BI O TI SE PATAKI TO LATI MAA PA AWỌN ENIYAN LASẸ DARA-DARA KI A SI MAA KỌ ABURU SISE FUN WỌN

Eko ni soki

Ipanilase daadaa ati ikofunni nipa aburu je ohun ti o tobi, eleyiti opolopo awon eniyan se ifonufora nipa re, melomelo awon iseriwa ofo ati aburu lori koowa ati awujo ti o ti waye, nigbati apakan awon akeeko imo ati awon odoo eniire ba jinna si ikopa ni awujo ni oniranran awon abala re ati itakete si ririn irin atunse sise, ni eniti yio maa panilase daadaa ti yio si maa koo aburu.

            Awọn Erongba Lori Khutubah naa:

1.         Alaye ohun tii jẹ mmi maa pa awọn eniyan lasẹ dara-dara ki a si maa kọ aburu sise fun wọn.

2.         Ise ikilọ nipa awọn àsà àtọhúnrìnwá

3.         Alaye lori awọn ọna ti a fii kọ aburu sise fun awọn eniyan

 

Khutuba Alakọkọ (fun ogún isẹju o le mẹrin)

الحمد لله منزل الكتاب، هدى وذكرى لأولي الألباب، والصلاة والسلام على نبينا محمد المفضل على البشر بجوامع الخطاب، وعلى آله والأصحاب. وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له، وأشهد أن محمداً عبده ورسوله شهادة تنجي صاحبها يوم الحساب.

 

Mi maa pa awọn eniyan lasẹ dara-dara ki a si maa kọ aburu sise fun wọn jẹ ọna kan Pataki ti afi nmọ Musulumi gidi. Kódà, ijọsin (ibaadah) kan pataki ni o jẹ funraarẹ, ti o si man se afihan awọn arole Annabi taara (Alfa) lori  ilẹ.

Sugbọn ohun ti ko jẹ ki awọn eniyan mọ pataki eleyi ni esu ti on tan ọmọniyan jẹ, pẹlu irufẹ adua tabi nafila kan ti ko fidi mulẹ ninu ẹsin ti wọn yoo si mura sii kankan ti wọn yoo si gbagbe mi maa pa awọn eniyan lasẹ dara-dara, ki a si maa kọ aburu sise fun wọn

Ninu ohun ti otilẹ waa bani lọkan jẹ niti pupọ ninu awọn ọdọ Musulumi loni ti wọn kewu ti wọn sin ri aburu ati itapa si ofin Ọlọhun lorisirisi lawujọ, sugbọn ti wọn fi ọwọ lẹran ti wọn nwo iran. Nigbati aburu naa ba waa gbilẹ tan wọn yoo maa wa se kayeefi!.

Oluwa Ọba ti Ọla Rẹ ga sọ pe "Ẹyin ọmọleyin Annabi Muhammad r ni ẹ dara julọ ninu ijọ ti a mu jade fun ọmọniyan; ti ẹ ma n pa awọn eniyan lasẹ dara-dara, ti ẹ sin kọ aburu sise fun wọn.

كُنْتُمْ خَيْرَ أُمَّةٍ أُخْرِجَتْ لِلنَّاسِ تَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَتَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنْكَرِ [آل عمران : 110]

Bakanaa ni Oluwa tun paa lasẹ fun wa ninu Aayah Al-Qur'an miran bayi pe: "Ki ẹ rii daju pe awọn ijọ kan wa ninuu yin ti yoo maa pe awọn eniyan lọ ibi oore, ti wọn yoo maa pa awọn eniyan lasẹ dara-dara, ti wọn yoo si maa kọ aburu sise fun wọn pẹlu; irufẹ awọn bẹẹ ni wọn yoo la, ti wọn yoo si se oriire.

 

وَلْتَكُنْ مِنْكُمْ أُمَّةٌ يَدْعُونَ إِلَى الْخَيْرِ وَيَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنْكَرِ وَأُولَئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ [آل عمران : 104).

Alfa wa Ibn al-Kọyyim sọ bayi pe: "Oore tabi ẹsin wo ni nbẹ lara ẹniti o laju silẹ ti awọn eniyan kọlu ọgba Ọlọhun, ti wọn ko si bikita fun sunnah Annabi r , sibẹ o dakẹ jẹ ẹ, o fi gbigbọ se alaigbọ, kódà ara ko taa rara. Iru ẹni bẹẹ esu ti o dakẹ ni, gẹgẹ bi ẹni ti o n sọrọ ibajẹ ti jẹ esù ti n fọhun. Njẹ adanwo kan a tun nbẹ ti nba ẹsin (Isilaamu) ti o tayọ eyi ti o n ti ọwọ awọn ti o jẹ pe bi okele wọn ba tin pọn lori, ti ẹnikan ko si ba wọn du ipo asiwaju ti wọn fẹ fun raa wọn, ko si ohun ti o kan wọn nibi ohunkohun ti ẹlomiran ibaa wi nipa ọrọ ẹsin. Bẹẹ ti wọn ba ba iru ẹni bẹẹ se fanfa lori nkankan ninu owo tabi iyi rẹ, bi o tilewu ki o kere mọ, nse ni iru wọn yoo tu itọ soke fi oju gbaa, ti wọn yoo si faraya yanna-yanna. Gbogbo ọna orisirisi ti a fin kọ ohun ti ọkan kọ (agbara, ẹnu ati ọkan) ni yoo fi kọọ.

Iru awọn eniyan bayii adanwo ti o ba wọn ko mọ lọkan. Lẹhin pe wọn ti yẹpẹrẹ loju Ọlọhun ti O si n binu siwọn pẹlu, ọkan wọn ti ku, bi o fẹ bi wọn wa laaye. Iku ọkan ni kii jẹ ki eniyan tara bi wọn ban fa ọgba Ọlọhun ya ti wọn si fi oju naani asẹ Rẹ".

Njẹ irẹ ọmọ iyaa mi, ti iwọ ba jẹ ẹniti ntara fun asẹ Ọlọhun ti o si ka ọrọ Rẹ kun, woye si orisirisi aipa ofin Oluwa mọ ti o wa ni awujọ, ki o si wo ewo ninu ọna ti o fi le dẹkun rẹ. Ti o ko ba se bẹẹ, tabi ti o n lọra lati se bẹẹ, ajẹwipe o o kawọ pọnyin rojọ niwaju Oluwa.  Lara ọrọ Oluwa ti o tọka si mi maa pa awọn eniyan lasẹ dara-dara ki a si maa kọ aburu sise fun wọn ni aayah al-Kur'ani ti o wipe:

الَّذِينَ إِنْ مَكَّنَّاهُمْ فِي الْأَرْضِ أَقَامُوا الصَّلَاةَ وَآتَوُا الزَّكَاةَ وَأَمَرُوا بِالْمَعْرُوفِ وَنَهَوْا عَنِ الْمُنْكَرِ وَلِلَّهِ عَاقِبَةُ الْأُمُور [الحج : 41]

"Awọn ti o se wipe ti a ba fun won ni agbara lori ilẹ, wọn a maa gbe irun duro, wọn a si maa yọ zakah, kódà wọn a maa pa awọn eniyan lasẹ dara-dara, wọn a si maa kọ aburu sise fun wọn. Atiwipe ti Ọlọhun ni igbẹhin ọrọ gbogbo".

Ti a ba ri awujọ ti wọn ko ti maa pa awọn eniyan lasẹ dara-dara ki wọn si maa kọ aburu sise fun wọn. Pataki julọ ti awọn ọdọ ti oni imọ ohun ti Oluwa fẹ ni iru awujọ bẹẹ ba kóyán iru isesi bayi kéré, ti wọn nwa awawi pe nse ni awọn ko raye, abi wipe kewu ti awọn nke, tabi isẹ oloore kan ti wọn nse ko jẹ ki awọn raye mi maa pa awọn eniyan lasẹ dara-dara, ki a si maa kọ aburu sise fun wọn. Apadabọ iru sise bẹẹ kii rọrun fun awujọ bẹẹ. Ninu hadith ti Hudhaifah bin Yamaan t gba wa, Annabi r sọ wipe:

عن النبيِّ - صلى الله عليه وسلم - قال: ((وَالَّذِي نَفْسِي بِيَدِهِ لَتَأْمُرُنَّ بالمَعْرُوفِ وَلَتَنْهَوُنَّ عَنِ المُنْكَرِ أو لَيُوشِكَنَّ الله أَنْ يَبْعَثَ عَليْكُمْ عِقَاباً مِنْهُ فَتَدْعُونَهُ فَلا يَسْتَجِيبُ لَكُمْ))

 "Mo fi Oluwa ti ẹmi mi nbẹ lọwọ Rẹ bura, Ninu ki ẹyin O maa pa awọn eniyan lasẹ dara-dara, ki ẹ si maa kọ aburu sise fun wọn, tabi ki Oluwa fi ọwọ ìyà bayin laipẹ; ti ẹ o si maa ke pe E ti ko nii daa yin lohun ". Iya nla wa Zainab –رضي الله عنها- bi Annabi r leere lọjọ kan bayi pe:  "Njẹ o ha seese ki Oluwa pawa rẹ kódà bi awọn eniyan rere nbẹ ninu wa. Annabi r fesi pe: bẹẹ ni o, ti aburu ba pọ (lawujọ).

Itumọ eyi ni pe pupọ awọn ẹni rere ko se ilu lanfaani ti wọn ko ba maa pa awọn eniyan lasẹ dara-dara, ki wọn o si maa kọ aburu sise fun wọn. Kódà, irufẹ awọn ẹni rere bẹẹ naa yoo parun ni pẹlu awọn ẹlẹsẹ ti wọn wo niran laibikita.

Oluwa ti Ọla Rẹ ga naa sọ pe:

لُعِنَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ بَنِي إِسْرَائِيلَ عَلَى لِسَانِ دَاوُودَ وَعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ ذَلِكَ بِمَا عَصَوْا وَكَانُوا يَعْتَدُونَ (78) كَانُوا لَا يَتَنَاهَوْنَ عَنْ مُنْكَرٍ فَعَلُوهُ لَبِئْسَ مَا كَانُوا يَفْعَلُونَ  [المائدة : 78 ، 79]

"A ti sẹ ibi-dandan (ibinu) le awọn alaimoore (keferi) ninu awọn ọmọ Israẹli lẹnu (Annabi) Dauda ati (Annabi) Isa ọmọ Maryam, nititori iwa ẹsẹ ti wọn hu ati ikọja ààlà wọn. Wọn kii kọ aburu sise fun araa wọn; ohun ti wọn nse nisẹ ma buru jọjọ! "

Bi a ba fẹ wa maa kọ aburu fun awọn eniyan, odi dandan ki a mọ nipa awọn majẹmu sise bẹẹ

AKỌKỌ: Ohun ti a fẹ kọ fun awọn eniyan ni aburu gbọdọ jẹ ohun ti ofin ẹsin Isilaamu laa kalẹ bẹẹ pe ko bojumu. Kii se pẹlu ifẹnu ni a fi nmọ aburu ti a gbọdọ kọ ninu ẹsin Isilaamu.

ẸẸKEJI: Ohun ti a fẹ kọ fun awọn eniyan ni aburu gbọdọ jẹ ohun ti o nlọ lọwọ. A kii lọra ki aburu sẹlẹ tan ki a to kọọ.

ẸẸKẸTA: Ohun ti a fẹ kọ fun awọn eniyan ni aburu gbọdọ jẹ ohun ti o han. A kii tọ pinpin asiri awọn eniyan tabi maa fi imu finlẹ wa ibajẹ wọn kiri. Ni igba aye asiwaju wa 'Umar ibn al-Khattab t, o gun iganna yọju wo arakunrin kan ti o n se aburu lọwọ ninu ile araarẹ. Arakunrin naa si sọ bayi pe: "Irẹ Alasẹ Mumini, ki a ti ẹ sọ wipe emi sẹ Ọlọhun ni ọna kan soso (eyi ti iwọ naa siti kami mọ orii rẹ bayi), sugbọn ọna mẹta ọtọọtọ ni iwọ fi sẹ Ọlọhun. Akọkọ: Ọlọhun pasẹ pe ẹ ko gbọdọ fi imu finlẹ wa laifi tabi asiri ọmọnikeji وَلَا تَجَسَّسُوا [الحجرات : 12]; ẹẹkeji; O tun paa lasẹ pe bi ẹ ba fẹ wo ile oju ọna ile ni ki ẹgba wọọ وَأْتُوا الْبُيُوتَ مِنْ أَبْوَابِهَا [البقرة : 189], ogiri ile mi ni iwọ pọn ti o fi rimi; ẹẹkẹta; Oluwa tun paa lasẹ pe ẹ ko gbọdọ wọ ile onile ayafi lẹhin ti ẹ ba gba iyọnda ti ẹ si salamọ si onile 

 لَا تَدْخُلُوا بُيُوتًا غَيْرَ بُيُوتِكُمْ حَتَّى تَسْتَأْنِسُوا وَتُسَلِّمُوا عَلَى أَهْلِهَا [النور : 27], iwọ ko se bẹẹ.  Nigbati Umar t gbọ bayi o fi arakunrin naa silẹ, sugbọn o baa se majẹmu ki o wa aforinjin lọdọ Ọlọhun ki o tuuba ẹsẹ.

ẸẸKẸRIN: Ohun ti a fẹ kọ fun awọn eniyan ni aburu gbọdọ jẹ ohun ti aridaju nbẹ lori pe aburu ni ninu Isilaamu, yatọ si ohun ti ariyanjiyan nbẹ lori ẹ ninu ọrọ ẹsin. Sugbọn ohun ti ẹri ti o daju nbẹ lori ẹ ninu Al-Qur'an tabi hadith, tulaasi ni ki a kọ ohunkohun ti o ba ta koo.

أقول قولي هذا، وأستغفر الله لي ولكم ولسائر المسلمين، فاستغفروه، إنه هو الغفور الرحيم


الحمد لله رب العالمين، والعاقبة للمتقين ولا عدوان إلا على الظالمين، والصلاة والسلام على رسوله الأمين محمد بن عبد الله، وعلى آله وصحبه أجمعين، أما بعد:

 Ọna mẹta ọtọọtọ ni a fi n kọ aburu sise gẹgẹ bi alaye rẹ ti wa ninu ọrọ Annabi r eyi ti Abu Saiid al-Khudri gba wa. O lọ bayi pe: صحيح مسلم - (1 / 50(

مَنْ رَأَى مِنْكُمْ مُنْكَرًا فَلْيُغَيِّرْهُ بِيَدِهِ فَإِنْ لَمْ يَسْتَطِعْ فَبِلِسَانِهِ فَإِنْ لَمْ يَسْتَطِعْ فَبِقَلْبِهِ وَذَلِكَ أَضْعَفُ الإِيمَانِ

"Ẹni ti o ba ri aburu tabi iwa ẹsẹ (munkar) kan ninu yin ki o yara fi ọwọ (agbara tabi ipò) rẹ yii pada, ti ko ba lagbara lati se bẹẹ, ki o fahan (ẹnu) rẹ kọọ, ti ko ba lagbara lati se bẹẹ nigbanaa ki o fi ọkan rẹ kọọ. Sugbọn o, fifi ọkan kọ aburu ni igbagbọ (Iman) ti o lẹ ju." (Imam Musilimu lo gbaa wa).

            Ti a ba n fi ọkan kọ aburu o di dandan ki alaburu ri kikọ naa ni oju ati isesi wa, kódà ki a yẹba kuro nibi ti wọn ti n se aburu naa, ki a maa se joko nibẹ.

Mi maa pa awọn eniyan lasẹ daradara ati mi maa kọ aburu fun wọn ni awọn ekọ ti agbọdọ mojuto.

Akọkọ: Ki a ni imọ nipa ohun ti an pa ni lasẹ rẹ tabi kọọ fun awọn eniyan.

Ẹẹkeji: Ki aniyan nipa sise bẹẹ jẹ titori Ọlọhun nikan soso, laini erongba miran rara.

Ẹẹkẹta: Ki a se pẹlẹpẹlẹ nipa sise bẹẹ.

Ẹẹkẹrin: Suuru ati ifarada di ọwọ wa nigbati a ba n pa awọn eniyan lasẹ daradara tabi kọ aburu fun wọn.

Ẹẹkarun: O di ọwọ wa lati jẹ awokọse rere ti a ba fẹ pa awọn eniyan lasẹ daradara ti a si fẹ maa kọ aburu fun wọn. Ki a ma dabi awọn ẹni ti ma n wipe: ọrọ ẹnu Alfa ni ki ẹ gbọ ẹ ma se tele iwa Alfaa!

            Ni akotan ọrọ Oluwa ti Ọla Rẹ ga sọ bayi pe:

يَا بُنَيَّ أَقِمِ الصَّلَاةَ وَأْمُرْ بِالْمَعْرُوفِ وَانْهَ عَنِ الْمُنْكَرِ وَاصْبِرْ عَلَى مَا أَصَابَكَ إِنَّ ذَلِكَ مِنْ عَزْمِ الْأُمُورِ [لقمان : 17[

Luqman se ikilọ fun ọmọ rẹ pe: "Irẹ ọmọ mi, maa gbe irun duro, ki o ma pani lasẹ ati se rere ki o si maa kọ aburu sise. Atipe ki o ni ifarada lori ohun ti o ba ba ọ, dajudaju eyi un wa ninu ipinnu awọn ọrọ".

اللهم اجعلنا من أهل طاعتك ولا تجعلنا من أهل معصيتك، اللهم حبب إلينا الإيمان وزيّنه في قلوبنا، وكره إلينا الكفر والفسوق والعصيان، واجعلنا من الراشدين.

عباد الله إن الله يأمركم بالعدل و الإحسان و إيتاء ذى القربى و ينهى عن الفحشاء و المنكر و البغي يعظكم لعلكم تذكرون فاذكروا الله العظيم يذكركم و اسألوه من فضله يعطكم و لذكر الله أكبر و الله يعلم ما تصنعون.