ÀWỌN ÒÓGÚN OLÓRÓ ATI ORÍPA WỌN NIBI BIBAGBESI AYE AWỌN ỌDỌ JẸ

Eko ni soki

Ninu ohun ti o ni ewu julo ti o maa nkoparun ba awon odoo ode oni ni awon nkan oloro je, nitori wipe nmaa nko iparun ba ilera ati opolo, yio si ju omoniyan sinu awon ohun ti a ko, beeni wipe, Olohun ti ola re ga se aponle omo anabi Adamo pelu laakaye ati agboye, laakaye je okan ninu awon idera Olohun ti o tobi julo lori eniyan, pelu re ni eniyan yio maa se iyato laari daadaa ati aburu, ati laarin ohun ti yio ko inira bani ati ohun ti yio seni ni anfaani, lati ara idi eyi ni esin Islam se seni lojukokoro imaa so laakaye yii, O wa se oti mimu ati nkan oloro lilo ni eewo ati gbogbo ohun yio je ki laakaye da ise re sile.

(ALMUHADDIRATU WAASARUHA FI TDI MIIRI SABAABI)

Awọn erongba khutuba                           

1.         Dajudaju idẹkun ni lakaye jẹ, o si jẹ dandan ki a maa dupẹ lori rẹ

2.         Kiki awọn ọdọ nilọ nipa òógún olóró eyiti o le ko iparun ba ìgbà ọdọ wọn.

3.         Gbigbe ogun ti ìmáà lo òógun olóró laarin awọn ọdọ

Akoko khutuba: isẹju marundinlogoji

Isẹju mẹẹdọgbọn

الحمد لله رب العالمين , خلق الإنسان ووهبه العقل  الذى ميزه به  عن سائر الحيوان . وأشهد ان لا إله إلا الله وحده لا شرك له وهو ذو الفضل والإحسان , وأشهد أن محمدا عبده ورسوله أنزل عليه القرآن هدى  للناس  وبينات من الهدى  والفرقان, صلى الله عليه وعلى آله وأصحابه ومن تبعهم باحسان , وسلم تسليما كثيرا. وبعد

Ọpẹ ni fun Ọlọhun Ọba to da gbogbo ẹda, o sẹda eniyan, o si taa lọrẹ laakaye, o fii pọn ọn le, laarin awọn ẹda toku. Mo jẹri pe ko si ẹnikan kan ti ijọsin ododo yẹ ayafi Ọlọhun nikan, Aaso ni, ko si orogun fun un, bẹẹni mo si gba pe Annọbi wa Muhammadu ẹrusin Ọlọhun ni ojise Rẹ si ni, O ran an si eniyan ati alujannu. Ikẹ ati igẹ Ọlọhun ki o maa ba ati awọn ara ile rẹ ati awọn sahabe rẹ, ati gbogbo awọn ti wọn ba tẹlee pẹlu daadaa.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, Ọlọhun ti ọla rẹ ga julọ ti sàpónlé ọmọ eniyan, ti o si gbọla fun un lori ọpọlọpọ ohun ti o da. Ọlọhun sọ pe:

"وَلَقَدْ كَرَّمْنَا بَنِي آدَمَ وَحَمَلْنَاهُمْ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَرَزَقْنَاهُم مِّنَ الطَّيِّبَاتِ وَفَضَّلْنَاهُمْ عَلَى كَثِيرٍ مِّمَّنْ خَلَقْنَا تَفْضِيلاً".

 “Atipe dajudaju Awa se apọnle fun awọn ọmọ (annabi) Adama, Awa ngbe wọn (rin) lori ilẹ ati odo, Awa si n fun wọn ni ijẹ-imu ninu awọn ohun ti o dara, Awa si dawọn lọla ju ọpọlọpọ ninu awọn ẹda ti A dá niti ọla”. Suratul Israi: 70.

 Ọpọlọpọ nkan lọlọhun fi pọn ọmọ annabi adamọ le, ti o si fi se ajulọ fun un lori gbogbo ẹda toku alujannu, irugbin, ati ẹranko, Ọlọhun fi laakaye to tobi julọ ninu idẹra Rẹ pọn ọn le; ki o le maa fi sèyàtọ laarin oore ati aburu, inira ati ànfaani. Ati ki o lee se orí rere laye yii ati lati fi maa dari ọrọ ara rẹ, pẹlu ki awujọ le maa gberu soke sii, ki idagbasoke le maa ba isẹmi aye. Bẹẹni laakaye tun jẹ àlúhùlúhù to niye lori julọ, ti awọn ọlọgbọn dori ẹja mú ẹda ma nse àmújòtó rẹ, ti wọn ko si ni fẹ ki awọn padanu rẹ. Bi laakaye se wa tobi to yii a ri ẹniti o se pe ko kaa kun, kódà abẹ ẹsẹ lẹlomiran fi tirẹ si.

Gbogbo ìgbà ti eniyan to ni laakaye ba ti mu ife kan ninu ọti tabi o da gẹhẹ kan ninu òógun olóró tabi o fin in simu, yoo se afẹku laakaye rẹ lẹsẹkẹsẹ, bẹẹni ohun ti a fi njẹ ọmọniyan yoo fo jade lara rẹ, yoo si wọ asọ iwa ọdaran ati ibajẹ, yoo si gbagbe oluwa rẹ, ko ni tiju ẹnikan mọ, yoo sọ awọn ọmọ rẹ di ọmọ orukan ti awọn iyawo yoo si di opó, nigbati o ba ti sàfẹku laakaye rẹ, laakaye to se pe gbogbo ẹsin to ti ọdọ Ọlọhun  wa lo se mimojuto rẹ lọranyan. Ẹniti o ba safẹku laakaye rẹ, latari òógun olóró tabi ohun ti o maa npa eniyan bii ọti, ti se aida si ẹmi ara rẹ ati awujọ rẹ, kódà yoo sọ ẹmi ara rẹ ati awujọ to fi dori gbogbo ẹniti mbẹ ninu awujọ naa si abẹ òrúlé iyẹpẹrẹ, iparun ati aibalẹ ọkan lawujọ. Ẹniti o nlo òógun olóró ko ni lẹnu ọrọ lori ọmọ, iyawo ati awọn ọmọ ọdọ re mọ, kódà aimọye lo ti parun latari òógun olóró ati awọn amúnihúnrìrà, èmí jade lara wọn lẹniti nke gbàjarè lọ si ọdọ Ọlọhun nipa awọn ọdaran, ẹlẹsẹ eda wọnyi, ti wọn ti ko iparun ba ẹmi ara wọn. Anisẹ òógun olóró yii ti sọ ọpọ di ẹniti o pẹ lẹwọn bi ọbọ, to sọ iyawo di opó ti awọn ọmọ di ọmọ orukan, bẹni awọn gaan ti rá igba èwe wọn láre.

Ẹyin mumini ododo ẹ jẹ kó dà wa loju pe gbigbilẹ ti òógun olóró gbalẹ bi ọwara òjò yii, ko se lẹhin awọn ọta isilamu, ti awọn oloku laakaye musulumi nra lọwọ wọn, ti awọn obilẹjẹ si nba wọn ọn polowo o rẹ.

Keemọ nipa ẹniti o nfi owó rẹ ra ohun ti yoo baa laye jẹ, kinni de ti wọn ko fi ti awọn ti òógun olóró ti parun se arikọgbọn? Tabi bawo leeyan yoo se mu ara rẹ kuro ninu ijọ ọlọgbọn, onilaakaye, lọ sọdọ awọn asiwèrè ẹda.

Afa Asani sọ pe: Bi laakaye ba dabi ọja tita, wọn o ba ta ni ọwọn.

Nitorinaa, gbogbo ohun ti o ba le fa ki ori daru, ni jijẹ mimu tabi finfin eewọ ni ninu isilamu. Ọlọhun sọ pe:

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ إِنَّمَا الْخَمْرُ وَالْمَيْسِرُ وَالأَنصَابُ وَالأَزْلاَمُ رِجْسٌ مِّنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ فَاجْتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ".

 “Ẹyin onigbagbọ ododo ọti, ati tẹtẹ-tita, ati orisa bibọ ati fifi ọfa pin nkan ẹgbin ni” Suratul Maidah: 90.

Abdullohi bun Abbas sọ pe: Nigbati ayah ti Ọlọhun fi sọ ọti di eewọ sọkalẹ, apakan awọn sahabe nsọ fun apa keji pe: “Wọn se ọti leewọ, wọn si fi se déède ẹbọ sise”. Orisirisi adiisi lo wa lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun to fi nse mimuti leewọ, to si nwani nisọra nibi mimuu rẹ. Ninu rẹ ni adiisi Abdur Rahmọn bun waala, o sọ pe: Mo bi Abdullọhi bunu Abbasi leere nipa ọti tita lo ba sọ fun mi pe: Ojisẹ Ọlọhun  ni ọrẹ kan lati sakifi, lanabi ba baa pade ni ọjọ ti ilu Mọkka di ilu musulumi, tohun ti akèngbè ọti lọwọ, to fẹ fita annabi lọrẹ, lojisẹ Ọlọhun ba sọ fun un pe : Irẹ lagbaja se o ko mọ pe Ọlọhun  ti se e leewọ ni, larakunrin naa ba sọ fun ọmọkunrin ti wọn dijọ wa pe: Lọ ọ tà á. Lojisẹ Ọlọhun  ba sọ pe: Lagbaja, asẹ kini o pa ọmọde kunrin naa? O ni mo paa laseọ ki o lọọ taa ni? Lojisẹ Ọlọhun ba sọ pe: Dajudaju ti Ọlọhun ba se mimu nkan leewọ, yoo se owo rẹ naa leewọ ni. Lo ba pasẹ pe ki wọn daa si bàtìháú” Musilimu lo gba a wa.

Ninu adisi miran ti Annọbi ti nse alaye ohun ti ojú rẹ to ni oru ti wọn muu lọ si sanma, o sọ pe: Wọn gbe igbá meji kan fun mi, ti ikan jẹ ti ọti, ti ikeji si jẹ ti wàrà ni ilu Eliyah ni òru ti wọn mu mi rin lọ si sanmọ. Mo wo awọn igbá náà, ni mo ba sẹsa igba wàrà, ni jibrilu ba sọ pe, ọpẹ ni fọlọhun ti o samọna rẹ lọ sibi adamọ, ti o ba le sẹsa ọti ni ijọ rẹ ko ba dẹni anù – Buhari lo gbaa wa.

Ojise Ọlọhun tun sọ pe: Ẹniti o ba mu ọti laye yii, ti ko si ronupiwada to fi kú, wọn yoo se mimu rẹ leewọ fun-un lọrun”. – Buhari ati Musilimu

Ninu adisi miran Ọlọhun sẹbi le eniyan mẹwa nitori ọti:

1.         Ẹniti o n fun un

2.         Ẹniti wọn n fun un fun

3.         Ẹniti o n pọn ọn fun wọn

4.         Ẹniti o mu-un

5.         Ẹniti o n taa

6.         Ẹniti o n raa lọwọ ẹniti o n taa

7.         Ẹniti o n gbee ru si ori ara rẹ

8.         Ẹniti wọn n gbee e lọọ fun

9.         Ẹniti o nna owo ọti

10.       Ẹniti wọn ra ọti fun

Gbogbo awọn eniyan wọnyi ẹni isẹbile ni wọn latẹnu Anọbi Muhammadu. Latari wipe titọ diẹ wo ninu ọti le fa mimu pupọ ninu rẹ, ni ojisẹ Ọlọhun se diẹ leewọ. Ojise Ọlọhun sọ pe: ohun ti pupọ ninu rẹ ba le pàà yàn, diẹ rẹ naa eewọ ni”. - Abu Daud ati Nosai lo gba wa.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun , ẹ jẹ ka sọra fun òógun olóòró, sìgá, igbó, ògógóró, àásà fínfín ati mimu ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti o maa n da ni lórírú, ti kii jẹ ki eniyan gbéwọn mọ lọwọ Ọlọhun  ati eniyan, ti o maa njẹ ki eniyan lẹ lágbára ati ni  ipinnu, leyiti o se pe dida gẹẹ kan mu ninu rẹ, maa nfọ ìríran ẹda, ti o si n sọ ni di aláàbọ-déèdé, Olùsìwàwù, ti yoo maa rẹrin tabi sunkun laini idi, ti oju rẹ yoo maa dà, bii oju ẹniti o ti fẹẹ ku.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun orisirisi ewu ati inira ni nti ara òógun olóòró ati awọn nkan amunihunrira yi maa nko ba ẹsin. Ọlọhun sọ pe:

"إِنَّمَا يُرِيدُ الشَّيْطَانُ أَن يُوقِعَ بَيْنَكُمُ الْعَدَاوَةَ وَالْبَغْضَاء فِي الْخَمْرِ وَالْمَيْسِرِ وَيَصُدَّكُمْ عَن ذِكْرِ اللّهِ وَعَنِ الصَّلاَةِ فَهَلْ أَنتُم مُّنتَهُونَ".

“Esu nfẹ lati da ọta ati ikorira silẹ laarin yin, nipa ọti ati tẹtẹ tita, ati ki o le kọdi nyin kuro nibi irun kiki, ẹ ki yoo ha siwọ”? Suratul Maidah: 91.

Òógun olóòró ati awọn amunihunrira, maa nkọdi ẹnia kuro nibi irun to jẹ ẹsin, o si tun nkọdi eniyan kuro nibi iranti Ọlọhun, bẹẹni o nle awọn mọlaika jinna si ẹda. Ninu adisi ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Mọlaika alanu ko ni sunmọ ẹniti ọti npa”. Ẹniti mọlaika ba jinna si, esu ni yoo sunmọ iru wọn, idi niyi to fi jẹ pe titẹle asẹ Ọlọhun maa nni iruu wọn lara, ti isẹ oloore ko ni wu wọn, lori lati se, sugbọn ti yoo nifẹ si ohun ti Ọlọhun se ni eewọ

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun ninu aburu, ati inira ti oogun oloro ma nfa fun alafia ni pe o maa nfa ki ọpọlọ gbẹ, bẹẹni o maa nfa ooyi pẹlu lilẹ ìsọkúkúlú ọkán, o si maa nfa ki ẹya ara da isẹ silẹ, bakannaa ni o ma nfa ìbẹrù bojo sinu ọkan ẹniti o n mu un, ti yoo si maa paya atubọtan buruku ati awọn ti o n gbẹmi ẹni.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, awọn ọta isilaamu ko le sọ adehun kankan lara yin gbogbo iyanju wọn ni bi wọn o se bayin jẹ, ti wọn wọn yoo si sọ awọn ọdọ di ìpátá ati olori buruku ọmọ. Se wèrè dun un wo lọja, sugbọn ko see bi lọmọ “ bẹẹ” ọmọ ọlọmọ laa fipaa ji, wọọrọwọ laa ji ọmọ ẹni”. Idi niyi ti wọn fi fi awọn oogun oloro yii si arọwọto tọmọde aàtàgbà eyiti o fa ki ọpọpọlọpọ ọdọ wa ni ile itọju ọpọlọpọ ati ọgba ẹwọn.

Ọ dọwọ ẹyin obi ati alagbatọ lati se amojuto ati akiyesi awọn ọmọ yin kuro nibi awọn oogun oloro wọnyi, ki ẹ si fi adua jagun naa ki Ọlọhun la wa lapapọ. Gbogbo awọn ọrọ ti o ti siwaju yii nọsiha ni, kódà itọnisọna ati iwaraẹni nisọra si ni pẹlu. Awọn ọta ẹsin isilaamu nsapa lori bi wọn yoo se da musulumi lagbo dàáná, idi niyi ti o fi di dandan fun gbogbo obi lati re awọn ọmọ lori iduro-sinsin nidi ẹsin Ọlọhun ati lati se daada, pẹlu titakete si gbogbo inira tabi ohun ti o le ba ni jẹ, ki a le fi jẹpe Ọlọhun  to sọ pe:

( يأَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ قُواْ أَنفُسَكُمْ وَأَهْلِيكُمْ نَاراً وَقُودُهَا النَّاسُ وَالْحِجَارَةُ عَلَيْهَا مَلاَئِكَةٌ غِلاَظٌ شِدَادٌ لاَّ يَعْصُونَ اللَّهَ مَآ أَمَرَهُمْ وَيَفْعَلُونَ مَا يُؤْمَرُونَ).

 “Ẹnyin ti ẹ gbagbọ ni ododo, ẹ gba ara nyin là ati awọn enia nyin nibi ina, ti o jẹ pe awọn Malaika ti o ni ipa ati agbara ni olusọ rẹ, nwọn ki yi asẹ Ọlọhun ti o ba pa fun wọn pada, nwọn a si ma mu asẹ ti a ba pa fun wọn sẹ”. Suratu Tahrimi: 6.

Ẹ ẹ wa jẹ ki a gbiyanju lati ri bi Ọlọhun se fẹ kari, atipe adaranjẹ ni ẹ jẹ, Ọlọhun  yoo si bi yin leere nipa bi ẹ se da ẹran yin jẹ si. Nipari a nrọ arawa, ọmọ iyawa ati gbogbo ẹniti ọrọ ẹsin, ba ka lara, lati dijọ kọ iwa ibajẹ yii lawujọ, tori ọrọ Ọlọhun to sọ pe:

"وَتَعَاوَنُواْ عَلَى الْبرِّ وَالتَّقْوَى وَلاَ تَعَاوَنُواْ عَلَى الإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ وَاتَّقُواْ اللَّهَ إِنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ".

“Ẹ ran ara-yin lọwọ lori ise rere ati ibẹru Ọlọhun, ẹ ma se ran aranyin lọwọ lati da ẹsẹ ati lati kọkọ tọ ija” Suratul Miadah: 2.

Ki Ọlọhun bawa se ikẹ ati igẹ Rẹ fun ojisẹ Rẹ, awọn ara ile, awọn ẹmẹwa anọbi ati gbogbo musulumi lapapọ.

Ẹyin ọmọ iya mi ninu ẹsin, ẹ jẹ ki a bẹru Ọlọhun, ki a si yago fun gbogbo awọn ohun ti wọn nse jade sugbọn ti o ni oogun olóró ninu. Awon ohun ti Ọlọhun se lẹto fun wa ni jijẹ mimu ati ni iwosan, a ko le kaa tan, o to fun wa ju ohun ti Ọlọhun se leewọ lọ, ki Ọlọhun jọwọ jare jẹ ki awọn ohun ti o se ni ẹtọ rọwa lọrọ, ki o mo jẹ ki a le lọ sibi ohun ti o se leewọ, ki o dawa lọla, ki o mafi bibiya bukata wa sọdọ ẹda kankan.

اللهم أغننا بحلالك عن حرامك  واكفنا بفضلك عمن سواك  ثم اعلموا أن خير الحديث كتاب الله  وخير الهدي هدي محمد صلّى الله عليه وسلم , وشرّ الأمور محدثاتها وعليكم  بالجماعة فإن يد الله مع الجماعة , ومن شذّ شذّ في النار . إن الله وملائكته يصلّون على النّبي يا أيها الذين آمنوا صلّوا عليه وسلموا تسليم اللهم صلّ على عبدك ورسولك محمد , وارض اللهم عن الخلفاء الراشدين أبي بكر وعمر وعثمان وعلي وعن الصحابة أجمعين. عباد الله إن الله يأمر بالعدل والإحسان وإيتاء ذي القربى وينهى  عن الفحشاء  والمنكر والبغي يعظكم لعلكم  تذكرون وأوفوا بعهد الله إذا عاهدتم  ولا تنقضوا الأيمان  بعد توكيدها  وقد جعلتم الله عليكم  كفيلا إن الله يعلم ماتفعلون .