IGBA AWỌN ORUKỌ OLUWA TI O RẸ WA JULỌ GBỌ ATI ALAYÉ DIẸ NINU WỌN

Eko ni soki

Ini igbagbo si awon oruko Olohun ati awon iroyin re je ipile kan ti o tobi ninu awon ipile esin, O si je okunfa kan ninu awon okunfa iwo alijanna eru, bakanna ni wipe, Olohun ti ola re ga ti gbee awon eru longbe imaa bee ati imaa baa soro kelekele pelu awon oruko re ti o rewa ati awon iroyin re ti o ga, nitori idi eyi, o too fun musulumi lati ko awon oruko ati iroyin wonyii ati lati gbo itumo re ye yekeyeke.

Erongba lori Khutuba naa:

1.         Igbani niyanjú lati ni igbagbọ si awọn orukọ Ọlọhun ti o rẹwa julọ

2.         Sise alaye diẹ ninu awọn orukọ Ọlọhun ti O rẹwa jùlọ

3.         Igbani niyanju lati ke pe Ọlọhun pẹlu awọn orukọ Rẹ ti O rẹwa jùlọ

4.         Alaye lori bi awọn orukọ Ọlọhun ko se see fi ọgbọn ori lásán-làsàn mọ

 

Khutuba Alakọkọ (ogún isẹju)

الحمد لله القائل في محكم تنزيله " وَلِلَّهِ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَى فَادْعُوهُ بِهَا وَذَرُوا الَّذِينَ يُلْحِدُونَ فِي أَسْمَائِهِ سَيُجْزَوْنَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ  والصلاة والسلام على خير خلقه نبينا محمد، خير من دعا اللهَ ودعا إلى الله U ، صلى الله عليه وعلى آله وصحبه ومن تبعهم بإحسان إلى يوم الدّين.  أما بعد:

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun,

Awọn orukọ ti o dara ti o rẹwa julọ ni Oluwa njẹ. Ọlọhun Ọba I sọ bayi pe:

وَلِلَّهِ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَى فَادْعُوهُ بِهَا [الأعراف : 180]

"Ati pe ti Ọlọhun ni awọn orukọ ti wọn dara julọ, nitori naa ẹ fi wọn pe E". (Al-A'raaf: 180)

Ki a gba awọn orukọ ati irohin Ọlọhun ti o rẹwa julọ gbọ jẹ origun kan pataki ninu igba Oluwa gbọ (Iman). Igbagbọ ti a si gbọdọ ni si awọn orukọ ati irohin Ọlọhun gbọdọ mọ toni kuro nibi afiwe, afijọ, iyi itumọ pada tabi atako si ọkankna ninu u wọn.

Awọn Oni mimọ se agbekalẹ awọn opomulero ọrọ nipa awọ orukọ ati irohin Ọlọhun.

Diẹ ninu awọn opomulero ọrọ ni wọn yi:

1.         Awọn orukọ Ọlọhun ko see fi ọgbọn ori lásán-làsàn mọ. Odi tulasi ki a ri ẹri lori eyikeyi orukọ ninun al-kur'an tabi Sunnah ki a too lẹtọ ati pe Oluwa bẹẹ. Nitorinaa, ko lẹtọ ki a pe Oluwa ni "Baba", "Ọba olori-funfun balau" "Alagbẹdẹ ọrun" ati bẹẹ bẹẹ lọ.

2.         Awọn orukọ Ọlọhun ko pin si ori onka kan. Kódà wọn pọ ju mọkandinlọgọrun (99) lọ.

3.         Gbobo awọn oruko Ọlọhun ni o dara julọ ninu orukọ. Nitorinaa, Oluwa kii jẹ orukọ ti ko ni itumọ tabi ti ko rẹwa.

Nibayi ki a se alaye lori diẹ ninu awọn orukọ Ọlọhun Ọba:

1.         Allahu: itumọ orukọ Ọlọhun (Allahu) ni Ẹni ti ọkan nsin tifẹ-tifẹ ati ni gbigbetobi.

2.         Ar-Rahamanir-Rahim: Ọba Onikẹ ti ikẹ Rẹ ju ti iya si ọmọ lọ. Ko si ore kan ti o ba ẹda ayafi lati ọwọ Rẹ. Bakanaa, pẹlu oripa ikẹ ati aanu Rẹ ni gbogbo iya ati isoro fi n kuro fun ni. Oluwa sọ pe:

وَمَا بِكُمْ مِنْ نِعْمَةٍ فَمِنَ اللَّه [النحل : 53]

3.         "Atipe eyikeyi ti o ba sẹlẹ siiyin ni idẹra, ọdọ Ọlọhun (Allahu) ni o ti wa"(Surat Al-Nahl: 53).

4.         Al-Malik: Ẹni ti O ni ayé, toke tilẹ, kinnikan ko si lee ru wuyẹ ayafi pẹlu imọ ati ero Rẹ. Oluwa sọ pe:

 

مَالِكِ يَوْمِ الدِّين [الفاتحة : 4]

" (Oluwa) Olukapa ọjọ ẹsan (Alikiyaamọ)". Surat Al-Fatihah: 3 . O tun sọ laaye ibomiran pe:

قُلِ اللَّهُمَّ مَالِكَ الْمُلْكِ تُؤْتِي الْمُلْكَ مَنْ تَشَاءُ وَتَنْزِعُ الْمُلْكَ مِمَّنْ تَشَاءُ [آل عمران : 26)

"Sọ pe: Mo pe Irẹ Ọlọhun Ọba ti O ni ọlá ati ipò; Iwọ a maa fun ẹni ti o ba wu Ọ ni ipo tabi ọla, bakanaa ni O si tun ma n gba ipo tabi ọla kuro lọwọ ẹni ti o ba wu Ọ (lati gbaa kuro lọwọọ rẹ) ". Aal Imran: 26).    

1.         Al-kuddus: Ẹni ti O mọ kangá kuro nibi aleebu gbogbo tabi abuku. O da gbogbo ẹda, ti àárẹ ko si muU (Wo: Surat Qọọf: 38)

2.         Al-kọwiyy al-kọhhaar: Gbogbo ẹda pata labẹ agbara Rẹ ni wọn wa. Ko si si alagbara aye kan ti ko ni yẹpẹrẹ niwaju titobi Rẹ. (Wo: Surat Al-Haji: 74).  

3.         Al-'Alim: Ẹni ti O mọ gbogbo asiri ati ikọkọ; O mọ ohun ti o n bẹ lori ilẹ ati ninu ibu odo; ewe kan ko le jabọ laimọ si Ọlọhun … (Wo: Surat Al-Anaam: 59).

4.         Al-'Aliyy al-A'laa: Ọba ti O ga ni ààye, ti O wa loke al-Arashi, bẹẹ naa ni awọn irohin Rẹ tun ga.

5.         Al-Jabbar: Ẹni ti n kun ọlẹ lọwọ ti O si ma n gba alagbara mu pẹlu agbara ti o ju agbara lọ.

 

6.         Al-Ghafuur: Ẹni ti O ma nse aforijin gbogbo ẹsẹ, ti O si ma n bo ni lasiri awọn kudiẹ-kudiẹ bio ti wu ki o pọ to.

7.         Al-Hakim: Ọba Ọjọgbọn nibi ofin ati ipebubu Rẹ

8.         Al-Ghọniyy: Ọba ti O rọrọ funraa Rẹ kuro lọdọ gbogb ẹda Rẹ.

Njẹ ti o ba waa ri bayi, o yẹ ki a gba ara wa ni iyanju lati maa ke pe Ọlọhun pẹlu awọn orukọ Rẹ ti O rẹwa jùlọ. Sugbọn ki a sọ ofin bi a ti le se adua naa ni ibamu pẹlu ilana Annabi wa Muhammad ki ikẹ ati Ọla Ọlọhun maa baa.

O wa ninu igbagbọ ti eniyan gbọdọ ni si awọn orukọ Ọlọhun, ki o maafi awọn oruko naa bẹ Ẹ.  Ojisẹ Ọlọhun r gbọ ti arakunrin kan nki Ọlọhun ni mẹsan-mẹwa ti o n wi bayi pe: "Irẹ Oluwa ni ọpẹ ati ẹyìn tọ si. Ko si kinnikan tabi ẹnikan ti o tọ lati jọsin fun ayafi iwọ Oluwa nikan Alailorogun. Ọba Ọlọpọ ọrẹ, Ẹniti O sẹda sanmọ ati ilẹ ni ọna ti ẹnikan ko se iru rẹ ri. Ọba ti O tobi ti O si kàyà, Alapọnle julọ ti I mọọ da asọ apọnle bo awọn ẹru rẹ. Ọba Alaaye, Oludaduro funraa Rẹ, ti O tun jẹ Ọlá rẹ ni ohun gbogbo fi duro.

" اللهم إني أسألك بأن لك الحمد، لا إله إلا أنت وحدك، لا شريك لك، المنان، بديع السموات والأرض، ذا الجلال والإكرام، يا حي يا قيوم"

Bi Annabi r ti gbọ iru adua ti arakunrin naa se ni o ba sọ pe: "Daju-daju iwọ ti fi orukọ Ọlọhun ti  o tobi julọ pe E; Ẹnikan kii si pee bẹ Ẹ ayafi ki O dahun; kódà ohun gbogbo ti a ba fi iru orukọ bẹẹ tọrọ Oluwa A maa fun ni".(Abu Dawuda lo gba hadith yi wa)

Nitorinaa, ẹyin Musulumi ẹ sa ẹsà ninu orukọ Ọlọhun lati fi bẹ Ẹ. Ẹ lo orukọ Rẹ "Al-Ghọfuur" (Alaforijin) fi wa aforinijn ẹsẹ yin; ẹ lo orukọ Rẹ "Ar-Rọzzaaq" (Ẹni ti O n se arisiki) ki ẹ fi beere ohun ti ẹ ba fẹ ninu ọrọ ile aye ti o jẹ halaali, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

بَارَكَ اللهُ لِيْ وَلَكُمْ فِي الْقُرْآن ِالْعَظِيْمِ وَنَفَعَنِيْ وَإِيَّاكُمْ بِمَا فِيْهِ مِنَ الْآياتِ وَالذِّكْر ِالحْكِيْمِ، أقُوْلُ قَوْلِيْ هَذَا وَأَسْتَغْفِرُ اللهَ لِيْ وَلَكُمْ فَاسْتَغْفِرُوهُ إِنَّهُ هُو َالْغَفُور ُالرَّحِيْمْ .

 

Khutubah Ẹlẹẹkeji (Isẹju mẹẹdogun).

الحمد لله وكفى والصلاة والسلام على نبيّه المصطفى، وعلى آله وصحبه.  أما بعد

Ẹyin ẹrusin Ọlohun, tulaasi ni ki a gbe ara le Al-kur'an ati sunnah ti o daju nikan,  lati le mọ awọn Orukọ Ọlọhun, Ọba ti O ga. Nitorinaa,, ko lẹtọ rara lati pe Ọlọhun ni orukọ ti ko pe ara Rẹ bẹẹ, tabi ki Ojisẹ Ọlọhun r pe E bẹẹ. Awọn orukọ Ọlọhun ko see fi ọgbọn ori lásán-làsàn mọ. Pupọ ninu awọn orukọ ati irohin Ọlọhun ni o si wa ninu Al-kuran al-Karim gẹgẹbi o ti wa ninu awon ọrọ Ọlọhun wọn yii:

هُوَ اللَّهُ الَّذِي لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ عَالِمُ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ هُوَ الرَّحْمَنُ الرَّحِيمُ (22) هُوَ اللَّهُ الَّذِي لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ الْمَلِكُ الْقُدُّوسُ السَّلَامُ الْمُؤْمِنُ الْمُهَيْمِنُ الْعَزِيزُ الْجَبَّارُ الْمُتَكَبِّرُ سُبْحَانَ اللَّهِ عَمَّا يُشْرِكُونَ (23) هُوَ اللَّهُ الْخَالِقُ الْبَارِئُ الْمُصَوِّرُ لَهُ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَى يُسَبِّحُ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ [الحشر : 22 - 24]

"Oun ni Ọlohun Ọba ti ko si ẹlomiran ti o lẹtọ ki a jọsin fun ayafi Oun nikan, Olumọ ikọkọ ati gbangba, Ọba Ajọke aye Asakẹ ọrun. Oun ni Ọlohun Ọba ti ko si ẹlomiran ti o lẹtọ ki a jọsin fun ayafi Oun nikan. Oun ni Ọba ti ohunkohun wa ni ikapaa Rẹ, Ẹni ti O mọ kangá  kuro nibi aleebu gbogbo tabi abuku, Ẹni ti njẹri awọn iransẹ Rẹ lododo, Olubori gbogbo ẹda, Alagbara, Ẹni ti N kun ọlẹ lọwọ ti O si ma n gba alagbara mu pẹlu agbara ti o ju agbara lọ, Ọba motó-motó. Mimọ fun Ọlọhun naa O ju gbogbo ohun ti wọn fi n se orogun Rẹ lọ. Oun ni Adẹda, Ẹni ti O se ẹda ohunkohun ni ipilẹ, ti O si ya aworan wọn (ni ọna to wu U), Oun   ni o ni awọn orukọ ti o dara julọ. Atipe gbogbo ohun ti o wa ni sanmọ ati ilẹ ni o n se afọmọọ Rẹ, Oun si ni Alagbara Ojọgbọn."

Oluwa tun sọ bayi pe:

قُلْ هُوَ اللَّهُ أَحَدٌ (1) اللَّهُ الصَّمَدُ (2) لَمْ يَلِدْ وَلَمْ يُولَدْ (3) وَلَمْ يَكُنْ لَهُ كُفُوًا أَحَدٌ (4).

"Sọ pe: Oun ni Ọlọhun Ọkan soso. Ọlọhun Ọba ti a n ronuu kan fun bukata gbogbo. Ko bimọ bẹẹni ẹnikan ko bi I. Atipe ko si alafijọ kan fun Un".

Bakanna ni a o ri pupọ ninu awọn orukọ Ọlọhun lati inu hadith Annabi wa Muhammad, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa baa.

Ọpọ igba ni Annabi r ma n fi awọn orukọ Ọlohun ti o dara julọ bẹ  Ẹ, bi o ti wa ninu awon akọsilẹ wọn yi:

v Annabi r se apejuwe adura kan pe ohun ni ọba gbogbo istigifaaru (iwa aforijin Ọlọhun). Adua naa lọ bayi pe:

اللَّهُمَّ أَنْتَ رَبِّي لَا إِلَهَ إِلَّا أَنْتَ خَلَقْتَنِي وَأَنَا عَبْدُكَ وَأَنَا عَلَى عَهْدِكَ وَوَعْدِكَ مَا اسْتَطَعْتُ أَعُوذُ بِكَ مِنْ شَرِّ مَا صَنَعْتُ أَبُوءُ لَكَ بِنِعْمَتِكَ عَلَيَّ وَأَبُوءُ لَكَ بِذَنْبِي فَاغْفِرْ لِي فَإِنَّهُ لَا يَغْفِرُ الذُّنُوبَ إِلَّا أَنْتَ.

"Iwọ Ọlọhun ni Oluwa mi, ko si Ọlọhun miran ti o tọ lati jọsin fun ayafi iwọ nikan. Iwọ ni O da mi, ẹru Rẹ ni emii se. Lori adehun (ati maa jọsin fun Iwọ Oluwa nikan soso, ati lati tẹle asẹ Rẹ) ni mo si wa, bi mo ti ni agbara mọ. Mo n wa isọri lọdọ Rẹ kuro nibi aburu ohun ti mo fi ọwọ ara mi se. Mo n jẹwọ idẹra Rẹ lori mi, bakanna mo n jẹwọ awọn ẹsẹ mi. Nitorinaa, fi ori jin mi; nitoripe ko si ẹni naa ti o le fi ori ẹsẹ jin eniyan ayafi Iwọ (Oluwa)". 

Ojisẹ Ọlọhun r fi kun pe, bi eniyan ba se adua yi ni ọsan tabi oru kan, ti o ba ku ni ọjọ naa, ọmọ Alijanna ni ẹni naa, ti ọkan rẹ ba gba adua yi gbọ (pẹlu itumọ rẹ).

Ninu hadith ti asiwaju wa Aliy ọmọ Abi Taalib t gba wa, o ni: Ti Ojisẹ Ọlọhun r ba dide lati kirun a maa se "Allah Akbar" lẹhinaa yoo se adua bayi pe:

وَجَّهْتُ وَجْهِىَ لِلَّذِى فَطَرَ السَّمَوَاتِ وَالأَرْضَ حَنِيفًا مُسْلِمًا وَمَا أَنَا مِنَ الْمُشْرِكِينَ إِنَّ صَلاَتِى وَنُسُكِى وَمَحْيَاىَ وَمَمَاتِى لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ لاَ شَرِيكَ لَهُ وَبِذَلِكَ أُمِرْتُ وَأَنَا أَوَّلُ الْمُسْلِمِينَ اللَّهُمَّ أَنْتَ الْمَلِكُ لاَ إِلَهَ لِى إِلاَّ أَنْتَ أَنْتَ رَبِّى وَأَنَا عَبْدُكَ ظَلَمْتُ نَفْسِى وَاعْتَرَفْتُ بِذَنْبِى فَاغْفِرْ لِى ذُنُوبِى جَمِيعًا إِنَّهُ لاَ يَغْفِرُ الذُّنُوبَ إِلاَّ أَنْتَ وَاهْدِنِى لأَحْسَنِ الأَخْلاَقِ لاَ يَهْدِى لأَحْسَنِهَا إِلاَّ أَنْتَ وَاصْرِفْ عَنِّى سَيِّئَهَا لاَ يَصْرِفُ سَيِّئَهَا إِلاَّ أَنْتَ لَبَّيْكَ وَسَعْدَيْكَ وَالْخَيْرُ كُلُّهُ فِى يَدَيْكَ وَالشَّرُّ لَيْسَ إِلَيْكَ أَنَا بِكَ وَإِلَيْكَ تَبَارَكْتَ وَتَعَالَيْتَ أَسْتَغْفِرُكَ وَأَتُوبُ إِلَيْكَ.

Ti o ba waa rukuu yoo tun se adua bayi pe:

اللَّهُمَّ لَكَ رَكَعْتُ وَبِكَ آمَنْتُ وَلَكَ أَسْلَمْتُ خَشَعَ لَكَ سَمْعِى وَبَصَرِى وَمُخِّى وَعِظَامِى وَعَصَبِى

Ti o ba si fi ori kanlẹ, a tun maa se adua bayi pe:

اللَّهُمَّ لَكَ سَجَدْتُ وَبِكَ آمَنْتُ وَلَكَ أَسْلَمْتُ سَجَدَ وَجْهِى لِلَّذِى خَلَقَهُ وَصَوَّرَهُ فَأَحْسَنَ صُورَتَهُ وَشَقَّ سَمْعَهُ وَبَصَرَهُ وَتَبَارَكَ اللَّهُ أَحْسَنُ الْخَالِقِينَ.

Ti o ba tun salamọ a tun maa se adua bayi pe:

اللَّهُمَّ اغْفِرْ لِى مَا قَدَّمْتُ وَمَا أَخَّرْتُ وَمَا أَسْرَرْتُ وَمَا أَعْلَنْتُ وَمَا أَسْرَفْتُ وَمَا أَنْتَ أَعْلَمُ بِهِ مِنِّى أَنْتَ الْمُقَدِّمُ وَالْمُؤَخِّرُ لاَ إِلَهَ إِلاَّ أَنْتَ

Abu- Dawud lo gba hadith yi wa: "Mi maa pe Ọlọhun ni orukọ ti ko pe ara Rẹ tabi ki Annabi r pe E bẹẹ, jẹ mi maa fẹnu ara ẹni sọ ohun ti a ko ni imọ nipaa rẹ. Ọlọhun ti kiwa nilọ lati jinna si eyi. Oluwa sọ pe:

وَلَا تَقْفُ مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ [الإسراء : 36]

"Ma se tẹle (tabi sọ) ohun ti iwọ ko ni imọ nipaa rẹ".  .

Ni ipari: Ẹranti lẹẹkan sii, dandan ni ki Musulumi ni igbabọ si awọn orukọ Ọlọhun, ati mima se isẹ tọ ọ.

Ẹyin Musulumi, ẹ bẹru Ọlọhun Ọba yin. Atipe o pẹ ni tabi o ya ni ẹyin yoo lọ jabọ fun Un. Nitorinaa, Tira Ọlọhun ati ilana Ojisẹ Rẹ r di ọwọ yin o. Ki ẹ si maa fi awọn orukọ ati irohin Rẹ bẹ Ẹ; adehun iya ina nbẹ fun awọn ti igberaga ba mu wọn ma se bẹẹ.

اللهم إنا نسألك بكل اسم هو لك سميت به نفسك أو أنزلته في كتابك أو  علمته أحدا من خلقك أو استأثرته في علم الغيب عندك أن تجعل القرآن ربيع قلوبنا و نور صدورنا و جلاء أحزاننا و ذهاب همومنا و غمومنا

اللهم اغفر للمسلمين والمسلمات والمؤمين والمؤمنات الأحياء منهم و الأموات، برحمتك يا أرحم الراحمين .

اللهم أعز الإسلام والمسلمين وأذل الكفر والكافرين. وصلى الله وسلّم على نبينا محمد وعلى آله وصحبه.