BI ALAISAN YOO SE MASE IMỌRA ATI BI YOO SE MA KIRUN

Eko ni soki

Ipo ti irun wa ni okan muumini je ipo ti o ga, ti yio maa soo ni gbogbo awon asiko re ati ni gbogbo awon isesi re, sugbon, o se se ki awon ohun iseriwa gegebii aare ki o seriwa leekookan eleyiti yio kapa lori omoniyan, ni ipo yi, ofin esin ko gbagbe ohun ti o je dandan le muumini lori, o se alaye bi yio se se imora ati bi yio ti kirun, ati gbaa aawe, o si se awon irorun ti o tobi le lori eleyiti o nfi ike ati aanu Olohun han nibi sise ofin re.

 

Erongba lori Khutuba naa:

·        Iranti nipa Pataki sisọ akoko irun

·        Alaye nipa adanwo atipe oluwa ni ọba alaafia

·        Kik fun alaisan lati ma fi irun lọra

·        Itaji fun  awn dokita ati awn ti n tọju alaisan .

الحمد لله رب العالمين، أكمل لنا الدين وأتمّ علينا النّعمة، وما جعل علينا فى الدّين من حرج، وأشهد أن لا إله إلاّ الله وحده لا شريك له، وأشهد أنّ محمّدا عبده ورسوله، صلّى الله عليه وعلى آله وأصحابه وسلّم تسليما.

Ọpẹ ni fun Ọlọhun, Ọba ti o pe ẹsin ati idẹra rẹ le wa lori, ti ko fi inira sibi ẹsin fun wa, a jẹri pe kosi Ọba ti a le jọsin fun lododo lẹyin Ọlọhun Ọba aaso ti ko ni orogun, ati pe Annabi wa Muhammad ẹrusin Ọlọhun, Ojisẹ Rẹ si ni. Ikẹ Ọlọhun ati   ọla  Rẹ ki o maa ba a ati gbogbo awọn ẹmẹwa rẹ titi laelae.

·        Ẹyin ẹrusin Oluwa, ẹ paya oluwa gẹgẹ bi o ti yẹ

·        Ki ẹ lọ re mo pe gbogbo ohun ti o ba sẹlẹ si ẹda ni ibanujẹ, inira ati àárẹ. gbogbo awon eleyi idaniwo ni lati ọdọ Oluwa wa o

·        Oluwa wipe: وَلَنَبْلُوَنَّكُمْ حَتَّى نَعْلَمَ الْمُجَاهِدِينَ مِنْكُمْ وَالصَّابِرِينَ {محمد : 31}

                  

"Daju-daju A o ma dan an yin wo titi ti a o fi mo awọn olugbiyanju tootọ ninu yin ati awọn onisuru"

·        Sahabe Anaabi (صلى الله عليه وسلم) ti n jẹ Suaib wipe: Anaabi (صلى الله عليه وسلم) wipe: ọrọ Olugbagbọ ododo (Musulumi) jẹ kayeefi nitoripe gbogbo ohun ti o ba kan an dada ni o jasi. Iwa yi j ti olugbagb ododo nikan. Ti idunnu ba de, yoo dupẹ, ti yoo si jẹ oore fun un. Ti inira ba de yoo si se suuru, eyun un naa yoo si jẹ oore fun un.

·   وعن صهيب الرومي رضي الله عنه قال قال رسول الله صلى الله عليه وسلم عجبا لأمر المؤمن إن أمره له كله خير وليس ذلك لأحد إلا للمؤمن إن أصابته سراء شكر فكان خيرا له وإن أصابته ضراء صبر فكان خيرا له. رواه مسلم.

 

·        Tobari bẹẹ, olugbagbọ ododo, ni igba ti isoro bade, yoo se suuru bakannaa yoo si yọnu ni ẹni ti n rankan adehun oluwa fun awn onisuuru.

·        Oluwa wipe:

{إِنَّمَا يُوَفَّى الصَّابِرُونَ أَجْرَهُمْ بِغَيْرِ حِسَاب}.

"A maa n san awn onisuuru ni ẹsan wọn ti ko ni onka".

Oluwa tun wipe:

{وَبَشِّرِ الصَّابِرِينَ (155) الَّذِينَ إِذَا أَصَابَتْهُمْ مُصِيبَةٌ قَالُوا إِنَّا لِلَّهِ وَإِنَّا إِلَيْهِ رَاجِعُونَ (156) أُولَئِكَ عَلَيْهِمْ صَلَوَاتٌ مِنْ رَبِّهِمْ وَرَحْمَةٌ وَأُولَئِكَ هُمُ الْمُهْتَدُونَ (157)}.

 "Fun awn onisuuru ni iro idunnu, awn ti o se pe , ni igba ti musiiba ba kan wn, ti wn yoo sọ pe 'ọdọ Oluwa ni a ti wa bẹẹ si ni ọdọ Rẹ naa ni ibusẹrisi wa. Awn ẹni wnyi ni ikẹ ati igẹ oluwa n bẹ fun bakannaa ẹni imọna ni wn nse".

·        Amọ musulumi ko gbọdọ maa rankan adanwo nitoripe ko m boya yoo le ni atẹmọra lori adanwo ti o n rankan.

·        Idi niyi ti Anaabi (صلى الله عليه وسلم) fi kọ fun Abas lati tọrọ adanwo sugbn pe ki o tọrọ Alaafia (Amojukuro)…(Ahmad ati Bukhari).

·        Muaasu bun Rafa’a wipe Abu bakr wipe: Anaabi (صلى الله عليه وسلم) duro ni ori minbari ni ẹni ti n sunkun pẹlu pe n sọ pe: ẹ bere amojukuro ati idanisi kuro nibi wahala lọdọ Ọlọhun nitoripe ko si ohun ti o tun dara lẹyin amọdaju ju gbigbe ni jinna si adanwo lọ.

·   وعن معاذ بن رفاعة عن أبيه قال : قام أبو بكر الصديق على المنبر ثم بكى فقال : قام فينا رسول الله صلى الله عليه وسلم عام أول على المنبر ثم بكى فقال : (سلوا الله العفو والعافية فإن أحدا لم يعط بعد اليقين خيرا من العافية).

                                                                                        

·        Ẹsunmo Ọlọhun ni igba idẹra nitoripe yoo ma san yin ni ẹsan rẹ lọ gbere ni igba ti ẹ ba jẹ alaisan tabi se irin ajo.

Annabi (صلى الله عليه وسلم) wipe: ti ẹru kan ba se aisan tabi jẹ onirin- ajo oluwa yoo maa kọ isẹ daada ti o maa n se ni akoko ti ko se aisan tabi ni igba ti ko se irin ajo.

وعن أبي موسى رضي الله عنه قال : قال رسول الله صلى الله عليه وسلم : (إذا مرض العبد أو سافر كتب له مثل ما كان يعمل مقيما صحيحا). رواه البخاري وأبو داود.

Bakannaa Oluwa pasẹ mimọ ki irun ni asiko ti o yẹ nitori pe ninu isesi musulumi ni ki o ma se fi irun lọra kuro ni akoko rẹ.

 

Oluwa wipe:

} وَالَّذِينَ هُمْ عَلَى صَلَاتِهِمْ يُحَافِظُونَ (34) أُولَئِكَ فِي جَنَّاتٍ مُكْرَمُون {المعارج : 34 ، 35

"Awn ti wn maa n ki irun wn deedee, ti wn n maa n sọ akoko irun wn, awn yẹn yoo wa ni ipo apọnle ni ọgba idẹra, Alijanna" .

·        Ọmọniyan gbọdọ ko akolekan akoko irun ti ko si nii gba akoko irun kan laye tabi lọọ  laara ni iwn ìgbà ti laakaye rẹ o ba yẹ.

·        Oluwa sọ nipa Anaabi Isa ọmọ Mọriyamọ pe:

{وَأَوْصَانِي بِالصَّلَاةِ وَالزَّكَاةِ مَا دُمْتُ حَيًّا}

 "Oluwa pa mi lasẹ irun ati Sakah ni iwn ìgbà ti mo ba n sẹmi".

·        Ko lẹtọ rara ki a gbe irun ju silẹ laiki ni gbogbo aye-kaye ti a ba wa, ni iwn igba ti laakaye si n sisẹ.

Olori majẹmu gbigba irun ẹda  ni Imra. Oluwa sọ pe: وَثِيَابَكَ فَطَهِّر [المدثر : 4] "Atipe ki o mọ asọ rẹ".

 Annabi (صلى الله عليه وسلم)fun wa ni iro nipa awn oku meji ti wn n fi iya saare jẹ, o ni se ẹ ri ohun ti o se okunfa iya wn kii se ohun ti o tobi sugbn ọkan ninu wn kii se imra ni igba ti o ba tọ…(Bukhari).

·        Annabi (صلى الله عليه وسلم) sọ pe : ẹ sọra fun itọ nitoripe ohun ni sababi iya inu saare julọ

. وعن ابن عباس رضي الله عنهما قال قال رسول الله صلى الله عليه وسلم :  (عامة عذاب القبر في البول فاستنزهوا من البول)

·        Annabi (صلى الله عليه وسلم) tun wipe 

 (لا تقبل صلاة أحدكم إذا أحدث حتى يتوضأ)) أخرجه مسلم من حديث أبي هريرة t

"Oluwa ko ni I gba irun ẹni ti o ba se ẹgbin titi ti yoo fi se aluwala"(Muslim lo gbaa wa).

·        Ki a se imọra asọ, ara ati aaye ti a o fi se ijọsin jẹ ara mojẹmu irun.

Sugbn ẹni ti ara rẹ o ya le kagara mimu awn mojemu yii wa, bi o ti tọ.

Ẹni ti ko ba le se imra funraa rẹ wn le baa se, lati le se ijọsin. Amo ẹni ti ko ba le lo omi rara anfani wa funun  lati se imra eleepẹ (Tayammọmu). Oluwa ni :

{وَإِنْ كُنْتُمْ مَرْضَى أَوْ عَلَى سَفَرٍ أَوْ جَاءَ أَحَدٌ مِنْكُمْ مِنَ الْغَائِطِ أَوْ لَامَسْتُمُ النِّسَاءَ فَلَمْ تَجِدُوا مَاءً فَتَيَمَّمُوا صَعِيدًا طَيِّبًا }.

 " …ti ẹ ba se afẹku omi, ki ẹ se tayamọmu (Aluwala Eleepẹ)."

·        Ni igbamiran eniyan le ni ọgbe lara ti o le kọdi rẹ lati ma lo omi ni gbogbo igba. Ohun ti o le se ni wipe ki o maa fi bi asọ si oju egbò naa tabi nkan miran ki o le ni anfani ati pa oriirẹ lasan laifi omi kan oju egbò naa tabi ki o kuku se Aluwala Eleepẹ.

·        Abdullọh bun Abbas (ki Oluwa yọnu sii) s wipe : okunrin kan ni ọgbe, ni aye Anaabi (صلى الله عليه وسلم), o wa la ala janaba, wn wa paa lasẹ pe ki o wẹ pẹlu omi, lyinnaa ni okunrin naa ku. Nigbati Anaabi (صلى الله عليه وسلم) gbọ si ọrọ na o wipe : ẹyin ni ẹ pa. Oluwa yoo pa ẹyin naa,’se oluwa ko ti se ògùn aimkan ni ibeere nibi  ?…(Abu Dawood)

·        Bakannaa dandan ni irun j fun alaisan ni iwn igba ti laakaye rẹ n sisẹ. Am o le kirun ni iduro ti o ba rọrun abi ki o fi ara ti ogiri tabi ki o tẹ ọpa.

·        O ni anfani ati ki irun ni ijoko tabi idubulẹ koda bi ko kọju si “Kibla”.ko da o le kii ni ẹni ti o fi ipakọ le lẹ.

·        Imran Ibn Husain wipe : ailera kan mu mi mi wa beere lọwọ Annabi (صلى الله عليه وسلم) nipa irun, o wipe : ki n duro kirun, ti mo ba lagbara lati se bẹẹ, tabi ki n joko ti n o ba le duro,  tabi ki n fi ẹgbẹ lelẹ ti mi o ba le joko …(Bukhari  ati Muslim).

عن عمران بن حصين t قال: (كانت بي بَوَاسير ، فسألت رسولَ الله صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ ؟ فقال : "صلِّ قائماً ، فإنْ لم تستطعْ ؛ فقاعداً ، فإن لم تستطعْ ؛ فعلى جنبٍ". متفق عليه .

 

·        Alaisan tun le kirun plu mimi ori lasan, ti yoo rẹ ori nilẹ diẹ fun rukuu, ti yoo si rẹẹ nilẹ pupọ fun sujuud, ti ko ba le gbe ara rara. Eleyi naa ni ẹri ninu  Hadiisi Annabi (صلى الله عليه وسلم) : Bi o ba wa jẹ pe o ko le tun kirun pẹlu mimi ori, kii pẹlu didi oju. Wa di oju diẹ fun ruku’u bakana o dii gan fun sujuudu. Ọpẹ ni fun Ọlọhun ti O se ẹsin Isilaamu ni irọrun fun wa to bẹẹ gẹẹ.

·        Sugbn bi awn alaisan kan se ma n kirun pẹlu itọka pẹlu ọwọ wọn nikan ko ni ẹri kankan.

Ẹyin ẹrusin oluwa, ẹ lọ mọ pe Oluwa ti se irun kiki ni ọranyan fun gbogbo ẹda Rẹ, lo pin igba ti ẹmi ba wa ti laakai ko si daru.

 

 

·        Dida oju kọ kibla jẹ mojẹmu irun kiki. Ko si ẹsẹ fun ẹni ti o kagara ati da oju kọ gabasi lati ki irun bi o ti se rọọ lọrun.

·        Ẹni ti ko le da omi ẹgbin kuro ni ara abi asọ ati aaye ti yoo ti ki irun latari aarẹ, ko si ẹsẹ fun un ki o ki irun naa bi o ti lagbara. Oluwa ni O ni m jul.

·        O se pataki ki gbogbo awn ti wn duro ti alaisan ni inu ilé bi ilé iwosan paya Ọlọhun lati maa ran awn alaisan wnyi lọwọ lati maa kirun ni gbogbo akoko irun ni pataki julọ ẹni ti o ba ni ẹbi ti n se aisan naa gbọdọ paya Ọlọhun wn lati maa ran wn lọwọ lori bi wn yoo se maa kirun ni asiko r. Oluwa ni: “pa asẹ irun kiki fun awn ara ilé rẹ”.

وَأْمُرْ أَهْلَكَ بِالصَّلَاة [طه : 132]                                

Bakannaa awn olutọju alaarẹ (Dokita )  naa gbọdọ ko akosọkan mimaa ran awn alaisan lọwọ ati maa kirun plu gbogbo iranlọwọ ti yoo fi rọrun fun wn.

Awn ti wn sọ akoko irun wn, ni awn ti yoo jogún alujanna ti o fi n ga jul (Firidausi) ti wn yoo si maa wa ni bẹ lọ gbere.

·        Abẹ Olu`wa ki o se wa ni ẹni ti yoo le maa sọ awn akoko irun ti yoo si le maa mu wa plu awn mjmu wn. (Amin).

فاتقوا الله – عباد الله – وتعلّموا من أحكام دينكم ما تمكنون به من أداء ما أوجب عليكم خصوصا أحكام الطهارة التى هي شرط من شروط الصلاة وهي تتكرّر عليكم فى اليوم واليلة خمس مرات فإن الطهور شطر الإيمان واشكروه أن يسّر لكم طريق العبادة ثم سلوه القبول. وصلّوا وسلّموا على رسول الله المحب لكم الخيرات وقد أمركم الله تعالى بذلك فى كتابه، قال تعالى:"إن الله وملائكته يصلون على النبي يأيها الذيمن آمنوا صلّوا عليه وسلّموا تسليما".

 

          Nipari, je ka bru Ọlọhun, ki a si paya R ni kk ati ni gbangba, bẹẹni ki si lọọ wa im to kun nipa idajo sin yin, lodiwn ti o le maa fi sin Ọlọhun yin nirọrun, ni pataki jul, awn idaj sin to jm imra, ti o j majmu ti irun yoo o fi ni alaafia, to tun j idaji ìgba Ọlọhun gb. Ki si tun maa dup ld Ọlọhun tó r sin naa fun yin, bẹẹni ki si maa tr lw R ki o two gbaa lsin fun yin. Bakannaa ni ki maa se asalatu lp yanturu fun ojis Ọlọhun to nif si ki oore maa j tiyin, Ọlọhun gan an til ti pa yin lasẹ r. Ọlọhun s pe: “Dajudaju Ọlọhun ati awn Malaika R n fi ibukun fun Annbi. Ẹyin ti gbagb ni ododo maa tr ibukun fun un. Ki si maa kii ni kiki alaafia”. Ki Ọlọhun bani sek seg fun Annabi wa naa ati awn sahabe r, bakannaa awn arole anabi ti wn j afinimna toot: Abu bakr, Umaru, Usman, ati Aliyu tofi dori awn Sahabe to sku, ki Ọlọhun ma si y enikọọkan wa naa sil ninu ik ati ig naa.