TÍTI IFẸ ỌLỌHUN, ATI IFẸ OJISẸ RẸ SIWAJU GBOGBO OHUNKOHUN

Eko ni soki

Inife Olohun ati ojise re je oranyan kan ninu awon oranyan igbagbo, omoniyan ki yio di musulumi ti o ni igbagbo ayafi ti o ba gbe ife Olohun ati ojise re siwaju gbogbo ohun ti o ni lowo, lomo, lobi ati awon eniyan patapata, gegebii ololufe wa, eniesa, anabi(Ki ike ati ola Olohun maa baa) se salaye re fun wa, bi odiwon ife naa ba se too, ni itele ati ijepe ase Olohun ati ojise re yio se too.

Awọn erongba lori Khutuba naa:

1-     Sise alaye ijẹ ọranyan titi ifẹ Ọlọhun, ati ifẹ Ojisẹ Rẹ siwaju gbogbo nkan;

2-     Ijẹ ki ifẹ Ọlọhun, ati ifẹ Ojisẹ Rẹ rinlẹ ni ọkan;

3-     Sise alaye awọn ami inifẹ Ọlọhun, ati ifẹ Ojisẹ Rẹ;

4-     Didarukọ awọn nkan ti o le se okunfa inifẹ Ọlọhun, ati ifẹ Ojisẹ Rẹ;

5-     Ifuni ni ara awọn ewu ti o wa ni ibi titi ifẹ ara, owo ati ọmọ lori inifẹ Ọlọhun, ati ifẹ Ojisẹ Rẹ.

 

 (ogun isẹju):

الحمد لله الذي أرسل رسوله محمّداً إلى الثّقلين، وجعل طاعته ومحبّته بعد طاعة الله ومحبّته عبادةً؛ فأمر الله بطاعته ومحبّته، والصّلاة والسّلام على نبيّنا محمّد الذي تجب طاعته ومحبّته على كلّ مسلمٍ، بل لا يكون المؤمن مؤمناً إلاّ بذلك، وعلى آله وصحبه ومَن تبعهم بإحسانٍ إلى يوم الدّين، وبعد؛

Ẹyin Musulumi lododo! Kókó ọrọ ti oni jẹ ọrọ nla, ti ẹnikọọkan wa si ni bukata si, kódà o jẹ ọkan lara awọn ọranyan nini igbagbọ; ọrọ naa ni: Ifẹ Ọlọhun, ati ifẹ Ojisẹ Rẹ, siwaju ohunkohun, ọmọ, obi tabi owo.

Ọlọhun ti Ọla Rẹ ga sọ bayi:

{إن كان آباؤكم وأبناؤكم وإخوانكم وأزواجكم وعشيرتكم وأموال اقترفتموها وتجارة تخشون كسادها ومساكن ترضونها أحب إليكم من الله ورسوله وجهاد في سبيله فتربصوا حتى يأتي الله بأمره والله لا يهدي القوم الفاسقين} [التوبة : 24].

قال القاضي عياض: "كفى بهذه الآية حظا وتنبيها ودلالة وحجة على لزوم محبته ووجوب فرضها واستحقاقه لها صلى الله عليه وسلم؛ إذ قرع تعالى من كان ماله وأهله وولده أحب إليه من الله ورسوله وأوعدهم بقوله تعالى (فتربصوا حتى يأتي الله بأمره) ثم فسقهم بتمام الآية و أعلمهم أنهم ممن ضل ولم يهده الله" [الشفا في حقوق المصطفى].

{Ti o ba se wipe awọn baba yin, ati awọn ọmọ yin, ati awọn ibatan yin, ati awọn tọkọ tiyawo yin, ati awọn ẹbi yin, ati awọn owo ti ẹ ko jọ, ati kata-kara ti ẹ n bẹru iparun wọn, ati awọn ibugbe ti ẹyọnu si bajẹ n kan ti ẹ ni ifẹ si ju Ọlọhun ati ju Ojisẹ Rẹ, ati ju igbiyanju si oju ọna Ọlọhun lọ, ẹya ko ara duro titi ti Ọlọhun yoo fi de pẹlu asẹ Rẹ, Ọlọhun ko ni fi ọna mọ awọn ijọ pooki}. [At-Taobah: 24].

Ọlọhun ti Ọla Rẹ ga tun sọ bayi:

{إن كنتم تحبون الله فاتبعوني يحببكم الله ويغفر لكم ذنوبكم} [آل عمران : 31]، وقال تعالى : {يا أيها الذين آمنوا لا تقدموا بين يدي الله ورسوله واتقوا الله إن الله سميع عليم} [الحجرات : 1].

{Sọ funwọn pe: ti o ba se wipe ẹni ifẹ Ọlọhun ni ododo, ki ẹ tẹle emi (Ojisẹ Ọlọhun), Ọlọhun yoo ni ifẹ yin, yoo si Se aforijin fun yin}. [Al-'imran: 31].

Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sọ pe:

"ẹni kankan ninu yin ko ti ni igbagbọ titi yoo fi ni ifẹ emi (Ojisẹ Ọlọhun) ju obi rẹ, ọmọ rẹ, ati awọn eyan lapapọ lọ. [Bukhari ati Musilimu ni o gbaa wa].

Ifẹ Ọlọhun, ati ifẹ Ojisẹ Rẹ ni ami ati okunfa, ninu awọn ami rẹ ni: titẹle asẹ Ọlọhun ati ifẹ Ojisẹ Rẹ, titẹle sunnah Annabi, sise asalatu fun un, riran ẹsin rẹ lọwọ pẹlu isẹ ati pẹlu ọrọ, mimọ daabo bo sunnah Annabi, mimọ ke Al-Quran, bibinu si ẹniti Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ n binu si.

Ẹwa ri awọn okunfa nini ifẹ Ọlọhun ati ifẹ Ojisẹ Rẹ, ninu wọn ni: nini igbagbọ si Ọlọhun ati ifẹ Ojisẹ Rẹ, isẹ rere, suru, daada sise, imọtoto. Ọlọhun sọ bayi pe:

{والله يحب الصابرين} {والله يحب المحسنين} [ال عمران : 148]. {إن الذين آمنوا وعملوا الصالحات سيجعل لهم الرحمن ود} [مريم : 96] وقال : {إن الله يحب التوابين ويحب المتطهرين} [البقرة : 222]. وقال : {يا أيها الذين آمنوا من يرتد منكم عن دينه فسوف يأتي الله بقوم يحبهم ويحبونه أذلة على المؤمنين أذلة على الكافرين يجاهدون في سبيله ولا يخافون لومة لائم} [المائدة 5: 54].

{Ọlọhun nifẹ awọn onisuru} [Al-Imran: 148], {Dajudaju Ọlọhun ni ifẹ awọn oluse dada} [Al-Baqorah: 195], {Dajudaju awọn ti wọn gbagbọ lododo, ti wọn se isẹ rere, Ọlọhun Onikẹ yoo se ifẹ fun wọn} [Maryam: 96], {Dajudaju Ọlọhun nifẹ awọn olutuba ati awọn oluse imọtoto} [Al-Baqorah: 222].

 


 

 

(isẹju mẹẹdogun):

الحمد لله والصّلاة والسّلام على رسول الله وآله وصحبه ومَن تبعهم بإحسانٍ إلى يوم الدِّين، وبعد؛

Alaye ifẹ awọn ẹni-isiwaju rere si Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ.

'Amru ibn Al-'as (رضي الله عنه), sọ wipe: ko si ẹni ti ifẹ rẹ wa ni ọkan mi ju Ojisẹ Ọlọhun, ko si ẹni ti o tobi loju mi juu lọ, kódà emi o lee si oju woo fun sise apọnle rẹ, ti wọn ba bimi pe ki n se iroyin rẹ bi o seri mi o le se e, nitori emi kii si oju woo. [Sahih Musilimu].

Wọn bi 'Ali ibn Abi Tọlib - ki Ọlọhun yọnu si-: bawo ni ifẹ yin fun Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم)? O dahun pe: "Mo fi Ọlọhun bura; a ni ifẹ rẹ ju awọn owo wa, awọn ọmọ wa, awọn baba wa, awọn iya wa, ati ju omi tutu lasiko ongbẹ lọ". [tira Al-shifa].

Ninu awọn nkan ti o tako inifẹ Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ ni: adadasilẹ ni inu ẹsin (Bidi'ah), fifi awọn ọrọ Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ silẹ, kikosi inu ẹsẹ, aibikita ẹsin Ọlọhun ati bẹẹbẹẹ lọ.

Alfa Agba Ibn Kathir sọ ninu itumọ ọrọ Ọlọhun pe:

{قُلْ إِن كُنتُمْ تُحِبّونَ اللّهَ فَاتّبِعُونِي يُحْبِبْكُمُ اللّهُ} [آل عمران : 31].

"Aaya yi jẹ ipenija fun gbogbo ẹni ti o sọ pe ohun ni ifẹ Ọlọhun ti ko si rin ọna Annabi ti Ọlọhun ran ni isẹ, dajudaju opurọ ni iru ẹnibẹ titi ti yoo fi tẹle ofin ati ẹsin Annabi nibi ọrọ, isẹ ati awọn isesi rẹ. Gẹgẹ bi o ti rinlẹ ninu ọrọ Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) pe: "ẹnikẹni ti o ba se nkankan ti o yatọ si eyi ti a fi asẹ si, a o daa pada si". Titẹle sunnah Annabi ati ilana awọn saabe rẹ jẹ ọranyan lori gbogbo Musulumi ododo.

Dajudaju iwọ Ọlọhun lori awọn ẹru Rẹ ni ki wọn maa jọsin fun Un lododo, ki wọn si ma pa nkan miran pọ mọọ, bẹẹ, iwọ ẹru Rẹ lori Rẹ nipe ki O mọ se fi iya jẹ ẹniti ko pa nkankan pọ mọ ọ.

Iwọ Ojisẹ Ọlọhun lori awọn ijọ rẹ ni ki wọn maa se apọnle ati igbe tobi rẹ, (Suratul-Nur: 63),

{لا تجعلوا دعاء الرسول بينكم كدعاء بعضكم بعضا} [النور : 63].

ki wọn si da abo bo ẹsin rẹ, ati awọn saabe rẹ.

عباد الله اعلموا أنّ الله أمرنا بعبادةٍ عظيمةٍ هي من أجل العبادات فقال: {إن الله وملائكته يصلون على النبي يا أيها الذين آمنوا صلوا عليه وسلموا تسليما} [الأحزاب :  56]. اللهم صلّ وسلّم على نبيّنا محمّد وآله وصحبه وسلّم.