Eko ni soki

Aanu je okan ninu awon iroyin Olohun ti ola re ga ti o fi royin ara re, O si fi si okan ojise re, o si se ni aami ti o han ninu ofin re, eniti o ba ronu si awon idajo ofin esin patapata, yio ri aanu ni eleyi ti o nhan pelu gbogbo aworan ati awon itumo re nibe, eniti o baa ronu si isemi anabi Muhammad(Ki ike ati ola Olohun maa baa), yio ri aanu ti o duro borogidi ninu iwa re pelu itumo ti o han julo

Awọn erongba khutubah naa:                             

1.      Jijẹ ẹni ti yoo ma kẹ ẹniyan gẹgẹ bii ti Oluwa Ẹlẹda.

2.      Fifi ẹkọ gbigbe ara le ikẹ Ọlọhun kọ awọn eniyan.

3.      Jijina si ijakọn kuro ninu ikẹ Ọlọhun.

                                                    

 Oluwa ti ọla Rẹ ga jẹ Alaanu ati Olukẹni, RAHMAH jẹ ohun ti Oluwa nfi ba awa ẹda Rẹ lo ni gbogbo igba. Gbogbo ẹda Rẹ ni O maa nkẹ laye, ti yoo si sa awọn ti o ba gbagbọ

laye kẹ ni ọrun alikiyama.

Ninu ikẹ Ọlọhun ni a ti njẹ igbadun mukulumukẹnkẹ eyi ti a ko lese onka rẹ tan. Ọlọhun sọ pe:

قال الله: {ما يفتح الله للناس من رحمة فلا ممسك لها وما يمسك فلا مرسل له من بعده}.

“ikẹ ti Ọlọhun ba si fun ẹniyan ko si ẹniti o le daduro, ohun ti Ọlọhun ba si mu duro ko si ẹni ti o le tuu silẹ lẹhin Ọlọhun”suratu fatir:

Oluwa fẹ ki a jẹ olukẹ laarin ara wa, eleyi jẹ asẹ lati ọdọ Ọlọhun Adẹda Annabi Muhammad (r) sọ pe:

قال النبى صلى الله عليه و سلم وهو على المنبر: (ارحموا ترحموا واغفروا يغفر لكم ويل لأقماع القول ويل للمصرين الذين يصرون على ما فعلوا وهم يعلمون). رواه أحمد ورجاله ورواه الطبراني كذلك

“ẹ maa kẹ awọn eniyan ki ẹyin na le ri ikẹ, ẹ moju kuro fun awọn eniyan, ki ẹyin naa le ri aforijin, ibi dandan Ọlọhun ni fun awọn ti ntaku lori ohun ti wọn nse, ti awọn na si mọ bẹ” Ahmadu ati Tọbarani lo gbaa wa

Ẹni ti o ba nkẹ awọn eniyan, iru ẹni bẹ nbeere ikẹ aye ati ti ọrun lọdọ Ọlọhun Annabi Muhammad (r) sọ pe :

عن عبد الله بن عمرو رضى الله عنه مرفوعا: (الراحمون يرحمهم الرحمن تبارك وتعالى: ارحموا من في الأرض يرحمكم من في السماء). أخرجه أحمد وأبو داود والترمذي والحاكم

“Oluwa Ar-rahman ma nse ikẹ fun ẹni ti o nkẹ awọn eniyan, ẹ kẹ eniyan, ẹ kẹ awọn ti wọn wa lori ilẹ, ki Ọlọhun ti o wa ni sanma lee kẹ ẹyin na.

Ninu ikẹ Ọlọhun ni bi o ti se se ẹda ọmọniyan daradara ti o si se apọnle rẹ, ti o si npese jijẹ ati mimu fun un ni irọrun, Allah sọ bayi:

“ko si ẹda kan lori ilẹ ti Ọlọhun ko jẹ olupese fun.

Suratu Huud:70 Ninu ikẹ Ọlọhun ni wipe O rọ gbogbo ohun ti o wa ni sanmọn ati ilẹ patapata fun ọmọ eniyan ki o le ri anfani rẹ jẹ, bẹẹ naa ni o rọ oru, ọsan, oorun, osupa, irawọ ati bẹẹbẹẹ lọ fun ọmọniyan. Oluwa sọ wipe:

وقوله: {وسخر لكم ما في السماوات وما في الأرض جميعا منه...}

“O si rọ fun yin gbogbo ohun ti o wa ni Sanmọn ati Ilẹ patapata awọn ami arironu wa nibẹ fun awọn ti wọn nronu.” Suratun Jasiyah: 13

Ninu ikẹ Ọlọhun ni bi o se ran asiwaju awọn ojisẹ, Imaamu awọn olupaya Ọlọhun Muhammad bin Abdullah (r)

وقال : {وما أرسلناك إلا رحمة للعالمين}.

 “A ran iwọ Annabi Muhammad (r) si gbogbo aye lati jẹ ikẹ”. Suratul Anbiyai:107

وفى صحيح مسلم عن أبى موسى الأشعرى - رضى الله عنه - قال : قال رسول الله صلى الله عليه وسلم : (والذى نفسى بيده لا يسمع بى رجل من هذه الأمة يهودى ولا نصرانى ثم لا يؤمن بى إلا دخل النار )

Annabi Muhammad (r) sọ pe: “Mofi ẹni ti ẹmi mi wa lọwọ Rẹ bura, ko si ẹni ti o wa laye lasiko ti Ọlọhun gbe ohun Annabi dide Yahudi tabi Nọsara ti ko si gba oun gbọ iru ẹni naa yo wọ ina” Muslim lo gba Hadiisi na wa.

Ninu ikẹ Ọlọhun ti o pe julọ, ti o si jẹ akoja gbogbo nkan tan ti o fi ta wa lọrẹ, Oluwa sọ pe:

قال تعالى : {اليوم أكملت لكم دينكم وأتممت عليكم نعمتي ورضيت لكم الإسلام دينا}.

 “ni oni yi ni mo pe ẹsin yin fun yin, mo si pari idẹra mi leyin lori, mosi yọnu si Isilaamu fun yin ni ẹsin” Suratun Maidah:3.

Ninu ikẹ Ọlọhun naa ni ikẹ ti Annabi wa Muhammad (r) ti Ọlọhun fẹ ki a kọ ẹkọ ti o pọ nibẹ, ki awa naa le maa kẹ awọn eniyan ara rẹ ni.

(a)              Annabi Muhammad (r) jẹ onikẹ si awọn ọta rẹ; ni igba ti o lọ si Taif ti wọn si juu loko, ti wọn se ọrisirisi aburu fun un ti ẹsẹ rẹ mejeji alapọnle bẹrẹ si i se ẹjẹ, ni Ọlọhun ba ran Malaika oke sii, ti o si sọ fun Annabi Muhammad (r) pe:

                     

 

يقول له: ((إن شئت أن أطبق عليهم الأخشبين، فيقول عليه الصلاة والسلام: لا تفعل عسى الله أن يخرج من أصلابهم من يعبد الله)).

“ti iwọ ba fẹ ki n si oke mejeeji (Akhsabain) ti o tobi ju lẹgbẹ Mọka lu wọn; Annabi sọ wipe: ma se bẹẹ, Oluwa le mu jade lati ara wọn awọn ti yoo maa sin Ọlọhun Allah.

(b)       Annabi Muhammad (r) fi aanu han si Larubawa oko ti o tọ si Masalasi Annabi ni Madinah ti awọn eniyan si fẹ jẹẹ ni iya, sugbọn Annabi Muhammad (r) kọ fun wọn, o si jẹ ki o pari itọọrẹ, lẹhina ni wọn da omi si ori itọ naa. Annabi si sọ fun awọn Musulumi wipe:

وقال للأصحاب: ((إنما بعثتم ميسرين ولم تبعثوا معسرين، فيسروا ولا تعسروا وبشروا ولا تنفروا

وقال للأعرابي: ((إنما بنيت هذه المساجد لذكر الله وللصلاة))

“Ọlọhun se ẹyin ijọ mi ni onirọrun fun awọn ẹda, eyin kii se ẹni ti yoo maa ko inira ba awọn eniyan; tori naa ẹ se irọrun, ẹ ma se inira fun wọn ẹ se ẹdẹ fun awọn eniyan, ẹ ma le wọn kuro ninu  ẹsin. Annabi si sọ fun Larubawa naa pe: Mọsalasi jẹ aye iranti Ọlọhun ati irun kiki”

(c)       Aanu Annabi Muhammad (r)pẹlu awọn ti ẹkọ Isilaamu ko tii ye daradara; ẹnikan lọ ba Annabi o si fi eekanna rẹ mu ejika Annabi, o sipe wipe:

 يأتيه أحدهم فيقول: يا محمد، ويضع أظفاره في كتف النبي عليه الصلاة والسلام، ويلتفت إليه رسول الله مبتسما

“Irẹ Muhammad! Sugbọn Annabi siju woo lẹni ti o n rẹrin ọmimi. eleyi jẹ diẹ ninu awọn orisirisi iwa aanu eyi ti Annabi Muhammad (r) fi silẹ fun wa.

Annabi pe akiyesi awọn oludari Musulumi lati jẹ alaanu si awọn ti wọn njẹ olori le lori. Annabi sọ wipe:

ومن دعاء الرسول الله عليه الصلاة والسلام يقول: (اللهم من ولي من أمر أمتي شيئا فرفق بهم، فارفق به، اللهم من ولي من أمر أمتي شيئا فشق عليهم، فاشقق عليه) متفق عليه.

“Oluwa se irọrun fun ẹni ti o ba se irọrun fun awọn ijọ mi ninu awọn ti wọn yoo maa jẹ olori fun wọn, ẹni ti o ba si jẹ olori fun wọn ti o si n da wọn laamu; Oluwa o ko idamu ba iru ẹni bẹẹ”. Bukhari ati Muslimu lo gbaa wa.

Abubakre jẹ Khalifah Annabi Muhammad (r) bẹẹ na ni Umar na; awọn mejeji ati awọn asaaju daradara bii wọn jẹ alaanu fun awọn ti wọn nse olori le lori, wọn ko ọrọ awọn eniyan le ookan aya wọn; wọn si ka wọn kun pẹlu.

Aanu Isilaamu de ọdọ awọn ẹranko naa; ọpọlọpọ ọrọ Annabi Muhammad (r) da lori ki a jẹ alaanu fun awọn ẹranko, lara rẹ ni:

قول النبي عليه الصلاة والسلام: ((دخلت امرأة النار في هرة حبستها حتى ماتت، فلا هي أطعمتها ولا هي تركتها تأكل من خشاش الأرض)).

Obinrin kan jẹ ọmọ ina nitoripe o so olongbo mọ ilẹ titi ti o fi ku; eyi onjẹ ko fun un, ko si tuu silẹ ki o lọ salẹjẹ.

 

((لعن النبي عليه الصلاة والسلام من اتخذ شيئا فيه روح غرضا)).

Ibi dandan Ọlọhun ki o ma ba ẹni ti o ba nfi ohun ti o jẹ ẹlẹmi tọ ọwọ.

رى النبي عليه الصلاة والسلام رجلا وقد أبطح شاة تحت قدمه، وهو يحد شفرته، فقال عليه الصلاة والسلام: ((ويلك! أمتها موتتان، هلا حددت شفرتك قبل أن تضجعها للذبح)).

Annabi ri ọkunrin kan ti o gbe ẹsẹ si itan ẹran o si npọn ọbẹ; o wa sọ fun nu pe: ki lo se ẹ! iku meji lo fi n pa ẹran yii, ki lo de ti iwọ ko pọn ọbẹ rẹ siwaju ki o to da ẹran naa dubulẹ!

-           Bawo ni eniyan se le de ipo alaanu?

(a)       Ki ọmọniyan mọ pe ipo ti oun wa loni yii dajudaju oun yoo kuro nibẹ lọla, olowo le di alaini, ẹni ti o ni alaafia le di alaarẹ, abarapa le di abirun, igba ko tọ lọ bii orere.

يرى النبي عليه الصلاة والسلام أبا مسعود وهو يضرب غلاما له، فيقول له النبي عليه الصلاة والسلام: ((اتق من هو أقدر عليك، منك عليه)).

Annabi Muhammad (r) ri Baba Masu’d ti o nlu ọmọ kan o wa sọ fun un  wipe: Paya ẹni ti agbara rẹ ju eyi ti o ni lori ẹni ti o nna yii lọ.

(b)       Maa hu iwa aanu ni gbogbo igba. Annabi sọ fun ẹnikan ti o wa baa pe ọkan hun le pupọ: maa fi ọwọ pa ori ọmọ orukan, ki o si maa fun alaini ni onjẹ” ti eniyan ba nhu iru iwa bayi, yoo ni aanu loju.

(c)       Ki o maa ronu ẹsan ti o tobi ti Ọlọhun yoo san fun alaanu, ohun ti a ba se ni a o gba ẹsan rẹ, a kii gbin alubọsa ki o hu ẹfọ. Annabi sọ pe:

قول النبي عليه الصلاة والسلام: ((من نفس عن مؤمن كربة من كرب الدنيا نفس الله عنه كربة من كرب يوم القيامة)).

”ẹni yowu ti o ba gbe inira aye kan kuro fun Musulumi Oluwa yoo gbe inira kan kuro fun iru ẹni bẹẹ ni ọjọ Alikiyamọh.

-           Ọdọ ti o ba pọn agbalagba le, Ọlọhun yoo ran ẹni ti yoo pọn oun naa le si ni ọjọ Alikiyamọ Annabi Muhammad (r) sọ wipe:

 

                                             قول النبي عليه الصلاة والسلام: ((بروا آباءكم، تبركم أبناؤكم))، يرى الناس رجلا يضرب أباه في السوق، فيجتمع الناس يحولون بين الوالد والولد، فيقول لهم الوالد: دعوا ولدي يضربني، لقد كنت أضرب أبي في هذا الموضع، فسلط الله علي ولدي من بعده.

“ẹ se daradara si awọn baba yin, ọmọ yin naa yoo se daradara si yin. Awọn eniyan ri ọmọ kan ti o nlu baba rẹ ni arin ọja! Awọn eniyan pe jọ le wọn lori ti wọn si n la wọn. Sugbọn baba yi sọ wipe: ẹfi ọmọ yii silẹ ẹ jẹ ki o lu mi; ẹsan loke lemi lori! Tori pe emi naa ti lu baba mi ni aye yii ri!

 


 

Erongba Lori Khutuba naa:

·        Ipepe si kik r ti o m j.

·        Alaye lori sise pl nipa kiko ohun aye j ati kiko ara ni ni ijanu ninu aye.

·        Ikil kuro nibi fifi to lt dun un.

·        Ajul ti o wa fun ohun ti o j to lori ohun ti o j eew.

الحمد لله رب العالمين أمر بالأكل من الطيبات ونهى عن اقتراب الخبائث المضرة بالبدن فقال عزّ من قائل: {يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آَمَنُوا كُلُوا مِنْ طَيِّبَاتِ مَا رَزَقْنَاكُمْ وَاشْكُرُوا لِلَّهِ إِنْ كُنْتُمْ إِيَّاهُ تَعْبُدُونَ} وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له وأشهد أنّ محمّدا عبده ورسوله صلى الله عليه وعلى آله وصحبه أجمعين.

Ọpẹ fun Ọlọhun Ọba gbogbo ẹda ti o pasẹ jijẹ ninu ohun mimọ ti o si kọ gbogbo ohun ti ko mọ ati eyi ti o le pawa lara nigbati o n sọ ninu ọrọ Rẹ wipe: “Ẹyin Olugbagbọ ododo, ẹ jẹ ninu arisiki yin eyi ti o mọ, ki ẹ si maa dupe fun Ọlọhun ti o see fun yin to ba jẹ pe Oun ni ẹ n sin ni tootọ”. Mo n se afirinlẹ lati inu ọkan mi pe ko si ọba miran taa le maa sin lododo ayafi Ọlọhun, Ọba ti ko ni orogun ati wipe Anabi Muhammad ẹru Ọlọhun ni, ojise Rẹ si ni pẹlu. Ikẹ Ọlọhun ati ọla R ki o maa ba gbogbo wọn lapapọ”.

·        Ẹyin ẹrusin Oluwa, Oluwa ti kẹ wa ni ikẹ ti o gbooro. A ko sile ka onka ikẹ naa.

·        Se alaafia ni a fe s ni abi iriran abi igbr ti oluwa se fun wa ati bẹẹbẹẹ l.

·        Ninu ohun ti o tobi julọ ninu oore r ti o se fun wa ni oore “Isilaamu”

·        Tani ninu wa ti ko wu lati gbe igbesi aye ti o ni adun ati oyin ni aye ati orun? Nitoripe oluwa ti see ni tọ pe ki a ma j ohun ti o m ki a si jinna si ohun eewo ni jij.

·        Ẹyin rusin lhun, wiwa arisiki ati igbesi aye ti o rọrun jẹ ohunti ẹsin dasi.

·        Oluwa ti se san fun  wiwa ij ati imu. Oluwa si se fun mniyan nibẹ aaye ti o tẹ lati na iyẹ. Oluwa pa wn lasẹ pe ki wn rin kaakiri oril lati wa arisiki l.

·        Oluwa wipe : awn ti n wa ohun jijẹ ati mimu ko yat si ẹniti n jagun si oju na Oluwa.(Suratu Muzamil)

·        Annabi fun wa ni iro pe. Ẹnikan ko j ounjẹ kan ti o ni oore fun un ju ohun ti o fi w ara rẹ kojọ lọ. Nitoripe Annabi Da’wood ma n j ninu isẹ w rẹ. (Bukhari)

·        Nini ayo ọkan kuro nibi ohun ti Ọlọhun se fun awn eniyan se pataki nitoripe o ma n se apnle fun eniyan.

·        Khalifa Umar bn Khatab ni, iru aye ti o ma n wu ohun ni pe ki iku ka oun m ni aaye ti oun ti n wa ohun ti awn ẹbi oun yoo jẹ.

·        Ninu asọtẹlẹrẹ Lukman ọjọgbọn fun ọmọ rẹ ni pe, ki wọn maa jẹ ninu ohun ti o mọ. Oluwa ti pasẹ bẹẹ fun awn musulumi gẹgẹ bi o ti se pasẹ rẹ fun awn ojis Rẹ.

·        Oluwa ni:

يَا أَيُّهَا الرُّسُلُ كُلُوا مِنَ الطَّيِّبَاتِ وَاعْمَلُوا صَالِحًا إِنِّي بِمَا تَعْمَلُونَ عَلِيمٌ

"Ẹyin ojisẹ ẹ maa jẹ ninu ohun ti o mọ ki ẹ si maa se daadaa. Daju-daju

Emi ni imọ ohun gbogbo ti ẹ n se"

·        Oluwa ti ọla Rẹ ga tun wipe:

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آَمَنُوا كُلُوا مِنْ طَيِّبَاتِ مَا رَزَقْنَاكُمْ وَاشْكُرُوا لِلَّهِ إِنْ كُنْتُمْ إِيَّاهُ تَعْبُدُونَ

"Ẹyin onigbagbọ ododo ẹ maa jẹ ninu eyi ti o mọ ninu ohun ti a pa lese fun yin, ki ẹ si maa dupẹ fun Ọlọhun ti o ba jẹ pe Ọlọhun ni ẹ

 nsin "...Suratul-l-Bakorah.

·        Ninu ohun ti o jẹ pataki ninu ohun ti Annabi (صلى الله عليه وسلم) se alaye rẹ fun wa ni mimọ ohun ẹto yatọ si ohun eewọ.

Ti o ba di ọjọ ikẹyin, inu idunnu ni awon ti ma n se nkan ti o tọ yoo wa. Oluwa wipe:

الَّذِينَ تَتَوَفَّاهُمُ الْمَلَائِكَةُ طَيِّبِينَ يَقُولُونَ سَلَامٌ عَلَيْكُمُ ادْخُلُوا الْجَنَّةَ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ

"Awn ti o se pe bi awọn Malaika ba n gba ẹmi wọn ti wn jẹ ẹni mimọ, wọn yoo ma s pe; alafia ki o maa ba ẹyin, ẹ wọ ọgba idẹra naa nitori ohun ti ẹ ti se (nisẹ)... Suratul Nahli-32

Abdullaọh bn Amri s pe: Annabi wipe: ẹniti o ba ni iroyin mẹrin kan, konii bukata si nkankan miran mọ. Awọn nkan mẹrin naa ni: ki eniyan ni asiri tori ohun ti won fi sii lọwọ, ododo sisọ, iwa rere ati asajẹ.

·        Mimọ wa arisiki ti o mọ jẹ alamọri ti o se dandan nitoripe ẹru ko ni re kja ni iwaju Oluwa ni ọjọ ikẹyin afi ki o dahun awọn ibeere kan. Nibo ni o ti ri dukia r ati pe nibo ni o naa

·        Wn ni ọmọ ọdọ Abubakri gbe ounjẹ kan wa fun’un, ni igbati o n jẹ ounjẹ naa ni ọmọ ọdọ naa wipe: n jẹ o mọ ibi ti ounjẹ yii ti wa? Ọmọ ọdọ naa ni mo se adadigba fun eniyan kan ni igba aimọ, tohun ti bi o ti jẹ pe mi o mọ adadigbaa se, sugbọn mo kan taan lasan ni.  Eleyi ni o fa ti o fi fun mi ni ohun ti o n jẹ yii. Wọn ni Abubakr si ki ọwọ bọ ọna ọfun rẹ ti o si fi pọ gbogbo ohun ti o  jẹ...(Bukhari ni o gbaa wa)

·        Ninu ẹgbawa miran, Abubakr wipe: koda ti yoo ba jade plu mi mi, n o kọ lati se bẹẹ. Sibẹ-sibẹ Abubakri  tun bẹ Oluwa ki O fi ori jin oun latari eyi ti o ti ropọ mọ ifun ati inu oun ninu ounjẹ eewọ naa, ti ko see pọ jade! اللهم إني أعتذر إليك مما حملت العروق وخالطه الأمعاء

·        Umar  na mu wara kan lẹyinaa ni o beere lọwọ ẹniti o fun un pe, nibo ni o ti rii? Nigbati o se alaye ibi ti o ti rii, ti o jẹ ọna erú,  Umar naa ki ọwọ bọ ọna ofun rẹ ti o si fi pọ ohun ti o ti mu.

·        Awọn apakan awọn iyawo awọn ẹni daadaa ninu awọn ẹni rere ti o ti l, maa n s fun awọn ọkọ wọn pe: irẹ ọkọ wa paya Oluwa nibi ohun ti o maa fun wa ni ounjẹ nitoripe awa le fi ara da ebi sugbọn a ko le fi ara da iya ina.

·        Awọn ti a se alaye ọrọ wọn wọnyi ni awọn oluse daadaa nitoripẹ wọn ko fi ààyè gba Arãmu ninu ikun wọn.

·        Ẹyin ẹru Oluwa, ẹ mọ daju pe Arãmu jijẹ ni suta ati ewu ti o ni agbara lori ẹnikọọkan ati awujọ. Nitoripe yoo se okunfa pipadanu alubarika ni awujọ.

·        Egbé Ọlọhun ni fun gbogbo awọn ti wọn jẹ ninu awọn nkan eewọ bakannaa ti wọn si nre awọn ọmọ wọn pẹlu rẹ. Ọrọ wọn da gẹgẹ bii ẹniti n mu omi ni odo sib-sib ni oungbẹ ko si ye gbẹ ẹ.

·        Annabi sọ pe: ti o ba di akoko kan, ọmọniyan ko ni bikita nipa ohun ti o n jẹ boya ibi ẹto ni o ti wa abi lati ibi eewọ.

·        O di ọwọ gbogbo ọmọniyan lati ri daju pe ohun ti a n jẹ ati ohun ti a n mu jẹ nkan alaali.

·        Oluwa rọ wa ni ọrọ pẹlu ẹto kuro  ni`bi eewọ bakana ko jẹ ki a le maa tle asẹ Rẹ. Bakana ki Oluwa ma se aye ni opin oore wa.

·        Ninu awọn ohun ti eniyan fi le sa fun aye ni ki o kuro nibi awọn ohun ti Oluwa se ni eewọ.

·        Abu Huraira s pe: Annabi (صلى الله عليه وسلم) s pe: ẹniti dukia ẹnikan ba wa ni ọdọ rẹ tabi ijẹ mniyan rẹ, ki o yara gbiyanju lati se adapada rẹ ki o to di ọjọ ti ko ni si Diinọri abi Diriamu. Sugbọn ti o ba ni awọn isẹ rere, ibẹ ni wn yoo ti baa san  gbogbo gbese rẹ. Ti ko ba si ni isẹ rere wọn yoo mu ninu ẹsan isẹ buburu ti ẹni ti o jẹ ni gbese wọn a si dii kun ẹru ti onitọhun.

 

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ عَنِ النَّبِيِّ r قَالَ : "مَنْ كَانَتْ عِنْدَهُ مَظْلَمَةٌ مِنْ أَخِيهِ، مِنْ عِرْضِهِ أَوْ مَالِهِ، فَلْيَتَحَلَّلْهُ الْيَوْمَ قَبْلَ أَنْ يُؤْخَذَ حِينَ لا يَكُونُ دِينَارٌ وَلا دِرْهَمٌ، وَإِنْ كَانَ لَهُ عَمَلٌ صَالِحٌ أُخِذَ مِنْهُ بِقَدْرِ مَظْلَمَتِهِ، وَإِنْ لَمْ يَكُنْ لَهُ أُخِذَ مِنْ سَيِّئَاتِ صَاحِبِهِ، فَجُعِلَتْ عَلَيْهِ" أخرجه أحمد

Khutuba Ẹlkẹẹji (Isju Mẹẹdogun)

·        Ẹyin olugbagbọ ododo, ninu ohun ti musulumi gbọdọ jinna si kikundun aye ati ọsọ aye. Musulumi gbd mu aye bi aaye ti eniyan kan re kọja ni ibẹ.

·        Ẹniti o ba jẹ pe aye ni opin ohun ti o wa ninu ọkan rẹ, Oluwa yoo se ifunpinpin fun un ninu aye, bakannaa ko le ri ninu aye tayọ ohun ti Oluwa ba kọ fun-un.

·        Abu Huraira sọ wipe Annabi s pe: Ẹru owo ti sofo, ti wọn ba fun un, inu rẹ yoo dun amọ ti wọn ko ba fun un yoo binu.

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ : "تَعِسَ عَبْدُ الدِّينَارِ، وَعَبْدُ الدِّرْهَمِ، وَعَبْدُ الْخَمِيصَةِ، إِنْ أُعْطِيَ رَضِيَ، وَإِنْ لَمْ يُعْطَ سَخِطَ

·        Ninu awọn nkan ti o maa ntọka si pe eniyan ni ifẹ aye nipe ko nii bikita nipa ohun ti o n jẹ.

·        Eniyan a maa ji ni owurọ ti yoo si di keferi ki ilẹ to su.

·        Bakana eniyan le sun ni alẹ ti yoo si di keferi ki ilẹ to mọ.

·        Annabi s pe: Ẹ maa gbe ile aye, gẹgẹ bii arinrin ajo tabi ọmọ ori-irin.

·        Bakannaa ẹ mọ dajudaju pe ohun ti ẹda yoo jẹ tabi ni ni dukia ni ile aye, yoo tẹẹ lọwọ ki o to fi aye silẹ.

·        Ẹ paya Oluwa yin ki ẹ si mọ pe ẹ o pade Rẹ ni ọjọ kan.

·        Ki ẹ si mọ pe ara ohun ti o maa nfa ibinu Oluwa lori ẹru kan ni Haramu jijẹ.

Ẹniti n jẹ Haramu yoo ma jina si Ọlọhun diẹ diẹ diẹ. Oluwa ni: Oun  yoo pa owo riba run َمْحَقُ اللَّهُ الرِّبَا وَيُرْبِي الصَّدَقَاتِ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ كَفَّارٍ أَثِيم [البقرة : 276]

                                

·        Ẹ jẹ ki a maa wa ohun halaali nitoripe Oluwa yoo fi alubarika sii, bakannaa yoo gba sọdakọ ti a ba se ninu owo wa.

·        Ninu ohun ti o ma n si ilẹkun ikẹ Ọlọhun ni ìpayà Ọlọhun wa.

·        Oluwa ni:

وَلَوْ أَنَّ أَهْلَ الْقُرَى آَمَنُوا وَاتَّقَوْا لَفَتَحْنَا عَلَيْهِمْ بَرَكَاتٍ مِنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ

"Bi o ba se pe awọn ara ilu naa ba gba Ọlọhun gbọ ti wọn si bẹru Rẹ, Awa

(Oluwa) i ba si ilẹkun alubarika fun wọn lati sanmọ ati ilẹ...Suratu Al-

Araf-66

·        Ohun ti o tun le fa ki ikẹ Ọlọhun maa sọ kalẹ fun eniyan ni pe ki o maa se adura ati ki o si fi ọkan rẹ si ọdọ Ọlọhun.

·        Ti eniyan ba ti tẹ le awn ofin Oluwa, Oluwa yoo se ikẹ Rẹ fun un ju bi o se ni ero lọ.

Ki Oluwa se halaali ni irọrun fun wa ki o si se eewọ ni inira fun enikọọkan wa. Bakana ki o si se wa ni ọmọ Alujannah.

 

 

فاشكروا الله على نعمه أن رزقكم من الطيّبات وأدّوا شكرها واستعملوها فى الطّاعة يغدق عليكم من واسع فضله. وصلّوا على رسول رب العالمين فقد أمر الله بذلك فى كتابه المبين قال تعالى: "إن الله وملائكته يصلّون على النّبي يا أيّها الذين آمنوا صلّوا عليه وسلّموا تسليما". اللهم صلّ وسلّم على عبدك ورسولك محمد بن عبد الله وارض اللهم عن الخلفاء الرّاشدين أبى بكر وعمر وعثمان وعلي وعن سائر أصحا نبينا محمد وعنّا معهم بمنّك وكرمك يا أرحم الرّاحمين. اللهم أعزّ الإسلام والمسلمين وأذلّ الشّرك والمشركين ودمّر أعداءك أعداء الدّين، اللهم آمنّا فى أوطاننا وسائر بلاد المسلمين. "إنّ الله يأمر بالعدل والإحسان وإيتاء ذي القربى وينهى عن الفحشاء والمنكر والبغي يعظكم لعلكم تذكّرون".

  

            Nitorinaa, ẹyin ẹrusin Ọlọhun, Ẹ dupe fun Ọlọhun lori awọn Idẹra Rẹ, Ọba to n pese ohun to dara fun yin ni jijẹ ati mimu, ki ẹ si maa loo lati fi tẹ le asẹ Ọlọhun, ki o le se ọpọ ikẹ miran fun yin. Bẹẹni ki ẹ maa tọrọ ikẹ ati igẹ fun Anabi Muhammad ni ibamu si asẹ Ọlọhun to sọ pe: « Dajudaju Ọlọhun ati awọn Malaika Rẹ n fi ibukun fun Anabi, ẹyin ti ẹ gbagbo ni ododo, ẹ maa tọrọ ibukun fun un, ki ẹ si kii ni kiki alaafia ». ki Ọlọhun bani sekẹ segẹ Rẹ fun ẹru Rẹ ati ojisẹ Rẹ Muhammad ọmọ Abdullahi, bẹẹni ki o bawa yọnu si awọn arole rẹ ti wọn jẹ afinimona : Abu bakr, Umaru, Usmanu, ati Aliyyu tofi kari awọn Sahabe re to seku, ki O ma yọ awa naa silẹ ninu ikẹ naa. Ọlọhun gbe asọ agbara wọ awa Musulumi ati Isilaamu lọrun. Bẹẹni ki o bawa run awọn ọta Rẹ ti wọn jẹ ọta ẹsin, Ọlọhun jogun ifọkanbale fun wa lorilẹ-ede yii ati awọn ile Isilaamu lapapo. Dajudaju Ọlọhun pawa lasẹ ẹtọ sise ati sise rere ati ki a maa fun awọn ẹbi (ni ẹtọ wọn), O si n kọ fun ni iwa ibajẹ ati iwa buburu ati rukerudo, O n se ikilọ fun un yin ki e le baa gba ikilọ naa ati ki ẹ maa mu adehun Ọlọhun sẹ nigbati ẹnyin ba se e, ati ki ẹ ma si tu ara bubu yin palẹ lẹhin igba ti e ti se e, bẹẹ si ni ẹ ti se Ọlọhun ni ẹlẹri le ara yin lori. Dajudaju Ọlọhun Mọ ohun ti ẹ ba n se ni isẹ ».