Eko ni soki

Osu Ramadan, osu aponle, ni osu yi ni a maa nsi awon ilekun alijanna, a si maa nti awon ilekun ile ina, osu ti Olohun gbola fun lori gbogbo osu ti o ku, Olohun se ajulo oore fun awon eru re pelu re lati lee silekun afokante pelu ibokun ina kuro lorun, ti Olohun oba ni bibokun ina kuro ni gbogbo oru kookan ninu awon oru re, ohun ti o to fun awon onigbagbo ododo ni ipesesile fun osu alaponle yii, ati igbaradi fun-un siwaju ki o to de, osu yi je alejo abiyi ti kii wa bawa ni odun ayafi ni eekan soso.

Erongba lori Khutuba naa:

1.         Gbigbani ni yanju fun imura silẹ de osu Rọmadan.

2.         Gbigbani ni iyanju nipa pataki ọla ti n bẹ fun awọn ọjọ ti o wa ninu osu Rọmadan.

3.         Sise alaye nipa ọla ti o wa fun awẹ ati awọn erenjẹ rẹ.

الحمد لله الذى جعل لعباده مواسم الخيرات يتسابقون فيها بأنواع الطاعات ويتوبون من السّيّئات، وأشهد أن لا إله إلاّ الله وحده لا شريك له فى ربوبيته وإلهيته، وما له من الأسماء والصفات وأشهد أنّ محمّدا عبده ورسوله أول سابق إلى الخيرات –صلى الله عليه وسلّم- وأصحابه الذين كل أوقاتهم طاعات وسلّم تسليما كثيراز أما بعد:

            A dupfun lọhun, ba ti o ssa awn asiko kan ti o lore fun awn ru R, ki wn le ni anfaani lati se alapantete l si ibi is oloore ki wn si ronu piwada kuro nibi awn aburu. A jri pe ko si nikankan ti a ltọ lati sin niti ododo ayafi lọhun nikan, ko ni orogun nibi dida, sinsin ati nibi awọn oruk R ati awn irohin R , bẹẹni a si jri pe anọbi wa Muhammad rusin lọhun ni, Ojis R si ni plu, asiwaju lo j nibi ise rere sise, ik ati ig lọhun ki o maa baa ati awọn ara ile r ati Sahabe r, to se pe gbogbo asiko wn tọlọhun ni wn fi se. 

·        Oluwa wa “Allah” wipe:

{شَهْرُ رَمَضَانَ الَّذِي أُنْزِلَ فِيهِ الْقُرْآَنُ هُدًى لِلنَّاسِ وَبَيِّنَاتٍ مِنَ الْهُدَى وَالْفُرْقَانِ فَمَنْ شَهِدَ مِنْكُمُ الشَّهْرَ فَلْيَصُمْهُ وَمَنْ كَانَ مَرِيضًا أَوْ عَلَى سَفَرٍ فَعِدَّةٌ مِنْ أَيَّامٍ أُخَرَ يُرِيدُ اللَّهُ بِكُمُ الْيُسْرَ وَلَا يُرِيدُ بِكُمُ الْعُسْرَ وَلِتُكْمِلُوا الْعِدَّةَ وَلِتُكَبِّرُوا اللَّهَ عَلَى مَا هَدَاكُمْ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ}.

 “Osu “Rọmadan” ni , ẹyi ti A sọ Al-Kur’an kal ninu rẹ. Ilana ni o jẹ fun eniyan, ẹri ododo ati ilana-otitọ naa ati ipinya (ododo yato si irọ); nitorinaA ẹnikẹni ti osu naa ba se oju rẹ ninu yin, ki o gba awẹ ninu rẹ; ẹniti o ba n se aisan tabi ti o nbẹ lori irin-ajo (yoo san awẹ na pada ninu) onka awn ọjọ miran. lhun nfẹ irọrun pẹlu yin ko si fẹ inira fun yin,  Atipe ki ẹ baa le pe onka (aawẹ) ki ẹ si se agbega fun- Un (orukọ) Ọlọhun nitori ọna ti O fi mọ yin, ati ki ẹyin le se ọpẹ…” Suratu al-Bakorah-2:185.

·        Asiko ni yi fun gbogbo olurankan daadaa.

·        Asiko ni yi fun ọmọniyan lati se òwò ase jere.

·        Eniba padanu ninu osu yi, ko si osu miran fun un lati jèrè ohun ti o padanu.

·        Eniba kọ lati sunmọ Oluwa rẹ ninu osu yii, ko le sunmọ Ọ mọ, bakannaa ati se oriire rẹ sòro.

·        Irẹ ọmọniyan, paya Oluwa rẹ ki o si maa dupe fun Un  lori awọn idẹra Rẹ lori rẹ, nipa ọla ati apọnle. Ninu ikẹ Ọlọhun lori rẹ nipe, o ba araa rẹ labẹ ase Rẹ ti o si jinna si awọn nkan ti O kọ.

·        Ẹyin ẹru Ọlọhun, ẹ lọ mọ wipe ẹ ti dojukọ osu alapọnle to kun fun èrè ti ko lẹgbẹ sugbọn fun ẹniti o ba se kongẹ ọna’mọ.

·        Osu ti ẹ dojukọ yii ni Oluwa sọ Al-kur’an kalẹ.

·        Osu yii kun fun adipele ẹsan fun isẹ rere bakannaa fun isafọmọ kuro nibi ẹsẹ.

·        Ibẹrẹ osu yi jẹ ikẹ, aarin ati ikẹyin rẹ wa fun aforijin ati ibọkun lorun ẹni kuro nibi ina.

·        Ara origun ẹsin ni gbigba aawẹ ni awọn ọsan osu naa, atipe didide fun ijọsin ni awọn oru osu naa jẹ oun ti o ni ọla.

·        Eniti o ba se awọn isẹ naa bi o ti tọ ati bi o ti yẹ, Oluwa yoo gbọn awọn ẹsẹ rẹ danu.

·        Laada ti o n bẹ fun ẹniti o ba se “Umura” ninu osu yii se deede ẹsan ti n bẹ fun “Haji” sise.

·        Inu osu yii ni wọn maa n si gbogbo ilẹkun Al-Janna ti ilẹkun ina yoo si di titipa. Bakana èsù ati awọn iransẹ rẹ yoo wa ni ori ìdè.

·        Imam Bukhari ati awọn miran gba ẹgbawa ọrọ kan wa ninu “Hadiisi Abu Hurairah” pe Annabi ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba sọ pe :’Oluwa wa sọ pe: gbogbo isẹ ọmọ Annabi Adama jẹ tirẹ, ayaafi awẹ. Nitoripe Emi ni n O San ẹsan rẹ. Awẹ gbigba jẹ gaga kuro nibi ina, ti o ba di akoko ti ẹ n gba awẹ, ẹ ma se sọ ọrọ alufansa tabi èébú. Bakannaa ti ẹniyan ba kọju ija si ọ tabi sọ ọrọ buruku si ọ, ki o sọ fun un wipe, emi jẹ alaawẹ. Mo fi ẹniti ẹmi “Muhammad” wa ni ọwọ rẹ bura, oorun ẹnu alawẹ yọ Ọlọhun ninu ju oorun “Al-Misiki” lọ. Idunu meji ni o wa fun alawẹ, nigba ti o ba n sinu, inu rẹ yoo dun bakannaa si ni nigbati o ba pade Oluwa rẹ.

·        Ẹyin eniyan, ẹ gba awẹ pẹlu riri iletesu bakannaa ẹ ma se gba awẹ ni ọjọ meji tabi ọjọ kan saaju osu “Rọmadan” ayafi ẹni ti o ba saaba maa n gba awẹ tẹlẹtẹlẹ, bii awẹ ọjọ mọnde tabi Alamisi. Bakannaa ẹ ma se gba awẹ ni ọjọ iye meji tii se ọgbọn ọjọ ninu osu “Shaaban” ti ẹ ba se afẹku iletesu latari kurukuru. Ninu “Hadiisi Bukari” Abdullah bn Umaru ki iyọnu Oluwa maa ba wọn sọ pe :. Dajudaju Annabi ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa baa  sọ pe: ẹ ma bẹrẹ awẹ titi ti ẹ o fi ri iletesu, ti o ba pamọ fun yin ẹ ka osu pe ọgbọn. Abu Huraira naa sọ pe Annabi sọ pe bi kurukuru ba bo oju ọjọ ti ẹ ko le rii, ẹ ka Shaaban ko pe ọgbọn. Amar bun Yaasir sọ pe: ẹniti o ba gba awẹ ni ọjọ iye meji ti sẹ Baba Kọọsimu.

·        Origun pataki ni awẹ Rọmadan jẹ ninu Isilaamu ti Ọlọhun see   ni ọranyan fun awọn ẹrusin Rẹ. Oluwa ni:

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آَمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الصِّيَامُ كَمَا كُتِبَ عَلَى الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ

(Mo pe ẹyin onigbagbo ododo, A se awẹ ni dandan leyin lori gẹgẹ bi A ti see ni dandan lori awọn ti wọn ti lọ, ki ẹ le paya (Ọlọhun)(.

·        Awẹ jẹ ọranyan lori gbogbo olu-jupa-jusẹ silẹ fun Ọlọhun (Musulumi).

·        Majẹmu awẹ ni ki ẹniti yoo gbaa ti balaga pẹlu ki o ni laakaye pẹlu agbara laisi jẹ arinrin àjò.

·        Obinrin ti o ba n se nkan osu ko nii gba awẹ.

·        Aawẹ kii se ọranyan fun keferi.

·        Ti keferi ba di musulumi lọsan aawẹ, o di dandan ki o ko ẹnu duro (maa gba aawẹ) fun eyi ti o ku ninu ọsan ọjọ naa ati awọn ọjọ aawẹ ti o ku.

·        Ọmọde ti ko tii balaga, kii se dandan ni ki o gba aawẹ sugbọn o dara lati maa fi kọọ ti ko ba nii jẹ inira fun un.Awọn sahabe Annabi a maa se bẹẹ.

·        Bakannaa, ẹni ti arun ọpọlọ ba n da laamu kii gba aawẹ gẹgẹ bii were, dìndìnrìn ati bẹẹ bẹẹ lọ. Kόdà ko si si itanran kankan fun iru ẹni bẹẹ.

·        Ẹni ti o ba jẹ arugbo tabi alaarẹ ti ko ni igbakan ti iru aarẹ naa yio mọwọ duro, ko nii gba aawẹ sugbọn dandan ni lati maa fun alaini kọọkan ni onjẹ dipo aawẹ kọọkan ti  wọn ko le gba.   

·        Ẹniti o ba jẹ alaisan. Ewọ ni fun alaisan ki o gba awẹ niwọn igba ti  ko ba le ko iparun baa. Ti ara rẹ ba ya yoo san awẹ rẹ pada, sugbọn ti o ba ku, ko si idapada awẹ fun un.

·        Wọn si see ni majẹmu fun oloyun ti ko le gba awẹ ki o sinu ki o si gbaa pada lẹyin ibimọ ati ti ẹjẹ ibimọ ba da.

·        Ẹniti n fun ọmọ ni ọyan naa ni anfani sisan awẹ pada niwọn igba ti ko ba le gba awẹ.

·        Ẹni ti o ba jẹ oniirinajo, ko si aburu fun-un ti o ba gba awẹ tabi ki o sinu. Sugbọn ẹni ti gbigba awẹ ko ba jẹ inira fun, wọn ni ki o gba awẹ naa.

·        Ẹniti o ba gba awẹ ti o wa se irinajo eyiti o fi n dara fun un ni ki o gba awẹ naa kolẹ. Sugbọn ti o ba nko inira ba ko si láìfí nibi jija irufẹ awẹ bẹẹ. Amọ yoo se adapada rẹ ti o ba de ilu rẹ pada.

·         Mo pe ẹyin musulumi, Anaabi ti se wa ni oju ọyin nipa ijọsin ninu osu Rọmadan. O wipe: ẹniti o gba awẹ rẹ tọkantọkan ati taratara, oluwa yoo se aforijin ẹsẹ rẹ ti o ti lọ fun-un.

·        Ninu pipe majẹmu awẹ ni “taraawii”asámu kiki wa,    ki i daada,  ki ẹ to ni ẹyin Imam titi di ipari. Nitoripe ẹniti o ba ki irun yii pẹlu Imam wọn yoo kọ  ẹsan ẹniti o fi gbogbo oru re jọsin fun oluwa fun un, koda ko fi gbogbo oru rẹ sun.

·        Ninu majẹmu taraawi ni pe ki a kii pẹlu pẹlẹplẹ lai kanju kii, ki a si rẹ ara wa ni lẹ fun oluwa wa.

·        Ninu majẹmu taraawii ni ki o ma ju mọkanla lọ (rakah) boya ninu Rọmadan  tabi ni awọn ọjọ aye toku nitori ẹgbawa ọrọ lati ẹnu Ibnu Abbas (ki ikẹ Ọlọhun maa ba) wipe Anaabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba) kirun fun awọn ọm lẹyin rẹ ninu osu Rọmadan (taarawii) fun akoko diẹ lẹyin naa wọn se afẹku rẹ nitoripe o n bẹru pe ki o maa di ọranyan ati pe ọrọ wa lati ẹnu Ummar bun Khatọb pe” o pasẹ  fun Ubayi bun kaab ati ọkunrin kan ti n jẹ Temiimi-daari pe ki wọn maa ki irun mọkanla fun awọn eniyan. Eleyi ni onka irun Anọbi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba) ninu osu awẹ. Ki Oluwa fi emi ati ẹyin naa se kongẹ oore.Ki O sun wa mọ isẹ rere, ki O si gbe wa jinna si ifẹ-inu.Bakannaa ki O ka wa mọ ara awọn ti wọn yoo tu okun ina kuro ni ọrun wọn.

·        Ounjẹ, mimu ati sisunmọ obinrin jẹ awọn nkan ti ẹmi ba saaba. Bi akoko awẹ ba wọle, awọn nkan wọnyi ti ẹmi n fẹ ni yoo di pipati fun awn akoko kan.

·        Akoko yii bakannaa ni awn olowo maa n mọ idẹra Oluwa lori wn nitoripe wn gbe jijẹ ati mimu silẹ ni eyi ti wn yoo fi mọ ohun ti n koju awn alaini. Eleyi ni yoo si fi jẹ ki wọn tubọ dupẹ oore oluwa lori wọn.

·        Bakannaa awẹ yoo le esu kuro ni ara wa lataripe ẹjẹ ki yoo le rin daadaa bi igba ti a n jẹun. Nitoripe èsù n rin ni rinrin ẹjẹ ni ara ọmọ anọbi adamu ni.

·        Nitori awẹ, Oluwa ma n gbe royiroyi aburu, ati ibinu jinna si ẹru Rẹ, idi ni yi ti wọn fi sọ awẹ ni isọ.

·        Ni asiko awẹ, eniyan yoo sun mọ oluwa rẹ yoo si jinna si irọ, abosi, itajẹ-silẹ laitọ ati ijẹ owo olowo laitọ bibẹẹkọ onitọun n fi ebi pa ara rẹ ni. Annabi wipe: Ẹniti ko ba gbe jusilẹ ọrọ irọ ati fifi se isẹ se ko si erenjẹ kan ti yoo ri nibi awẹ re jupe o fi ebi ati ongbẹ pa ararẹ lasan lọ.

·        Saabe Annabi ti n jẹ Jaabir (Ki oluwa yọnu sii) sọpe: bi o ba n gba awẹ, jẹ ki igbọran rẹ, oju rẹ ati ahon rẹ naa gbawẹ kuro nibi ọrọ irọ ati awọn nkan eewọ ati fifi suta kan alabagbe- ẹni. Ki o si se pẹlẹ ni awon ọjọ awẹ rẹ ki iyatọ le baa wa nibi awon ọjọ awẹ ati awọn ọjọ miran.

·        Ninu ise awọn salaafi ni wipe wọn a maa joko pa si mọsalasi ni asiko awẹ ni eniti n wipe. ‘A n sọ awẹ wa, a ko ni fẹnu tẹnbẹlu ẹnikan’.

·        Ẹniti o ba gba awẹ pẹlu awon majẹmu, irufẹ ẹnibẹ ti ba Oluwa dowopọ pẹlu pe yoo fi alujanna se ifa jẹ.

·        Anaabi wipe: Ilẹkun kan n bẹ ninu alujanna, orukọ rẹ n jẹ “Ar-rọyyan”. Ibẹ ni awọn alaawẹ yoo gba wọle ti ẹnikan kan kosi nii lẹtọ sii  lẹyin wọn.

·        Ninu ẹgbawa miran, bi wọn ba ti wọle tan won yoo tii pa.

·        Ninu ẹgbawa miran, ẹni ba wọle lati ẹnu ilẹkun naa ti o ba si fi mu omi naa, oungbẹ ki yoo gbẹẹ mọ lailai.

·        Oluwa sọ ninu Hadiisi kudusi pe: Gbogbo ise ọmọ annabi Adamọ jẹ tirẹ ayafi awẹ nitoripe Emi ni yoo san ẹsan awẹ rẹ.

·        Ninu isesi alaawẹ ni ko sọ oriirẹ ati  ohun to n kọja sinu ikun rẹ ati awọn ohun to n koojọ, ki o si maa ranti iku ni ẹniti n kọ aye ati ọsọ rẹ silẹ lati ri ile idẹra wọ.

·        Nitoripe alaawẹ yoo dunnu nigba ti o ba sinu ati igba ti o ba pade oluwa rẹ. Oluwa wipe:

{فَمَنْ كَانَ يَرْجُو لِقَاءَ رَبِّهِ فَلْيَعْمَلْ عَمَلًا صَالِحًا وَلَا يُشْرِكْ بِعِبَادَةِ رَبِّهِ أَحَدًا}.

“Ẹniti n ba n rankan ipade Oluwa rẹ ki o yaa se isẹ rere ki o ma si fi ẹnikan se orogun ninu ijọsin Oluwa rẹ”.

·        Oluwa sa osu “Rọmadan” ni ẹsa toripe “Al-kur’an” sọ kalẹ ni osu naa. Oluwa ni: شَهْرُ رَمَضَانَ الَّذِي أُنْزِلَ فِيهِ الْقُرْآن [البقرة : 185]

 « Osu Rọmadan” eyi ti A sọ Al-kuran kalẹ ninu rẹ ... ».

·        Saabe Annabi ti n jẹ Ibn Abbas (ki oluwa yọnu sii) wipe: Al-kuran sọ kalẹ lẹẹkan soso lati Lao’u Mahfoosi si Baitu-L-Issa ni òru abiyi (Lailatul-kọdri). Ẹri eleyi ni ọrọ oluwa to wipe:

{إِنَّا أَنْزَلْنَاهُ فِي لَيْلَةٍ مُبَارَكَةٍ }.

« Dajudaju Awa ni A sọ ọ (Al-kuran) kalẹ ni oru alalubarika kan ».

·        Ti osu “Rọmadan” ba wọle, ọga wa suhri yoo wipe: kika Al-kur’an ati bibọ alaini ni

·        Alfa Agba Abdul Akeem sọpe: ti osu “Rọmadan” ba wọle, Imam Malik ma n jina si kika Hadiisi ati jijoko ti onimimọ lati le gbajumọ kike Al-kur’an.

·        Didide ni awọn òru awẹ fun ijọsin jẹ isẹ ti laada rẹ ko lonka.

·        Itọrẹ aanu jẹ isẹ ti o ni laada lori. Sahabe Anaabi (ki oluwa ba wa yọnu sii) jẹ ẹniti o  maa n  sare lọ sibi isẹ rere nipataki julọ ninu osu awẹ. Bakannaa Jubriilu (A.S) ma n wa bẹ annabi wo ni alaalẹ osu awẹ lati ke Al-kur’an fun-un.

·        Ninu ohun ti o  maa n mu eniyan sunmọ Al-Jannah ni ki eniyan maa se itọre aanu ninu osu “Rọmadan”.

·        Abu Huraira (ki Oluwa yọnu si) wipe: Annabi (صلى الله عليه وسلم) sọ pe: Tani ẹni ti o ji ni owurọ yii ninu yin ni ẹniti n gba awẹ? Abu bakri (t) wipe: emi. O tun wipe tani o ti tẹ le oku de ile iboji ni aarọ yii? Abu bakr ni emi. O tun bere pe, tani o ti bẹ alaisan wo ni owuro yii? Abu bakr tun wipe emi. Annabi (صلى الله عليه وسلم) wipe: awon nkan wonyii ko nii papọ fun ẹnikan afi ki o wọ Al-Jannah.

·        Pipa awẹ ati saara pọ ma n pa ẹsẹ rẹ.

·        Abu Dar’dai (R.A) wipe: Ẹ maa ki irun ninu okunkun òru nitori okunkun saare, ẹ maa gba awẹ ni igba ti oorun ba mu gidi nitori oorun ati igbona ọjọ akojọ, ki ẹ si ma se kaarẹ nitori aburu ọjọ ikẹyin.

·        Oluwa gba awẹ wa ati ijọsin wa.Oluwa ki O fi ori jin awọn oku musulumi, ọmọkekere wọn, agba wọn, ọkunrin wọn. Ikẹ oluwa ati igẹ Rẹ ki o maa ba Annabi ati awọn Sahabe rẹ.

فاتقوا الله أيّها المسلمون وعظّموا شهر رمضان كما عظّمه الله واغتنموه كما أمركم الله واعلموا واعلموا أنّ خير الحديث كتاب الله وخير الهدي هدي محمّد – صلى الله عليه وسلّم- وشرّ الأمور محدثاتها وكلّ محدثة بدعة وكلّ بدعة ضلالة.

Nitorinaa, beru lhun yin Musulumi ki si pataki osù naa bi lhun se pataki re, bakannaa ni ki ko ọrọ osu naa pelu is rere. lọọ m pe r lhun lo loore jul, bni ilana anbi wa lo dangajia jul plu, atipe adadaasil (bid’ah) lo buru jul nibi gbogbo n kan, gbogbo bidia anu ni, ki lhun ma sewa lẹni anu laye ati lọrun