Eko ni soki

Esin Islam se wa lojukokoro lori sise awon okun ife laarin awa musulumi ni eyiti yio ni agbara, ati siso okun ije omo iya di eleyiti yio nipon, O wa pepe losi ibi gbogbo ohun ti yio se ikunlowo fun ife yii, gegebii imaa fon salamo kaa, ati iba ara eni bowo nigbati a ba pade, ati bee bee lo, Islam si lewasa kuro nibi gbogbo ohun ti yio so ife yii ti ohun ti yio le, gegebii imaa da aba aburu sini laarin awa musulumi, ati oro eyin siso, ati ofoofo, ati bee bee lo, dajudaju, aba aburu dida je eleyiti o ni agbara julo ninu ategun fifon ota sise ati ikorira ati ijaa okun ajosepo ati pipin ebi yeleyele ati ipa ije omo iya esin run, lati ara bee, E ya maa da aba daadaa si awon omo iya yin.

Erongba Lori Khutuba

·                    Iwosan kuro nibi iwa aburu yii.

·                    Titọ niyan bi a ti n ni ọkan ti o ni alaafia (ti ko nii maa ro irokuro si ẹnikẹni).

·                    Bi ijẹ ọmọ iya ẹsin yoo se duro tọ. 

الحمد لله رب العالمين حرم أذية المسلمين والتعدى على حرماتهم وتوعد من فعل ذلك بأشدّ الوعيد، أحمده عل نعمه وقد وعد الشاّكر بالمزيد، وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له وأشهد أن محمدا عبده ورسوله والقائل: "إيّاكم والظن فإنّ الظنّ أكذب الحديث". صلى الله عليه وعلى آله وأصحابه وسلم تسليما كثيرا.

                        A dup fun lhun, ba ti o se sise Musulumi ni suta ati ikja aala le lori leew, to si leri leka iya to lagbara fun ni ti o ba kọti ọgbọin si as yii, A n dup lori ọpọlp idra R lori wa, ki o le salekun r fun wa, A si n jri ajdẹkan pe ko si lomiran ti o ltọ si ijsin lododo lyin “Allah” , ba ti ko ni orogun ati pe “Annọbi Muhammad”  r ru R ni, ojis R si ni, ni ti o s ninu r r pe: “:Ẹ sra fun ero buruku erokero nitoripe erokero iro n la ni”. Ikẹ Ọlhun, , Ola lhun, ki o maa baa, ati gbogbo awn ara ile  r ati gbogbo awn alabarin rẹ ni yanturu.        

 

O ti di dandan lori gbogbo musulumi lati jẹ ki ajọ-sepọ ti o wa laarin awa ati awọn ọmọ iya wa yoku ti o jẹ musulimi mu ina doko

 

Ninu ibalopọ ti o yanranti ni ki a jẹ ki ẹmi ati ọkan wa mọ si ara wa lai sẹku nkankan ninu wa ti ko dara si ọmọ nikeji wa.

Ki a se ọkan wa daada si ọmọnikeji wa nipa erongba wa sii, jẹ nkan pataki ninu ẹsin Isilaamu.

Ki oju wa ma yatọ si ọkan wa. Ki a tu ọkan ka si ọmọ- nikeji gẹgẹ bi a ti se n tujuka sii.

Ki a ma korira eniyan ẹgbẹ wa tabi fi oju yẹpẹrẹ rẹ tabi isẹ ti o ba n se, ni iwọn igba ti ko ba ti se ohun ti Ọlọhun ati Annabi rẹ kọ fun wa.

Ki a mojuto okun ti o sowa papọ ki o ma baa ja. Nitoripe ọpọlọpọ igba ni

o ma ri ti awn eniyan yoo maa wipe lagbaja sọ bayi, tamodo gbero nkan bayi. Bi a ko ba ni erongba daada si ara wa awọn nkan wonyii ni wọn yoo ge okun ti o sowa papọ, yoo si da isoro ati wahala sil lawujọ.

plop awn awujọ ti o fọ loni j esi erongba ti o buru ti  wọn n ro si arawọn. Nini ni ero buburu si ẹnikeji ẹni, maa n fa ikorira. Bakannaa kii jẹ ki a le fi ọkan balẹ le ara ẹni lori.

Nini ero buburu si ara ẹni yoo se okunfa ki agbara-wa ati isọkan-wa lọ, ti a ko si ni le bori ogun lailai. Oluwa ni:

وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَلَا تَنَازَعُوا فَتَفْشَلُوا وَتَذْهَبَ رِيحُكُمْ وَاصْبِرُوا إِنَّ اللَّهَ مَعَ الصَّابِرِين

 Ẹ tẹle Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ, ẹ ma se ariyanjiyan, ki ẹ ma baa  kọlẹ tabi se ojo, ki agbara yin o ma baa lọ. Atiwipe ki ẹni agbamọra (suuru), dajudaju Ọlọhun nbẹ pẹlu awọn oni-suuru.

Ero buruku ko ni mu oriire wa ayafi ikorira, ọta sise ati fifọnka yẹlẹyẹlẹ, bakannaa yoo se okunfa ki ijẹ ọmọ-iya ẹsin di ohun igbagbe.

Ẹwẹ ero buruku yoo sọ olowo rẹ sinu ẹsẹ miran bẹẹ ni  yoo wa ninu awọn ti wọn yoo kabamọ ti o ba di ọjọ ẹsan.

Iwa buruku yoo jẹ ki ẹni ti wọn hu u  si gba okun ni ọdọ Oluwa. Eleyi ni yoo se okunfa Alujanna fun  wọn ti awọn ti wọn n fi wọn se yẹyẹ yoo si pada di ọmọ-ina. Oluwa wipe:

 

{إِنَّ الَّذِينَ أَجْرَمُوا كَانُوا مِنَ الَّذِينَ آَمَنُوا يَضْحَكُونَ (29) وَإِذَا مَرُّوا بِهِمْ يَتَغَامَزُون}.

"Dajudaju awon ẹniti wọn n dẹsẹ, wọn tun nbẹ ninu awọn ti nfi awọn onigbagbọ rẹrin. Nigbati nwọn ba nkọja lọ lara wọn, wọn o ma sẹju si ara wọn (wọn o maa fi ọwọ tọ ara wọn)…Suratu Mutọfifina-83

Oluwa tun sọ pe:

فَالْيَوْمَ الَّذِينَ آمَنُوا مِنَ الْكُفَّارِ يَضْحَكُون [المطففين : 34]

"Sugbọn loni awọn onigbagbọ ododo ni nwọn o maa fi awọn alaigbagbọ rẹrin".

 

Oluwa sọ ninu Suratul Bakọrah pe:

زُيِّنَ لِلَّذِينَ كَفَرُوا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا وَيَسْخَرُونَ مِنَ الَّذِينَ آمَنُوا وَالَّذِينَ اتَّقَوْا فَوْقَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَاللَّهُ يَرْزُقُ مَنْ يَشَاءُ بِغَيْرِ حِسَاب [البقرة : 212]

 

 "A se ile aiye ni ohun ti yoo ma a jọ awọn ti ko gbagbọ l’oju, (nipa bayi) awọn a ma fi awọn onigbagbọ se ẹfẹ. Sugbọn awọn ti wọn bẹru Ọlọhun, yio juwọn lọ (nipa ikẹ  Ọlọhun) ni ọjọ ikẹhin  Ọlọhun A maa se arisiki fun ẹni ti O ba fẹ lai ni osun-wọn.

 

·                    Oluwa tun ni:

{يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آَمَنُوا اجْتَنِبُوا كَثِيرًا مِنَ الظَّنِّ إِنَّ بَعْضَ الظَّنِّ إِثْمٌ وَلَا تَجَسَّسُوا وَلَا يَغْتَبْ بَعْضُكُمْ بَعْضًا أَيُحِبُّ أَحَدُكُمْ أَنْ يَأْكُلَ لَحْمَ أَخِيهِ مَيْتًا فَكَرِهْتُمُوهُ وَاتَّقُوا اللَّهَ إِنَّ اللَّهَ تَوَّابٌ رَحِيم}.

"Ẹyin ti ẹ gbagbọ ni ododo, ẹ jinna si ọpọlọpọ erokero, dajudaju apakan erokero (abadida) jẹ ẹsẹ. Ki ẹ si ma se maa fi imu finlẹ wadi laifi araayin, ki ẹ si ma se maa sọ ọrọ araa yin lẹhin pẹlu. Njẹ o ha le wu ẹnikan ninu yin ki o maa jẹ ẹran ara ọmọ iya rẹ ti o ti ku bi? Ẹyin korira lati se bẹẹ. Atipe ki ẹ bẹru Ọlohun, Daju-daju Ọlohun naa jẹ Olugba ironupiwada lọpọlọpọ Alaanu julọ".

Awọn aaya yii n tọka si fun wa pe ki a maa sọ orukọ musulumi kuro nibi ibajẹ ki a si maa se iwadi ohun gbogbo siwaju ki a to le sọ pe lagbaja ni o sọ pe.

Itaniji ni eyi jẹ fun gbogbo muslumi, torinaa   ki a gbe ju silẹ ohun ti o ba le se akoba fun enikan nipa èrò buruku.

·                    Anaabi (صلى الله عليه وسلم) sọ ninu Hadiisi . Abu Hurairah sọ pe: ẹ sọra fun abadida (mo ro pe lagbaja se nkan bayi …ati bẹẹ bẹẹ lọ), nitoripe abadida jẹ ọga fun irọ.

·                    Ofin pawa lasẹ pe ki a jinna si gbogbo ohun ti o ba sokunkun siwa ti a ko ni imọ nipa rẹ lati ma sọ.

·                    Ẹni apọnle ni ẹni ti o pa ọkan lofo kuro nibi riro erokero si muslumi ẹgbẹ rẹ.

·                    Ninu eroburuku ni gbigbe ọrọ ẹlomiran lati aayekan si ekeji ni aniyan lati ba ẹnikeji jẹ lai-si ẹri ti o fẹsẹ mulẹ lori ẹsun ti a fi kan ẹni naa.

·                    Ninu ẹkọ ẹsin nipe ki a maa sọ nipa eniyan kan ayaafi ohun ti a ba mọ nipa rẹ.

·                    Ummar (ki Ọlohun yọnu si) sọ ninu Hadiisi Utba bun Mos’ood pe: waayi ni o maa n se ofofo awọn eniyan ni igba aiye Annabi, sugbọn  ni iwọn ìgbà ti ko ti si mọ,  ki a  maa se idajọ lori ohun ti o ba han siwa loku. Ẹniti o ba fi daada han siwa a  o fi ọkan tan-an, a o ni bukata si kọkọ rẹ. oluwa yoo se idajọ kọkọ rẹ,

·                    Musulumi si gbọdọ se akiyesi iru gbolohun ti yoo ba maa fi ẹnu rẹ sọ nitoripe Oluwa wipe:

وَلَا تَقْفُ مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ إِنَّ السَّمْعَ وَالْبَصَرَ وَالْفُؤَادَ كُلُّ أُولَئِكَ كَانَ عَنْهُ مَسْئُولًا

« Iwọ ma se sọ ohun ti o ko ba ni imọ nipa rẹ, nitoripe igbọran, iriran ati ọkan ni A o beere nipa wọn ».

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, awọn ohun ti o maa n fa ki eniyan  maa  ro ero buruku, pọ ninu rẹ ni ; kojẹpe eniyan jẹ eeyan’buru, tabi ki o wulẹ ni ẹmi buruku.

·                    Ti eniyan ba ti n te le ifẹ-inu rẹ ko si bi ko se   nii  maa ro eroburuku, nitori ẹmi ko ni asẹ kan ti n paa, ju asẹ buruku lọ. Nitorinaa eniyan gbọdọ jinna si ifẹ-inu.

·                    Bi eniyan ba korira alasunmọ rẹ kan, ko si ọgbon, ero buruku ni yoo maa ro si irufẹ ẹni bẹẹ.

·                    Ohun ti o tun ma n fa eroburuku ni ki ẹnikan ri ara rẹ lori ododo ki o si ri awọn yoku ni opurọ tabi ki o ma ni ero pe oun daa ju awọn ara yoku lọ.

·                    Mimọọ  gbero buruku nipa musulumi ti di ohun ti o kari ni akoko ti a wa yii. Eleyi yoo si pada se okunfa wahala ti o tobi ni awujọ ẹsin.

Oluwa sọ wipe:

وَالَّذِينَ يُؤْذُونَ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ بِغَيْرِ مَا اكْتَسَبُوا فَقَدِ احْتَمَلُوا بُهْتَانًا وَإِثْمًا مُبِينًا [الأحزاب : 58]

"Awọn ẹni ti nko inira ba awọn olugbagbọ lọkunrin ati obirin (pẹlu ọrọ tabi iwa) lori ohun ti wọn ko se, wọn ti pa irọ (nla) wọn si da ẹsẹ ti o foju han gbangba".

Ki a lọ mọ pe, eroburuku jẹ okunfa iparun atipe a gbọdọ se itọju ẹmi wa kuro ni bi aisan yii, ki a le ẹmi araawa kuro nibi iparun.

Awọn ọna ti a fi le tọju ẹmi ara wa ni pe ki a maa gbiyanju lati maa ro daradara si araawa ki a si jinna si mimaa sọ kọkọ onikọkọ.

Bẹẹni ki a dunnimọ awon kọ sin daadaa.

فاتقوا الله  - عباد الله – واجتنبوا إساء الظن بإخوانكم المسلمين وتفطّنوا أن هذا من مكائد الشيطان اللعين ثم اعلموا أن الله سبحانه أمرني وإيّاكم بأمر بدأ به بنفسه الكريمة وملائكته الكرام. قال عزّىمن قائل: {إن الله وملائكته يصلون على النبي يأيها الذين آمنوا صلّوا عليه وسلّموا تسليما}

اللهم صل وسلم على عبدك ونبيك محمد بن عبد الله وارض اللهم عن الخلفاء الراشدين أبي بكر وعمر وعثمان وعلي وعن سائر أصحابه وعنا معهم برحمتك يا أرحم الراحمين. اللهم أعزّ الاسلام.

 

Ẹ bru Ọlọhun –yin rusin Ọlọhun - Ẹ jinna si erokero si awn m iya yin Musulumi, ki si lọọ m pe erokero ninu ète esu ni, atipe Ọlọhun kọọ fun wa.

Ẹ lọọ m pe dajudaju Ọlọhun pawa lase sise Asalatu fun Annabi r

eyi ti o bẹrẹ lati ori ara r ati awn Malaika R,

Ọlọhun bawa se ik se ig fun Ojisẹ nla Anabi Muhammad, ki o si bani ynu si awn arole r latori Abu bakr, Umar, Usman, Ali ati gbogbo awn Sahabe latoke del ati gbogbo awa olutle- wn di j igbende Alukiyaomo. Ọlọhun bani ro Isilaamu lagbara.