ARA AWỌN AAMI ỌLỌHUN TI O WA LAYE

Eko ni soki

Dajudaju, imaa se ironu nipa awon aami Olohun ati agbara re ti o wa laye, yio jogun inigbagbo si agbara Olohun ati ije okansoso re fun eru ni aye yii, niti paapaa, Olohun Oba ti ogbongbon ti o tobi ti se wa lojukokoro eleyii ninu tiira re, O si pase imaa wo eda sanmo ati ile ati oke ati bee bee lo ninu awon aami re, ki awon eru le mo wipe, dajudaju, aye yi ni eleda ti o nseto re, atipe, oun naa ni oba aaso ti o leto lati maa josin fun.

Awọn erongba lori khutubah naa:

1-     Riran awọn eniyan leti diẹ ninu awọn ami aye ti a fi le mọ Ọlọhun.

2-     Alaye titobi Ọlọhun Allah, Bakannaa, a ko gbọdọ jọsin fun ẹlomiran lẹhin Ọlọhun.

3-     Pipe akiyesi awọn eniyan lati dupẹ fun Ọlọhun, ọba ti o rọ awọn ohun ti O se ẹda rẹ fun ọmọ ẹda eniyan.

4-     Ki a pe akiyesi awọn eniyan lati lo anfaani awọn ohun ti Ọlọhun da, lati fi se ijọsin fun Ọlọhun.

KHUTUBAH ALAKK ( OGUN ISẸJU )

أيها الناس : إن في كل شيء مما خلق الله سبحانه وتعالى آية تدل على أنه واحد مستحق للعبادة دون سواه.

O yẹ ki ẹda ọmọniyan wo oye si awọn ẹda ti Ọlọhun se ẹda wọn, a o mọ pe gbogbo nkan wọnyi lo ntọka si ọkan soso Allah, ati pe Oun nikan soso lo lẹtọ lati jọsin fun. Oluwa sọ ninu Suratu Ghasiyah: 17-20:

وقال : {أفلا ينظرون إلى الإبل كيف خلقت. وإلى السماء كيف رفعت. وإلى الجبال كيف نصبت. وإلى الأرض كيف سطحت} [الغاشية 17 – 20].  "

Ẹ woye si bi A ti se da rakunmi, ẹ wo bi A ti se gbe sanma ga, ẹ wo bi A ti se fi awọn oke mu  ilẹ duro, ẹ wo bi A se tẹ ilẹ".

Ninu awọn ohun ti a le fi da Ọlọhun mọ ni dida awọn sanma ati ohun ti o wa ninu rẹ, bi Ọlọhun se da ẹda awọn ilẹ ati awọn ohun ti o njade ninu rẹ; gẹgẹ bi ohun ọgbin ti wọn yatọ ni awọ, jijẹ ati titọwo.

Ninu awọn ohun ti a le fi mọ Ọlọhun siwaju sii ni awọn orisirisi ẹranko, iyatọ oru ati ọsan, oorun ati ọsupa, ọrisirisi irawọ, Oluwa da awọn nkan ọrisrisi fun igbadun wa, ki wọn le ran wa lọwọ lori ijọsin fun Ọlọhun Allah.

Awọn kan wa ninu ẹda Ọlọhun ti wọn njẹ anfani fun ọmọ Anabi Adam, awọn miiran jẹ ohun oloro gẹgẹ bi imọ ti Ọlọhun fi mọ ẹda eniyan, ki ẹda eniyan le mọ Bakannaa pe ọlẹ ni oun jẹ niwaju  Ọlọhun Adẹda. Ti awọn ẹda ọrisirisi yii si njọsin fun Un. Ọlọhun Allah sọ bayii pe

قال تعالى : {تسبح له السموات السبع والأرض ومن فيهن وإن من شيء إلا يسبح بحمده ولكن لا تفقهون تسبيحهم}

"Awọn sanma meejeje ati ilẹ, ati awọn ohun tio wa ni inu wọn nse afọmọ orukọ Ọlọhun Allah, ko tilẹ si ohun kan ti kii se afọmọ orukọ Ọlọhun Allah, Sugbọn ẹyin ọmọ eniyan ko gbọ agbọye afọmọ wọn". (Surat….)

Bakanna o yẹ ki ọmọ eniyan mọ wipe ijẹ ati imu awọn ẹda Ọlọhun wọnyii wa ni ọwọ Ọlọhun. Allah sọ bayii

{وما من دابة في الأرض إلا على الله رزقها ويعلم مستقرها ومستودعها}.

"Ko si ẹda Ọlọhun kan lorilẹ ti Allah kii se ijẹ ati imu fun un, Ọlọhun si mọ aye ti wọn wa ati aye ti wọn nkọja lọ"

Ninu ami ti a tun le fi mọ Ọlọhun Allah ni oru ati ọsan. Ọlọhun se oru ni asiko isinmi fun awọn ẹda Rẹ, ti ọsan si jẹ asiko igbiyanju fun wiwa jijẹ mimu. Ọlọhun sọ bayii pe:

{قل أريتم إن جعل الله عليكم الليل سرمدا إلى يوم القيامة من إله غير الله يأتيكم بضياء أفلا تسمعون ...الخ }

"sọ fun wọn pe ti ẹ ba n lo oru lọ titi di ọjọ Alukiyamo tani o le yii pada si ọsan fun yin lẹhin Ọlọhun Allah  ẹyin ko wa gbọ ọrọ Ọlọhun bi (Surat…)".

Ẹyin ẹru Ọlọhun Allah , Ọlọhun kan soso Allah  ni o se ẹda awọn ọrisirisi nkan si aye, ẹlomiran ko kun un lọwọ nibẹẹ, tori na Ọlọhun kan soso yii ni a gbọdọ jọsin fun, mimọ ni fun Ọlọhun ti O da ẹda Rẹ daradara.

Awọn orisirisi ẹda Ọlọhun wọnyii ko le maa bẹ fun ara wọn, bi ko jẹ wipe ẹnikan ni o se ẹda wọn, gẹgẹ bi ko se se ki a ri ile kan lori ilẹ aye yii laijẹ wipe awọn kan lo kọ ọ, bẹẹ gẹlẹ ni aye yii pẹlu bi o ti se fẹ too, ti o si dara to, ohun kọ ni o da ara rẹẹ. Ọlọhun Allah nikan soso lo se ẹda wọn.

 

 

KHUTUBAH ẸLẸẸKEJI  ( ISẸJU MẸẸDOGUN )

أيها الناس : إنه مما يجب علينا أن نشكر الله تعالى هذه المخلوقات التي خلقها لنا وسخرها لنا، فإنها والله نعمة عظيمة تستوجب الشكر لله عز وجل..

Dandan ni ki ẹda dupẹ fun Ọlọhun Ẹlẹda rẹ ti O jẹ ki awọn ẹda wọnyi rọ fun ọmọ Anabi Aadamọ. Asiko yowu ti ọmọ Anabi Aadamọ na ba njọsin fun Ọlọhun yoo ma jẹ ọpẹ fun un lọdọ Oluwa Allah.

أيها المسلمون : اتقوا ربكم واشكروه على ما هداكم وعلمكم ما لم تكونوا تعلمون علمكم ما فيه صلاح دينكم ودنياكم، وحجب عنكم من العلم ما لا تدركه عقولكم، ولا تتعلق به مصالحكم، رحمة بكم وما أوتيتم من العلم إلا قليلا .

Oluwa Allah tun se alaye fun ọmọ Anabi Aadamọ, asiko ti o fi se ẹda sanma ati ilẹ, ati awọn ohun ti o wa laarin mejeeji, Oluwa se awọn alaye wọnyi ki ẹda eniyan fi le mọ Pataki aanu Oluwa ati ikẹ Rẹ lori ọmọ Anabi Aadam, gbogbo rẹ ki a fi le sin in daada gẹgẹ bi o ti se tọ ati gẹgẹ bi o ti se yẹ. Allah sọ pe:

هذا، ومما يجب أن لا يغيب عن بالنا أن الله سبحانه وتعالى سخر لنا هذه المخلوقات لنعبده وحده لا شريك له، قال تعالى : {وما خلقت الجن والإنس إلا ليعبدون} فيجب على كل واحد منا أن يعبد الله تعالى كما أمر، شكرا لله تعالى على هذه النعم العظيمة، يقول الله تعالى : {يا أيها الذين آمنوا كلوا من طيبات ما رزقناكم واشكروا لله إن كنتم إياه تعبدون} [البقرة : 172].

"Emi kódà ẹda ọmọ eniyan ati alijannu bi ko jẹ pe ki wọn fi le jọsin fun Oun Ọlọhun Allah ni" Suratu Adh-Ohariyaat: 56.

هذا، قال الله تعالى : "إن الله يأمر بالعدل والإحسان وإيتاء ذي القربى وينهى عن الفحشاء والمنكر والبغي يعظكم لعلكم تذكرون  "

اللَّهُمَّ لاَ تَدَعْ لَنَا فِي مَقَامِنَا هَذَا ذَنْبًا إِلاَّ غَفَرْتَه، وَلاَ دَيْناً إِلاَّ قَضَيْتَه، وَلاَ مَرِيضاً إِلاَّ شَفَيْتَه، وَلاَ مُسَافِراً إِلاَّ رَجَعْتَه وَلاَ ضَالاًّ إِلاَّ هَدَيْتَه وَلاَ دَاعِيًا فِي سَبِيلِكَ إِلاَّ  وَفَقْتَه، وَلاَ حَاجَةً مِنْ حَوَائِجِ الدُّنْيَا وَالآخِرَةِ هِيَ لَكَ فِيهَا رِضَا وَلَنَا فِيهَا صَلاَح إِلاَّ قَضَيْتَهَا وَيَسَّرْتَهَا لَنَا يَا رَبَّ الْعَالَمِين.

رَبَّنَا هَبْ لَنَا مِنْ لَدُنْكَ رَحْمَةً وَهَيِّئْ لَنَا مِنْ أَمْرِنَا رَشَدا. رَبَّنَا هَبْ لَنَا مِنْ أَزْوَاجِنَا وَذُرِيَاِتنَا قُرَةً أَعْيُنٍ وَاجْعَلْنَا لِلَمُتَقِينَ إِمَامًا.

رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الأَخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَذَابَ النَّارِ.