Eko ni soki

Olohun daa ina, O si kilo fun awon eru nipa re ki won le baa beru re, O si daa alijanna, O si se awon eru lojukokoro imaa rankan re, iberu Olohun ti ola re ga je onwa fun okan losi bi gbogbo daadaa sise, o si je olukodi fun-un nibi sise gbogbo aburu. Ise afokante je oludari eru losi ibi iwa iyonu Olohun ati esan re, o si tun je ohun ti o maa gbeni dide si iniakolekan awon ise oloore, ti yio si maa kodi eru nibi awon ise laabi.

            (ALHAOFU WARJAHU)

Awọn erongba khutuba

-           Alaye paapaa ipaya ati irankan

-           Alaye nipa pataki mejeeji ninu Igbesi aye musulumi kọọkan

-           Pipanilasẹ ipaya Ọlọhun ati irankan-an Rẹ

-           Ẹsan ti o wa nibi ipaya Ọlọhun ati irankan Rẹ

الحمد لله ذي الفضل والإنعام , توعّد من عصاه بأليم الإنتقام, ووعد من أطاعه بجزيل الثواب والإكرام , أحمده على  إحسانه العام,  وأشهد أن لاإله إلا الله وحده لا شريك له تبارك اسم ربّك ذي الجلال والإكرام, وأشهد أن محمدا عبده ورسوله حثّ على فعل الطاعات وحذّر من المعاصي والأثام, صلّى الله عليه وعلى آله وأصحابه البررة الكرام وسلم تسليما كثيرا مستمرا على الدوام ... وبعد

Ọpẹ ni fỌlọhun ọba to ni ọla ati idẹra lọwọ. O se ileri iya ẹlẹta elero fun ẹniti o ba yapa asẹ Rẹ bẹẹni o se adahun ẹsan to pọ fun ẹniti o ba  tẹle asẹ Rẹ. Mo dupẹ lọwọ Ọlọhun lori awọn daada Rẹ ti o se ti o si kari. Mo jẹri pe ko si ẹniti ijọsin tọ si, tayọ Ọlọhun nikan soso, ọba ti ko lorogun, toto fun hun Oluwa rẹ, O ni titobi ati apọnle lọdọ. Mo si tun jẹri pe Anọbi wa Muhammadu ẹrusin Ọlọhun ni ojisẹ Rẹ si ni, O sewa loju ọyin sibi isẹ rere, bẹẹni o kilọ fun wa, nibi yiyapa asẹ Ọlọhun ati dida ẹsẹ, ki Ọlọhun bani kẹ Annọbi wa ati awọn ara ile rẹ ati awọn to sugba rẹ (sahabe) ti wọn jẹ ẹnirere ẹnipataki, ki ikẹ naa pọ, ki o si se gbere ati ọla naa.

Awọn ijọsin ti a fi ọkan se, se pataki pupọ, ti awọn isẹ ti a nfi ara se si ntọọ lẹhin, toripe ọkan dabi ọba ti awọn orike yoku si jẹ ọmọ ogun fun-un, idi niyi ti ẹsan isẹ ọkan fi tobi ju ẹsan ẹyiti a ba fi ara se lọ. Ojisẹ Ọlọhun (S.A.W) sọ pe igbagbọ eniyan ko tii le duro sinsin titi ti ọkan Rẹ yoo fi duro sinsin” Iduro sinsin ọkan nii imọ Ọlọhun lọkan soso nibi ijọsin, gbigbe tobi, pipataki Rẹ, ninifẹ, bibẹru ati rirankan, titẹle asẹ Rẹ, ati kikorira yiyapa asẹ Rẹ, Ojisẹ Ọlọhun (S.A.W) sọ pe “Ọlọhun ko ni wo awọ yin tabi dukia yin (mọ yin lara), sugbọn yoo wo awọn ọkan ati isẹ yin’’. Idi niyi ti afa wa Asan fi sọ fun arakunrin kan pe: ọkan rẹ ni kio tọju daada toripe didara ọkan ni Ọlọhun bukata si julọ lọdọ awọn ẹru Rẹ.

Ibẹru Ọlọhun ati irankan Rẹ, ni o maa ntani nidi pẹ lọ sibi isẹ oloore ti o si maa njẹ ki eniyan raye sá, jinna si ẹsẹ, ninu isẹ ọkan ni o wa. Ọlọhun tilẹ ti pawa lásẹ ibẹru Rẹ nikan yatọ si ẹlomiran, Ọlọhun sọ pe:

            Suratu Al-imran : 175 ati ati Bakora : 40.

"فلا تخافوهم وخافون إن كنتم مؤمنين".

“Nitorinaa, ẹ mase bẹru wọn Emi Ọlọhun ni ki ẹ bẹru bi ẹ bajẹ onigbagbọ ododo”.

Ojisẹ Ọlọhun sọ pe ti ẹ ba mo nkan ti mo mọ ni, ẹ ba rẹrin mọ niwọn, ẹ ba si maa sunkun lọpọlọpọ bayi ni awọn sahabe dọwọ boju ti oju wọn si nda omije - Buhari & Musilimu.

            Ibẹru Ọlọhun, aibalẹ ọkan, aifararọ, ati ìpayà ìyà Rẹ lori sise ohun ti Ọlọhun se leewọ tabi gbigbe ọranyan kan silẹ, tabi sise aseeto nibi awọn isẹ ti wọn fẹ sise rẹ fun wa, to fi dori ifoya lori pipa ẹsan isẹ rere lofo, ti yoo bi jijinna si awọn nkan eewọ, ti yoo si fa titara sisẹ rere. Yoruba bọ wọn ni inu didun nii morii ya atipe “ọwọ tọọ nii mu ọwọ tọọ wa” Ọlọhun ti se oniran nran adehun fun ẹniti o mbẹru Rẹ ti ibẹru naa si mun-un jinna sẹsẹ, ti o wa dari rẹ sibi titẹle asẹ Ọlọhun. Ọlọhun sọ pe:

"وَلِمَنْ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِ جَنَّتَانِ (46) فَبِأَيِّ آلاءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ (47) ذَوَاتَا أَفْنَانٍ".

 Ọgba meji ni mbẹ fun ẹniti nbẹru ibuduro rẹ niwaju Oluwa rẹ, nitorinaa, ewo ninu ti Oluwa ẹyin mejeeji ti ẹ npe nirọ, wọn jẹ ọlọpọlọpọ ẹtúntún”( ẹka) suratu Rahmon: 46 – 48.

 Ọlọhun tun sọ pe:

{فأما من خاف مقام ربه ونهى النفس عن الهوى * فإن الجنة هى المأوى}.

"Sugbọn ẹniti o paya lati duro niwaju Oluwa rẹ ti o si kó ara rẹ nijanu kuro nibi ifẹnu, Dajudaju ọgbà idẹra ni yoo jẹ ibugbe rẹ Suratu Nosiati: 40 - 41 .

O tun sọ pẹ:

"وَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَى بَعْضٍ يَتَسَاءَلُونَ (25) قَالُوا إِنَّا كُنَّا قَبْلُ فِي أَهْلِنَا مُشْفِقِينَ (26) فَمَنَّ اللَّهُ عَلَيْنَا وَوَقَانَا عَذَابَ السَّمُومِ (27) إِنَّا كُنَّا مِنْ قَبْلُ نَدْعُوهُ إِنَّهُ هُوَ الْبَرُّ الرَّحِيمُ".

"Apakan wọn yoo da ojú kọ apakan, ti wọn yoo maa bere ọrọ lọwọ ara wọn, nwọn yoo si sọ pe: dajudaju awa jẹ olupaiya (Oluwa) laarin awọn ẹniwa ni isiwaju. Dajudaju awa jẹ, ẹniti a nke pe e ni isiwaju. Dajudaju on jẹ olore onikẹ “Suratu Turi: 25 - 28.

Ọlọhun sọ pe ẹniti o ba bẹru Oun, Oun yoo laa kuro nibi ohun ti ọkan kọ, Oun yoo si too, Oun yoo si jẹki atubọtan rẹ dara jọjọ

            Awọn sahabe anọbi (SAW) jẹ ẹniti ibẹru Ọlọhun maa nbo dáru, ti wọn si maa nsise rere, ti wọn tun maa nrankan ikẹ Ọlọhun, eyi ni ibusẹrisi. Ẹ wo Umaru lapẹrẹ jẹ ẹniti o maa nrin kaakiri ilu loru lati se iwadi nipa isesi awọn to ndari, gẹgẹ bi isesi rẹ, o jade loru ọjọ kan, nibiti o ti nrin lọ, o gbọ ohun okunrin kan to nka Suratu Turi loba sọ kalẹ lori kẹtẹkẹtẹ rẹ lẹniti o fi ẹyin ti ọgba, ti ohun ti o gbọ na si jẹ okunfa arẹ fun ni osu kan gbako, ti awọn eniyan ko si mọ iru aarẹ ti o muu ati ohun ti o se okunfa aarẹ naa.

            Bakannaa ni imam Aliu pari irun asunba ni ọjọ kan, lẹniti ibanujẹ gba gbogbo ọkan rẹ, to si nfi ọwọ luwọ niti iya lẹnu, ti o si nsọ pe mo tiri awọn sahabe anọbi (SAW) sugbọn loni n o ri ẹniti o jọ wọn mọ nipa káfòru faragbolẹ fọlọhun, ti wọn yoo maa ke Alkur’an, bilẹ ba tun mọ tan wọn yoo maa se iranti Ọlọhun, wọn tẹ bi igi se maa ntẹ nigbati afẹfẹ iji ba fẹ luu. Bẹni oju wọn yoo maa da omije titi ti asọ wọn yoo fi tutu. Bẹẹ naa ni Sufuyanu Saori maa nse aisan latari ibẹru Ọlọhun.

            Abu Sulaimon sọ pe ibẹru Ọlọhun koni kuro ninu ọkan ayafi ki ọkan naa di ahoro. Abu Afsi sọ pe ibẹru Ọlọhun imolẹ ni ninu ọkan.

 

Ibẹru to ntani nidi lọ sibi sise isẹ rere to si nkọ ibajẹ fun ni, ni ibẹru tootọ, bi ibẹru bati kọja eleyi o ti di ijakan kuro ninu oore Ọlọhun nuu, kódà ninu ẹsẹ nla lowa.

            Musulumi gbudọ maa wa laarin ibẹru meji lori isẹ to ti se koja ati eyiti yoo pada se ti ko si mọ Idajọ Ọlọhun lori rẹ.

            Ki o si maa fisẹ rere, ijinna sẹsẹ ati tituba rankan oore lọdọ Ọlọhun. Sugbọn riran kan aanu Ọlọhun pẹlu didagunla si awọn nkan wọnyi, ifọkanbalẹ ninu ete Ọlọhun lo jẹ. Ọlọhun sọ pe:

"فلا يأمن مكر الله إلاّ القوم الخاسرون"

“Nitorinaa, ẹnikan koni fi aiyabalẹ si ete ti Ọlọhun ayafi awọn ijọ olófò”. Suratul arofu: 99.

            Ọlọhun tun jẹ ko di mimọ fun wa pe irankan ko le waye ayafi ki isẹ rere ti siwaju rẹ. Yoruba sọ pe “Ilẹ laa kọkọ tẹ kato tẹ yanrin” Ọlọhun sọ pe:

"إِنَّ الَّذِينَ يَتْلُونَ كِتَابَ اللَّهِ وَأَقَامُوا الصَّلاةَ وَأَنْفَقُوا مِمَّا رَزَقْنَاهُمْ سِرّاً وَعَلانِيَةً يَرْجُونَ تِجَارَةً لَنْ تَبُورَ".

 "Dajudaju awọn ẹni ti wọn nke tira Ọlọhun ti wọn si gberun duro ti wọn si na ninu ohun ti a pese fun wọn ni kọkọ ati ni gbangba, nwọn nse ireti owó kan ti ko ni parun. Suratu Fatiri : 29, awọn  to jọ eleyi naa mbẹ ninu Suratul Bakora : 218.

            Ijọsin fọlọhun ni irankan jẹ, atẹgun nla sini ti a fi nwa oore Ọlọhun ni pẹlu, nitorinaa, a ko gbọdọ rankan oore lọdọ ẹlomiran yatọ si Ọlọhun, ẹniti o ba rankan ẹlomiran yatọ si Ọlọhun ti sẹbo, Ọlọhun sọ pẹ:

{ قُلْ إِنَّمَآ أَنَاْ بَشَرٌ مِّثْلُكُمْ يُوحَى إِلَيَّ أَنَّمَآ الهكُمْ اله وَاحِدٌ فَمَن كَانَ يَرْجُواْ لِقَآءَ رَبِّهِ فَلْيَعْمَلْ عَمَلاً صَالِحاً وَلاَ يُشْرِكْ بِعِبَادَةِ رَبِّهِ أَحَدَاً } [الكهف:110]

 

"Nitorinaa, ẹniti o ba ngbero lati ba Oluwa rẹ pade, ki o se isẹ rere ki o si ma sisẹ fi ẹnikan se orogun ninu ijọsin pẹlu Oluwa rẹ” (Suratul Kahf 18 vs 110).

            Bẹẹ ni irankan tun jẹ oun ti a maa n fise atẹgun oore ta n wa lọdọ Ọlọhun. Wọn ti ẹ gba Hadisi kan wa lọdọ Anabi, o ni Ọlọhun ọba àlekè ọla sọ pe; “Mo n bẹ pẹlu ẹru mi nigbati oba nrankan mi, Un o si maa bẹ pẹlu rẹ ni gbogbo igba ti o ba n ranti mi” (Buhari ati Musulumi lọgba wa)

            Toba ribẹ, a jẹ wipẹ o di òranyàn fun Musulumi lati jẹ ẹniti yoo maa bẹru ìyà ti yoo si maa rankan oore Ọlọhun.

            Ẹyi ti o fi n daaju fun eniyan ni ki o nifẹ Ọlọhun, ki o si wa ni iwọntunwọnsi laarin ibẹru ìyà Ọlọhun ati irankan oore Rẹ. Eleyi ni isesi awọn anọbi Ọlọhun ki igẹ ati ikẹ Ọlọhun ki o maa ba wọn, oun naa si ni ihuwasi awọn onigbagbọ òdodo. Ọlọhun tun sọ pe:

"إِنَّهُمْ كَانُوا يُسَارِعُونَ فِي الْخَيْرَاتِ وَيَدْعُونَنَا رَغَبًا وَرَهَبًا وَكَانُوا لَنَا خَاشِعِين".

 

"Nitoripe dajudaju awọn jẹ ẹniti nyara lọ si bi isẹ rere, atipe wọn si maa nke pewa pẹlu ireti ati ipaya, wọn si jẹ olutẹriba fun wa (Suratul Anbiyaai 21vs 90).

Ọlọhun tun sọ pe;

"تتجافى جنوبهم عن المضاجع يدعون ربّهم خوفا وطمعا ومما رزقناهم ينفقون"

“Nwọn fi ibusun wọn silẹ nwọn o maa kepe Oluwa wọn niti ibẹru ati niti ireti, Nwọn o si maa na ninu ohun ti a pa lese fun wọn (si oju ona rere) (Suratu Sajdah 32vs16)

            Nitorinaa, bi musulumi ba mo bi ikẹ Ọlọhun rẹ se gboro to ati bi anu rẹ se tobi to, ati bi o se ma nfi oju fo awọn  ẹsẹ nla nla, pẹlu bi alujanna se fẹ to , pẹlu bi ẹsan rẹ se tobi to, ara rẹ koba ya gágáágá lati maa se irankan ore lọdọ Ọlọhun.

            Bakanna ti o ba mọ bi iya rẹ se lagbara to, ati bi o se maa nfi ọwọ agbara muni, ati bi ìsirò Rẹ se le to, pẹlu ẹrujẹjẹ ọjọ alukiyamo ati bi ina se buru to, ati onirannran iya to mbẹ ninu ina, kiba ko ẹmi ara rẹ ro nibi isẹ ibi, koba si sọra nibi yiyan aidara laayo. A rika ninu adisi abu Uraẹra pe Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: “Bi Onigbagbọ òdodo ba mọ bi iya Ọlọhun sẹ lagbara to ni, ẹnikan ko ba ti tanmọọ pe oun yoo wọ alujana, bẹẹ bi keferi (alaigbagbọ) ba mọ bi anu Ọlọhun se gboro to, ẹni kankan ko ba ti jakan kuro nibi pe oun yoo wo alujana (Musilimu lọ gbawa).

            Ọpọlọpọ aye ni Ọlọhun ti sọ ọrọ nipa aforijin Rẹ ti o si nfi ọrọ nipa ijiya rẹ tii nidi Ọlọhun sọ pe;

( إن ربك لذو مغفرة للناس على ظلمهم )

“Dajudaju Oluwa rẹ jẹ alaforijin fun awọn ẹnia lori àbòsí wọn. Dajudaju Oluwa rẹ le koko lati gbẹsan (iya) (Suratu Ra’du 13vs6).

            Ninu tira Modaariju Saalikina, Alufa wa agba Ibnul Koyyimi sọ pe; “Bi ẹyẹ ni ọkan se ri nibi ririn lọ pade Ọlọhun, Ifẹ toni si Ọlọhun ni o dabi ori rẹ, ibẹru Ọlọhun ati irankan oore Rẹ si ni iyẹ rẹ ti yoo fi fo bi ẹyẹ. Gbogbo igbati ori ba ti wa lọrun ti iyẹ basi mbẹ lapa, ẹyẹ gidi ni ọkan da ti yoo le fo daadaa, bakanna nipe bi ori bati kuro lọrun ẹyẹ, ẹyẹ naa yoo ku. Awọn ẹniire, ẹniisaju maa n fẹ ki eniyan jẹ ẹniti yoo maa bẹru Ọlọhun pupọ toba n sẹmi lọwọ, sugbọn bi iku ba ti sunmo, ki o yara gbọla fun mi maa rankan ikẹ Ọlọhun lori ibẹru Rẹ.

Nitorinaa, ifẹ ti a ni si Ọlọhun ni nkan ìgùn wa, irankan si ni yoo jẹki irun le se deede, ti ibẹru Ọlọhun si jẹ oludari (dẹrẹba) ti o n wa wa. Ọlọhun ni yoo wa fi ikẹ ati anu rẹ muwa de ebute ogo.

Ẹyin Musulumi ẹ lọọ mọ amọdaju pe irankan aanu Ọlọhun lalai sisẹ, ẹtanjẹ lasan ni, Ọlọhun si ti kọ eleyi fun wa ninu alukurani, Ọlọhun sọ pe:

{يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ فَلا تَغُرَّنَّكُمُ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا وَلا يَغُرَّنَّكُمْ بِاللَّهِ الْغَرُورُ}.

“Ẹyin ẹnia dajudaju adehun Ọlọhun jẹ otitọ, Ẹ maa se jẹki igbesi aye tan nyin jẹ si Ọlọhun” (Suratul Fatiri 35 Vs. 5).

            Nitorinaa, ẹ bẹru Ọlọhun ẹyin musulumi, ẹ si maa bẹru ìyà rẹ, ẹyin naa ẹ gbọ ohun ti Ọlọhun wi:

"اعْلَمُواْ أَنَّ اللّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ وَأَنَّ اللّهَ غَفُورٌ رَّحِيم".

“Ki ẹ mọ pe dajudaju Ọlọhun le koko nibi ẹsan ìyà atipe dajudaju Ọlọhun ni Alaforijin Alaanu” (Suratul Maidah 5 Vs 98).

            Imam Buhari ati Musilimu gba adisi wa lati ọdọ Nuhumọnu ọmọ Basiru (RLA) o sọ pẹ mo gbọ lẹnu Ojisẹ Ọlọhun (S.A.W.) to sọ pẹ; “Dajuadaju ẹniti iya rẹ yoo sẹ pẹrẹ julọ ninu awọn ọmọ ina lalukiyamọ ni arakunrin ti wọn yoo rora fi ògùnná meji pere sibi kojẹgbin ẹsẹ rẹ (sabẹ ẹsẹẹ rẹ mejeeji), latibẹ si ni ọpọlọ rẹ yoo ti maa sọ tohun ti bẹẹ naa yoo maa lero pe ko si ẹniti ìyà rẹ to toun, aliali oun ni iya rẹ sepẹrẹ julọ (kere).

            Bẹẹni Musilimu tun gba adisi miran wa lati ọdọ Su’bat (R.L.A.) O sọ pe: “Ojisẹ Ọlọhun (S.A.W.) Sọ pe: “Anọbi Musa bere lọwọ Ọlọhun pe; taani ẹniti ipo rẹ yoo kere julo ninu alujanna, Olọhun daa lohun pe: Arakunrin kan ni yoo wa lẹyin ti awọn ọmọ alujana bati wọ alujanna lọ, yoo si sọ fun Ọlọhun pe; “Irẹ Oluwa mi bawo ni aye rẹ ti gbogbo rẹ si ti kun fọfọ, Ọlọhun yoo sọ fun un pe; Njẹ o fẹ ki n fun ọ ni ọla to pọ bii ti ọba kan ninu awọn ọba aye bi? Yoo da Ọlọhun lohun pe: mo yọnu si bẹẹ irẹ Oluwa mi, Ọlọhun yoo wa sọ pẹ; iru ọla bẹẹ ni ilọpo mẹrin ki o ma jẹ tirẹ; Arakunrin naa yoo wa sọ pe; ani o ti tẹmi lọrun sẹẹ.Olọhun yoo waa sọpe: ilọpo mẹrin ni tirẹ nii se, ati ilọpo mẹwa miran iru rẹ, kódà gbogbo ohun ti ẹmi rẹ nfẹ tirẹ nii se.

            Sugbọn, ni asiko ti a wa yii latari ọkan awọn eeyan ti o le bi okuta, ti ifẹ aye si ti jọba ninu ẹmi wọn, o fa ki ọpọlọpọ ẹda ma da ẹsẹ lọ titi ti asiko iku rẹ yoo fi sunmọ, nigbayi ni yoo maa wa se agbiyele, ikẹ ati aanu Ọlọhun tori adisi to sọ pe; “ẹnikankan ninu yin ko gbudọ ku ayafi ki o jẹ ẹniti o daba rere si Ọlọhun (rankan ikẹ Ọlọhun Oluwa rẹ).

            Bi o ba bẹru Ọlọhun ni tooto, o yẹ ki ibẹru Rẹ mu ọ maa se awọn nkan ti Ọlọhun se ni ọranyan, ki o si jinna si isẹ aseeto, bẹni ki o jinna si sise àbòsí ẹnikẹji rẹ, ati titayo ẹnu ààlà rẹ si ọmọnikeji, kódà ki ibẹru naa mu ọ pe iwọ ati ẹtọ fun awọn ti wọn nii, lalai nii raa lare tabi fi ọwọ ẹrẹhẹnhẹ mu un, ti yoo tun mu o sọra fun aye, ati fitinọti rẹ, lẹniti yoo maa jẹran ọjọ ikẹhin ati idẹra rẹ.

 

Nitorinaa, ẹ bẹru Ọlọhun, ki ẹ si kọminu Rẹ. Ẹ maa tele asẹ Ọlọhun lẹniti nrankan ẹsan Rẹ, ki ẹ si jinna si iyapa asẹ Rẹ. lẹniti o fi mbẹru iya Rẹ, ẹ mọ si gbagbe pe amọdun ko jinna kẹni ma meebu isu jẹ, ileri Ọlọhun ko ni salaisẹ "Dajudaju ohun ti a ba nyin se adehun rẹ yoo de, ẹ ko jẹ ẹniti o le bọ (lọwọ rẹ).

فاتقواالله عباد الله واعملوا بطاعته  راجين ثوابه واتركوا معصيته خائفين من عقابه  فإن كل آت قريب إن   ما توعدون لأت  وما أنتم بمعجزين  عباد الله أن الله يأمر بالعدل  والإحسان وإيتاء ذي القربى وينهى عن الفحشاء والمنكر والبغي يعظكم لعلكم تذكرون وأوفوا بعهد الله إذا عاهدتم ولا تنقضوا الأيمان بعد توكيدها  وقد جعلتم الله عليكم كفيلا إن الله يعلم ما تفعلون.