Eko ni soki

Osu Ramadan je osu nla, osu ti awon ilekun alujanna maa ndi sisi sile, ti awon ilekun ina si maa ndi titi pa, dajusaka, Olohun ti sadayanri osu yi pelu alekun ajulo nigbati o fi oru kan ti o loore ju egberun osu lo sibe, eleyi ni oru lailatul kodiri, ohun naa ni oru kan ninu awon oru ojo mewa igbeyin,lati ara be ni Anabi( Ki ike ati ola Olohun maa ba) se maa ngbiyanju eleyi ti ko ni afiwe nibi mewa igbeyin lati lee ri oru naa, ti o ba je bee, o dowo musulumi lati maa se ojukokoro ti o lagbara lori iroro awon oru alalubarika naa , paapaajulo ise atipo nile Oluwa(Al-ihtikaf) o je okan ninu awon ise ti o lola julo ninu awon oru wonyii.

Awọn erongba lori Khutuba naa:

1.         Riran awọn eniyan leti i ọla ti o wa fun awọn ọjọ mẹwa ti o gbẹyin Ramadan;

2.         Sise alaye sunnah awọn ọjọ naa;

3.         Mimu isunmọ Ọlọhun ni agbara, ati gbigbani ni iyanju ati maa sunmọ Ọlọhun.

 

Khutubah Alakọkọ (ogun isẹju):

الحمد لله ربّ العالَمين القائل في محكم تنزيله: {إنا أنزلناه في ليلة القدر . وما أدراك ما ليلة القدر . ليلة القدر خير من ألف شهر . تنزّل الملائكة والرّوح فيها بإذن ربّهم من كلّ أمر . سلام هي حتّى مطلع الفجر}. والصّلاة والسّلام على رسول الله القائل: ((مَن صام رمضان إيماناً واحتساباً غُفِرَ له ما تقدّم مِن ذنبه. ومَن قام ليلة القدر إيماناً واحتساباً غُفِرَ له ما تقدم مِن ذنبه)). وقال صلّى الله عليه وسلّم: ((تحروا ليلة القدر في الوتر من العشر الأواخر من رمضان)). وبعد؛

Ọla ti o wa fun awọn ọjọ mẹwa ti o gbẹyin Ramadan, ati alaye igbiyanju Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ni inu wọn pẹlu awọn ara ile rẹ (awọn iyawo ati ọmọ).

Ẹyin ẹrunsin Ọlọhun! ẹ bẹrun Ọlọhun, ibẹrun Ọlọhun ni o dara ju ni nkan ti eniyan fi n pamọ, oun si ni o pe ju lati se afihan rẹ, oun naa si ni o ni ọla ju ti eniyan yoo lọ lee deba, ki Ọlọhun ran wa lọwọ ki a le bẹru Rẹ bi o ti tọ ati bi o ti yẹ, ki O si fun wa ni laada rẹ. Ki a se iranti ọjọ kan ti yoo kuwa ku isẹ ọwọ wa. Gẹgẹbi ọrọ Ọlọhun:

:{ يَوْمَ تَجِدُ كُلُّ نَفْسٍ مَّا عَمِلَتْ} [آل عمران: 30].

Ẹyin musulumi ododo, awọn ọjọ awẹ n lọ diẹdiẹ, ti awọn oru abiyi rẹ si n dinku, awọn isẹ daada ti ẹ se ni inu rẹ wa ni akọsilẹ ti ẹ o lọ lee de ba ni ọjọ ikẹyin. Ki olugbiyanju fi kun igbiyaju rẹ, ki awọn miran naa ma se afira. Oorun ti o ku ni oke o to sa asọ. Ọjọ mẹwa ti o sẹ ku ni inu osu yi; osu Ramadan o to lati se isẹ rere. Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) a maa gbiyanju pupọ ni inu osu Ramadan, a tun maa fi kun igbiyanju rẹ ni inu awọn ọjọ yi. Ni inu awọn ogunjọ ti o ti si waju, Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) a maa lo wọn pẹlu gbigba awẹ ni ọsan ti o si maa n sun ni oru wọn, sugbọn ni ọjọ mẹwa igbẹyin a maa jinna si ibusun rẹ, a si maa ji awọn ara ile rẹ pẹlu, kódà a maa kan ilẹkun Fatimọ ọmọ rẹ ati 'Ali ọkọ rẹ pẹlu, ti yoo si maa wi fun wọn pe: se ẹ ko ni dide ki ẹ kirun ni bi?! Yoo maa kan ilẹkun ni ẹni ti n ka ayah Al-Kuran yi:

{وَأْمُرْ أَهْلَكَ بِالصلاةِ وَاصْطَبِرْ عَلَيْهَا لاَ نَسْأَلُكَ رِزْقاً نَّحْنُ نَرْزُقُكَ وَالْعَاقِبَةُ لِلتَّقْوَى} [طه: 132].

{Pa awọn ara ile rẹ ni asẹ irun, ki ọ si se suuru ni ori rẹ, Awa ko ni beere arisiki ni ọwọ rẹ, A wa ni A n se jijẹ ati mimu fun ọ, dajudaju ti olubẹru Ọlọhun ni igbẹyin adun} [Tohah: 132].

Lẹyin naa ni yoo gba iyara awọn iyawo rẹ lọ, ti yoo maa pasẹ pe: Ẹ ji awọn ti wọn wa ni inu awọn iyara yi, melomelo ni ẹni ti o wọ asọ ni aye, ti o si se wipe ihoho ni yoo wa ni ọjọ igbende (Al-kiyamọ).

Ninu awọn sunnah awọn ọjọ yi ni; igbiyanju idide ni oru, dajudaju ohun ti wọn yoo beere lọwọ musulumi ni awọn irun ọranyan, sugbọn kinni o fi da eniyan ni oju wipe awọn irun ọranyan yi pe perepere? Dajudaju Musulumi ni bukata si awọn nafila wọnyi lati lekun awọn ọranyan rẹ.

Ninu Hadith Kudusi ti Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) gba wa ni ati ọdọ Ọlọhun wipe: "Oluwa wa sọ pe: ẹ wo irun ẹru mi, n jẹ o kii pe tabi o dinku? Ti o ba pe, wọn yoo kọ fun un pe , ti o ba dinku, Ọlọhun yoo wipe: ẹ woo, njẹ ẹru mi ni nafila bi? Ti wọn yoo si pe isẹ rẹ pẹlu rẹ(nafila)". [Abu Dauda gba ẹgbawa rẹ].

Bakannaa ni gbogbo Musulumi gbọdọ maa kọ ise Annabi (صلّى الله عليه وسلّم), gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti sọ wipe:

{لقد كان لكم في رسول الله أسوة حسنة لمن كان يرجو الله واليوم الآخر} [الأحزاب: 21].

{Dajudaju awokọse ti o dara wa fun yin lati ara Ojisẹ Ọlọhun fun ẹnikẹni ti o ba n rankan Ọlọhun ati ọjọ ikẹyin}, [suratut-Al-Ahzaab: 21].

Ni inu awọn ọla osu yi ni sise kongẹ oru èbùbù (Laelatul Kọdir), oru abiyi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ nipa rẹ wipe:

{ليلة القدر خير من ألف شهر} [ القدر : 3 ].

{Oru èbùbù  (Laelatul Kọdir) ni oore ju ẹgbẹrun osu miran lọ}, [suratul-Kọdir: 3].

Ọkan ni inu awọn agba oni mimọ ti orukọ n jẹ Imamu Nakha'i sọ pe: Isẹ kan soso ni inu oru yii ni oore ju isẹ ti eniyan se fun ẹgbẹrun osu miran ti ko si oru abiyi ni ibẹ lọ. Ẹyin ẹru Ọlọhun! ẹ ranti pe ẹgbẹrun osu se deede ọgọrin ọdun ati ọdun mẹta, ati osu mẹrin. Itumọ eleyi nipe isẹ ẹyọkan ni inu oru yii ni oore ju isẹ ọgọrin ọdun ati ọdun mẹta, ati osu mẹrin lọ.

O tun wa ni inu Sahih Bukhari ati Musilimu Hadith ti Abu Hurairah gba wa ni ati ọdọ Ojisẹ Ọlọhun pe: "Ẹnikẹni ti o ba dide ni oru èbùbù (Laelatul Kọdir) pẹlu igbagbọ, ti o si n wa ẹsan ati ojurere Ọlọhun, wọn yoo fi ori gbogbo ẹsẹ ti o ti kọja jin in". Oru yi jẹ ọkan ni inu awọn ọjọ mẹwa ti o gbẹyin osu Ramadan. Eyi ti o rinlẹju ni ki onigbiyanju wa oru naa si aarin mẹwa igbẹyin ninu Ramadan.

Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pa imọ oru abiyi mọ fun awọn ẹru Rẹ ki wọn le maa lekun ni igbiyanju wiwa osu naa ni inu awọn ọjọ mẹwa ti o ni ọla yi, pẹlu irun, iranti Oluwa ati adua ti wọn yoo si lekun ni isunmọ Ọlọhun. Bakannaa lara awọn ẹkọ ti o wa lara pipamọ imọ oru yi ni ki o le jẹ idanwo fun awọn ẹru Ọlọhun lati mọ taa ni yoo gba iyanju lori wiwa rẹ, ti yoo si se oju kokoro lori rẹ, yatọ si ẹni ti yoo ko agara, ti yoo si se ọlẹ lati waa. Dajudaju ẹni ti o ba se oju kokoro nkan yoo sa ipa ati igbiyanju lati waa.

Ninu awọn ami oru èbùbù ni: orun ti yoo yọ ni owurọ ọjọ naa yoo funfun gboo, ti ko ni ta eniyan lara. Ami yi wa lẹyin igbati asiko oru yii ti kọja, eleyi ri bẹẹ ki Musulumi le lekun ni igbiyanju lati waa ni.

Bakannaa, ẹri wa ni inu Sunnah pe a le mọ oru abiyi yi pẹlu ala ti o dara. Gẹgẹ bi o ti wa ni inu sahihu Bukhari ati Musilimu wipe awọn ara kunrin kan ni inu awọn saabe Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ri ni oju orun wipe ọjọ oru abiyi wa laarin awọn ọjọ meje ti o kẹyin osu Ramadan, Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) si wipe: mori ala yin pe o se dede ọjọ meje ti o kẹyin osu Ramadan, ẹnikẹni ti o ba n wa oru abiyi naa ki o ya waa si ọjọ meje ti o kẹyin osu Ramadan. Kódà Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) paapa ri asiko oru abiyi (Laelatul Kọdir) yi ni oju ala, sugbọn o pada gbagbe rẹ (gẹgẹ bi Oluwa ti fẹ bẹẹ). O si wipe: ẹ waa si aarin mẹwa igbẹyin, dajudaju mo ri pe mo n fi ori kanlẹ ni ori omi ati ori amọ. Saabe ti o gba Hadith yi wa (Abu Sa'id رضي الله عنه) sọ pe: Mo ri Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) ti o fi ori kanlẹ ni ori omi ati amọ. O fi kun un wipe: kódà mo ri apẹẹrẹ amọ ni iwaju rẹ. [Sahihu Bukhari].

Al-I'itikafu: Ninu awọn isẹ lada ti o wa ni inu awọn ọjọ yi ni sise ikoraduro – Al-I'itikafu ni mọsalasi. Lati ko ara duro fun isunmọ Ọlọhun ati lati sin In. Wo [suratul Baqarah: 187].

{ولا تباشروهن وأنتم عاكفون في المساجد} [البقرة 2: 187].

Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sọ wipe: "ẹni ti o ba se i'itikafu pẹlu emi –Annabi- ki o see ni ọjọ mẹwa igbẹyin Ramadan, wọn ti fi oru naa han mi, sugbọn wọn tun gbami ni agbe rẹ". O tọ fun ẹni ti o ba ni gbara ati dide ni oru yi ki o se oju kokoro rẹ ni itori laada ti o wa nibẹ.

Ẹni ti o n se I'itikafu ti ko ara rẹ duro fun ijọsin fun Ọlọhun ati sise iranti Rẹ, ti o si jinna si gbogbo isẹ ti o le ko airoju baa. Dajudaju itumọ Al-I'itikafu ni gige ibasepọ pẹlu awọn eniyan, ni itori ibasepọ pẹlu Ọlọhun.

Bakanna, gbigbiyanju lati maa ke Al-Kuran ni ọpọlọpọ. Kódà eleyi jẹ ilana (Sunna) Maleka Jibril pẹlu Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) ni inu osu awẹ. Tori pe Jibril a maa ke Al-kuran fun Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ni gbogbo ọdọọdun ni inu Ramadan, ni igbati ti odi ọdun ti o kẹyin ni igbesi aye Annabi, ẹẹmeji ọtọọtọ ni Jibril ke Al-kuran fun Annabi (صلّى الله عليه وسلّم). [Sahihu Bukhari ati Musilimu].

Bakannaa ni mi maa ta ọrẹ ni ọpọlọpọ ni inu awọn oru yii. O fi ẹsẹ rinlẹ pe Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) a maa ta ọrẹ ju awọn eniyan lọ, sugbọn o tun maa n ta ọrẹ pupọ ni igbati o ba pade Jibril, ti yoo kọ ni Al-Kuran, Jibril si maa wa n ba ni gbogbo alẹ Ramadan ti yoo si kọ ni Al-kuran. Ni igbati Jibril n pade Annabi yii a maa ta ọrẹ ju atẹgun ti a ran ni isẹ tabi tu silẹ lọ. [Bukhari ati Musilimu].

 


 

 

الحمد لله ربّ العالَمين. والصّلاة والسّلام على رسول الله وبعد؛ عباد الله!

Ninu awọn ẹri fun ọla Al-'Itikafu nipe:

1.   Dajudaju oru kan n bẹ ni inu awọn ọjọ mẹwa igbẹyin ti o ni oore ju ọgọrin ọdun o le ọdun mẹta lọ ti ko si oru abiyi yi ni inu wọn. Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) a maa se 'Itikafu ni awọn ọjọ igbẹyin Ramadan ni ẹniti n rankan ki ohun se kongẹ oru naa. Kódà o se I'itikafu ni mẹwa akọkọ ati mẹwa ti aarin, ni ẹyin naa ni o wa yọ ori rẹ si awọn eniyan ti o si bawọn sọrọ ni igbati wọn sun maa pe: mo se Al-i'itikafu ni mẹwa akọkọ ti mo n wa oru yii, ni ẹyin naa mo see ni mẹwa ti aarin, ni ẹyin naa ni wọn wa bami ti wọn si wi fun mi pe: oru naa wa ni inu mẹwa igbẹyin, nitori naa, ẹnikẹni ti o ba wu lati se i'itikafu, ki o yaa se e.

1-     Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ko fi Al-I'itikafu silẹ ni awọn ọjọ mẹwa igbẹyin Ramadan, ti o si maa nse Al-I'itikafu ni ọjọ mẹwa ni gbogbo ọdọọdun, sugbọn ni ọdun ti o ku (صلّى الله عليه وسلّ) ogun ọjọ ni o fi se Al-I'itikafu. Eyi un nikan kọ, awọn iyawo rẹ paapa tun se alapantete sise Al-I'itikafu, igba naa ni Annabi fi Al-I'itikafu silẹ ni mẹwa igbẹyin, ti o si pada san an pada ni mẹwa akọkọ ni inu osu Shawal (osu kẹwa oju ọrun, eyi ti o tẹle Ramadan) [Bukhari];

2-     Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) a maa fi nkan ti o jẹ ẹtọ fun un gẹgẹ bi orun ati awọn iyawo rẹ silẹ ki o le se Al-I'itikafu ni awọn ọjọ igbẹyin Ramadan;

3-     Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ni igbamiran a maa se nkan ti o se ni ewọ fun awọn ijọ rẹ, gẹgẹ bi awẹ agbayipo, bẹẹ Annabi a maa gba, papa julọ ni awọn ọjọ mẹwa, bakannaa ni Annabi kọ funwa mi maa da oorun mọju ni gbogbo oru, sugbọn Annabi da oorun mọju ni oru yi, ni titori pe Oluwa paa ni asẹ bẹẹ, gẹgẹ bi iyawo rẹ ti o mọọ julọ se sọ;

4-     Awọn iyawo Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) naa se Al-'Itikafu ni awọn ọjọ igbẹyin Ramadan pẹlu Annabi ati ni ẹyin rẹ, kódà iya nla wa 'Aishat (رضي الله عنها) sọpe obinrin kan ni inu awọn iyawo Annabi ti o wa ni asiko ẹjẹ awọọda (Istihadah) se i'itikafu pẹlu Annabi.

Ninu awọn aala ati idajọ Al-I'itikafu:

1-     Ọranyan ni ki ẹniti o n se I'itikafu tẹle awọn ilana rẹ.

2-     Ko pọn dandan ki ẹni ti o daniyan I'itikafu ki o pari rẹ, kódà o le jaa, paapajulọ ti o ba n bẹru karimi;

3-     Ko si Hadith ti o fi ẹsẹ rinlẹ lori ọjọ ti o kere ju fun I'itikafu;

4-     Ki ẹni ti o fẹ se 'Itikafu bẹrẹ ki orun to wọ ni o dara, eleyi ni ọrọ awọn Imamu mẹrẹẹrin (Abu Hanifah, Malik, Shafi'i ati ibn Hambali);

5-     O dara ki ẹniti o n se I'itikafu mu aye kan fun ara rẹ ni inu Masalasi;

6-     Ko si laifi ki ẹniti o n se 'Itikafu parọ aye rẹ ni inu Masalasi, sugbọn eyi ti o dara ju ni ki o wa ni aye kan, ki o lee kọ se Annabi, ati nitori ọrọ Annabi ti o ni: awọn Malaikah yoo maa se adua fun ẹni kọọkan yin lopin igbati o ba si wa ni ibukirun rẹ;

7-     Mẹta ni ijade kuro ni inu Masalasi pinsi:

a)     jijade ti o tọ, ohun naa ni jijade fun nkankan ti o se ọranyan ni inu ẹsin, tabi adamọ, bii irun jimọ, tabi lati lọ jẹun ati mu omi;

b)     jijade fun isẹ ti ko jẹ ọranyan lori rẹ; gẹgẹ bi jijade lati lọ bẹ alaarẹ wo, tabi isinku, ayafi ti o ba se majẹmu rẹ ki o too bẹrẹ I'itikafu ni o to ni ẹtọ ati jade fun iru awọn idi bayi;

8-     jijade fun nkankan ti o tako I'itikafu, gẹgẹ bi jijade kuro ni inu masalasi lati lọ ta ọja tabi ra ọja, tabi ni asepọ pẹlu iyawo rẹ, ti o ba se bẹẹ 'Itikafu rẹ ti bajẹ.

Mo pe iwọ ti o gbiyanju ni ipilẹ, ti o wa n fi awọn oru igbẹhin sere, ati gbogbo awọn onigbagbe, ẹ yara taji. Bakannaa ni mo pe iwọ oni sunnah, ẹ taji. Mo pe gbogbo awọn ti wọn ri iyanju gba, o di ọwọ yin, ẹ ma se gba itanjẹ, ki ẹ si ma se jẹ ki isẹyin jọyin ni oju. Ki ẹ mọ wipe kongẹ Oluwa ati aanu Rẹ ni ẹ fi  rii se.

Ni ipari ki a ranti pe iya nla wa 'Aishat (رضي الله عنها) ti o tun jẹ iyawo Annabi, o bi Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) leere wipe: ti oru abiyi (Lailatul Kọdir) ba bami ni aye, ki ni ki n maa wi ni oru yi ni? Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) paa ni asẹ ki o maa wipe: ((اللهم إنك عفو تحب العفو فاعف عني). "Iwọ Oluwa mi, dajudaju Iwọ ni Alamojukuro, ti O si fẹran amojukuro, se amojukuro fun mi".

اللهم وفّقنا بتوفيقك وسدّد خطانا لِما تحب وترضى، واجلعنا من الذين يستمعون القول فيتّبعون أحسنه. وصلّى الله على نبيّنا محمّد وآله وصحبه وسلّم.