AWỌN AAMI ASIKO (ỌJỌ-IKẸYIN

Eko ni soki

Inigbagbo si ojo ikeyin je origun kan ninu awon origun igbagbo, igbagbo omoniyan si ojo ikeyin ko tii pe titi ti yio fi ni igbagbo si awon aamin ojo igbende, eleyi ti ojise Olohun fun wa niro nipa re, ninu ohun ti o nfun wa niro nipa isunmo isele re. Oranyan ni fun awon eru lati seri pada losi ibi isiro won, ati lati lo pade Oluwa won, nigbanaa ni igbagbo emi kan ki yio se ni anfaani, nigba ti ko ba ti gbagbo teletele.

Awọn erongba lori Khutuba naa:

1-     Fifi nini igbagbọ si Ọlọhun ati Ọjọ-ikẹyin rinlẹ;

2-     Igbaniyanju lori awọn isẹ daadaa ati síse amulo awọn anfaani to wa nibẹ;

3-     Pipe akiyesi awọn eniyan si sisunmọ Asiko (Ọjọ-ikẹyin);

4-     Ifunilara nipa awọn fitina ati awọn ọna igba sọra ti o dara;

5-     Sise alaye diẹ ninu awọn ami Asiko (Ọjọ-ikẹyin);

 

 (ogun isẹju):

الحمد لله القائل: {فهل ينظرون إلا الساعة أن تأتيهم بغتة فقد جاء أشراطها فأني لهم إذا جاءتهم ذكرهم} [محمد : 18]. والصّلاة والسّلام على رسوله المبعوث رحمة بين يدي السّاعة، والذي بيّن لنا أشراط السّاعة غاية البيان، وبعد؛

Janmọ Muslumi, koko ọrọ wa ninu Khutubah ti oni tobi pupọ, ọrọ nipa ikọkọ ni, ọrọ nipa awọn amin Asiko (Ọjọ-ikẹyin). Ọlọhun ti Ọla Rẹ ga sọ bayi pe:

{فهل ينظرون إلا الساعة أن تأتيهم بغتة فقد جاء أشراطها فأني لهم إذا جاءتهم ذكرهم} [محمد : 18].

{Njẹ wọn n reti n kankan yatọ si ki Asiko (Ọjọ-ikẹyin) waa bawọn lojiji, bẹẹ sini awọn amin rẹ ti de waa bawọn, bawo ni wọn yoo ti se gba iranti ni igbati o ba de wa bawọn?!} [Muhammad: 18].

Ọranyan ni nini igbagbọ pẹlu Ọjọ-ikẹyin, ti Ojisẹ Ọlọhun si se alaye pataki rẹ. Igbagbọ eniyan si Ọjọ-ikẹyin ko pe ayafi ki o gba awọn amin Asiko (Ọjọ-ikẹyin) gbọ.

Ninu Hadith Jubril ti o gbajumọ, ti Imam Musilimu gba wa, o wi fun Ojisẹ Ọlọhun pe:

"fun mi ni iro nipa Igbagbọ! Ojisẹ Ọlọun sọpe: Nini igbagbọ ni ki o gba Ọlọhun, ati awọn Malaika Rẹ gbọ, ati awọn Tira Rẹ, ati awọn Ojisẹ Rẹ, ati Ọjọ-ikẹyin, ati Kadara; daada rẹ ati aburu rẹ".

Bakanna ni Hudhaifah ibn Asiyadi Al-gifari sọpe:

"Awa joko ni ọjọ kan ti a si n sọrọ ni iboji yara Ojisẹ Ọlọhun -Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba- ni a ba mu ẹnu ba Asiko (Ọjọ ikẹyin) ti awọn ohun wa si ga soke, ni Ojisẹ Ọlọhun - Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba – ba wi pe: Asiko (Ọjọ ikẹyin) ko ni sẹlẹ tabi ko ni dide titi ti awọn àmì mẹwa yoo fi sẹlẹ siwaju rẹ…, Abu Dauda ni o gba wa".

Ninu awọn imọ ikọkọ ti o se wipe Ọlọhun nikan ni O ni mimọn rẹ ni Asiko (Ọjọ ikẹyin) wa. Ko si ẹni kankan ti o mọọ yala Malaika ni o tabi Ojisẹ kan. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọpe:

{يسألونك عن الساعة أيان مرسها. قل إنما علمها عند ربي لا يجليها لوقتها إلا هو ثقلت في السموات والأرض لا تأتيكم إلا بغتة يسألونك كأنك حفي عنها قل إنما علمها عند الله ولكن أكثر الناس لا يعلمون} [الأعراف : 187].

{wọn o maa bi ọ nipa Asiko (Ọjọ ikẹyin) igba wo ni yoo de? Sọpe dajudaju ọdọ Ọlọhun Ọba mi ni imọ rẹ wa. Nkankan ko le mun un sẹlẹ lasiko rẹ afi Oun (Ọlọhun) naa. O wuwo ni sanmọ ati ilẹ. Kosi ni de afi lojiji. Wọn o maa bi ọ gẹgẹ bi ẹni pe iwọ mọ nipa rẹ. sọpe ọdọ Ọlọhun ni imọ rẹ wa, sugbọn ọpọ awọn eniyan ko mọ} [Al-'araaf: 187]. Tun wo:

{يسألك الناس عن الساعة قل إنما علمها عند الله وما يدريك لعل الساعة تكون قريبا} [الأحزاب : 63].

{يسألونك عن الساعة أيان مرساها فيما أنت من ذكراها إلى ربك منتهاها} [النازعات : 42 – 43].

Ni igba ti Malaika Jibril bi Annabi (صلى الله عليه وسلّم) nipa rẹ, o fun lesi wipe: ẹni ti wọn n bi ko ni imọ nipa rẹ ju olubere lọ. Eyi ti o tu mọ siwipe Ọlọhun nikan ni O ni imọ nipa rẹ. Kódà gbogbo awọn Annabi Ọlọhun ni wọn ko ni imọ rẹ.

Asiko (Ọjọ ikẹyin) si ti sunmọ pẹlu awọn ẹri lati inu Al-Quran:

{اقترب للناس حسابهم وهم في غفلة معرضون} [الأنبياء : 1]

{وما يدريك لعل الساعة تكون قريبا} [الأحزاب : 63]

 Annabi (صلى الله عليه وسلّم) si sọ wipe: "apejuwe gbigbe mi dide ati Asiko (Ọjọ ikẹyin) sun mọ ara wọn, gẹgẹ bi pipa ọmọ-nika meji pọ.

Ọna meji ni awọn ami Asiko (Ọjọ ikẹyin) pin si: awọn ami keekeeke, ati awọn ami nla. Awọn ami ti wọn kere yi yoo sẹlẹ siwaju Asiko (Ọjọ ikẹyin) fun awọn igbati o pẹ, wọn si jẹ nkan ti a ba saaba. Awọn miran ninu wọn yoo sẹlẹ pẹlu awọn ami nlanla, tabi ki wọn siwaju wọn. Ninu awọn eyi ti wọn kere ni: gbigbe Annabi dide ni Ojisẹ, ki fitina nla de, ti ododo ati irọ yoo daru, ti igbagbọ yoo si dinku, debi wipe eniyan le ji ni ẹniti o ni igbagbọ ti yoo si dalẹ ni alaigbagbọ, ninu wọn tunni ina kan ti yio jade ni agbegbe Hijaz (Ilẹ-larubawa), ina naa ti jade ni idaji ọgọrun keje osu oju-ọrun, ni ọdun (654 A.H), awọn onimimọ ti o se oju wọn ati awọn ti wọn wa lẹyin wọn se alaye ina naa. Ninu awọn ami naa ni rira Amọna (ifokantan) lare.

Sugbọn awọn ami nla, awọn ni awọn isẹlẹ nla ti yoo sẹlẹ siwaju Ọjọ-ikẹyin, ti wọn si jẹ nkan ariseemọ, gẹgẹ bi jijade Dajalu (Opurọ kan ti yoo pe ara rẹ ni Ọlọhun) ati bẹẹbẹ lọ.

Awọn apakan ami ti sẹlẹ ti ko si ni sẹlẹ mọ, awọn miran si n sẹlẹ lọwọ, ti awọn miran koiti sẹlẹ.

 

 

(isẹju mẹẹdogun)

الحمد لله ربّ العالَمين. والصّلاة والسّلام رسولنا الكريم. أيّها المسلمون اتّقوا الله وراقبوه.

Ninu awọn ami keekeeke ti Ojisẹ Ọlọhun (صلى الله عليه وسلّم) salaye rẹ ni: ọpọ sina sise, debi wipe, ọkurin yoo mọ ba obinrin ni asepọ ni oju titi, ẹniti o daraju ni igba naa ni yoo wipe: ọ ba duro si ẹyin odi yi. Bakannaa ni ọpọ riba, ọpọ awọn akọrin (musicians) ati awọn ti wọn n gbọ orin, ọpọ awọn ile gogoro-gogoro, ki ẹru-binrin maa bi olowo rẹ, pipọ awọn ọja.

Awọn ami nla ni: jijade Dajalu (Opurọ kan ti yoo pe ara rẹ ni Ọlọhun), jijade Yajuju ati Majuju (awọn ijọ kan ti yoo pọ bi esú), isọkalẹ Annabi 'Isa, jijade Al-mahdi.

Awọn ami Asiko (Ọjọ-ikẹyin) niyi, o jẹ ọran yan fun ẹnikọọkan lati ronu piwada, ki o si sẹri lọ si ọdọ Ọlọhun pẹlu tituba, ati awọn isẹ rere.

 

اللّهم أعنا على ذكرك وشكرك وحسن عبادك، وصلّى الله على نبيّنا محمّد وعلى آله وصحبه ومَن والاهم بإحسانٍ إلى يوم الدّين. 

"يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُواْ إِنَّمَا الْخَمْرُ وَالْمَيْسِرُ وَالأَنصَابُ وَالأَزْلاَمُ رِجْسٌ مِّنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ فَاجْتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ".

 “Ẹyin onigbagbọ ododo ọti, ati tẹtẹ-tita, ati orisa bibọ ati fifi ọfa pin nkan ẹgbin ni” Suratul Maidah: 90.

Abdullohi bun Abbas sọ pe: Nigbati ayah ti Ọlọhun fi sọ ọti di eewọ sọkalẹ, apakan awọn sahabe nsọ fun apa keji pe: “Wọn se ọti leewọ, wọn si fi se déède ẹbọ sise”. Orisirisi adiisi lo wa lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun to fi nse mimuti leewọ, to si nwani nisọra nibi mimuu rẹ. Ninu rẹ ni adiisi Abdur Rahmọn bun waala, o sọ pe: Mo bi Abdullọhi bunu Abbasi leere nipa ọti tita lo ba sọ fun mi pe: Ojisẹ Ọlọhun  ni ọrẹ kan lati sakifi, lanabi ba baa pade ni ọjọ ti ilu Mọkka di ilu musulumi, tohun ti akèngbè ọti lọwọ, to fẹ fita annabi lọrẹ, lojisẹ Ọlọhun ba sọ fun un pe : Irẹ lagbaja se o ko mọ pe Ọlọhun  ti se e leewọ ni, larakunrin naa ba sọ fun ọmọkunrin ti wọn dijọ wa pe: Lọ ọ tà á. Lojisẹ Ọlọhun  ba sọ pe: Lagbaja, asẹ kini o pa ọmọde kunrin naa? O ni mo paa laseọ ki o lọọ taa ni? Lojisẹ Ọlọhun ba sọ pe: Dajudaju ti Ọlọhun ba se mimu nkan leewọ, yoo se owo rẹ naa leewọ ni. Lo ba pasẹ pe ki wọn daa si bàtìháú” Musilimu lo gba a wa.

Ninu adisi miran ti Annọbi ti nse alaye ohun ti ojú rẹ to ni oru ti wọn muu lọ si sanma, o sọ pe: Wọn gbe igbá meji kan fun mi, ti ikan jẹ ti ọti, ti ikeji si jẹ ti wàrà ni ilu Eliyah ni òru ti wọn mu mi rin lọ si sanmọ. Mo wo awọn igbá náà, ni mo ba sẹsa igba wàrà, ni jibrilu ba sọ pe, ọpẹ ni fọlọhun ti o samọna rẹ lọ sibi adamọ, ti o ba le sẹsa ọti ni ijọ rẹ ko ba dẹni anù – Buhari lo gbaa wa.

Ojise Ọlọhun tun sọ pe: Ẹniti o ba mu ọti laye yii, ti ko si ronupiwada to fi kú, wọn yoo se mimu rẹ leewọ fun-un lọrun”. – Buhari ati Musilimu

Ninu adisi miran Ọlọhun sẹbi le eniyan mẹwa nitori ọti:

1.         Ẹniti o n fun un

2.         Ẹniti wọn n fun un fun

3.         Ẹniti o n pọn ọn fun wọn

4.         Ẹniti o mu-un

5.         Ẹniti o n taa

6.         Ẹniti o n raa lọwọ ẹniti o n taa

7.         Ẹniti o n gbee ru si ori ara rẹ

8.         Ẹniti wọn n gbee e lọọ fun

9.         Ẹniti o nna owo ọti

10.       Ẹniti wọn ra ọti fun

Gbogbo awọn eniyan wọnyi ẹni isẹbile ni wọn latẹnu Anọbi Muhammadu. Latari wipe titọ diẹ wo ninu ọti le fa mimu pupọ ninu rẹ, ni ojisẹ Ọlọhun se diẹ leewọ. Ojise Ọlọhun sọ pe: ohun ti pupọ ninu rẹ ba le pàà yàn, diẹ rẹ naa eewọ ni”. - Abu Daud ati Nosai lo gba wa.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun , ẹ jẹ ka sọra fun òógun olóòró, sìgá, igbó, ògógóró, àásà fínfín ati mimu ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti o maa n da ni lórírú, ti kii jẹ ki eniyan gbéwọn mọ lọwọ Ọlọhun  ati eniyan, ti o maa njẹ ki eniyan lẹ lágbára ati ni  ipinnu, leyiti o se pe dida gẹẹ kan mu ninu rẹ, maa nfọ ìríran ẹda, ti o si n sọ ni di aláàbọ-déèdé, Olùsìwàwù, ti yoo maa rẹrin tabi sunkun laini idi, ti oju rẹ yoo maa dà, bii oju ẹniti o ti fẹẹ ku.