani ni ọjọ ikẹyin, atipe kosi nkankan ti o lee la eniyan kuro ni ibi iya yatọsi ododo.

وقال تعالى: { وبشر الذين آمنوا أن لهم قدم صدق عند ربهم} [يونس: 2]، أي: إيماناً صادقاً بأن لهم جزاء موفور، وثواب مدخور عند ربهم بما قدموه وأسلفوه من الأعمال الصالحة الصادقة.

"Fun awọn ti wọn gbagbọ ni iro idunnu pe; dajudaju wọn ni atisiwaju ododo ni ọdọ Oluwa wọn" [Yunus: 2].

وقال تعالى: { والذي جاء بالصدق وصدق به أولئك هم المتقون} [الزمر: 33].

قال ابن القيم: فلا يكفي صدقك بل لا بد من صدقك وتصديقك للصادقين؛ فكثير من الناس يصدق، ولكن يمنعه من التصديق كبر أو حسد أو غير ذلك.

"Ẹni ti o mu ododo wa, ti o si tun gbaa ni ododo, awọn ni olubẹru ni ododo" [Az-Zumar: 33]. Pupọ ninu awọn eniyan ni wọn n sọ ododo, sugbọn ti wọn kii gba nitori motómotó, igberaga ati ijọ ara-ẹni loju.

 

Ọlọhun (سبحانه وتعالى) paapa royin Ara Rẹ pẹlu ododo:

ووصف الله نفسه به فقال سبحانه: {قل صدق الله} [آل عمران: 95].

"Sọ pe: ododo ni Ọlọhun sọ" [Al-i-'Imran: 95].

وقال سبحانه:{ ومن أصدق من الله حديثا} [النّساء: 87].

"Taa ni o tun sọ ọrọ ododo ju Ọlọhun lọ?!" [An-nisaa: 87].

قال الله تعالى: {فلو صدقوا الله لكان خيراً لهم} [محمّد: 21].

"Ko ba ma dara fun wọn o, ti wọn ba gba Ọlọhun ni ododo ni" [Muhammad: 21].

Ọlọhun tun pe awọn iroyin ati ẹyin ti o dara ni ododo:

قال الله تعالى: {وبشر الذين آمنوا أن لهم قدم صدق عند ربهم) [يونس: 2].

 قال ابن عباس (قدم صدق): منزل صدق بما قدموا من أعمالهم .

"Fun awọn ti wọn gbagbọ ni iro idunnu pe; dajudaju wọn ni atisiwaju ododo ni ọdọ Oluwa wọn" [Yunus: 2].

وقال تعالى: {وجعلنا لهم لسان صدق عليا} [مريم 50].

 فعن ابن عباس : الثناء الحسن.

"A si fun wọn ni ahan ododo ti o ga" [Maryam: 50]. Ibn 'Abbas (رضي الله عنهما) tumọ

rẹ si: ẹyin ti o dara.

وقال تعالى : {إن المتقين في جنات ونهر, في مقعد صدق} [القمر: 54-55]، أي: مجلس حق لا لغو فيه، ولا تأثيم وهو الجنة.

"Dajudaju awọn olubẹru yoo wa ni inu awọn ọgba Alijannah ati awọn odo, ni ibujoko ododo kan" [Al-Qamar: 54-55]. Ni aaye ti ko si ọrọ isọkusọ ni ibẹ, ohun naa ni Alijannah.

وقوله: {وقل رب أدخلني مدخل صدق وأخرجني مخرج صدق} [الإسراء: 80]، أي: اجعل مداخلي ومخارجي كلها في طاعتك، وعلى مرضاتك وذلك لتضمنها الإخلاص وموافقتها الأمر.

"Sọpe: Oluwa mi! mumi wọle ni ibuwọle ti ododo, ki O si mu jade ni ibujade ti ododo" [Al-Israa: 80]. Itumọ rẹ nipe: se gbogbo awọn ọna abawọle ati abajade mi ni ti itẹle ti Ẹ, ti yoo mu mi ri iyọnu Rẹ.

 

Awọn orisirisi ipin ti ododo pin si: ododo pin si orisi ti o po. Eleyi ni yoo jẹ ki o ye wa wipe asise ni ki a fi ododo mọ ni ori ọrọ sisọ nikan. Ododo wa ni ibi ọrọ sisọ, isẹ sise ati gbogbo isesi pata.

Ibn Al-Qoyim se alaye bayi pe: "Ẹni ti o mu ododo wa o gbọdọ wa ni inu ọrọ sisọ, isẹ sise ati gbogbo isesi rẹ pata.

Ododo ni ibi ọrọ ni ki ahan o se deede gẹgẹ bi ọmọ yangan se maa se deede ni ori suku.Ododo ni ibi isẹ, ni ki isẹ o se deede ni ori asẹ Ọlọhun ati itẹle Ojisẹ Rẹ, gẹgẹ bi ori se maa n duro le ara.Ododo ni gbogbo isesi ni ki awọn isẹ afi ọkan se ati afi ara se ki wọn duro lori itẹle asẹ Ọlọhun ati itẹle Ojisẹ Rẹ.

Bi eniyan ba se duro ni ori awọn koko wọnyi, bẹẹ gaan ni ijẹ olododo rẹ yoo se to. Eleyi naa si ni o fa ti Abu-bakr As-Sidiq fi bori, ti o si gba ipo olododo.

Nipa bayi, a ni lati sọ ọrọ sisọ wa, ki a si mase sọrọ abosi. Wo [An-Nur: 24].

{يوم تشهد عليهم ألسنتهم وأيديهم وأرجلهم بما كانوا يعملون} [النّور: 24].

Ki a si jẹki isẹwa ni ikọkọ ki o ba ita wa mu. Ni inu iroyin agba aafa kan ti o gbajumọ pẹlu: Al-hasan Al-basri nipe: ti o ba pasẹ kinikan ohun ni yoo kọkọ se, bẹẹ gẹlẹ ni ti o ba kọ sise kinikan, oun ni yoo kọkọ fi nkan naa silẹ, dajudaju ni inu awọn ti ikọkọ wọn ba ọkankan wọn mu ni aafa yi wa.

Aafa Mutarif naa sọpe: "ti ikọkọ eniyan ba ba ọkankan rẹ mu; Ọlọhun yoo wipe: dajudaju eleyi ni ẹru mi ni ododo".

Ipo ododo isesi ni o ga ju, gẹgẹ bi ododo ni ibi sise afọma, ibẹru, tituba, irankan, ifẹ ati bẹẹbẹ lọ. Idi niyi ti ododo fi jẹ ipilẹ fun gbogbo awọn isẹ ti a n fi ọkan se. [Al-Baqarah: 177].

{ولكن البر من آمن بالله واليوم الآخر والملائكة والكتاب والنبيين وآتى المال على حبه ذوي القربى واليتامى والمساكين وابن السبيل والسائلين وفي الرقاب وأقام الصلاة وآتى الزكاة والموفون بعهدهم إذا عاهدوا والصابرين في البأساء والضراء وحين البأس أولئك الذين صدقوا وأولئك هم المتقون} [البقرة: 177].

وقال تعالى : {إنما المؤمنون الذين آمنوا بالله ورسوله ثم لم يرتابوا وجاهدوا بأموالهم وأنفسهم في سبيل الله أولئك هم الصادقون} [الحجرات: 15].

 

Khutubah Ẹlẹẹkeji: (Isẹju mẹẹdogun)

الحمد لله ربّ العالَمين الذي أمر بالصّدق وأثاب عليه، ونهى عن الكذب ووعد الكاذبين بالعقاب، والصّلاة والسّلام على رسول الله الصّادق المصدوق الأمين، وآله وصحبه ومَن تبعهم بإحسانٍ إلى يوم الدين، وبعد؛

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun ni ododo! Isilaamu fun ẹtọ ati ododo ni ọwọ ati apọnle pupọ, ti O si yẹpẹrẹ irọ ati awọn opurọ. Ti O si pe irọ ni ọkan ni inu awọn ami munaafiki. Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sọpe: "awọn ami munafiki mẹta ni: ti o ba sọrọ irọ ni yoo jẹ, ti o ba se adehun ko ni mu un sẹ, ti wọn ba fi ọkan tan an yoo dalẹ".

Irọ, jamba ati ọdalẹ ko si ninu Isilaamu, ko si gbọdọ si ni inu iwa musulumi odododo.

Awọn isesi irọ ni inu isẹmi ọpọ awọn musulumi ni oni; ẹniti o ba wo isesi pipọ ninu awọn musulumi ni oni yoo ri aise deede ni abala ododo, nkan ti o se okunfa eleyi ni lilẹ igbagbọ ni ọkan ọpọlọpọ wọn, ti oniranran iwa ẹsẹ si gbilẹ ni aarin wọn, ti ifẹ aye si jẹ ọba ni ọkan awọn eniyan. Eyi mu ki ododo sapamọ ni inu ọrọ, isẹ ati isesi awọn eniyan. Ti Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) si sọpe: "Ibalẹ ọkan ni ododo jẹ, ti irọ si jẹ iruju".

Diẹ ninu awọn isesi irọ:

a.         Irọ awọn baba ati awọn iya ni ori awọn ọmọ wọn. Isilaamu kọwa ni ẹkọ bi ati gbọdọ tọ awọn ọmọ wa pẹlu ododo ti o jinna si irọ tefetefe. Ki wọn le dagba le ori ododo, igboya ati otitọ ni ibi ọrọ ati isẹ wọn. 'Adbullahi ibn 'Amir (رضي الله عنه) ti o jẹ ọkan ni  inu saabe Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) sọ wipe: "mọmọ mi pe mi ni ọjọkan ni igbati mo wa ni kekere, ni asiko ti Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) joko ni inu ile wa. Mọmọ mi wipe: wa, n o fun ọ ni nkan! Ni Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) ba bii pe: "kini nkan naa ti o fẹ fun un?" O dahun: dabidun ni. Ni Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) ba dahun pe: "sugbọn ti o ba jasipe iwọ ko fun un ni nkankan ni, wọn ko baa kọọ kalẹ pe ọ ti pa irọ". Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) tun sọ ni inu ẹgbawa Abu Hurairah pe: "Ẹnikẹni ti o ba sọ fun ọmọde pe wa, n o fun ọ ni nkan, ti ko wa fun un, onitọun ti pa irọ". Pẹlu ododo yi ni o yẹ ki a fi kọ awọn ọmọ wa.

b.         Gbigbilẹ ti irọ gbilẹ ni inu ọrọ awọn eniyan, ọkan ni inu awọn iya nla ẹsẹ si ni irọ.

{فنجعل لعنة الله على الكاذبين} [آل عمران: 61]. [Al-Quran: Aal-'Imran 61].

ففي الصحيحين: عن أنس بن مالك قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم : (ثلاث من كن فيه كان منافقاً إذا حدث كذب، وإذا وعد أخلف، وإذا أؤتمن خان).

Anas ibn Malik (رضي الله عنه) gba ẹgbawa wipe Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sọ pe: "awọn nkan mẹta kan wa, ẹnikẹni ti o ba bọ si inu wọn ti di munaafiki: ti o ba sọrọ yoo pa irọ, ti o ba se adehun ko nii muu sẹ, ti wọn ba fi ọkantan yoo jamba". [Sahihu Bukhari ati Musilimu].

c.         Gbigbilẹ yiyapa adehun laarin awọn eniyan, ti ohun naa si jẹ ọkan ni inu awọn iya nla ẹsẹ gẹgẹ bi o ti wa ni inu Hadith ti o siwaju. Asa aimu adehun sẹ gbilẹ debiwipe awọn olumu adehun sẹ jẹ onka ti o see ka.

Diẹ ni inu awọn apejuwe aitẹle adehun ni awujọ:

Pipẹ de si ibi ijoko lai ni idi. Tabi pipẹ tayọ asiko adehun, gẹgẹ bi ki adehun jẹ aago mẹjọ aarọ, ki o maa wa bọ ni aago mẹsan aarọ, ki o wa mu awijare wa pe: ohun ya ra awọn nkankan ni. Eyi ti o buru ju ni ki a ri iru awọn iwa yi ni ọwọ awọn ti a n rankan oore ni ati ọdọ wọn. Ni inu apejuwe eleyi ni ki baba o pẹ ki o too ra nkan ti o se adehun rẹ fun ọmọ rẹ. Ibn Mas'ud (رضي الله عنه) sọpe: "irọ kotọ ni igba kankan, kódà ni asiko ere tabi awada, bẹẹ ko tọ ki ẹnikan ninu yin se adehun nkan fun ọmọ rẹ ki o ma wa se fun un".

d.         Jijamba Amaanat ati riraa lare, ọpọ eniyan ni wọn kii se isẹ wọn bi o ti tọ ati bi o ti yẹ, bi ki o pẹ ki o to de ibi isẹ, mi maa fi isẹ se awẹwa, mi maa kaa iwe iroyin ni asiko isẹ, mi maa wo telifisan, mi maa sọrọ ti ko ba isẹ mu ni asiko isẹ ati bẹẹbẹẹ lọ lai ti pari isẹ. Bakanna ni mi maa gba isimi aisan, ti ko si si aarẹ tabi amodi, gbogbo eleyi ijamba amaanat ni o jẹ, ki a jinna sii ki owo ti a n gba le ni alubarikah.

e.         Sise èrú, ijamba ati magomago ni ibi tita ọja, bi fifi ojusilẹ pa alebu ti o wa ni ara ọja mọ laise alaye rẹ fun oluraja, eleyi a maa mu alubarika kuro ni ibi ọja. Hakim ibn Hizam (رضي الله عنه) gba ẹgbawa pe: Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sọ wipe: "Olutaja ati oluraja si ni ẹtọ ati sa ẹsa ni opin igba ti wọn si wa papọ ti wọn kotii tuka, ti wọn basi sọ ododo ti wọn se alaye ti o yẹ alubarika yoo wọ inu owo wọn, sugbọn ti wọn ba parọ, ti wọn si se abosi, alubarika yoo kuro ni inu owo naa". [Sahih Bukhari ati Musilimu].

f.          Ki ẹni ti kii se alaini maa beere fun iran lọwọ lati maa fi ko owo jọ. Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) si kọ eleyi fun musulumi ni inu hadith Abu Hurairajh (رضي الله عنه): "ẹnikẹni ti o ba bi awọn eniyan ni owo wọn ni itori ati ko owo jọ, dajudaju ogunna kan ni n beere, ko yara beere diẹ tabi pupọ".

g.         Pipa alebu ti o wa ni ara ọkọ tabi iyawo mọ, ati sise iroyin ati apọnpo ti o tayọ ala, gbogbo eleyi maa n mu alubarika kuro ni ibi igbeyawo ni.

Ninu awọn ti wọn gbajumọ pẹlu irọ ni awọn onisowo, awọn ontaja. Wọn a maa pa irọ fun awọn alabara wọn ki wọn le jẹ owo wọn ni ọna ti ko tọ. Wọn le paarọ owo, ọja tabi mejeeji, tabi ki wọn bura ni ori irọ, ki wọn pe ọja ni gidi ti wọn si mọ ni ọkan wọn wipe kiise gidi. Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) kiwa ni ilọ gidigidi ki a le jinna si awọn iwa wọn yi, ti o si se apejuwe wọn ni okunfa-iparun ni inu hadith 'Abdullahi ibn 'Amru (رضي الله عنه) wipe: "awọn iya nla ẹsẹ ni: ipa nkan pọ mọ Ọlọhun, sisẹ awọn obi mejeeji, pipa eniyan laini idi ati ibura irọ -Alyeminul-gamuus-". [Sahihu Bukhari].

Agba aafa Ibn Bata se alaye ibura irọ -Alyeminul-gaamus- wipe: "ohun ni ki eniyan bura lori nkana ti o si mọ ni ọkan ara rẹ wipe kori bẹẹ, ki o le fi yọ ẹnikan ni inu, tabi ki o jẹ owo kan ti ko tọ".

labara wọn. [Al-A'araf: 96, Al-Talaaq: 2-3].

{ولو أن أهل القرى آمنوا واتقوا لفتحنا عليهم بركات من السماء والأرض} [الأعراف: 96]. وقوله: {ومن يتق الله يجعل له مخرجا, ويرزقه من حيث لا يحتسب} [الطّلاق: 2-3].

Ni inu akiyesi tun ni ijẹri irọ eyi ti o wọpọ ni awujọ. Eewọ ni eleyi ni inu Isilaamu. [Al-Hajii: 30, Al-Baqarah: 283, Al-Maidah: 108].

{فاجتنبوا الرجس من الاوثان واجتنبوا قول الزور} [الحجّ: 30].

{ولا تكتموا الشهادة ومن يكتمها فإنه آثم قلبه والله بما تعملون عليم} [البقرة: 283].

 وقال: { ومن يكتمها فإنه آثم قلبه} قال السدي: يعني: فاجر قلبه.

وهذه كقوله تعالى: { ولا نكتم شهادة الله إنا إذا لمن الآثمين} [المائدة: 106].

Bakanaa ni Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) si kaa si inu awọn iya nla ẹsẹ ti o yara paniyan run.

Ni inu awọn anfaani ati ere ododo:

1-     Wiwọ Alijannah, Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sọwipe:

{هذا يوم ينفع الصادقين صدقهم لهم جنات تجري من تحتها الأنهار خالدين فيها أبدا رضي الله عنهم ورضوا عنه ذلك الفوز العظيم} [المائدة: 119].

"Ododo jẹ isẹ Alijannah". Ododo yoo si se olododo ni anfaani ni ọjọ ikẹyin. Wo suratul Al-Maidah: 119.

2-     Sise kongẹ gbogbo oore. Gẹgẹ bi Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ti wi fun Ka'b ibn Malik (رضي الله عنه) wipe: "Ka'b sọ ododo". Ka'b ibn Malik yi si jẹ ọkan lara awọn mẹta ti wọn ko pẹlu awọn saabe toku ba Annabi ja ogun Tabuk.

3-     Igbala ni ododo jẹ kuro ni ibi iparun, ifunpinpin ati ilekoko. Gẹgẹ bi Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ti wi ni inu hadith awọn mẹta ti apata pade mọ: "ko si nkankan ti o le la yin afi ododo, ki onikaluku yin tọrọ pẹlu nkan ti o mọ pe ododo ni".

4-     Ki ikọkọ eniyan dara.

5-     Ododo ni okunfa gbogbo oore aye ati ti ọrun.

6-     Ododo nii jogun ifayabalẹ fun eniyan.

7-     Fitina kii damu olododo.

8-     Ododo ni ipilẹ gbogbo oore ati daada, irọ sini ipilẹ gbogbo aburu.

9-     Iroyin munaafiki ko si fun olododo.

10-Ododo a maa jogun oye fun olododo.

11-Ẹnikẹni ti o ba sọ ododo ni inu awijare rẹ ẹri rẹ yoo rinlẹ.

12-Ododo nii jogun iroyin ti o dara fun olododo ni ati ọdọ awọn eniyan.

13-Ododo jẹ okunfa alubarika ni ibi ọja, isẹ-ọwọ ati bẹẹbẹ lọ.

 

اللهمّ طهّر قلوبنا من أوساخ الكذب، وارزقنا بالصّدق في القول والعمل، واجعلنا من الهداة المتّقين. وصلّى الله على نبيّنا محمّد وآله وصحبه وسلّم.