OJUSE OLORI ATI AWỌN TI WỌN WA NI ABẸ WỌN

Eko ni soki

Ojise Olohun ki ike ati ola Olohun maa baa je ki o ye wa wipe gbogbo wa pata ni adaranje a o si bi wa leere bi a se da awon eran naa je si,eniti o ba je olori ni aaye kan ninu wa ki o gba wipe gbogbo lilo bibo oun ni Olohun ri, ti yio si san an ni esan bi o ba se se pelu awon ti Olohun ko si ni abe.

Awọn erongba Khutubah naa:                 

1.         Alaye pipe sariah ninu eto ati igbekalẹ rẹ

2.      Alaye lori wipe dandan ni ki a se akoso ara ẹni ninu sariah

3.         Sise alaye awọn ojuse ti o wa fun awa ti wọn ndari

4.      Ki a ran olori leti awọn ojuse rẹ.

Oluwa sọ wipe :              

اليوم أكملت لكم دينكم وأتممت عليكم نعمتي ورضيت لكم الإسلام دينا"

“oni yi ni mo pe ẹsin yin fun yin, mo si pari idẹra mi leyin lori, mo si yọnu si Isilaamu fun yin ni ẹsin” suratul maidah:3

ẹsin Isilaamu jẹ ẹsin ti o pe ye ti ko si agbegbe ti ko sọ ọrọ asọye lori rẹ, ko si ohun ti o le se anfani fun eniyan ti sariah Isilaamu ko dasi, ko si si iran ẹda ti sariah Isilaamu ko sọ nipa wọn yala olowo ni tabi talika, ọmọde ni tabi agbalagba,ọkunrin ni tabi obinrin, koda ti o fi de ori (dabba) ẹranko.

Isilaamu se akolekan idari ẹni, jijẹ olori ati asiwaju, Isilaamu ko fi ọmọ eniyan silẹ lasan lai ni si oludari, koda Annabi Muhammad (r) rọ awọn ti wọn ba n se irin ajo papọ ki wọn yan olori laarin wọn koda bi o se pe eniyan meji ni wọn jẹ lori irin ajo naa.Isilaamu ran wa leti Pataki ti o wa lori ki a yan olori daradara, nititori ki olori bẹẹ le sun oore mọ wọn, ki o si da aabo bo wọn, ki o si jẹ ki aburu jinna si wọn pẹlu, ojuse ẹsin ni yiyan olori jẹ ki a to le pee ni ojuse ti oselu ati ti aye; nitori pe titẹle alasẹ wa ninu itẹle ti Ọlọhun ati Annabi Rẹ. Oluwa sọ wipe:

قال تعالى : {يا أيها الذين آمنوا أطيعوا الله وأطيعوا الرسول وأولي الأمر منكم}

“ẹyin ti ẹ gba Ọlọhun gbọ, ẹ tẹle ti Ọlọhun, ẹ si tẹle ti ojisẹ Rẹ, bakannaa ki ẹ si tẹle ti awọn alasẹ yin” Suratun Nisaa:59.

Annabi Muhammad (r) sọ wipe:

وقال رسول الله r : "من أطاعني فقد أطاع الله، ومن عصاني فقد عصا الله، ومن يطع الأمير فقد أطاعني، ومن يعصِ الأمير فقد عصاني، وإنما الإمام جُنَّة يُقاتَل مِن ورائه، ويُتَّقَى به، فإن أمر بتقوى الله وعَدَل فإن له بذلك أجرًا، وإن قال بغيره فإنّ عليه مِنْهُ" متفق عليه وهذا لفظ البخاري.

“ẹniba tẹle mi ti tẹle ti Ọlọhun, ẹni ba sẹ mi sẹ Ọlọhun, ẹni ba tẹ le ti olori ti tẹ le temi, ẹni ba sẹ olori ti sẹ mi, a se olori ni aabo ti a o ma jagun lẹhin rẹ, ti olori ba pasẹ ipaya Ọlọhun ti o se dọgbadọgba; yoo gba ẹsan rẹ, ti olori ba si sọ nkan miran, nkan ti ọ ba se ni yo jẹ tirẹ”. Bukhar ati Muslim lo gba Hadiisi yii wa.

Ninu ohun ti a gbọdọ se fun olori ni ki a tẹ le asẹ rẹ gẹgẹ bi ọrọ Ọlọhun ati Hadiisi ti a darukọ si oke yii, ki a se iranlọwọ fun un lori bi yoo se se lori awọn kudiẹ kudiẹ kọọkan ti o ba n se, ki a maa se adura fun un ki Ọlọhun tun  un se, ki a ripe ifọkanbalẹ ridi joko ni awujọ, ki a si maa se ikilọ fun un pẹlu.

Ninu ohun to olori gbọdọ se fun awọn ti o wa ni abẹ rẹ ni ki o se deede pẹlu wọn, ki o si maa se dada fun wọn pẹlu. Ọlọhun sọ wipe: “Dajudaju Ọlọhun pasẹ ki a ma se deede ki a si maa se daradara”. Suratun-Nakhi: 90. Annabi Muhammad (r) sọ wipe:

وفي الحديث : "كلكم راع وكلكم مسؤول عن رعيته".

“Gbogbo yin ni adaran jẹ, gbogbo yin ni a o bere gẹgẹ bi ọ se da ẹran naa jẹ si”.

Olori gbọdọ maa yanju awọn ede-aiyede larin awọn eniyan, ki o si pa ina aawọ, ki o si ri wipe ẹtọ awọn eniyan nde ọdọ wọn daadaa, ki olori mu oju to ẹtọ ti o peye fun awọn ti wọn wa labẹ rẹ, ki olori mu oju to eto ẹkọ, ati gbogbo ohun ti o ba le ko orire, ayọ ati idunu ba awọn ara ilu rẹ.

 

Ko lẹtọ ki ara ilu tapa si olori ayafi ti a ba ri ẹsẹ ti Sariah tako lati ọdọ olori. Ninu Hadiisi ti Bukhari gba wa Annabi sọ wipe:

قال رسول الله r : "سَتَكُونُ أَثَرَةٌ وَأُمُورٌ تُنْكِرُونَهَا قَالُوا يَا رَسُولَ اللَّهِ فَمَا تَأْمُرُنَا قَالَ تُؤَدُّونَ الْحَقَّ الَّذِي عَلَيْكُمْ وَتَسْأَلُونَ اللَّهَ الَّذِي لَكُمْ " أخرجه البخاري.

 “Ẹyin ko ni se alai ri oun ti ọkan yin kọ, wọn si bere wipe iwọ ojisẹ Ọlọhun ki ni a gbọdọ se? Annabi si sọ wipe: ki ẹyin se ojuse ti o yẹ  lati se, ki ẹ si bẹ Ọlọhun yin lati bayin  gba ẹtọọfun yin .

قال شيخ الإسلام ابن تيمية : "ولهذا كان المشهور من مذهب أهل السنة أنهم لا يرون الخروج على الأئمة وقتالهم بالسيف، وإن كان فيهم ظلم كما دلت على ذلك الأحاديث الصحيحة المستفيضة عن النبي صلى الله عليه و سلم، لأن الفساد في القتال والفتنة أعظم من الفساد الحاصل بظلمهم بدون قتال ولا فتنة، فلا يدفع أعظم الفسادين بالتزام أدناهما، ولعله لا يكاد يعرف طائفة خرجت على ذي سلطان إلا وكان في خروجها من الفساد ما هو أعظم من الفساد الذي أزالته.

Afa Ibnu  Tai’miyah sọ bayi pe: eyi ti o gbajumọ ju laarin awọn oni Sunnah ni ki wọn ma se tapa si asẹ olori wọn, ki wọn si ma se kọ oju ida si, koda bi a ba ri abosi lati ọdọ iru olori bẹẹ. Nitori pe ibajẹ ti o wa ninu dida oju ida kọ ara ẹni buru pupọ ju ibajẹ ti o wa ninu abosi sise yẹn. A ko ri awọn ti wọn kọju ida kọ ara wọn ti ko buru ju ibajẹ ti wọn fẹ kọ lọ. Awọn yowu ti wọn ba daju ida kọ olori wọn nse ohun ti o yapa si ohun ti Sunnah sọ ati ọrọ awọn alfa ẹsin daada ti wọn ti kọja lọ.

O di ọwọ awọn ti wọn ndari ilu lati maa se dọgbadọgba si awọn ara ilu.Afa Ibnu   Taimiyah sọ wipe:

إنَّ اللَّهَ يُقِيمُ الدَّوْلَةَ الْعَادِلَةَ وَإِنْ كَانَتْ كَافِرَةً؛ وَلا يُقِيمُ الظَّالِمَةَ وَإِنْ كَانَتْ مُسْلِمَةً، وَيُقَالُ : الدُّنْيَا تَدُومُ مَعَ الْعَدْلِ وَالْكُفْرِ، وَلاَ تَدُومُ مَعَ الظُّلْمِ وَالإسْلامِ،

“Dajudaju Ọlọhun ma nkun ijọba onideede lọwọ, koda bi iru ijọba bẹẹ ba jẹ keferi, Ọlọhun kii kun ijọba alabosi koda bo jẹ Musulumi, toripe aye le maa jẹ aye pẹlu ijọba onideede pẹlu keferi, sugbọn ko le seese ki aye wa pẹlu ijọba abosi pẹlu Isilaamu. Annabi Muhammad (r) sọ wipe:

Iya ti Ọlọhun tete maa n fi jẹ ọmọniyan ni iya ẹsẹ abosi ati jija okun ẹbi”.

هذا، قال الله تعالى : "إن الله يأمر بالعدل والإحسان وإيتاء ذي القربى وينهى عن الفحشاء والمنكر والبغي يعظكم لعلكم تذكرون  "

اللَّهُمَّ لاَ تَدَعْ لَنَا فِي مَقَامِنَا هَذَا ذَنْبًا إِلاَّ غَفَرْتَه، وَلاَ دَيْناً إِلاَّ قَضَيْتَه، وَلاَ مَرِيضاً إِلاَّ شَفَيْتَه، وَلاَ مُسَافِراً إِلاَّ رَجَعْتَه وَلاَ ضَالاًّ إِلاَّ هَدَيْتَه وَلاَ دَاعِيًا فِي سَبِيلِكَ إِلاَّ  وَفَقْتَه، وَلاَ حَاجَةً مِنْ حَوَائِجِ الدُّنْيَا وَالآخِرَةِ هِيَ لَكَ فِيهَا رِضَا وَلَنَا فِيهَا صَلاَح إِلاَّ قَضَيْتَهَا وَيَسَّرْتَهَا لَنَا يَا رَبَّ الْعَالَمِين.

رَبَّنَا هَبْ لَنَا مِنْ لَدُنْكَ رَحْمَةً وَهَيِّئْ لَنَا مِنْ أَمْرِنَا رَشَدا. رَبَّنَا هَبْ لَنَا مِنْ أَزْوَاجِنَا وَذُرِيَاِتنَا قُرَةً أَعْيُنٍ وَاجْعَلْنَا لِلَمُتَقِينَ إِمَامًا.

رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الأَخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَذَابَ النَّارِ.