ZAKAH (ITỌRẸ ỌRANYAN)AWỌN ẸKỌ ATI AWỌN IDAJỌ RẸ

Eko ni soki

Bi o ti je wipe gbogbowa ni a mo wipe ti aso ba doti, o ni bukaata si fifo ki o le ba se anfaani fun eniti o nii, bee naa ni, owo ti Olohun ba bun eda naa ni bukaata si ki a fomo kuro nibi idoti ki o le ba je owo tabi dukia alalubarika. Eleyi je ase lati odo Olohun Oba Adedaa lori gbogbo eniti o ba ni owo ati dukia ti zakah wo lowo.

Awọn erongba lori Khutuba naa:

1.         Sise alaye idajọ Zakah ati alaye ipo rẹ ninu Isilaamu;

2.         Sise alaye awọn ẹkọ nlanla ti o wa ni inu ofin Ọlọhun yi;

3.         Sise alaye awọn idajọ ti o rọmọ awọn iran owo ti a maa n yọ Zakah wọn;

4.         Sise alaye awọn aaye ati agbegbe ibi ti o lẹtọ ati yọọ si, ati sise ofin toto gbigba ati fifun rẹ.

 

Khutubah Alakọkọ (ogun isẹju):

الحمد لله الذي بسط لِمَن يشاء ويقدر. وجعل الزّكاة طهرة للمال وربّه، والصّلاة والسّلام على نبيّنا محمّد الذي أمر بأخذ الزّكاة من أغنياء أمته وتعطى لفقرائهم، وبعد؛

Dajudaju ajulọ n bẹ laarin awọn ẹda ti Ọlọhun da nipa nini arisiki wọn. Ọlọhun tẹ arisiki kalẹ fun ẹlomiran, ti O si diwọn rẹ fun ẹlomiran. Gbogbo rẹ adanwo ni, lati wo bawo ni abọrọ yoo se dupẹ, ki O si le mọ bi alaini yoo se se suuru. Atọka si eleyi wa ni inu Al-Kuran Alapọnle;

{قُلْ إِنَّ رَبّى يَبْسُطُ الرّزْقَ لِمَن يَشَاء وَيَقْدِرُ وَلَاكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لاَ يَعْلَمُونَ} [السّبأ: 36].

Bakanna ni Al-Kuran Alapọnle:

فَأَمَّا الإِنسَانُ إِذَا مَا ابْتَلاهُ رَبُّهُ فَأَكْرَمَهُ وَنَعَّمَهُ فَيَقُولُ رَبّى أَكْرَمَنِ وَأَمَّا إِذَا مَا ابْتَلَاهُ فَقَدَرَ عَلَيْهِ رِزْقَهُ فَيَقُولُ رَبّى أَهَانَنِ  [الفجر:15-17].

[Suratul Al-fajr: 15-17] jẹ ki o ye wa wipe fifun ẹru kan ni ọrọ ti o pọ ki se ami ifẹ Ọlọhun fun un, àìsí ni ọrọ jaburata ko tumọsi ibinu lati ọdọ Ọlọhun.

Ọlọhun dan awọn ọlọrọ wo pẹlu awọn alaini, ti O si dan awọn alaini naa wo pẹlu awọn ọlọrọ. Ni inu ẹkọ ati ọgbọn ti Ọlọhun fi se bayi ni lati wo boya ọlọrọ yoo dupẹ, ti alaini yoo si se suru. Ani ọrọ yi a maa jẹ idẹra fun apakan awọn eniyan, ti o si jẹ ibalẹjọ lori awọn miran. idẹra ni o jẹ fun awọn ti wọn ni ni ọna ti o tọ, ti wọn si n naa si ọna ti o tọ, ti wọn si mọ pe ẹtọ ti Ọlọhun wa ni inu rẹ ti awọn gbọdọ yọ, ti wọn si n yọ pe perepere. Odikeji awọn ti a sọ yi ni awọn ti ọrọ wọn mu wọn ya pokii, ti wọn si kọ ti Ọlọhun ti O fun wọn ni ọrọ naa, ti wọn kọ lati yọ ẹtọ ati iwọ ti Ọlọhun ti o wa ni inu dukia wọn ti Ọlọhun fun wọn. Alaye eleyi wa ni inu Al-Kuran Alapọnle:

{فَلاَ تُعْجِبْكَ أَمْوالُهُمْ وَلاَ أَوْلَادُهُمْ إِنَّمَا يُرِيدُ اللَّهُ لِيُعَذّبَهُمْ بِهَا فِي الْحياةِ الدُّنْيَا وَتَزْهَقَ أَنفُسُهُمْ وَهُمْ كَافِرُونَ} [التّوبة: 55].

{هَذَا مِن فَضْلِ رَبّى لِيَبْلُوَنِى أَأشْكُرُ أَمْ أَكْفُرُ} [النّمل: 40]  

{إِنَّمَا أُوتِيتُهُ عَلَى عِلْمٍ عِندِى} [القصص: 78].

Gbogbo Musulumi ododo! Ki a mọ pe ọranyan ni Zakah jẹ, kódà origun kan ni inu origun Isilaamu maraarun ni pẹlu, ti Ọlọhun se yiyọ rẹ ni ọranyan lati inu owo awọn abọrọ fun awọn alaini. Wo

{وَالَّذِينَ فِى أَمْوالِهِمْ حَقٌّ مَّعْلُومٌ لّلسَّائِلِ وَالْمَحْرُومِ} [المعارج 24-35].  

Zakah jẹ origun ẹlẹẹkẹta ni inu origun Isilaamu maraarun gẹgẹ bi o ti se wa ni inu Hadith ti Ibn 'Umar ati Ibn 'Abas gbawa ni inu Sahih Bukhari ati Musilimu. Itọkasi pọ ni ati inu Al-Kuran Alapọle ati Sunnah Annabi lori jijẹ ti Zakah jẹ ọranyan.

{وَمَا أُمِرُواْ إِلاَّ لِيَعْبُدُواْ اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدّينَ حُنَفَاء وَيُقِيمُواْ الصلاةَ وَيُؤْتُواْ الزكاةَ وَذَلِكَ دِينُ القَيّمَةِ} [البيّنة: 5].

{خُذْ مِنْ أَمْوالِهِمْ صَدَقَةً تُطَهّرُهُمْ وَتُزَكّيهِمْ بِهَا وَصَلّ عَلَيْهِمْ إِنَّ صلاتَكَ سَكَنٌ لَّهُمْ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ} [التّوبة: 103].

Afọmọ ọkan ati owo ni Zakah jẹ, ti o situn jẹ idagba soke ati alekun fun owo. Musulumi ododo, adanwo ni Zakah jẹ lati ọdọ Ọlọhun fun olowo, ẹni ti o basi jẹ olugbagbọ ni ododo yoo yọ Zakah rẹ pẹlu ododo ni ẹni ti o yọnu, ti o tẹle asẹ Ọlọhun, ti o si tun n da ọpẹ fun Un pẹlu. Ọlọhun pa Ojisẹ Rẹ ni asẹ ni inu suratul Taobah: 103 ki o mu Zakah ni inu owo awọn ọlọrọ fun awọn alaini, ki o le fọ owo wọn mọ. Nipa bayi Zakah n fọ ahun ọkan mọ, ti o si n fọ owo mọ kuro ni ibi eeri ati idọti, ti o si nmu ki igbagbọ rinlẹ sinsin. Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) jẹ ki o ye wa pe Zakah ma n jẹ ki owo pọ si ni, ki i din owo ku rara.

Ti o bari bẹẹ irẹ musulumi olowo, yọ Zakah owo rẹ ni ẹni ti n tẹle asẹ Ọlọhun, ti o si tun n da ọpẹ fun Un pẹlu, ni ẹni ti o gba pe ọranyan ni, ti o si fi n tẹle ti Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم). Yọ Zakah owo rẹ ki owo naa le pọ si, ki alubarikah si wọ inu owo naa. Ki o fida ọpẹ fun Ọlọhun ti O pese owo naa fun ọ. Ki o le de baa ni inu osuwọn isẹ daada rẹ ni ọjọ ti owo ati ọmọ ko nii wulo.

{يوم لاَ يَنفَعُ مَالٌ وَلاَ بَنُونَ إِلاَّ مَنْ أَتَى اللَّهَ بِقَلْبٍ سَلِيمٍ} [الشّعراء: 88-89].

Awọn iran owo ti Zakah se ọranyan nibẹ ni: Awọn irugbin ti n jade ni ati inu ilẹ, gẹgẹ bi nkan ọgbin oni horo ati eso. Majẹmu ti a fi n yọ Zakah nkan ọgbin oni horo ati eso ni ki wọn pe apo marun. Ti o se deede 900klg. Tun wo

{وَءاتُواْ حَقَّهُ يَوْمَ حَصَادِهِ} [الأنعام: 41]        

{يا أَيُّهَا الَّذِينَ ءامَنُواْ أَنفِقُواْ مِن طَيّبَاتِ مَا كَسَبْتُمْ وَمِمَّا أَخْرَجْنَا لَكُم مّنَ الأرْضِ وَلاَ تَيَمَّمُواْ الْخَبِيثَ مِنْهُ تُنفِقُونَ} [البقرة: 267].         

Idakan ni inu ida mẹwa si ni o se ọranyan lati yọ lati ara irugbin ti a o fi owo fọn omi si. Sugbọn eyi ti a se wahala ki a to fi omi si idaji idakan ni inu ida mẹwa (1/20) ni a o yọ. Isilaamu ko se Zakah yiyọ ni ọranyan lori awọn ewebẹ, ẹfọ ati awọn eso tutu, ni titoripe awọn wọnyi ama n jẹ wọn ni asiko wọn ni, wọn ko see ko pamọ, yatọ si awọn irugbin oni horo ati awọn eso ti o see ko pamọ ti a si le wọn pẹlu osunwọ.

Zakah awọn ẹran osin ati idajọ wọn. Musulumi ododo! Ninu awọn nkan ti Zakah tun se ọranyan ninu rẹ ni: Rakunmi, Maalu ati Ẹran ti a ko so mọlẹ tosewipe wọn n sa ilẹ jẹ funrawọn ni ọpọlọpọ ọdun, ti a kii fun wọn ni omi tabi onjẹ funraawa. Ondiwọn Zakah Rakunmi bẹrẹ lati marun, ti Maalu bẹrẹ lati ọgbọn, ti ti Ẹran ọsin si bẹrẹ lati ogoji.

Zakah ko jẹ ọranyan lori awọn ẹran osin ti a saaba n so mọlẹ ti wọn kii sa ilẹjẹ funrarawọn. sugbọn ti olówó rẹ ba saa ni ẹsa fun kata-kara (tita) ni igba naa yiyọ Zakah rẹ di ọranyan. Yoo maa se afojuda iye ti o to ni gbogbo ọdọọdun, ti yoo si yọ idaarin idakan ni inu ida mẹwa iye owó rẹ (2.5%).

Bakanna ni gbogbo awọn ẹran ọsin ti wọn wa ni inu oko, ti kii se fun tita, ti kii si jẹlọ funrawọn, ti o se wipe olówó wọn ni wọn n ra onjẹ ati omi fun wọn, ti wọn n sinwọn fun jijẹ, ati mimu wara wọn, gbogbo iru bẹẹ Zakah ko jẹ ọranyan lori wọn.

Awọn nkan ti a gbe kalẹ fun tita. Gbogbo orisirisi nkan ti a gbe kalẹ fun tita ati rira, yala nkan jijẹ ni tabi ti a n wọ, tabi nkan ti a n gun, ati bẹẹbẹ lọ ni Zakah jẹ ọranyan lori wọn. A o mu osu kan ni inu ọdun gẹgẹ bii gbedeke ti a o diwọn iye ti wọn to, ti a o si maa yọ idaarin idakan ni inu ida mẹwa (2.5%) iye owó wọn. Awọn onjẹ, asọ, abọ, mọto, ẹya ara ọkọ, ilẹ, ile ati bẹẹbẹ lọ ni a n pe ni nkan owó. A o wo iye owó wọn ni asiko ti a fẹẹ yọ Zakah wọn, ko baa lekun iye ti ara wọn lakọkọ tabi ki o dinku sii. Ti musulumi ba ra ilẹ fun apejuwe ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan Naira, sugbọn ni ẹyin ọdun kan o ti di ẹgbẹrun lọna ọgọrun marun Naira, iye ti Zakah se ọranyan ni inu rẹ ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun marun Naira. Yoo yọ idaarin idamẹwa rẹ (2.5%). Ti o ba wa dinku si aadọta Naira pere, ori aadọta Naira pere naa ni yoo gbe Zakah yiyọ le. Eleyi ni alaye ofin –Shari'ah- Ọlọhun.

Zakah owó goolu ati fadaka pẹlu awọn idajọ wọn. Ọlọhun se Zakah ni ọranyan lori owó goolu ati fadaka. Ni titoripe awọn mejeeji jẹ ipilẹ fun awọn owó ti o sẹku. Gẹgẹ bi Ọlọhun ti sọ ni inu Al-Kuran Alapọnle

{وَالَّذِينَ يَكْنِزُونَ الذَّهَبَ وَالْفِضَّةَ وَلاَ يُنفِقُونَهَا فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَبَشّرْهُمْ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ يَوْمَ يُحْمَى عَلَيْهَا فِى نَارِ جَهَنَّمَ فَتُكْوَى بِهَا جِبَاهُهُمْ وَجُنوبُهُمْ وَظُهُورُهُمْ هَاذَا مَا كَنَزْتُمْ لأنفُسِكُمْ فَذُوقُواْ مَا كُنتُمْ تَكْنِزُونَ} [التوبة: 34].

        Ti o ba ri bẹẹ, owó goolu ati fadaka pẹlu gbogbo awọn owó beba ti a n na ni ode oni Zakah se ọranyan ni ori wọn. Idarin idakan ni inu idamẹwa (2.5%) ni ojẹ ọranyan ti a o yọ.

Zakah awọn ipin ile-isẹ (shares). Orisi meji ni awọn ipin yi. Awọn ipin ti a n ta ki a le ri ere ni ori rẹ. Eyi ti o sewipe a ma n polowo rẹ lasiko ọja rẹ nikan, ti a si ma n paamọ ni asiko ti ko si ọja rẹ, iru ipin bayi Zakah se ọranyna lori rẹ ni ipari ọdun kọọkan. Iye ti o ba jẹ ni asiko ti afẹ yọ Zakah rẹ ni a o wo, ti a o si yọ idarin idakan ni inu idamẹwa rẹ (2.5%), nitoripe idajọ owó goolu ati fadaka ni idajọ oun naa.

Sugbọn awọn ipin ile-isẹ (shares) ti o jẹ orisun owó lasan, ti kii se fun tita tabi rira, sugbọn ti a n se anfaani ni ibi owó ti n wọle nibẹ. Awọn owó ti n wọle nibẹ ti a n se anfaani nibẹ yi ni a o maa yọ Zakah rẹ ni ẹyin igba ti a ba gbaa tan, ti ọdunkan gbako si kọja ni ori rẹ. idarin idakan ni inu idamẹwa rẹ (2.5%) ni o jẹ ọranyan lati yọ. Ti o ba si tan siwaju ki ọdunkan gbako to kọja ni ori rẹ, Zakah ko se ọranyan ni igba naa.

Zakah awọn ile ati ilẹ ti a fi n se rẹnti. Asiko ti a ta koko ọrọ (tọwọ bọ iwe) pẹlu tẹnanti (ayalegbe) ni a o ti bẹrẹ si ka ọdunkan. Orisirisi ọna ni gbigba owó ile rẹnti. O le jẹ ẹkan gbogi ni a o gbaa, boya ni ibẹrẹ ọdun tabi ni ipari ọdun. Ti eniyan ba gbaa ni ipilẹ odun ti o si fi pamọ titi ọdun fi yipo lori rẹ Zakah jẹ ọranyan nibẹ. Bakannaa ti eniyan ba gba owó rẹnti ni ipari ọdun Zakah jẹ ọranyan nibẹ pẹlu. Majẹmu ikinikeji yi ni ki o ma na ni inu owó naa rara, sugbọn ti o ba na ni inu rẹ ti o fi waa dinku si gbedeke Zakah, Zakah ko jẹ ọranyan ni igba naa.

Owó rẹnti ti n a gba diẹdiẹ ni ipari osu kọọkan, tabi ni osu mẹfamẹfa ti a si n naa, Zakah ko jẹ ọranyan lori rẹ.

Awọn ile ti a n gbe, ati ọkọ ti a n lo, Zakah ko jẹ ọranyan lori wọn. Eleyi ni itumọ ọrọ Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ti Abu Huraerah gba wa ni inu Sahihu Bukhari ati Musilimu.

 

 

الحمد لله على آلاء نعمه وجزيل فضله، والصّلاة والسّلام على رسول الله وبعد؛ أيّها المسلمون! إنّ للزّكاة مصاريفها كما بيّنها الله سبحانه وتعالى في كتابه.

Awọn agbegbe (aaye) ti a n yọ Zakah si.

Gẹgẹ bi a ti se mọ wipe ọranyan ni Zakah jẹ. wo

{إِنَّمَا الصَّدَقَاتُ لِلْفُقَرَاء وَالْمَسَاكِينِ وَالْعَامِلِينَ عَلَيْهَا وَالْمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمْ وَفِى الرّقَابِ وَالْغَارِمِينَ وَفِى سَبِيلِ اللَّهِ وَابْنِ السَّبِيلِ فَرِيضَةً مّنَ اللَّهِ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ} [التّوبة: 60].

[Suratul Taobah: 60]. Ni ibi ti ọrọ Zakah kanpa de, Ọlọhun (سبحانه وتعالى) fun raa Rẹ ni O pin Zakah, ko fi pinpin rẹ si ọdọ Annabi kan, tabi Malaikah kan. Nitori naa, iwọ Musulumi ododo bẹru Ọlọhun, ki o si mọ pe amaanat (gba fi pamọ) ni Zakah jẹ, ọranyan si ni sisọ rẹ. Ni inu sisọ rẹ naa ni ki o de ibi ti o yẹ ki o de, lasiko ti o yẹ ki o de bẹ.

{إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُكُمْ أَن تُؤدُّواْ الأمَانَاتِ إِلَى أَهْلِهَا} [النّساء: 58]            

Awọn ti Al-Kuran ni ki a yọ Zakah fun ni:

-           Awọn talika ati awọn alaini, ti wọn ko ni nkankan, tabi ti nkan ti wọn ni ko to bukata wọn. Ko si owo-osu kan ti n wọle funwọn, ko si ere ọja bẹẹsi ni kosi ile isẹ kan fun wọn, inawo wọn kosi jẹ ọranyan lori ẹnikankan. A o maa fun wọn ni iye ti yoo to wọn di ọdun kan ti o ba rọrun ni inu Zakah. A le fun ẹni ti o fẹ gbe iyawo lati ran lọwọ.

-           Sugbọn talaka tabi alaini ti aripe o ni okun ati agbara lati se isẹ, ọranyan ni ki a se ikilọ fun ki o dẹkun gbigba Zakah, ki a si gbaa ni iyanju isẹ sise. Eleyi ni sunnah Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) bi o ti se wa ni inu Musnad Ahmad, ati Sunanu Abi Dauda ati an-Nasaai.

-           Ni inu awọn ti a le fun ni Zakah ni ẹniti gbese mu ni ọrun, yala ni titori anfaani ara rẹ ni o, tabi ni titori anfaani ẹlomiran, kódà bi o ba jẹ olówó, pẹlu majẹmu ki o ma jẹ opurọ.

-           Titu awọn musulumi ti o wa ni oko ẹru tabi igbekun silẹ pẹlu owo Zakah.

-           Riran awọn ti wọn n jagun si oju ọna Ọlọhun lọwọ pẹlu owo Zakah.

-           Riran awọn onirin-ajo ti nkan tan mọ lọwọ ni inu owo Zakah.

-           Riran awọn ọmọ orukan lọwọ ni inu owo Zakah.

Sise ikilọ gbigba Zakah laini ẹtọ sii, ẹnikẹni ti ko ba ni ẹtọ si ki o gba Zakah, ti o si gbaa ti o si jẹẹ, ki iru ẹni bẹẹ mọ pe ina ni ohun jẹ, yoo si dide ni ọjọ agbende ni ẹni ti ko nii ni ẹran loju. Iwọ ọmọ iya mi musulumi! Bẹru Ọlọhun, ki o si jinna si gbigba Zakah ti Ọlọhun si se ikẹ fun ọ. Mọ pe ikilọ ti o pọ ni o wa ni ati ọdọ Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم). Ni inu ọrọ rẹ: "Eni ti o ba gba Zakah ti ko si ni ẹtọ sii, yoo wa lọrun rẹ titi di ọjọ idajọ, ti ko si ni ni ẹran loju". "Ẹnikẹni ti o ba mu mi maa bi awọn eniyan ni ọna wiwa owo, ki o mọ pe ina ni ohun n jẹ, bofẹ ki o bere ni iwọnba ti o basi fẹ ki o maa bere ni ọpọlọpọ". "Ẹnikan ko ni si ilẹkun ibeere fun ara rẹ, afi ki Ọlọhun si ilẹkun osi fun un". "Ẹni ti o ni owo ti o pọ kii se abọrọ kii se olowo, sugbọn abọrọ gangan ni ẹni ti o ni ayọ ọkan". "Ẹni ti ko ni okele kan, tabi ti koni okele meji kọ ni alaini, sugbọn alaini gan ni ẹni ti kii bi awọn eniyan, ti o se wipe awọn ni wọn maa n mọwọn ti wọn yoo si se sara fun wọn". Eleyi ni diẹ ni inu awọn ikilọ ti o pọ ti o wa ni ati ọdọ Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم).

Iwọ ọmọ iya mi musulumi! Melomelo ni awọn ti wọn n beere Zakah ti wọn ko si lẹtọ si?! Bẹẹ Ọlọhun fun ni okun ati agbara lati sisẹ, sugbọn wọn ti muu ni asa ni. Melomelo ni wọn ti bi, ti wọn ko ni, ti Ọlọhun tun waa sọ wọn di ọlọrọ?!

Nitori naa, awọn alaini ti wọn n tiju ati beere ni ki a yọ Zakah fun.

{المتعففين، الذين لا يسألون الناس إلحافاً، يَحْسَبُهُمُ الْجَاهِلُ أَغْنِيَاء مِنَ التَّعَفُّفِ} [البقرة: 273].

Okunfa ifẹ, aanu ati iran ara ẹni ni ọwọ ni Ọlọhun fi Zakah se. Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) sọ pe: "Ẹ kẹ awọn ti wọn wa ni ori ilẹ, Ẹni ti O wa ni sanma -Ọlọhun- yoo kẹ ẹyin naa". [Ahmad, Abu Dauda ati Tirmithi].

Bi awọn ọlọrọ ba yọ Zakah owo wọn bi o ti tọ ati bi o ti yẹ ni, alaini ati talaka ko ba mọ ti din ku ni awujọ.

Ni itori naa, ki ẹ se ojukokoro yiyọ Zakah owo yin si ibi ti o tọ ti o yẹ, ki ẹ si paa mọ fun awọn ti wọn kii bere lọwọ awọn eniyan.

Ki Ọlọhun gba isẹ daada ni ọwọ mi ati ni ọwọ yin.

اللهم تقبّل طاعاتنا وحبّب إلينا عبادتك، وطهّر نفوسنا من آثار الشّحّ. وصلّى الله على نبيّنا محمد وآله وصحبه وسلّم.