Diẹ Ninu awọn Oripa Ẹsẹ Dida Ni Igbesi Aye Ọmọniyan

Eko ni soki

Kosi bi omoniyan ti fe wa laye ti ko ni dese sugbon Olohun Oba ti ola re ga fe ki a maa tuuba ni gbogbo igba ti a ba dese, beeni O so funwa wipe Oun nife gbogbo eru ti o ba maa nronupiwada ti o ntuuba ese beeni, ko too fun eniyan lati maa fi tuuba lora nitoriwipe a ko mo igba ti titan yio de.

Awọn erongba khutuba

-        Sisẹri pada lọ ọdọ Ọdọ Ọlọhun

-        Rire awọn eniyan lori bi wọn yoo se se atunse aarin wọn ati Ọlọhun

-        Jijinna si ìjákàn ninu ikẹ Ọlọhun

          Akoko Khutuba mejeeji: Isẹju marundinlogoji

          Khutuba Alakọkọ – Ogun Isẹju

الحمد لله القائل في كتابه المبين  : "وتوبوا إلى الله جميعا أيها المؤمنون لعلكم تفلحون" (النور 31) أحمده إذ فتح لعباده باب  التوبة . ودعاهم إليها , ووعدهم أن يتقبلها  منهم ويمحو بها  سيئاتهم . واشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له  ولا نعبد إلا إيّاه . وأشهد أن محمدا عبده ورسوله  صلّ الله عليه وأصحابه وبعد/

         Ọpẹ ni fun Ọlọhun to sọ ninu tira Rẹ pe: “Nitorinaa, ẹ ronupiwada lọ si ọdọ Ọlọhun, gbogbo nyin patapata, ẹyin onigbagbọ ododo ki ẹ le baa la. (Suratul Nuru 31).” Mo jẹri pe ko si ẹniti isin ododo yẹ, ayafi Ọlọhun nikan ti ko ni orogun, bẹẹni mo si jẹri pe Annọbi wa Muhammadu ẹrusin Ọlọhun ni Ojisẹ Rẹ si ni, ki Ọlọhun bawa kẹ Annọbi, awọn ara ile rẹ, awọn sahabe rẹ ati gbogbo ẹlẹsin isilaamu titi ọjọ ikẹyin.

Ẹyin musulumi ẹ lọọmọ pe isẹ ọmọniyan laye yii ni ki o jọsin fun Ọlọhun, sebi tori ijosin naa ni Ọlọhun fi daa ti o ba se rere o see fun ẹmi ara rẹ ni, bi o ba si se aida, oun naa ni yoo da iya rẹ jẹ, se ẹluluu to pe ojo ni ori rẹ ni yoo da le, “Ẹni da éérú ni éérúú tọ”. Ẹsẹ Ko ni ipalara Kankan ti yoo ko ba Ọlọhun, bẹni rere ẹda ko le se Ọlọhun ni anfani kankan.

         Eeri ni ẹsẹ gẹgẹ bi Ojisẹ Ọlọhun ti sọ: sugbọn kii se idọti ti a le fi oju ri, tabi ti a le gboorun rẹ, sugbọn oripa ẹsẹ yoo maa han lọkan, bẹni yoo maa boo titi ti ọkan yoo fi dudu, wo suratu Mutọffifina: 14 Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Bi eniyan ba da ẹsẹ, ẹsẹ naa yoo di oripa dudu sinu ọkan rẹ, bi o ba tuba, wọn yoo ba si kuro lọkan rẹ, sugbọn ti o ba lekun lẹsẹ, oripa dudu naa yoo fẹ sii”.

Ọgọrọ eniyan lo ntọju asọ sugbọn to fi ọkan rẹ si pẹlu eeri ẹsẹ  toti dudu ọkan naa, lalai ranti tuuba kuro nibi ẹsẹ, lotitọ gbogbo eniyan ni ẹlẹsẹ sugbọn kii se gbogbo wọn ni wọn nranti tọrọ aforijin ẹsẹ lọdọ Ọlọhun bẹni Ọlọhun si nrọwa pe ki a tuba, Oun yoo forijinwa . Wo suratu Sumar : 53.

Ninu awọn orukọ Ọlọrun Ni gafuuru (oba to nfi ori ẹsẹ jinni) ati A-ttawabu (oba to ngba tituuba ẹda). Wo suratul Kosọsi, 16 ati suratu Tahrimu; 8 ati Suratu AI-imran: 135. Ojisẹ Ọlọrun sọ pe: dajudaju Ọlọrun maa ntẹ ọwọ rẹ silẹ lọsan ki ẹniti o sẹ ẹ loru le tuuba, ko ni ye bẹẹ se titi ti oorun yoo fi yọ, ni ibuwọ rẹe” Ọlọrun yoo fori ẹsẹ jin ẹniti o nigbagbọ si orukọ rẹ tin njẹ Al-gafuur, bẹni yoo si gba tutuba rẹ, pẹlu majẹmu fifi ara gbolẹ, titọrọ idarijin ẹsẹ lọdọ Rẹ lalaini jakan muna nibi ikẹ rẹ.

          O jẹ dandan fun eniyan lati tete tuba lọ si Ọlọrun kuro nibi gbogbo ẹsẹ atipe lilọọ lara jẹ apẹrẹ ori buruku ati iyẹpẹrẹ wo suratu Nuru; 31 ati   suratu Tahrimi :8 ati awọn aya miran to n tọkasi wipe dandan ni titara tuba nibi gbogbo ẹsẹ.

"وَتُوبُوا إِلَى اللَّهِ جَمِيعًا أَيُّهَا الْمُؤْمِنُونَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ".

 Abu Urọera sọ pe mo gbọ lẹnu Ojisẹ Ọlọrun to nsọ pe: "Mofi Ọlọrun bura pe dajudaju emi maa ntọrọ aforiji lọdọ Ọlọrun mo si maa ntuba lọ sọdọ rẹ nigba to le ni aadọrin lojumo - buhari

          Aliagaru ọmọ Yasaru sọ pe, Ojisẹ Ọlọrun (S.A.W) sọ pe ẹyin eniyan ẹ maa tuba lọ si ọdọ Ọlọrun, ẹ si maa tọrọ aforijin Rẹ, toripe dajudaju emi paapaa maa ntuba ọgọrun lojumọ. Musilimu

          Awọn onimimo sọ pe: "bi eniyan ba tuba kuro ninu awọn ẹsẹ kan, tituba rẹ yoo jẹ itẹwọgba, sugbọn ẹsẹ yoku yoo wa ni ọrun rẹ titi ti yoo fi tuba".

          Tituba Ni: sisẹri kuro nibi ẹsẹ lọ si bi titẹle asẹ Ọlọhun lalaini pada sibi ẹsẹ naa mọ. Majẹmu mẹta lo si mbẹ fun un:

1.      Jijawọ kuro nibi ẹsẹ, kódà ki o ti gbe ẹsẹ wọ bi asọ

2.      Kikabamọ lori dida ẹsẹ naa

3.      Ki o si pinnu pe oun ko ni debi ẹsẹ mo lailai

4.      Dida ẹtọ pada fun ẹniti o nii.

            Ki tituuba nibi ẹsẹ le pe Olútúùba nibi ẹsẹ gbọdọ fi Ara rẹ silẹ fun ijiya to ba yẹ. Ọpọlọpọ Olutuuba ni yoo lero pe oun ti tuba kuro nibi ẹsẹ, sugbọn ti ko jawọ nibi ẹsẹ naa, pelu bẹẹ naa yoo maa rankan ikẹ ati aanu Ọlọhun, ti ko si ni bẹru ìyà Ọlọhun, iru awọn ẹda wọnyi ni wọn ti fẹmi balẹ si ete Ọlọhun, Ọlọhun sọ pe: “Njẹ nwọn le fi ayabalẹ si ete Ọlọhun bi? Nitorinaa, ẹnikan ko ni fi ayabalẹ si ete Ọlọhun ayafi awọn Olófo”. Suratul Arọf: 99.

"وَتُوبُوا إِلَى اللَّهِ جَمِيعًا أَيُّهَا الْمُؤْمِنُونَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ".

          Afa ibnu Kesiri sọ pe: Ete Ọlọhun ni iya, agbara ati ifi ọwọ iya gbanimun sikun ni asiko ti eniyan ti gbagbara.

          Afa wa Asani sọ pe: “Mumuni yoo maa sisẹ, yoo maa tẹle asẹ Ọlọhun pẹlu bẹẹ naa ẹmi rẹ ko ni balẹ”.

          Ọmọ Afa wa Arrobiu bun At’am sọ fun baba rẹ pe: kinni o sẹlẹ ti gbogbo eniyan maa nsun, sugbọn ti irẹ baba mi ki sun? O si da lohun pe: Irẹ ọmọ mi baba rẹ nbẹru ki ìyà Ọlọhun ma ba lojiji ni”. O nfi eleyi ranti ọrọ Ọlọhun kan to wa ninu suratul Arofu: 97.

"أَفَأَمِنَ أَهْلُ الْقُرَى أَنْ يَأْتِيَهُمْ بَأْسُنَا بَيَاتاً وَهُمْ نَائِمُونَ".

          Lẹhin ti awọn majẹmu ti o ti siwaju yii ba ti pe tan, o se pataki ki Olutuuba se aluwala ki o yan nọfila raka meji, ni ibamu si ọrọ ojisẹ Ọlọhun (SAW) to sọ pe: ko si ẹniti yoo da ẹsẹ kan, ti yoo wa se aluwala, ti yoo si yan nọfila lehin rẹ ti yoo tọrọ aforijin ẹsẹ lọdọ Ọlọhun ayafi kọlọhun fori ẹsẹ naa jin-in” Imam Ahmad lo gbaa wa. Ninu Sọhihu Musilimu, Ojisẹ Ọlọhun tun sọ pe: ko si ẹniti yoo se aluwala ninu yin, ti yoo si se aluwala naa daada, lẹhinna ti yoo sọ pe mo jẹri pe ko si ẹlomiran ti ijọsin òdodo tọ si ayafi Ọlọhun nikan sọsọ, kosi orogun fun-Un, mo si jẹri pe anọbi wa Mohammad ẹrusin Ọlọhun ni Ojisẹ Rẹ si ni, ayafi ki wọn silẹkun alujanna mẹjọọjọ fun-un, ki o gba ibi to ba wuu wọle”

          Ọlọhun yoo tẹwọ gba tituba ẹru Rẹ lopin igbati òrùn o baa ti yọ ni ibuwọ rẹ, Ọlọhun sọ pe: Nwọn ko reti nkankan ju pe ki awọn malaika wa ba wọn tabi ki apakan awọn àmì Oluwa rẹ wa ba wọn, ọjọ ti apakan àmì Oluwa rẹ ba wa, ki yoo se anfaani fun ẹmi kan ti ko ti gbagbọ siwaju tabi ti ko sisẹ rere kun igbagbọ rẹ, Ọlọhun sọ wipe: Ẹ maa reti awa na yoo maa reti” Suratul Aniam 158. Awọn àmì yi yoo maa foju han, bi o ba ku die ki alukiyamo to. Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Alukiyamọ kò ni tó, titi ti oorun yoo fi yọ lati ibuwọ rẹ, bi awọn eniyan ba ti ri èyí, gbogbo ẹniti nbẹ lori ilẹ ni yoo gbagbọ, ìgbà yii ni asiko ti igbagbọ ko nii wulo mọ fun ẹniti ko ti gbagbọ tẹlẹ”. Buhari lo gbaa wa. Ninu adiisi miran: Ojisẹ Ọlọhun tun sọ pe: Dajudaju Ọlọhun yoo maa tẹ ọwọ Rẹ silẹ loru, ki ẹniti o da ẹsẹ lọsan le tuuba, bẹni o si maa ntẹ ọwọ Rẹ silẹ lọsan , ki ẹlẹsẹ oru le tuuba (yoo maa se bẹẹ) titi ti oorun yoo fi yọ ni ibùwọ rẹ.

          Bakannaa ni tituba ko ni jẹ itẹwọgba bi ẹmi ba ti debi gògóngò, Ọlọhun sọ pe "ko si igba ironupiwada fun awọn ti nwọn se aburu titi ti iku fi de ba ọkọọkan wọn ti o wa wipe: Dajudaju emi ronupiwada nisinyi, bẹẹni ko si fun awọn ẹniti o ku sinu keferi sise. Awọn wọnyi, Awa ti pese iya olóro silẹ fun wọn". Suratu-Nisai: 18. Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Dajudaju Ọlọhun yoo gba ironupiwada ẹru bi ẹmi re ko ba ti de gògóngò.

"وَلَيْسَتِ التَّوْبَةُ لِلَّذِينَ يَعْمَلُونَ السَّيِّئَاتِ حَتَّى إِذَا حَضَرَ أَحَدَهُمُ الْمَوْتُ قَالَ إِنِّي تُبْتُ الآنَ وَلاَ الَّذِينَ يَمُوتُونَ وَهُمْ كُفَّارٌ أُوْلَائِكَ أَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَاباً أَلِيما".ً

          Ẹ jẹki a ronu piwada lọsi ọdọ Ọlọhun toripe tituba maa n fa orire ainipẹkun ati isẹmi toni itumọ ba ẹda làyé ati lọrun.

Isẹ rere gbọdọ Ko nkan mẹta sinu:  

1.         Ki o se wẹku pẹlu ohun ti Ojisẹ Ọlọhun muwa, toripe Ọlọhun sọ pe: Atipe ohunkohun ti Ojisẹ naa ba fun nyin, ẹ gbaa, ohunkohun ti o ba kọ fun nyin, ki ẹ kọ ọ; suratul Hashri: 7.

"وَمَآ آتَاكُمُ الرَّسُولُ فَخُذُوهُ وَمَا نَهَاكُمْ عَنْهُ فَانتَهُواْ وَاتَّقُواْ اللَّهَ إِنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ".

2.    Ki o se afọmọ isẹ naa fọlọhun, Ọlọhun sọ pe: A ko pa wọn lasẹ ju pe ki wọn jọsin fun Ọlọhun lọ, ki nwọn fọ ẹsin mo fun-Un , Suratul Bayyinah: 5.

"وَمَآ أُمِرُواْ إِلاَّ لِيَعْبُدُواْ اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ حُنَفَآءَ".

3.      Ki isẹ naa wa lori ipilẹ adiọkan (igbagbọ) ti o lalaafia. Wo suratul Bayyinat.

Lataari ironupiwada, ifọkanbalẹ ati imọna yi maa jẹ ti ẹda, boya eniyan jẹ ẹlẹbọ to si tuuba ifokanbalẹ yoo jẹ tirẹ bẹni imọna. Wo suratul Anam: 82.

{الَّذِينَ آمَنُوا وَلَمْ يَلْبِسُوا إِيمَانَهُمْ بِظُلْمٍ أُولَئِكَ لَهُمُ الْأَمْنُ وَهُمْ مُهْتَدُونَ}

          Bẹẹni Ọlọhun yoo sọ isẹ buburu rẹ di rere yoo si pa ẹsẹ aburu rẹ rẹ, Ọlọhun sọ pe: “Ayafi ẹniti o ba ronupiwada ti o si gbagbọ ni ododo, ti o si se isẹ rere; awọn wọnyi ni Ọlọhun yoo sọ isẹ buburu wọn di isẹ rere. Ọlọhun jẹ alaforiji, alaanu’’ suratul Furkoni:70.

{إِلَّا مَنْ تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ عَمَلاً صَالِحاً فَأُولَئِكَ يُبَدِّلُ اللَّهُ سَيِّئَاتِهِمْ حَسَنَاتٍ}

          Ninu rẹ naa ni pe yoo jere iyọnu Ọlọhun, yoo si la kuro nibi ìyà ina. Wo suratul Al’imraan:135 -136.

"وَالَّذِينَ إِذَا فَعَلُوا فَاحِشَةً أَوْ ظَلَمُوا أَنْفُسَهُمْ ذَكَرُوا اللَّهَ فَاسْتَغْفَرُوا لِذُنُوبِهِمْ وَمَنْ يَغْفِرُ الذُّنُوبَ إِلا اللَّهُ وَلَمْ يُصِرُّوا عَلَى مَا فَعَلُوا وَهُمْ يَعْلَمُونَ(135) أُولَئِكَ جَزَاؤُهُمْ مَغْفِرَةٌ مِنْ رَبِّهِمْ وَجَنَّاتٌ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا وَنِعْمَ أَجْرُ الْعَامِلِين".

          Ninu Musnadu Imam Ahmod, ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Dajudaju bi eniyan kan ba dẹsẹ kan, ti o si sọ pe Ọlọhun mi, mo ti da ẹsẹ kan fori jin mi, Ọlọhun yoo sọ pe: Ẹru mi sẹsẹ kan, o si mo pe, oun ni Ọlọhun To le fori jin oun, ti o si le fi iya jẹ oun, torinaa, mo ti fori jin-in. Lẹhinnaa to ba tun dẹsẹ miran, to tun sọ pe: Irẹ Ọlọhun mi, mo ti dẹsẹ fori jin mi, Ọlọhun yoo tun sọ pe: ẹru mi mọ pe oun ni Ọlọhun to le fori jin oun, to si le fi ìyà jẹ oun, Mo ti forijin-in. Lẹhinaa to ba tun dẹsẹ miran to tun sọ  pe: irẹ Ọlọhun mi, mo ti dẹsẹ kan fori jin mi, Ọlọhun yoo tun sọ pe: ẹru mi mọ pe oun ni Ọlọhun to le fori ẹsẹ jinni, o si le fiya jẹni, mo nfi yin jẹri pe Mo ti fori jin ẹru mi, ki o maa se ohun ti o ba wu.

Ni ipari ẹ bẹru Ọlọhun ẹyin eyan mi, ẹ si tara ronupiwada siwaju ki asiko atise bẹẹ to bọ, toripe ko si ẹniti o mọ ẹniti iku kan”. O n bọ loke, o n bọ nilẹ awọn la dẹ ẹ de e”. Ki Ọlọhun se wa lẹniti yoo le jawọ kuro ninu ẹsẹ, ki o si fi orijinwa lapapọ.


فاتقوا الله -  عباد الله وبادروا  بالتوبة قبل فوات  أوانها . فإن الأعمار  محدودة والمهلة   مقدرة ولكل   أجل كتاب وكل ما هو آت قريب  وفقني الله  وإيّاكم للتوبة النصوح والعمل الصالح . أعوذ بالله من الشيطان الرجيم " يايها الذين ءامنوا لاتلهكم أموالكم ولا أولادكم عن ذكر الله ومن يفعل ذلك فأولئك هم الخاسورون.  وأنفقوا مما رزقناكم من قبل أن يأتي أحدكم الموت فيقول رب لولا أخرتني إلى  أجل قريب  فأصدّق وأكن من الصالحين ولن يؤخرا الله  نفسا  إذا جاء أجلها  والله خبير بما تعملون." ( المنفقون 9-11)