APAKAN NINU IDERA ALIJANNAH ATI IYA INA

Eko ni soki

Alijanna ogba idera je oja ti o won, eleyi ti o se wipe awon osise nsise nitori re, nibe ni awon oju ti o ntanmole, ti o nrerin ti o ndunnu wa, nibe ni ewa ti o foju han ati awon omoge eleyinjuege wa. Ni ida miran, ina je iya gbere, nibe ni awon omi igbona, iya eletaelero, ti oniyepere wa. Enikan ko ni mo alijanna ayafi ki o daamu ati waa, enikan ko si ni mo ina ayafi ki o daamu atisa fun.

Awọn Erongba Lori Khutubah Naa:

1- Sise awọn eniyan lojukokoro lọ si wiwa Alijanna ati kiki wọn nilọ nipa iya Ina.

2- Gbigba wọn niyanju lati maa se isẹ daadaa.

3- Ikilọ lori aburu sise

4- Alaye lori awọn irohin ti Alijanna ni

5- Alaye lori awọn irohin ti Ina ni

 

الحمد لله الذي جعل جنة الفردوس لعباده المؤمنين نزلاً،  وجعل النار مصيرا محتما لمن كفر به طغياناً وجدلاً، ويسر المكلفين للأعمال، وهداهم النجدين؛ ليبلوهم أيهم أحسن عملاً.

أحمده سبحانه وأشكره، وأتوب إليه وأستغفره، أرسل الرسل، وأنزل الكتب، وأقام الحجة على خلقه؛ فهو لم يخلقهم عبثاً ولا سُدىً ولم يتركهم هملاً. وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له، وأشهد أن سيدنا ونبينا محمداً عبده ورسوله دعا إلى الحق، وأوضح المحجة؛ فلا نبغي عن محجته بدلاً. صلى الله وسلم وبارك عليه وعلى آله وأزواجه وذريته وصحبه والتابعين، ومن تبعهم بإحسان إلى يوم الدين.  أما بعد:

 

Alijanna ni ile ikẹ ti gbogbo olugbagbọ-ododo nfẹ lati wọ, nigbati Ina jẹ ile iya ti wọn pese kalẹ fun gbogbo keferi, olorikunkun, ẹlẹsẹ.

 

Ati Alijanna ati Ina jẹ ohun ti Ọlọhun ti sẹda wọn bayi (ko sẹsẹ di ni ọjọ Alikiyaamọ ki O too da wọn). Alkur'an Alapọnle lo sọ bẹẹ:

وَسَارِعُوا إِلَى مَغْفِرَةٍ مِنْ رَبِّكُمْ وَجَنَّةٍ عَرْضُهَا السَّمَاوَاتُ وَالْأَرْضُ أُعِدَّتْ لِلْمُتَّقِينَ [آل عمران : 133]

"Ẹ tara sare lọ wa aforijin lọdọ Oluwa yin ati ọgba-idẹra (Alijanna) kan, eyiti fifẹẹ rẹ (gbooro) to sanma ati ilẹ; a paa lese fun awon olubẹru (Ọlọhun)".

فَإِنْ لَمْ تَفْعَلُوا وَلَنْ تَفْعَلُوا فَاتَّقُوا النَّارَ الَّتِي وَقُودُهَا النَّاسُ وَالْحِجَارَةُ أُعِدَّتْ لِلْكَافِرِينَ [البقرة : 24]

"Ti ẹ ko ba waa le se bẹẹ (ki ẹ mu iru sura kan pere wa ninu awọn sura Al-kur'an) atipe ẹ ko ti ẹ nii le se bẹẹ (lai), nitorinaa ki ẹ bẹru Ina eyi ti wọn yoo fi eniyan ati okuta kòó; a paa lese fun awọn alaigbagbọ"..

 

Irohin ọgba idẹra Alijanna  kọja bẹẹ! Ile ti awọn akeremọdo nsan ni isalẹ rẹ; ile ti a fi bulọọku goolu ati fadaka mọ; ẹrọfọ ibẹ jẹ turaare oloorun; aluuluu okuta olowo iye biye ni awọn okuta rẹ jẹ; iyẹpẹ ile Alijanna fun raa rẹ jẹ oloorun didun; bẹẹ ni awọn ipagọ rẹ jẹ ti aluu luu.

 

Alijanna jẹ imọle ti n tan yanran-yanran ati oorun aladun; awọn eso ati ẹfọ alajẹgbadun kun inu rẹ pẹlu. Awọn iyawo rere ti o si rẹwa bi egbin wa ninu Alijanna naa.

A kii shu bẹẹni a kii tọ ni Alijanna, koda a kii gburo kẹlẹbẹ belentase pe a o haa danu. Ohunkohun ti ara ko ba nii lo yoo ma jade bi aliminsiki oloorun didun ni.

 

Ẹrìn ni ara Alijanna yio maa rin, ko nii si ẹkun lọrọ tiwọn lai.

Ero Alijanna kii kú bẹẹ ni wọn kii rùn, koda bi o ti wu ki wọn o dagba to, wọn ko nii gbo.

Oju ọmọ Alijanna a tutu gbẹdẹ-gbẹdẹ. Awọn obinrin ẹlẹyinju-ẹgẹ si wa nibẹ pẹlu.

Igbadun lailai ni ti Alijanna, koda alekun oore tun n bẹ fun awọn ọmọ Alijanna nipa fifi oju wọn gaani Ọlọhun lai si gaga Kankan.

 

Ah! Ohun ti oju ko riri, ti eti ko gbọ ri, koda ti ko ru wuyẹ ni ọkan ẹda kan ri wa ni Alijanna. Oluwa sọ bayi pe:

فَلَا تَعْلَمُ نَفْسٌ مَا أُخْفِيَ لَهُمْ مِنْ قُرَّةِ أَعْيُنٍ جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ [السجدة : 17]

"Ẹmi kan ko le mọ ohun ti a ti tọju fun wọn (awọn olugbagbọ-ododo) ni ohun itutu-oju, ni ẹsan oore fun ohun ti wọn ti n se nisẹ". (Surat al-Sajdah: 17).

 

Bakanaa ni ọpọ Hadiisi Annabi r tun tọka si awọn irohin ti a mẹnuba siwaju wọnyi .

Lafikun, Ojisẹ Ọlohun r sọ bayi pe:

« مَنْ يَدْخُلُ الْجَنَّةَ يَنْعَمُ لاَ يَبْأَسُ لاَ تَبْلَى ثِيَابُهُ وَلاَ يَفْنَى شَبَابُهُ ». [أخرجه مسلم].

"Ẹniyowu ti o ba wọ Alijanna yoo maa gbadun lọ titi lai ni ri inira, asọ rẹ ko nii gbo, bẹẹ ni ijẹ ọdọmakunrin tabi ọdọmanbinrin rẹ ko nii tí". (Muslim lo gbaa wa).

Ojisẹ Ọlọhun tun sọ bayi pe:

« يُنَادِى مُنَادٍ إِنَّ لَكُمْ أَنْ تَصِحُّوا فَلاَ تَسْقَمُوا أَبَدًا وَإِنَّ لَكُمْ أَنْ تَحْيَوْا فَلاَ تَمُوتُوا أَبَدًا وَإِنَّ لَكُمْ أَنْ تَشِبُّوا فَلاَ تَهْرَمُوا أَبَدًا وَإِنَّ لَكُمْ أَنْ تَنْعَمُوا فَلاَ تَبْتَئِسُوا أَبَدًا ». فَذَلِكَ قَوْلُهُ عَزَّ وَجَلَّ {وَنُودُوا أَنْ تِلْكُمُ الْجَنَّةُ أُورِثْتُمُوهَا بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ} [أخرجه مسلم].

"Olupepe kan yoo pepe (si eti awọn ọmọ Alijanna) bayi: Daju-daju tiyin ni ki ẹ maa ni alaafia ki ẹ si ma se  aarẹ lai-lai; ki ẹ maa sẹmi lọ titi, ti ẹ ko si nii ku mọ lai-lai, ki ẹ si maa jẹ ọdọ ti ẹ ko ni darugbo lai-lai, ki ẹ si maa gbadun lalai  nii mọ inira lai-lai." Eyi ni ibamu si ọrọ Ọlọhun Ọba ti O tobi julọ wipe "Wọn yoo si pe wọn (awọn ọmọ Alijanna) pe: Eyiun ni Alijanna ti a jẹ ki ẹ jogun rẹ nititori ohun ti ẹ ti se nisẹ " (Al-A'raaf:43)

 

Ẹ ẹ waa ri Ina, ile iya ati adanwo ni. Ohun gbigbona jan-jan ti o le jani ni ifun ni ohun mimu awọn ero ina. Oluwa sọ pe:

وَالَّذِينَ كَفَرُوا لَهُمْ شَرَابٌ مِنْ حَمِيمٍ وَعَذَابٌ أَلِيمٌ بِمَا كَانُوا يَكْفُرُونَ [يونس : 4]

Atipe awọn alaigbagbọ, tiwọn ni ohun mimu gbigbona yoo jẹ ati iya ẹlẹta-elero nitoripe wọn se aigbagbọ" (Yunus: 4)

Ina buru pupọ ni  ibusẹri si fun awọn ẹlẹsẹ. Oluwa sọ bayi pe:

هَذَا وَإِنَّ لِلطَّاغِينَ لَشَرَّ مَآبٍ (55) جَهَنَّمَ يَصْلَوْنَهَا فَبِئْسَ الْمِهَاد [ص : 55 ، 56]

"Eyi (ti o siwaju ninu ayah 49-54) jẹ ti awọn ẹni rere ). Atipe daju-daju ibu-sẹri si ti o buru nbẹ fun awọn olukọja aala. Ina Jahannama,  wọn yoo si jóo. O   buru ni ìtẹ". (Surat Sọọd: 55-56)

Oluwa tun sọ pe:سَرَابِيلُهُمْ مِنْ قَطِرَانٍ وَتَغْشَى وُجُوهَهُمُ النَّار [إبراهيم : 50]

"Ohun ti o le gbina mọ eniyan lara ni asọ wọn (awọn ọmọ Ina), atipe nse ni ina yio  bo oju wọn daru". (Surat Ibrahim: 50).

 

O wa ninu Hadiisi ti Abu Hurairah t gba wa pe: Ojisẹ Ọlọhun r se akawe ina ile aye ti a mọ yẹn gẹgẹ bii idakan pere ninu ida aadọrin (1/70) gbigbona ti ina ti ọrun ti a n kilọ rẹ yi! (Imam Muslim ni o gbaa wa).

Ninu Hadiisi miran ti Samurat t gba wa, Ojisẹ Ọlọhun sọọ di mimọ pe: Ina yio mu ẹlomiran ninu awọn ọmọ ina de koko ẹsẹ rẹ; yio si mu ẹlomiran ninu wọn de idaji ara rẹ, bẹẹ si ni ina yio mu ẹlomiran ninu wọn de ọrun! (Imam Muslim ni o gbaa wa).

وعَنْ سَمُرَةَ أَنَّهُ سَمِعَ نَبِىَّ اللَّهِ -صلى الله عليه وسلم- يَقُولُ «إِنَّ مِنْهُمْ مَنْ تَأْخُذُهُ النَّارُ إِلَى كَعْبَيْهِ وَمِنْهُمْ مَنْ تَأْخُذُهُ إِلَى حُجْزَتِهِ وَمِنْهُمْ مَنْ تَأْخُذُهُ إِلَى عُنُقِهِ» [مسلم].

بارك الله لي لكم في الكتاب والسنة ونفعنا بما فيهما من الهدي والحكمة، وصلى الله وسلم على نبينا محمد وعلى آله وصحبه.

الحمد لله، رضي من عباده اليسير من العمل، وتجاوز لهم الكثير من الزلل، وخص من شاء بهدايته وتوفيقه نعمة منه وفضلاً، أحمده سبحانه وأشكره، وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له وأن محمدً عبده ورسوله، صلوات الله وسلامه عليه وعلى آله وصحبه.

Ohun ti o le mu ni wọ Alijanna ni igbagbọ ododo ati isẹ rere. Aawẹ, Irun kiki, ijagun si oju ọna  Ọlọhun, ninawo si oju ọna Ọlọhun ati sise dara-dara si awọn obi ẹni naa ko gbẹyin nibẹ.

Lẹhin ti eniyan ba ki irun ọranyan rẹ, naafila yiyan wa lara ohun tii gbeni wọ Alijanna.  Ojisẹ Ọlọhun r sọ pe: "Ẹni yowu ti o n ki nafila raka mejila ni oru ati ọsan kan Oluwa yio kọ ile (alara) kan fun iru ẹni bẹẹ ni Alijanna: rakaa meji ki a to ki irun alFajr;  mẹẹrin siwaju irun Suhuri (Ayila) ati meji lẹhin rẹ; rakaat meji lẹhin irun Mọgribi ati meji lẹhin irun Ishai". (Imam Muslim ni o gbaa wa).

((من صلى اثنتي عشرة ركعة في اليوم والليلة بنى الله له بيتا في الجنة: ركعتان قبل صلاة الصبح، وأربعا قبل الظهر، واثنتان بعدها، وركعتان بعد صلاة المغرب، وركعتان بعد صلاة العشاء)). رواه مسلم

Idìde yan nafila ni oru nigbati awọn eniyan yoku ngbadun oorun lọwọ, jẹ ọkan pataki ninu isẹ ọmọ Alijanna. Oluwa sọ pe:

تَتَجَافَى جُنُوبُهُمْ عَنِ الْمَضَاجِعِ يَدْعُونَ رَبَّهُمْ خَوْفًا وَطَمَعًا وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنْفِقُونَ [السجدة : 16]

(Awọn olugbagbọ ododo) a maa pa ibusun wọn ti, wọn yoo maa kepe Ọlọhun niti ipaya (iya Ọlọhun) ati ireti (aanu Rẹ), wọn a si tun maa na ninu ohun ti a pa lese fun wọn". (As-Sajdah: 16)

Adhikiri (Iranti Ọlọhun) ni ọna ti o ba Sunnah Annabi r mu, naa wa lara ohun tii mu ni wọ Alijanna.

Ninu Hadiisi meji ọtọọtọ ni a ti rii ka pe mimaa wi gbỌlọhun سبحان الله والحمد لله  "Subhanal lọhi walhamdulillah" wa lara isẹ ti eniyan le se ni abọwaaba ni Alijanna. (Imam Tirmidhi ni o gbaa wa).

Iwa rere nbẹ ninu isẹ ti i gbe ni wọ Alijanna. Ojisẹ Ọlọhun r juwe iru awọn isẹ ọmọ Alijanna titi o fi darukọ ẹni ti on lọ ki ọmọ iya rẹ Musulmi nitori ti Ọlọhun, bi o ti le wu ki ile rẹ  jina to. O tun darukọ obinrin ti o sẹ ọkọ rẹ ti o si  wa n bẹẹ ti o n wipe: mi o ni fi oju le oorun titi waa fi yọnu si mi, iwọ ọkọ mi. (Imam Al-Nasai ni o gbaa wa).

((ألا أخبركم برجالكم في الجنة: النبي في الجنة، والصديق في الجنة والشهيد في الجنة، والرجل يزور أخاه في ناحية المصر لا يزوره إلا لله في الجنة، ونساؤكم من أهل الجنة الودود الولود التي إذا غضبت جاءت حتى تضع يدها في زوجها ثم تقول: لا أذوق غمضا حتى ترضى)) [النسائي].

Sise keferi si Ọlọhun,kikọtiikun si   asẹ awọn obi tabi aise daada si wọn, ọrọ ẹyin ati ofofo  ati bẹẹ bẹẹ lọ wa ninu ohun tii mu eniyan di ero Ina. Ki Oluwa yawa ya gbogo isẹ ọmọ ina o.

O ma di ọwọ yin ẹyin Musulumi lati mura si isẹ Alijanna, ki a si jinna si isẹ Ina. Atipe ki a mura lati ronupiwada kuro nibi iwa ẹsẹ lorisirisi.

ثم صلوا وسلموا على نبيكم محمد رسول الله فقد أمركم بذلك ربكم، فقال عز من قائل: { إِنَّ اللَّهَ وَمَلائِكَتَهُ يُصَلُّونَ عَلَى النَّبِيِّ يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا صَلُّوا عَلَيْهِ وَسَلِّمُوا تَسْلِيماً } . اللهم صلِّ وسلم وبارك على عبدك ورسولك محمد وعلى آله وأزواجه وذرياته، وارض اللهم عن الخلفاء الراشدين، وعن الصحابة أجمعين، والتابعين ومن تبعهم بإحسان إلى يوم الدين، وعنا معهم بعفوك وجودك وإحسانك يا أكرم الأكرمين.