SISỌRA KURO NIBI FITINA TI OBINRIN LE KO BA ENIYAN

Eko ni soki

Ninu ohun ti anobi so asoole re fun awa alhummah re ni wipe ki a sora fun aye ati obinrin, Ojise Olohun ko sadede wi bee bikose wipe o fe gba awa ijo re kuro nibi fitinah ti obinrin le ko bani ni.Ti o ba ri bee, e jae ki a sora nibe.

Awọn erongba Khutubah naa:

1. Isọra nibi wahala obinrin

2. Kikọ obinrin ni iwa pẹlẹ ati itiju

3. Riran awọn Musulumi leti awọn ojuse wọ

            Oluwa ti ọla Rẹ ga pe akiyesi gbogbo eniyan si ipaya Rẹ, tori pe ipaya Oluwa ni aabo kuro nibi gbogbo fitinah ati isoro. Ipaya Ọlọhun yii wa fun ọkunrin ati obinrin, sugbọn Ọlọhun di ẹru ti o tobi ru ọkunrin ti o see ni  oludari      fun obinrin, ti yoo si kọ obinrin ni awọn ẹkọ ati ọna orisirisi ti yoo sọ di ẹni ti o npaya Ọlọhun. Ọlọhun fun ọkunrin ni ọla ju obinrin lọ ni ti tori ohun ti wọn nna lowo ati laakaye ati ironu wọn si nkan, ọrọ Ọlọhun sọ wipe:

 {الرجال قوامون على النساء بما فضل الله بعضهم على بعض وبما أنفقوا من أموالهم}.

“Awọn ọkunrin ni opomulero fun awọn obinrin nitoripe Ọlọhun se ajulọ fun apakan wọn ju apakan lọ ati nitori ohun ti wọn nna ninu dukia wọn”. Suratun-Nisai:34.

Onikaluku lo mọ ohun ti o nsẹlẹ si ọpọlọpọ awọn obinrin Musulumi lawujọ wa loni, ti wọn nse ọpọlọpọ ohun ti o ya tọ si ohun ti o sẹlẹ ni aye A]nnabi Muhammad (r) ti ọpọlọpọ wọn nse bii keferi ninu ihuwasi wọn ati isesi wọn fun apẹẹrẹ, nse ni awọn obinrin ndapọ mọ ọkunrin ni ibi isẹ  gbogbo, ni ile-ẹkọ, ni ọja ati ni ibi gbogbo, eleyi jẹ eewọ ti Isilaamu korira rẹ. Gbogbo wa ni a mọ apejuwe rere ti ọ sẹlẹ nigba ti Annabi Musa (u) sa kuro ni Misra ti o si de ilu Madyan ni ibi ti o ti ri awọn ọpọlọpọ ọkunrin ti wọn pọn omi ninu kanga, sugbọn si iyalẹnu rẹ, o ri awọn ọmọge meji ti wọn kora duro lẹgbẹkan lai dapọ mọ awọn ọkunrin wọn ni ti wọn npọn omi, esi ti wọn fun Annabi Musa (u) nigba ti o bere lọwọ wọn wipe:

    ...  ( قال ما خطبكما قالتا لا نسقي حتى يصدر الرعاء و أبونا شيخ كبير  )

Awa duro lẹgbẹ kan ki awọn ọkunrin pari omi ti wọn npọn; lẹhin eleyi ni a o wa pọn omi tiwa na ti a ko ni dapọ mọ ọkunrin ọlọkunrin”  Suratul Qasọs:22-28.

Ẹ jẹ ki a se agbeyẹwo ohun ti o sẹlẹ yii pẹlu ohun ti a n fi oju ri ni awujọ wa loni? ẹ gbo ohun ti Annabi Muhammad (r) sọ :

وفى الحديث: (مروا أولادكم بالصلاة وهم أبناء سبع سنين ، واضربوهم عليها وهم أبناء عشر وفرقوا بينهم في المضاجع).رواه أبوداود ، والحاكم

“ẹ pa awọn ọmọ yin lasẹ ki wọn maa ki irun ti wọn ba di ọmọ ọdun keje, ẹ lu ọmọ ti ko ba kirun ti o si ti di ọmọ ọdun mẹwa bakannaa ki ẹ ma jẹ ki ọkunrin ati obinrin sun papọ mọ ni akoko yii”. Abu Dawud ati awọn miran ni wọn gba Hadiisi yii wa.

Ọrọ Annabi Muhammad (r) yi ntọka sipe Isilaamu se idapọ laarin ọkunrin ati obinrin ni eewọ lati kekere.

Asọ iwọkuwọ eyi ti o nse afihan aye ti o yẹ ki obinrin bo lọ jẹ  apejuwe miran lawujọ ti ọpọlọpọ obinrin nse. Ọlọhun Ẹlẹda ko fe ki won se bẹẹ, tori pe eleyi ma nse okunfa sina. Ọlọhun korira eleyi, ni O fi se Hijab ni ọranyan bakannaa ki a si rẹ oju wa silẹ, ki obinrin  ma se jade ni  ijade  kijade. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ ninu Suratun Nuur: 30-31 pe:

قال تعالى: {قل للمؤمنين يغضوا من أبصارهم ويحفظوا فروجهم ذلك أزكى لهم إن الله خبير بما يصنعون . وقل للمؤمنات يغضضن من أبصارهن ويحفظن فروجهن ولا يبدين زينتهن إلا ما ظهر منها وليضربن بخمرهن على جيوبهن ولا يبدين زينتهن إلا لبعولتهن أو آبائهن أو آباء بعولتهن أو أبنائهن أو أبناء بعولتهن أو إخوانهن أو بني إخوانهن أو بني أخواتهن أو نسائهن أو ما ملكت أيمانهن أو التابعين غير أولي الإربة من الرجال أو الطفل الذين لم يظهروا على عورات النساء ولا يضربن بأرجلهن ليعلم ما يخفين من زينتهن وتوبوا إلى الله جميعا أيه المؤمنون لعلكم تفلحون}.

“Sọ fun awọn olugbagbọ ododo lọkunrin pe ki nwọn maa rẹ oju wọn silẹ ati ki wọn Sọ abẹ wọn. Eyi ni lo mọ ju fun wọn. Dajudaju ọlohun na ti mọ ohun ti wọn nse nisẹ. Ati ki o sọ fun awọn olugbagbọ ododo l’obinrin pe ki awọn naa maa rẹ oju wọn silẹ ati ki wọn si sọ abẹ wọn ati ki nwọn ma si se afihan  ọsọ wọn ayafi eyiti ko le sai han ninu rẹ. Ati ki nwọn ma fi ibori wọn le ori ẹwu wọn ki wọn fibo igbaya ati ọrun wọn. Ati ki nwọn ma se fi ọsọ wọn han si ode ayafi fun awọn ọkọ wọn abi awọn baba (ti o bi) wọn abi baba ọkọ wọn, abi awọn ọmọ wọn lọkunrin abi awọn ọmọ ọkọ wọn lọkunrin, abi awọn ọmọ iya wọn lọkunrin abi awọn ọmọkunrin ti awọn ọmọ iya wọn lọkunrin bi, abi awọn ọmọkunrin ti awọn ọmọ iya wọn lobinrin bi, ati awọn obinrin bi ti wọn na, abi awọn ti ọwọ ọtun wọn kapa rẹ (lọkunrin), abi awọn olutẹle (wọn) ti nwọn ko le fẹ obinrin ninu awọn ọkunrin, abi awọn ọmọ oponlo ti nwọn ko ti ma naga ri ihoho awọn obinrin. Ati ki nwọn ma se ma fi ẹsẹ wọn lu ara wọn ki a ba le mọ ohun ti wọn fi pamọ ni ọsọ. Nitorinaa ẹ ronupiwada lọ si ọdọ Ọlọhun gbogbo nyin patapata, ẹnyin onigbagbọ ododo ki ẹ le ba la”.       

Awọn Alfa se alaye wipe: oju jẹ ilẹkun ti ohun gbogbo le gba de inu ọkan ati awọn ayika ara ti o ku; idi ni yi ti Isilaamu fi se ni dandan  lati rẹ oju wa silẹ, ki a si sọ abẹ wa; bakannaa ki a tun bo ihooho wa pẹlu.

Isilaamu pa asẹ pe ki obinrin bo ihoho ara rẹ patapata wọn ko si gbọdọ fi ọsọ wọn han ayafi  eyi ti o ba han funra rẹ lo ku, sugbọn ki obinrin se ọpọlọpọ igbiyanju lori bi ko se nii fi nkankan han ninu ọsọ rẹ. Eyi ti o seese ki o han naa ni oju ati ọwọ obinrin ti o si gbọdọ bo eyi ti o ku daradara. Bi o tilẹ jẹ pe ki obinrin gbiyanju lati bo gbogbo rẹ (ati oju ati ọwọ rẹ) ni o fi ndara julọ.

Ti obinrin ba nfi ara rẹ han jẹ ohun ti o le jẹ ki o wọ ina Ọlọhun Annabi Muhammad (r) sọ wipe:

 ثبت فى مسند أحمد وصحيح  مسلم عن أبي هريرة مرفوعا : صنفان من أهل النار لم أرهم بعد : قوم معهم سياط كأذناب البقر يضربون بها الناس ، ونساء كاسيات عاريات مميلات مائلات رؤسهن كأسنمة البخت المائلة ، لا يدخلن الجنة ولا يجدن ريحها ، وإن ريحها لتوجد من مسيرة كذا وكذا).

“Awọn iran meji kan yoo  wọ ina ti wọn ko tii si laye lakoko yii: Awọn kan ti wọn ni ohun ti wọn ma nfi lu eniyan ti ọ da gẹgẹ bi iru maalu, ẹni keji ni obinrin ti wọn si ara wọn ati ọsọ wọn silẹ, ti wọn si maa n yan sọtun ati ọsi, ti irun ori wọn si da gẹgẹ bi ike Rakunmi ti o nyi sọtun ati osi, awọn wọnyi ko ni wọ Al-jannah, koda wọn ko ni gbọ oorun rẹ, oorun Al-jannah jẹ ohun ti a ma ngbọ lati bi irin ajo ọjọ bayi bayi” Muslim lọgba Hadiisi yi wa.

Hadiisi yi ntọka si awọn obinrin kan – gẹgẹ bii agbọye awọn Alfa – ti wọn wọ asọ fẹlẹfẹlẹ tabi eyi ti o fun mọ  ara wọn eyi ti o nse afihan ihoho wọn, ti ko si bo ihooho ara wọn pẹlu, ani awọn obinrin ti wọn ko gba ododo ti wọn sin se ipolowo ẹwa ti Ọlọhun fi si wọn lara, tori naa asọ ti obinrin gbọdọ wọ jẹ eyi ti ko ni fi ihooho ara wọn han, ti ko nii fun mọ wọn lara pẹlu.

 

Awọn obinrin isiwaju gba fun Ọlọhun Ẹlẹda wọn, wọn ni itiju, wọn si ma mbo ihooho ara wọn ni abotan lai yọ ibi kankan silẹ. Ni igba ti Aayah Hijab sọ kalẹ awọn iyawo awọn sahabe tẹle asẹ Ọlọhun ni ọjọ naa lọhun lai lọra rara.

وفى الصحيح عن صفية بنت شيبة، عن أم سلمة قالت: لما نزلت هذه الآية: { يُدْنِينَ عَلَيْهِنَّ مِنْ جَلابِيبِهِنَّ } ، خرج نساء الأنصار كأن على رؤوسهن الغربان من السكينة، وعليهن أكسية سود يلبسنها . الله أكبر سرعة الإستجابة لأمر الله ورسوله.

Iya wa Sọfiyah bintu Saibah sọ fun wa pe iya wa Ummu Salmah sọ pe ni igba ti Aayah Hijab sọ kalẹ Suratun-Nur:31 ti wọn ba jade nse ni o da gẹgẹ bii pe ẹyẹ kanakana wa lori wọn, fun ifara- balẹ, ti wọn si gbe asọ dudu wọ” Bukhari lọ gba Hadiisi yii wa eleyi jẹ iyara tẹle asẹ Ọlọhun Ẹlẹda wọn.

وعن أم سلمة قالت لها امرأة : إني امرأة أطيل ذيلي وأمشي في المكان القذر ؟ قالت : قال رسول الله صلى الله عليه وسلم: (يطهره ما بعده) . رواه مالك وأحمد والترمذي وأبو داود والدارمي.

Obinrin kan sọ fun Umu Salmah ikan ninu awọn iyawo Annabi Muhammad (r) pe: emi ma njẹ ki asọ mi wọlẹ lẹyin; mo si maa nrin ni ibi ti idọti wa. Umu Salmah sọ pe: Annabi Muhammad (r) sọ pe: ti o ba tile ko idọti; ilẹ eyi ti o ba tun gba kọja miran yo sọọ di mimọ. Maalik, Ahmad, Tirimidhi, Abu Daaud ati Darimi lo gba Hadiisi yii wa.

Ewu ti o tobi pupọ ni o jẹ ti a ko ba fun awọn iyawo wa ati awọn obinrin wa ni idanilẹkọ ọrọ Ọlọhun, tori pe eleyi yoo ko wa si inu iparun. Ọlọhun se ọkunrin ni alamoju to ati opomulero fun wọn, Oluwa si da wa ni ọla, wọn si jẹ ẹni ti laakaye  ati ẹsin rẹ dinku si ti ọkunrin.

Eleyi ni Annabi Muhammad (r) fi sọ ninu ọrọ idagbere rẹ ni Haji ikanhin wipe: “ẹ tẹti gbọ, mọ sọ asọlẹ fun yin pe ẹ maa se daradara pẹlu awọn ọbinrin, awọn obinrin yi jẹ oluranlọwọ labẹ yin”, ninu Hadiisi Annabi Muhammad (r) sọ pe:

حديث عمرو بن الأحوص الجشمى رضى الله عنه، أنه سمع النبى صلى الله عليه وسلم فى حجة الوداع يقول بعد أن حمد الله تعالى و أثنى عليه و ذكر ووعظ ثم قال : (ألا واستوصوا بالنساء خيرا ، فإنما هن عوان عندكم - وفى بعض ألفاظه-: استوصوا بالنساء فإن المرأة خلقت من ضلع، وإن أعوج شيء في الضلع أعلاه، فإن ذهبت تقيمه كسرته، وإن تركته لم يزل أعوج فاستوصوا بالنساء

“Mo sọ asọ silẹ daradara fun awọn obinrin, dajudaju a a se ẹda obinrin lati ibi ẹfọnha yin, ibi ẹfọnha ti oke ti o wọ julọ ni a ti se ẹda wọn, ti iwọ ọkunrin ba se ni dandan lati tọọ yoo kan, ti o ba fi kalẹ bẹẹ, o o maa gbadun rẹ pẹlu bi o se tẹ , ti o si wọ kọdọrọ; mo sọ asọlẹ daradara fun awọn obinrin”.

Oluwa da ọrọ obinrin sọ ni aarin yi nitori jijẹ ọlẹ wọn ati wipe wọn ni bukata si ẹniti yoo maa tun wọn se, ẹ gba ọrọ emi Annabi yii, ki ẹ si muu lo, ki ẹ se suuru pẹlu wọn, ki ẹ si se pẹlẹpẹlẹ pẹlu wọn; koda ki ẹ se daada si wọn.

Ẹyin Musulumi, o lewu lati fi obinrin silẹ, tabi lati pa wọn ti, eleyi yoo sọ wọn di ẹni buburu ati ẹni ti o le ya iyakuya.

هذا، قال الله تعالى : "إِنَّ اللهَ يَأْمُرُ بِالْعَدْلِ وَالْإِحْسَانِ وَإِيْتَاءِ ذِي الْقُرْبَى وَيَنْهَى عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ وَالْبَغِيِ يَعِظُكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَرُونَ. وَأَوْفُوا بِعَهْدِ اللهِ إِذَا عَهَدْتُمْ وَلاَتَنْقُضُوا الْأَيْمَنَ بَعْدَ تَوْكَيدِهَا وَقَدْ جَعَلْتُمُ اللهُ عَلَيكُمْ كَفِيلاً إِنَّ اللهَ يَعْلَمُ مَا تَفْعَلُونٍَ"

اللَّهُمَّ أّرِنَا الْحَقَّ حَقًا، وَارْزُقْنَا اتِّبَاعَه، وَأَرِنَا الْبَاطِلَ بَاطِلاً ، وَارْزَقْنَا اجْتِنَابَه.

اللَّهُمَّ وَلِّ أُمُورَنَا خِيَارَنَا، وَلاَ تُوَلِّ أُمُورَنَا شِرَارَنَا، اللَّهُمَّ اصْلِحْ وُلاَةَ أُمُورَنَا، وَلاَ تُوَلِّ عَلَيْنَا بِذُنُوبِنَا مَنْ لاَ يَخَافُكَ فِيْنَا وَلاَ يَرْحَمُنَا. اللَّهُمَّ اغْفِرْ جَمِيعَ أَمْوَاتِ الْمُسْلِمِينَ الَّذِينَ شَهِدُوا لَكَ بِالْوَحْدَانِيَةِ وَبِنَبِيِّكَ بِالرِّسَالَةِ وَمَاتُوا عَلَى ذَلِكَ. اللَّهُمَّ اغْفِرْلَهُمْ وَارْحَمُهُمْ وَاعَفْ عَنْهَمْ وَاكْرِمْ نُزُلَهُمْ، وَوَسِّعْ مُدْخَلَهُمْ وَاغْسِلْهُمْ بِاْلَماَءِ وَالثَّلْجِ وَالْبَرَدِ، وَنَقِّهِمْ مِنَ الُّذنُوبِ وَالْخَطَايَا كَمَا يُنَقَّى الثَّوْبُ الْأَبْيَضُ مِنَ الدَّنَسِ وَارْحَمْنَا اللَّهُمَّ إِذّا صِرْنَا إِلَى مَا صَارُوا إِلَيْهِ بِرَحْمَتِكَ يَا أَرْحَمَ الرَّاحِمِينَ.