Eko ni soki

Kosi isinmi beeni kosi ifayabale fun eru ayafi ki o ni igbagbo si ebubu Olohun ati kadara re, eleyi ni ki o gbagbo wipe ohun ti Olohun ba fe ki o se, ni yio se,ohun ti ko baa fe ki o se,ki yio se,atiwipe, dajudaju, ti gbogbo aye yii ba parapo lori atifi inira kan-an, won ko lee se bee, ayafi ohun ti Olohun ba ti ko sile le lori, ni idakeji, ti won baa korajo lati se e ni anfaani, won ko le se bee, ayafi ohun ti Olohun ba ti ko sile fun-un.

Awọn erongba Khutuba.

  •   Alayẹ lori paapaa igbagbọ ninu kadara atipe orígun kan lo jẹ ninu awọn orígun igbọlọhun gbọ.
  •   Alayẹ nipa pe kadara kose fise ikẹwọ lọri ẹsẹ dida.
  • Ojuse ẹniti ohunti ko tẹẹ lọrun ba sẹlẹ sii ninu kadara.
  •   Awọn oore to mbẹ nibi inigbagbọ ninu kadara.
  •  Isọra kuro nibi ìròrí awọn ẹni anù nibi kadara.

       

الحمد لله رب العالمين , خلق  كل شيئ فقّدره تقديرا, وقال في محكم تنزيله: " إنا خلقنا الإنسان من نطفة أمشاج نبتليه فجعلنه سميعا بصيرا (1)  إنا هديناه السبيل إما شاكرا وإما كفورا"  وأشهد أن لا إله ألا الله وحده لا شريك له, سبحانه وتعالى عما يقول الظالمون علوا كبيرا , وأشهد  أن محمدا عبده ورسوله بعثه شاهدا وبشيرا  ونذيرا, وداعيا إلى الله بإذنه وسراجا منيرا, صلّ الله عليه وعلى آله وأصحابه وسلم تسليما كثيرا أما بعد

 Ọpẹ ni fun Ọlọhun, ọba to sẹda gbogbo agbaye. O da gbogbo nkan, O si  pebubu rẹ daada , O sọ ninu tira Rẹ rẹ pe: Dajudaju Awa ni A da eniyan lati ara omi gbọlọgbọlọ ti a ropọ mọ ara wọn, ki a le baa dan an wo, nitorinaa ni A se ni olugbọrọ Oluriran. Dajudaju A ti fi mọ ọna ti o tọ taara: O le jẹ oluse ọpẹ, o si le jẹ alaimore” Suratul Insani: 2 – 3.

Mọ jẹri pe: ko si ẹnikankan ti ijọsin ododo yẹ ayafi Ọlọhun nikan soso, ko ni orogún bẹni o si mọ tayọ ohunti awọn ọsẹbo nsọ nipa Rẹ. Mo si tun gba lododo pe Annọbi wa Muhammad ẹrusin Ọlọhun ni, ojisẹ Rẹ si ni, Ọlọhun ran ni olujẹri, olufinni ni iro idunnu olukininilọ ati olùpèpè si oju ọna Ọlọhun pẹlu iyọnda Re. Ikẹ Ọlọhun ati igẹ Rẹ ki o maa ba Anọbi ati awọn ara ile rẹ ati awọn ẹmẹwa rẹ ni ikẹ ti o pọ.

Akori khutuba toni yii tobi pupọ, toripe o da lori ọkan ninu awọn orígun igbagbọ mẹfẹẹfa, leyi to sepe ẹniti o ba kuna nipa rẹ Ọlọhun ko ni tẹwọ gba isẹ rẹ, akori naa ni inigbagbọ ninu kadara. Nipasẹ rẹ leeyan lefi ni ifọkanbalẹ, bẹni o jẹ idahun fun ọpọlọpọ ibere. Wo suratul Kọmari: 49 ati suratul Ala: 1-3 ati Suratul Furkoni: 1-2.

Ninu adisi to lalafia ojisẹ Ọlọhun sẹ alaye fun mọlaika Jibril to wa laworan eniyan to si bii lere nipa igbagbọ: igbagbọ ni ki a gba Ọlọhun gbọ ati awọn molaika Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojisẹ Rẹ ati ọjọ alukiyamọ ati kadara ore rẹ ati aburu rẹ. “O sọ pe: òdodo lo sọ”.

       Inigbagbọ ninu kadara ni inigbagbọ si imọ Ọlọhun to ti siwaju gbogbo nkan ki nkan naa to sẹlẹ, ati akosilẹ Rẹ fun gbogbo nkan ti yoo sẹlẹ ki o to sẹlẹ, ati siwaju ki o to da sanmo mejeeje ati ilẹ mejeeje, ni bii ẹgbẹrun odun lọna aadọta (50,000), atipe gbogbo ohunti Ọlọhun ba fẹ ko sẹlẹ ni yoo sẹlẹ bẹẹni o si da gbogbo nkan.

       Mumini gbudọ nigbagbọ pe gbogbo ohunti o nsẹlẹ ko sajoji ninu imo Ọlọhun bẹni kosi baa lẹja fu u, bẹni ko salaimọ nipa rẹ ko to sẹlẹ, atipe Ọlọhun gbero dida awọn nkan, O si nimọ nipa rẹ siwaju, o si sẹlẹ nibamu si bọlọhun sẹ mọọ.

       Bẹni muminu gbudọ nigbagbọ pe Ọlọhun ti kọ akọsilẹ gbogbo nkan sinu (laohil maafus) siwaju dida sanmọ mejeeje ati ilẹ, nibi ẹgbẹrun lọna aadọta ọdun (50,000) gẹgẹ bi ojisẹ Ọlọhun sẹ salaye rẹ ninu awọn adiisi to lalafia ati bi Ọlọhun se salaye rẹ ninu suratul Hadid : 22.

{مَا أَصَابَ مِنْ مُصِيبَةٍ فِي الْأَرْضِ وَلا فِي أَنْفُسِكُمْ إِلَّا فِي كِتَابٍ مِنْ قَبْلِ أَنْ نَبْرَأَهَا إِنَّ ذَلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ}.

“Adanwo kan ko nii sl ni ori il tabi ninu ara yin ayafi ki o maa b ninu Tira kan siwaju ki a to muu jade dajudaju eyi j irrun fun lhun”. 

           

Tobari bẹẹ a jẹ pe: igbagbọ ninu kadara ni inigbagbọ pe ohun ti Ọlọhun ba fẹ ko sẹlẹ ni yoo sẹlẹ, ohun ti ko ba si fẹ ko sẹlẹ, ko lẹ sẹlẹ atipe bi awọn  ẹniyan ba pejọ lati se nkan sugbọn ti Ọlọhun ko lọwọ sii, nkan naa ko ni seése. Wo suratul Insan: 30 – 31.

        Ki o si ni igbagbọ pe Ọlọhun kii jẹniyan nipa sisẹ, buruku tabi rere, bi ko se pe Olusẹsa daada tabi aida lọmọniyan nibi kadara. O le sẹsa rere, o si lẹ sẹ sa ibi. Wo Suratul Baladi: l0 ati Suratul Samsi: 9 - 10.

"وَلِسَاناً وَشَفَتَيْنِ (9) وَهَدَيْنَاهُ النَّجْدَيْن".

“Ati ahọn kan ati ete meji atipe A wa ti fi ọna meji ti o yanju mọ ọ”

       Imọ Ọlọhun to siwaju gbogbo nkan ko tu mọ si ijẹni-nipa sugbọn ki o le jẹ ibalẹjọ fun ọmọniyan atipe nkankan koni sẹlẹ a fi ki Ọlọhun ti nimọ nipa rẹ. Wo suratul Asabi: 40.

"وَكَانَ اللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيما".

 Isọkusọ iwikuwi ati asise nla ni ifi kadara se ikẹwọ lọri dida ẹsẹ ja si tori awọn idi to mbọ yii.

1.         Bi a ba gbagbọ pe kadara see se ikẹwọ lọri dida ẹsẹ, koyẹ ki a bu alàbòsí ẹda, ole, onisina, apaniyan, obilẹjẹ lọri asemase wọn toripẹ kadara lọ faa.

2.         Bi kadara ba see fise ikẹwọni, Asetani, firiaona ijọ Nuhu ati Adi ti Ọlọhun ti parun, ki ba ro arojare niwaju Ọlọhun, bẹni iru ọrọ yii si jẹ iwa aigbọlọhun gbọ.

3.         To ba se e se ikẹwọ, ko ba ti si iyatọ laarin ẹnirere ati ẹniburuku, laarin ọmọ alujana ati ọmọ ina, ati laarin ọrẹ Ọlọhun ati ọta Rẹ sugbọn ẹyi tako ọrọ Ọlọhun. Wo suratal Fatir; 19 - 22 ati suratu Sọdi: 28 ati suratu jasiya: 21 idi niyi ti yoruba fi sọ pẹ “Àgbò kii sẹgbẹ ọda”.

"وَمَا يَسْتَوِي الْأَعْمَى وَالْبَصِيرُ(19) وَلا الظُّلُمَاتُ وَلا النُّورُ(20) وَلا الظِّلُّ وَلا الْحَرُور".

4.      Atipe wọn bi ojisẹ Ọlọhun nipa rẹ, o si dawọn lohun pe: ko si ẹniti wọn ko tii kọ àyè rẹ ninu alujana ati àyè rẹ ninu ina, lawọn sahabẹ ba sọ pẹ ewo la wulẹ nsisẹ si? Ti a ko wulẹ gbe ara le akọsilẹ naa? Ojisẹ Ọlọhun dahun pe: Rara o ẹ maa sisẹ toripẹ kaluku ni Ọlọhun yoo Rọ fun ohunti o ba tori rẹ daa. Buhari ati Musilimu.

Ninu adiisi miran wọn sọ pẹ : Irẹ Ojisẹ Ọlọhun se alaye fun wa nipa isẹ ati wahala ti eniyan nse, se lọri ohun ti Ọlọhun ti kọ silẹ to ti pari ni, tabi awọn  isẹ ti a sẹsẹ nse? Ojisẹ Ọlọhun dahun pe: biko sepe lori ohun ti Ọlọhun ti kọ silẹ ni, awọn sahabẹ ba sọ pe kinni a wulẹ nda arawa lamu sisẹ fun? Ojisẹ Ọlọhun (SAW) si sọ pe: ẹ maa sisẹ kaluku ni Ọlọhun yoo rọ fun ohunti o tori rẹ daa.

5.      Tabi ki a dahun pẹ: latari pe Ọlọhun ti nimọ nipa gbogbo nkan, o si kọọ silẹ nibamu si bi yoo se jẹ, idi ni yi to fi kọọ silẹ pe lagbaja yoo gbọlọhun gbọ, yoo si sisẹ rere, yoo si wọ alujana, bẹni lamorin yoo yapa asẹ Ọlọhun, yoo huwa poki, yoo si wọna, bẹẹna ni dòólà yoo fẹyawo yoo baa lasepo yoo si di ọmọ, ẹniti o ba sọ pe bọlọhun ba ni n o wọ alujana, n o wọọ, kódà bi n o sisẹ kankan, ọrọ rirun ni onitohun nsọ jadẹ lẹnu, kódà o tako kadara toripe ọrọ rẹ nigbana bii ti ẹniti o nreti ọmọ, sugbọn ti ko f iyawo ni.

O jẹ ọranyan fun ẹniti kadara ti ko dara sẹlẹ si ki o yara se atẹmra, ati ifarada, ki o si yọnu si isẹlẹ naa, ki o si sẹri ọkan ati ara si ọdọ Ọlọhun.

 

Diẹ ninu awọn anfani ti a o ri bi a ba gba kadara gbọ

1.         Gbigbe ara lọlọhun tòdodo tòdodo ọmọniyan yoo nigbagbọ pe: Ohun ti o ba sẹlẹ si oun, kosi ninu kadara pe yoo fo oun ru ni.

2.         Ifọkanbalẹ ninu ẹmi pẹlu ibalẹ ọkan.

3.         Onithun koni jọ ara rẹ loju, toripe gbogbo ohun ti ẹda nse nisẹ Ọlọhun lọ njẹ ki o rii se.

            Ẹri awọn anfani wọnyi:-

            Ọlọhun sọ pe:

 "مَا أَصَابَ مِنْ مُصِيبَةٍ إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ وَمَنْ يُؤْمِنْ بِاللَّهِ يَهْدِ قَلْبَهُ وَاللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيم".

Adanwo ko le sẹlẹ ayafi pẹlu iyọnda ti Ọlọhun, atipe ẹnikẹni ti o ba gba Ọlọhun gbọ yoo fi ọkan rẹ mọnà, Ọlọhun ni Onimimọ gbogbo nkan. Wo suratu Tagọbuni 11 ati Hadid: 22.

Ọlọhun tun sọ pe: {الَّذِينَ آمَنُوا وَتَطْمَئِنُّ قُلُوبُهُمْ بِذِكْرِ اللَّهِ}

"Awọn ni ẹniti nwọn gbagbọ ti ọkan wọn si balẹ si iranti Ọlọhun, jẹ ki nsọ fun ọ pẹlu iranti Ọlọhun ni awọn ọkan fi nbalẹ" suratu Radu: 28.

 

 Ojisẹ Ọlọhun (SAW) sọ pe: “Jẹki o di mimọ fun ọ, pẹ bi gbogbo aye ba fi orí ikoko sọọdúnrún (fẹnuko) lati fi inira kan ọ, wọn o lee fi ara kan ni ọ, ayafi ohunti o ba wa ninu akọsilẹ Ọlọhun, bakannaa bi wọn ba pejọ lati se ọ  ni ore kan, wọn o ni ikapani lati se ọ ni ore, ayafi ohun ti Ọlọhun ba ti kọ tẹlẹ pe yoo sẹlẹ si ọ” Ojisẹ Ọlọhun (SAW) tun sọ pe : Mumini to lagbara loore, Ọlọhun si nifẹ sii ju mumini to jẹ ọlẹ lọ, bọtilẹjẹpe ore mbẹ lara awọn  mejeeji, maa sapá lori ohunti yoo se o ni anfani ki o si maa wa iranlọwọ Ọlọhun, ma se kágara, bi aidara ba sẹlẹ si ọ, masẹ sọ pe: ti mo ba se bayi ni ko bari bayi, sugbọn sọ pe kadara ti ko, ohunti Ọlọhun ba si fẹ ni yoo sẹ, toripẹ sisọ bẹẹ nsi ilẹkun fun esu ni “Musilimu.

Ojisẹ Ọlọhun (SAW) tun sọ pe: Ẹ sèémò nipa ọrọ mumini, gbogbo alamori ọrọ rẹ ore ni, bẹni ko si eleyi fun ẹnikan kan ayafi musulumi, bi iduunu ba sẹlẹ sii, yoo dupẹ fọlọhun, yoo si jẹ ore fun-un, bi inira ba si de baa yoo se ifarada yoo si jẹ ore fun-un. Musilimu Ahmad ati ibinu Mojaha lọ gba wa.

            Ẹyin musulumi, njẹ ẹ mo pẹ awọn ikọ meji kan ti dẹni anu latipasẹ kadara ikọ kinni-in: kọdiriyya, awọn ni ikọ ti o sọ pe kosi kadara, ti wọn sọ pe ọtun ni gbagbọ nkan.

Ikọ kẹji ni “Aljabriyyatu awọn ni sọ pe ọmọniyan dabi iyẹ adirẹ ti atẹgun ndari kaa kiri.

Ikọ mejeeji ti sina kódà wọn ti sọnu pẹlu, lotitọ ni pe Ọlọhun ti mọ gbogbo nkan ti o si se akọsilẹ rẹ, ti nkan kan ko si nii sẹlẹ ayafi ohunti Ọlọhun ba fẹ, pẹlu bẹẹ naa, ọmọniyan kii se ẹniti ko lero ati ifẹ, Ọlọhun sọ pe: "وَهَدَيْنَاهُ النَّجْدَيْنِ".

Atipe Awa ti fi ọna mẹji ti o yanju mọọ” Suratul Balad; 10 tun wo saratul Insani: 3.

            Nitorinaa, irẹ musulumi jinna si awọn adisọkan radarada to yapa tira Ọlọhun ati ilana ojisẹ Rẹ, ki o si mọ pe Ọlọhun koni tẹwọ gbasẹ ẹniti o ba tako kadara.

            Yahya ọmọ Yaamuru sọ pe: "Akọkọ ẹniti o kọkọ bu ẹnu atẹ lu kadara ni ilu Basira ni Maabadul-juani, ni mo ba gbera atemi ati Humaedu ọmọ Abdur Rahmon Alamri lati lọ se isẹ Haji tabi umrah, a wa njẹran ki a ba ẹnikan pade ninu awọn  sahabe ojisẹ Ọlọhun, ki a lee bii leere nipa awọn  to nbu ẹnu atẹ lu kadara, nigbati Ọlọhun yoo se e, laba pade Abdulọhi bun Umar ti o nwọ inu mọsalasi lọ, lemi ati ẹnikẹji mi ba lọ baa, ẹnikan duro lọtun, ẹnikẹji duro losi rẹ, ni mo ba bii leere pe. Irẹ baba Abdur Rahmon okiki awọn  eniyan kan ma ti gbalẹ laarin wa, ti wọn nke Alkur’an ti wọn si …… wọn ni lẹmi pe ko si kadara, atipe Ọlọhun kò nimọ nipa gbogbo nkan ki o to sẹlẹ, ni Abdullọhi bunu Umar ba sọ pe: mo ti yọwọ ninu ọrọ rẹ, oun naa si ti yọwọ ninu ọrọ mi, o si fi Ọlọhun bura pe bi a ba ri ẹnikan ninu wọn, ti o na owó goolu ti o pọ, to si ga bi oke hudu soju ọna Ọlọhun, Ọlọhun koni gba lọwọ rẹ, ko si ni san an lẹsan rere titi yoo fi gba kadara gbọ. Lẹyin naa lo wa kaa adiisi Jibrilu to gbajumo yẹn, ti ojisẹ Ọlọhun fi salaye nipa orígun igbagbọ.

            Ẹyin musulumi ẹ jẹki a gbẹkẹ lọlọhun, ẹniba gbẹkẹle E, Yoo to o, Yoo pese fun un nibi to lero ati ibi ti ko fọkan si, ẹ si tẹlẹ awọn  ilana ti Ọlọhun la kalẹ lori gbogbo ohun ti ẹ ba nfẹ, ki ẹ gba pe dajudaju Ọlọhun nimọ nipa gbogbo nkan bẹni O si lagbara lorii rẹ.

 

A n bẹ Ọlọhun, ọba iyi, ọba to gbọngbọn ki o se wa lọkan ninu awọn onigbagbọ si idajọ ati ayanmọ Rẹ, bakanna ni ki o sewa lẹniti yoo le maa tẹle asẹ Rẹ ti yoo si jinna si ẹsẹ.

نسأل الله عز وجل أن يجعلنا  من المؤمنين بقضائه وقدرهء والعاملين بطاعته التاركين لمعاصيه .  اللهم أعزّ الإسلام  والمسلمين  , وأذلّ الشرك والمشركين , ودمّر أعداء الدين اللهم اجعل هذا البلد آمنا مطمئنا وسائر بلاد المسلمين عامة يا رب العالمين.