AGBỌYE ÌJỌSÌN NÍNÚ ISLAM

Eko ni soki

Dajudaju, agboye ijosin ninu esin Islam je agboye alakotan ti o ko gbogbo daadaa ninu alaamori esin ati aye sinu, paapaa ijosin je oruko kan ti o ko gbogbo awon gbolohun ati awon ise eleyiti Olohun ni ife si ti o si tun yonu si sinu, atiwipe musulumi ni aye yi, yio mo ni ododo wipe erusin Olohun ni oun se niti erusin tooto, yio si maa sise too ise ijerusin naa ni ododo ki o le ba je erusin tooto fun Oluwa re,iyi ati ola re yio maa je ijerusin Olohun oba, yio maa tele awon ase Olohun yio si maa jinna si awon eewo re nibi gbogbo alaamori esin ati aye re.


Erongba khutuba:

1.      Sise alaye titori ohun tỌlọhun fi da ẹda

2.      Sise alaye lakotan nipa agbọye ìjọsin nínú Isilaamu

3.      Sise afihan awọn orisirisi ìjọsin to nbẹ ninu Isilaamu.

4.      Sise alaye nipa pé ẹniba se nkan ẹtọ kọlọhun le san an lẹsan yoo ri ẹsan nàá gba.

الحمد لله رب العالمين أكمل لنا الدين وأتمّ علينا النعمة ورضي لنا الإسلام دينا , وأمرنا بالتمسك به إلى الممات . وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لاشريك له ونحن له مسلمون , وأشهد أن محمدا عبده ورسوله الصادق المأمون , أنزل الله عليه " واعبد ربّك حتى يأتيك اليقين".

اللهم صلّ على عبدك ورسولك نبينا محمد وعلى آله وأصحبه أجمعين  وسلم تسليما كثيرا.

A da ọpẹ fun Ọlọhun ọba to sẹda gbogbo agbanla aye, o da wa ki a lee maa jọsin fun Un bẹẹni o pawa lasẹ titẹle asẹ Rẹ. mo jẹri pe ko si ẹnikẹni ti isin ododo tọ si ayafi Ọlọhun nikan ko lorogun ko lẹgbẹra, mo si jẹri pe Annọbi wa Muhammadu ẹrusin Ọlọhun ni, ojisẹ Rẹ si ni. Oun ni o pe julọ ni ijọsin fỌlọhun ati ibẹru Rẹ. O pepe si oju ọna Ọlọhun, o si jagun ẹsin niti papa jijagun, o sin Ọlọhun debi wipe ẹsẹ abiyi rẹ mejeeji fi wu ti o si la pẹpẹpẹ, latari pipẹ ninaro nibi ijọsin fỌlọhun, ikẹ ati igẹ Ọlọhun ki o maa ba ati awọn ara ile rẹ ati awọn ẹmẹwa rẹ lapapọ.

Ọlọhun da ẹda ki a le maa sin-in, wo suratu Sariyati 56.

"Atipe emi ko se ẹda alujọnu ati enia lasan ayafi ki wọn le maa sin Mi". ati Suratu Nisai: 36, bẹẹ ni o ran awọn Ojisẹ Rẹ lati máà fun wọn niro idunnu, kìwọn nilọ nipa aida ati lati salaye ohun ti o tori rẹ dawọn.

Ijọsin ni agbọye kan to kari, ipilẹ ijọsin ni sise afọmọ ẹsin fọlọhun, sisin lọhun nikan didari ọkan si ọdọ Rẹ, nini ìfẹ, bibẹrú, rírankan Rẹ, kikirun fun un ati mi maa kè pè e, nigba irọrun ati inira, gbara le e, gbe e tobi loun nikan, wo suratul lukumanu : 30

ذَلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ هُوَ الْحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدْعُونَ مِنْ دُونِهِ الْبَاطِلُ""

Gbogbo oore ayé ati tọrun ni agbọye ijọsin ko sinu, àní ijọsin ni orúkọ kan ti o kó gbogbo awọn ọrọ ati isẹ ti Ọlọhun nifẹ sii to si yọnu sii sinu.

Musulumi gba lododo pe ẹrusin Ọlọhun ni oun jẹ, yoo si maa se afimulẹ ijẹrusin fun un, ki o le jẹ ẹru tootọ fọlọhun rẹ, toripe iyi ati apọnle nbẹ nibi jijẹ ẹru Ọlọhun, ti yoo maa tẹle asẹ rẹ ti yoo si jinna si awọn ohun ti Ọlọhun kọ.

Ọlọhun kẹwa pupọ, pẹlu pe o se ijọsin loniran-nran ninu rẹ ni:

1.      Ijọsin àfọkàn se, lara rẹ si ni sisafọmọ ẹsin fọlọhun wa.

2.      Ijọsin ti a nfi ara se, oun ni ni irun wakati marun-un ojoojumọ

3.      Ijọsin afowose tii se saka yíyàn.

4.      Ijọsin ti a fi nko ara ro kuro nibi awon nkan igbadun, lati fi tẹle

asẹ Ọlọhun (awẹ gbigba).

5.      Ijọsin ti a nfi owo ati ara se; Hajii, rirele Ọlọhun lati jọsin fun-un.

          Gbogbo awọn ijọsin ti a sàlàyé wọnyi ni wọn jẹ ọranyan ti wọn situn ni nọfila tii se ènì tabi asegbọre ki a le ga nipo ati sise rere.

Jihadu - jijagun soju ọna Ọlọhun ni ipin to gaju lọ ninu gbogbo ipin ijọsin fọlọhun.

Ijọsin ko nii jẹ itẹwọgba lọwọ ẹda ayafi pẹlu majẹmu mèjí:

1.      Sise afọmọ ijọsin fun Ọlọhun ti konii ni sekarimi tabi sekagbọmi ninu.

2.      Ki ijọsin naa wa nibamu si ofin Ọlọhun ati ilana anọbi (S.A.W), lainii se alekun nkan kan, tabi se adadaalẹ, toripe gbogbo ọrọ ẹsin pata ni anọbi ti salaye rẹ. Ohun ti o ba si múwá ni ẹsin ododo ti eyan yoo gba ẹsan le lori, sugbọn ohun ti o ba yatọ sii, anù ni, wo suratul Kọsọsi: 50.

قال تعالى: "وَمَنْ أَضَلُّ مِمَّنِ اتَّبَعَ هَوَاهُ بِغَيْرِ هُدىً مِنَ اللَّهِ إِنَّ اللَّهَ لا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِين"

"Bẹ si ni ẹnikan ko sina ju ẹni ti o ba tẹle ifẹ inu rẹ lọ, laisi imọna kan lati ọdọ Ọlọhun wa, dajudaju Ọlọhun naa ko ni fi awọn ijọ alabọsi mọ ọna"

Gbogbo ígbòkègbodò ẹdá Nile aye yii, ni yoo maa wa nipo ẹsin ti a o gba laada le lori, lopin igbati o ba ti see lẹniti o fi nwa ojú rere Ọlọhun nikan. Daada to nse si obii rẹ, okùn ibi ti o ndapọ, owo ti o nna lori ọmọ ati iyawo rẹ, ati títọ ti o n tọ wọn, obinrin ti o fẹ lero ati kẹmi ara rẹ nijanu ati rirẹ oju silẹ kuro nibi wiwo ohun ti Ọlọhun se wiwoo rẹ leewọ, ijọsin ni gbogbo rẹ jẹ ti o o gba laada le lori.

          Jijinna si awon ohun ti Ọlọhun se ni èwọ, ati iwa pálapàla, Sise atunse laarin onija meji, to fi dori jijẹ mimu sisun ati bẹbẹẹlọ ninu awon nkan ẹtọ ni yoo wa nipo ẹsin ti o ba ti daniyan Sise rẹ lero ati ni agbara lati se ijọsin fọlọhun.

          Ìrẹ Musulumi, duro sinsin lori title asẹ Ọlọhun lalaini ko susú tabi kaarẹ

          Ma se jẹ ki o je pe èrò re ni ki o sá jọsin tabi ki ijọsin pari, sugbọn sapá lori bi o o se see dada pẹlu idunnu ati idara ya emi. Ojise Ọlọhun maa nsọ fun Bilal pe “Ẹ j ka fi irun wa ifọkanbal lọdọ Ọlọhun” O tun sọ pe “Wn fi itutu ojú mi sibi irun”.

          Toba ri bẹẹ a jẹ pe ijọsin ìwá ifọkanbalẹ ẹmi ati itutu ojú onigbagbọ ododo ni ti yoo maa se ijọsin naa tidunnu taraya, jẹ ki gbogbo ilọbibọ rẹ jẹ titori lọlọhun nikan, ki o le gbesan lori rẹ. Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: “Ẹsan rere mb fun niti o ba mba iyawo r lasepọ”. Awọn Sahabe sọ pe: Irẹ Ojisẹ Ọlọhun: bawo leeyan yoo se maa ba iyawo rẹ lasepọ ti yoo si maa gba laada?  Lojise Ọlọhun ba sọ pe: tọba loo sibi eewọ, sebi yo je ibalejọ buruku fun, bẹẹ naa ni toba mulọ sibi ẹtọ yoo je ẹsan rere fun-un.

          Ọlọhun maa sikẹ wa pupọ, awon nkan ẹtọ ati ígbádún tun di ohun ti a o ma gba laada le lori, yoo tun wa nipo pe, eeyan ntẹle àsẹ Ọlọhun kódà beeyan ba sún tabi o simi lerongba ki agbara rẹ le dọtun, ko le tun lagbara lati se isẹ rere yoo tun gba laada lee lori.

          Ojisẹ Ọlọhun se aseju ati itayọ-ala nibi ijọsin leewọ kódà nigbati iyawo Abdulohi bun Amru wa si ọdọ anọbi lẹniti o wa fi ẹjọ ọkọ re sun-un, nipa aseju rẹ nidi ẹsin, pe o maa nlo gbogbo òru rẹ fun nọfilat ati kika Kurani, ti o si n lo ọsan fun lati fi gba awẹ, Ojisẹ Ọlọhun kọ fun-un lati se bẹẹ, o wa wi fun un pe: Ọlọhun rẹ ni awọn iwọ kan lori rẹ, ẹmi rẹ naa ni iwọ lori rẹ, bẹni awọn ara ile rẹ naa ni iwọ lori rẹ, nipa bẹẹ gba awẹ mẹta ni gbogbo osù, ki o si fi idaji òru rẹ sun, ki o si fi ìdá kan ninu mẹta yan nọfila, ìdá kan ninu mẹta to sẹku sun, ki o si pari kurani ni ẹkan losu. Sugbọn nkan wọnyi ko tẹẹ lọrun ti o si nbeere alekun. Leyiti o ko súsú ati abamọ baa lágbà.

          Bakannaa ni ìjọsín ni iwọntun-wọnsi tun jẹ ilana Ojisẹ Ọlọhun, mama wa Aisha sọ pe: Ojisẹ Ọlọhun maa ngba awẹ lera lera depo ti a o fi sọ fun-un pe se ko ni tunu mọ, a si maa tunu (saigbaawẹ) titi ti a o fi sọ pe ko ni gba awẹ mọ.

          Nitorinaa, gbogbo adadasilẹ ti ko ba ofin ẹsin mu, ko lore ninu, sugbọn sise nkan laini se aseju tabi aseeto gan ni ilana ti Musulumi gbudọ maa tẹle toripe Ọlọhun bu ẹnu atẹ lu awọn Yahudi ati Nọsọra latari aseju wọn ninu ẹsin. Wo suratul Adiidi: 27.

قال تعالى: "ثُمَّ قَفَّيْنَا عَلَى آثَارِهِمْ بِرُسُلِنَا وَقَفَّيْنَا بِعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ وَآتَيْنَاهُ الْإنجِيلَ وَجَعَلْنَا فِي قُلُوبِ الَّذِينَ اتَّبَعُوهُ رَأْفَةً وَرَحْمَةً وَرَهْبَانِيَّةً ابْتَدَعُوهَا مَا كَتَبْنَاهَا عَلَيْهِمْ إِلَّا ابْتِغَاءَ رِضْوَانِ اللَّهِ فَمَا رَعَوْهَا حَقَّ رِعَايَتِهَا فَآتَيْنَا الَّذِينَ آمَنُوا مِنْهُمْ أَجْرَهُمْ وَكَثِيرٌ مِنْهُمْ فَاسِقُونَ"

            "Lẹhinnaa, a fi ọpọlọpọ ojisẹ Wa tẹle oripa wọn, A si mu Isa ọmọ Mọriyamọ tẹle wọn, A si fun ni tira injila, A si se aanu ati ikẹ sinu ọkan awọn ẹni ti o tẹle tirẹ, atipe asa ki a ma ni iyawo jẹ ohun ti wọn da silẹ, A ko si se ni ọranyan fun wọn bi ko ba se lati fi wa iyọnu lọhun, sibẹsibẹ wọn ko sọ bi o ti tọ ki wọn sọ ọ, nitorinaa, a fun awọn ẹni nwọn gbagbọ lododo ninu wọn ni ẹsan wọn. Sugbọn ọpọlọpọ ninu wọn jẹ obilẹjẹ".

Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: “Dajudaju eyiti Ọlọhun nifẹ si ju ninu is rere ni eyiti eeyan dunnim (tẹpamọ) daada kódà ko kere pọ”.

       Nitorinaa, isẹ to ba mọ niwọn, teeyan si n se ni gbogbo igba dara pupọ ju isẹ to pọ sugbọn ti eyan nse ni ẹẹkọọkan lọ.

       Mo bẹ Ọlọhun, ki o femi ati ẹyin se kongẹ oore aye ati tọrun, ki o si se amọna wa lọ sibi imọna gbogbo oore, tori Oun ni alagbara lori gbogbo nkan wo Suratul Fusilat 30 – 32.

       O jẹ ọranyan fun eniyan lati jẹ ẹru Ọlọhun, nitoripe jijẹ ẹru Ọlọhun iyi ni, ẹyẹ ni, apọnle ni kódà oriire ati erenjẹ nla si ni pẹlu, idi niyi to fi jẹ pe ẹru Mi (Ọlọhun) ni Ọlọhun, maa npe anọbi wa. Wo Suratul Jin 19.

"Atipe dajudaju nigbati ẹrusin Ọlọhun ba duro, ti o n ke pe E, nwọn a fẹ ẹ fun u pa (nibẹ)" Isirai 1 ati Alfurikoni 1.

          A jẹ pe gbogbo ẹniti o ba yin anọbi layinju to fi pee lỌlọhun ti wa lori asise ati adanu nla.


 

 

          Ijọsin fọlọhun idẹra nla ni ti ko si ẹniti o le mọ pataki rẹ ayafi ẹniti o ba safẹku rẹ, ẹ jẹka sewadi lọdọ awọn wayewaye ati awọn ti wọn ti saye rii, kinni abalọ-babọ wọn wo suratul Muhammad :12.

"إِنَّ اللَّهَ يُدْخِلُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ وَالَّذِينَ كَفَرُوا يَتَمَتَّعُونَ وَيَأْكُلُونَ كَمَا تَأْكُلُ الْأَنْعَامُ وَالنَّارُ مَثْوىً لَهُم".

            "Dajudaju Ọlọhun yoo jẹ ki awọn onigbagbọ ododo ti nwọn si se isẹ rere wọ awọn ọgba idẹra ti awọn odo nsan ni abẹ wọn, Atipe awọn ti ko gbagbọ yoo maa gbadun, nwọn yoo maa jẹ onjẹ bi ẹranko ti n jẹ onjẹ, ina ni ibugbe fun wọn".

Ọmọniyan ti ko ni igbagbọ tó kún nipa Ọlọhun, ti kii sii sin-in dabi ẹranko ìgbẹ lasan. Sugbọn bi o ba gba Ọlọhun gbọ, to si nsin-in, yoo maa lo ẹkọ ati ilana Isilaamu fi dari alamọri ọrọ aye ati ọrun rẹ Botilẹ je pe awon ọta esin n pete pero lati gbewa kuro ninu ẹsin wa, sugbọn awa mọ amọdaju pe iyi, ògo, kongẹ oore, oriire erenjẹ aye ati tọrun ati imọna ko le jẹ tiwa, ayafi pẹlu didi Isilaamu yii mu sinkun ni ibamu si tira Ọlọhun ati suna anọbi wa Muhammad.

          Ọpọlọpọ lo nbẹ loni ti ko lagbọye ijọsin gan gan, orisi mẹta si niwọn:

Ik kinni: Lawọn ti wọn lero pe ijọsin ko tayọ irun kiki, awẹ gbigba, saka yiyan, ati rirele Oluwa fun haji, bi iru wọn ba nbẹ ni mọsalasi wọn a maa lo ofin Ọlọhun, sugbọn bi wọn ba kuro nibẹ tan wọn a gba riba (owó èlé), wọn a se sina, mutí, ati gbogbo awọn iwa yoku ti kódàra. Iru wọn ni Ọlọhun rohin ninu Suratul Bakọra: 85.

Ikọ keji: Lawọn ti n sin ẹlomiran yatọ si Ọlọhun, ti wọn n bura, pẹran, seleri, ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu awọn onirannran ijọsin fun ẹlomiran yatọ si Ọlọhun, kódà ofin to tako tọlọhun ni wọn n lo.

 Se wọn ti gbagbe ọrọ Ọlọhun ti mbẹ ninu suratul Ali-Umran: 154 ati Suratul Namli: 2 pẹlu Aniam: 17.

Ikọ kẹta: Awọn to n sin Ọlọhun ti wọn si nwa oju-ire Rẹ, sugbọn pẹlu ilana to yatọ si ilana anọbi ni wọn fi nsin Ọlọhun. Irufẹ awọn wọnyi, ijọsin wọn ko ni jẹ itẹwọgba lọdọ Ọlọhun. Wo Suratul Kahafi: 110. Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: “Ẹniti o ba se adadasil ohun ti ko si as wa (anbi) nib ninu sin yii, wn o ni gbaa lw r ni ijsin”.

          Ijọsin fỌlọhun ko lopin, Musulumi gbudọ maa jọsin fọlọhun titi ti yoo fi kú ni. Ọlọhun sọ pe: Atipe ki o sin Oluwa r titi ti amdaju yoo fi wa ba (eyini ikú).

Ikú ni amọdaju je gẹgẹ bi Ojisẹ Ọlọhun se sọ ninu adisii ti Buhari gba wa; “O o ri oun ni tirẹ ikú ti wọle ti, sugbọn emi nse agbenle ore fun –un lọdọ Ọlọhun.

 Nitorinaa, ẹ bẹru Ọlọhun ẹyin ẹrusin Rẹ, ki ẹ tẹnpẹlẹ mọ titẹle asẹ Ọlọhun, ki ẹ si maa jọsin fun Un, ki ẹ le ri oore Rẹ gba laye ati lọrun. Ẹ ma si gbagbe adehun ti ẹ maa nse fỌlọhun bi ẹ ba nke suratul Fatiat pe: Irẹ Ọlọhun ni a o maa sin, ọdọ Rẹ nikan ni a o si maa wa iranlọwọ si, ki ẹ mase yapa adehun naa. Ọlọhun sọ pe:

ki ẹ si mu majẹmu mi sẹ, emi yoo mu majẹmu yin sẹ. Emi nikansoso ni ki ẹ si paya” Suratul Bakọrah : 40

 

فأتقوا الله-  عباد الله وحافظوا على أعمالكم من المبطلات والآفات , واعلموا  أن خير الحديث كتاب الله , وخيرا الهدي هدي محمد صلّى الله عليه وسلم وشرّ الأمور محدثاتها وعليكم  بالجماعة فإن يد الله مع الجماعة , ومن شذ شذ في النار . إن الله وملائكته يصلّون على النّبي يا أيها الذين آمنوا صلّوا عليه وسلموا تسليم اللهم صى على عبدك ورسولك محمد , وارض اللهم عن الخلفاء الراشدين أبي بكر وعمر وعثمان وعلي وعن الصحابة أجمعين.

عباد الله إن الله يأمر بالعدل والإحسان وإيتاء ذي القربى وينهى  عن الفحشاء  والمنكر والبغي يعظكم لعلكم  تذكرون وأوفوا بعهد الله إذا عاهدتم  ولاتنقضوا الأيمان  بعد توكيدها  وقد جعلتم الله عليكم  كفيلا إن الله يعلم ماتفعلون .