Eko ni soki

Dajusaka, wiwa ati didaamu lori ohun ti o to je alaamori ti o je oranyan ti o si je dandan gbon lori omoniyan, ese eru koni ye kuro nibi isiro ni ojo igbehinde titi ti won yio fi bi nipa owo ti o ni, nibo ni o ti ko jo atiwipe nibo ni o na si, laisi tabi sugbon, iwo ni o je lori gbogbo musulumi lokunrin ati lobinrin lati wa ohun o mo ninu ise ki o le ba maa je ohun ti o to ki o si le maa na ninu ohun ti o to, ki o si jinna si jije ohun eewo ati ohun ti o ruju ti o jo nkan eewo, gbogbo ara ti o ba tobi lati ibi nkan eewo, ina ni yio jo ara naa.

Erongba Lori Khutuba naa:

 Ipepe si kik r ti o m j.

 Alaye lori sise pl nipa kiko ohun aye j ati kiko ara ni ni ijanu ninu aye.

 Ikil kuro nibi fifi to lt dun un.

Ajul ti o wa fun ohun ti o j to lori ohun ti o j eew.

الحمد لله رب العالمين أمر بالأكل من الطيبات ونهى عن اقتراب الخبائث المضرة بالبدن فقال عزّ من قائل: {يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آَمَنُوا كُلُوا مِنْ طَيِّبَاتِ مَا رَزَقْنَاكُمْ وَاشْكُرُوا لِلَّهِ إِنْ كُنْتُمْ إِيَّاهُ تَعْبُدُونَ} وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له وأشهد أنّ محمّدا عبده ورسوله صلى الله عليه وعلى آله وصحبه أجمعين.

Ọpẹ fun Ọlọhun Ọba gbogbo ẹda ti o pasẹ jijẹ ninu ohun mimọ ti o si kọ gbogbo ohun ti ko mọ ati eyi ti o le pawa lara nigbati o n sọ ninu ọrọ Rẹ wipe: “Ẹyin Olugbagbọ ododo, ẹ jẹ ninu arisiki yin eyi ti o mọ, ki ẹ si maa dupe fun Ọlọhun ti o see fun yin to ba jẹ pe Oun ni ẹ n sin ni tootọ”. Mo n se afirinlẹ lati inu ọkan mi pe ko si ọba miran taa le maa sin lododo ayafi Ọlọhun, Ọba ti ko ni orogun ati wipe Anabi Muhammad ẹru Ọlọhun ni, ojise Rẹ si ni pẹlu. Ikẹ Ọlọhun ati ọla R ki o maa ba gbogbo wọn lapapọ”.

 Ẹyin ẹrusin Oluwa, Oluwa ti kẹ wa ni ikẹ ti o gbooro. A ko sile ka onka ikẹ naa.

Se alaafia ni a fe s ni abi iriran abi igbr ti oluwa se fun wa ati bẹẹbẹẹ l.

Ninu ohun ti o tobi julọ ninu oore r ti o se fun wa ni oore “Isilaamu”

Tani ninu wa ti ko wu lati gbe igbesi aye ti o ni adun ati oyin ni aye ati orun? Nitoripe oluwa ti see ni tọ pe ki a ma j ohun ti o m ki a si jinna si ohun eewo ni jij.

Ẹyin rusin lhun, wiwa arisiki ati igbesi aye ti o rọrun jẹ ohunti ẹsin dasi.

 Oluwa ti se san fun  wiwa ij ati imu. Oluwa si se fun mniyan nibẹ aaye ti o tẹ lati na iyẹ. Oluwa pa wn lasẹ pe ki wn rin kaakiri oril lati wa arisiki l.

Oluwa wipe : awn ti n wa ohun jijẹ ati mimu ko yat si ẹniti n jagun si oju na Oluwa.(Suratu Muzamil)

Annabi fun wa ni iro pe. Ẹnikan ko j ounjẹ kan ti o ni oore fun un ju ohun ti o fi w ara rẹ kojọ lọ. Nitoripe Annabi Da’wood ma n j ninu isẹ w rẹ. (Bukhari)

 Nini ayo ọkan kuro nibi ohun ti Ọlọhun se fun awn eniyan se pataki nitoripe o ma n se apnle fun eniyan.

Khalifa Umar bn Khatab ni, iru aye ti o ma n wu ohun ni pe ki iku ka oun m ni aaye ti oun ti n wa ohun ti awn ẹbi oun yoo jẹ.

 Ninu asọtẹlẹrẹ Lukman ọjọgbọn fun ọmọ rẹ ni pe, ki wọn maa jẹ ninu ohun ti o mọ. Oluwa ti pasẹ bẹẹ fun awn musulumi gẹgẹ bi o ti se pasẹ rẹ fun awn ojis Rẹ.

 Oluwa ni:

يَا أَيُّهَا الرُّسُلُ كُلُوا مِنَ الطَّيِّبَاتِ وَاعْمَلُوا صَالِحًا إِنِّي بِمَا تَعْمَلُونَ عَلِيمٌ

"Ẹyin ojisẹ ẹ maa jẹ ninu ohun ti o mọ ki ẹ si maa se daadaa. Daju-daju

Emi ni imọ ohun gbogbo ti ẹ n se"

 Oluwa ti ọla Rẹ ga tun wipe:

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آَمَنُوا كُلُوا مِنْ طَيِّبَاتِ مَا رَزَقْنَاكُمْ وَاشْكُرُوا لِلَّهِ إِنْ كُنْتُمْ إِيَّاهُ تَعْبُدُونَ

"Ẹyin onigbagbọ ododo ẹ maa jẹ ninu eyi ti o mọ ninu ohun ti a pa lese fun yin, ki ẹ si maa dupẹ fun Ọlọhun ti o ba jẹ pe Ọlọhun ni ẹ

 nsin "...Suratul-l-Bakorah.

 Ninu ohun ti o jẹ pataki ninu ohun ti Annabi (صلى الله عليه وسلم) se alaye rẹ fun wa ni mimọ ohun ẹto yatọ si ohun eewọ.

Ti o ba di ọjọ ikẹyin, inu idunnu ni awon ti ma n se nkan ti o tọ yoo wa. Oluwa wipe:

الَّذِينَ تَتَوَفَّاهُمُ الْمَلَائِكَةُ طَيِّبِينَ يَقُولُونَ سَلَامٌ عَلَيْكُمُ ادْخُلُوا الْجَنَّةَ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ

"Awn ti o se pe bi awọn Malaika ba n gba ẹmi wọn ti wn jẹ ẹni mimọ, wọn yoo ma s pe; alafia ki o maa ba ẹyin, ẹ wọ ọgba idẹra naa nitori ohun ti ẹ ti se (nisẹ)... Suratul Nahli-32

Abdullaọh bn Amri s pe: Annabi wipe: ẹniti o ba ni iroyin mẹrin kan, konii bukata si nkankan miran mọ. Awọn nkan mẹrin naa ni: ki eniyan ni asiri tori ohun ti won fi sii lọwọ, ododo sisọ, iwa rere ati asajẹ.

 Mimọ wa arisiki ti o mọ jẹ alamọri ti o se dandan nitoripe ẹru ko ni re kja ni iwaju Oluwa ni ọjọ ikẹyin afi ki o dahun awọn ibeere kan. Nibo ni o ti ri dukia r ati pe nibo ni o naa

 Wn ni ọmọ ọdọ Abubakri gbe ounjẹ kan wa fun’un, ni igbati o n jẹ ounjẹ naa ni ọmọ ọdọ naa wipe: n jẹ o mọ ibi ti ounjẹ yii ti wa? Ọmọ ọdọ naa ni mo se adadigba fun eniyan kan ni igba aimọ, tohun ti bi o ti jẹ pe mi o mọ adadigbaa se, sugbọn mo kan taan lasan ni.  Eleyi ni o fa ti o fi fun mi ni ohun ti o n jẹ yii. Wọn ni Abubakr si ki ọwọ bọ ọna ọfun rẹ ti o si fi pọ gbogbo ohun ti o  jẹ...(Bukhari ni o gbaa wa)

 Ninu ẹgbawa miran, Abubakr wipe: koda ti yoo ba jade plu mi mi, n o kọ lati se bẹẹ. Sibẹ-sibẹ Abubakri  tun bẹ Oluwa ki O fi ori jin oun latari eyi ti o ti ropọ mọ ifun ati inu oun ninu ounjẹ eewọ naa, ti ko see pọ jade!

اللهم إني أعتذر إليك مما حملت العروق وخالطه الأمعاء

 Umar  na mu wara kan lẹyinaa ni o beere lọwọ ẹniti o fun un pe, nibo ni o ti rii? Nigbati o se alaye ibi ti o ti rii, ti o jẹ ọna erú,  Umar naa ki ọwọ bọ ọna ofun rẹ ti o si fi pọ ohun ti o ti mu.

 Awọn apakan awọn iyawo awọn ẹni daadaa ninu awọn ẹni rere ti o ti l, maa n s fun awọn ọkọ wọn pe: irẹ ọkọ wa paya Oluwa nibi ohun ti o maa fun wa ni ounjẹ nitoripe awa le fi ara da ebi sugbọn a ko le fi ara da iya ina.

 Awọn ti a se alaye ọrọ wọn wọnyi ni awọn oluse daadaa nitoripẹ wọn ko fi ààyè gba Arãmu ninu ikun wọn.

 Ẹyin ẹru Oluwa, ẹ mọ daju pe Arãmu jijẹ ni suta ati ewu ti o ni agbara lori ẹnikọọkan ati awujọ. Nitoripe yoo se okunfa pipadanu alubarika ni awujọ.

Egbé Ọlọhun ni fun gbogbo awọn ti wọn jẹ ninu awọn nkan eewọ bakannaa ti wọn si nre awọn ọmọ wọn pẹlu rẹ. Ọrọ wọn da gẹgẹ bii ẹniti n mu omi ni odo sib-sib ni oungbẹ ko si ye gbẹ ẹ.

 Annabi sọ pe: ti o ba di akoko kan, ọmọniyan ko ni bikita nipa ohun ti o n jẹ boya ibi ẹto ni o ti wa abi lati ibi eewọ.

O di ọwọ gbogbo ọmọniyan lati ri daju pe ohun ti a n jẹ ati ohun ti a n mu jẹ nkan alaali.

 Oluwa rọ wa ni ọrọ pẹlu ẹto kuro  ni`bi eewọ bakana ko jẹ ki a le maa tle asẹ Rẹ. Bakana ki Oluwa ma se aye ni opin oore wa.

 Ninu awọn ohun ti eniyan fi le sa fun aye ni ki o kuro nibi awọn ohun ti Oluwa se ni eewọ.

Abu Huraira s pe: Annabi (صلى الله عليه وسلم) s pe: ẹniti dukia ẹnikan ba wa ni ọdọ rẹ tabi ijẹ mniyan rẹ, ki o yara gbiyanju lati se adapada rẹ ki o to di ọjọ ti ko ni si Diinọri abi Diriamu. Sugbọn ti o ba ni awọn isẹ rere, ibẹ ni wn yoo ti baa san  gbogbo gbese rẹ. Ti ko ba si ni isẹ rere wọn yoo mu ninu ẹsan isẹ buburu ti ẹni ti o jẹ ni gbese wọn a si dii kun ẹru ti onitọhun.

 

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ عَنِ النَّبِيِّ r قَالَ : "مَنْ كَانَتْ عِنْدَهُ مَظْلَمَةٌ مِنْ أَخِيهِ، مِنْ عِرْضِهِ أَوْ مَالِهِ، فَلْيَتَحَلَّلْهُ الْيَوْمَ قَبْلَ أَنْ يُؤْخَذَ حِينَ لا يَكُونُ دِينَارٌ وَلا دِرْهَمٌ، وَإِنْ كَانَ لَهُ عَمَلٌ صَالِحٌ أُخِذَ مِنْهُ بِقَدْرِ مَظْلَمَتِهِ، وَإِنْ لَمْ يَكُنْ لَهُ أُخِذَ مِنْ سَيِّئَاتِ صَاحِبِهِ، فَجُعِلَتْ عَلَيْهِ" أخرجه أحمد


 Ẹyin olugbagbọ ododo, ninu ohun ti musulumi gbọdọ jinna si kikundun aye ati ọsọ aye. Musulumi gbd mu aye bi aaye ti eniyan kan re kọja ni ibẹ.

 Ẹniti o ba jẹ pe aye ni opin ohun ti o wa ninu ọkan rẹ, Oluwa yoo se ifunpinpin fun un ninu aye, bakannaa ko le ri ninu aye tayọ ohun ti Oluwa ba kọ fun-un.

Abu Huraira sọ wipe Annabi s pe: Ẹru owo ti sofo, ti wọn ba fun un, inu rẹ yoo dun amọ ti wọn ko ba fun un yoo binu.

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ : "تَعِسَ عَبْدُ الدِّينَارِ، وَعَبْدُ الدِّرْهَمِ، وَعَبْدُ الْخَمِيصَةِ، إِنْ أُعْطِيَ رَضِيَ، وَإِنْ لَمْ يُعْطَ سَخِطَ

Ninu awọn nkan ti o maa ntọka si pe eniyan ni ifẹ aye nipe ko nii bikita nipa ohun ti o n jẹ.

 Eniyan a maa ji ni owurọ ti yoo si di keferi ki ilẹ to su.

Bakana eniyan le sun ni alẹ ti yoo si di keferi ki ilẹ to mọ.

 Annabi s pe: Ẹ maa gbe ile aye, gẹgẹ bii arinrin ajo tabi ọmọ ori-irin.

 Bakannaa ẹ mọ dajudaju pe ohun ti ẹda yoo jẹ tabi ni ni dukia ni ile aye, yoo tẹẹ lọwọ ki o to fi aye silẹ.

 Ẹ paya Oluwa yin ki ẹ si mọ pe ẹ o pade Rẹ ni ọjọ kan.

Ki ẹ si mọ pe ara ohun ti o maa nfa ibinu Oluwa lori ẹru kan ni Haramu jijẹ.

Ẹniti n jẹ Haramu yoo ma jina si Ọlọhun diẹ diẹ diẹ. Oluwa ni: Oun  yoo pa owo riba run

َيمْحَقُ اللَّهُ الرِّبَا وَيُرْبِي الصَّدَقَاتِ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ كَفَّارٍ أَثِيم [البقرة : 276]

 

 Ẹ jẹ ki a maa wa ohun halaali nitoripe Oluwa yoo fi alubarika sii, bakannaa yoo gba sọdakọ ti a ba se ninu owo wa.

Ninu ohun ti o ma n si ilẹkun ikẹ Ọlọhun ni ìpayà Ọlọhun wa.

 Oluwa ni:

وَلَوْ أَنَّ أَهْلَ الْقُرَى آَمَنُوا وَاتَّقَوْا لَفَتَحْنَا عَلَيْهِمْ بَرَكَاتٍ مِنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ

"Bi o ba se pe awọn ara ilu naa ba gba Ọlọhun gbọ ti wọn si bẹru Rẹ, Awa

(Oluwa) i ba si ilẹkun alubarika fun wọn lati sanmọ ati ilẹ...Suratu Al-

Araf-66

 Ohun ti o tun le fa ki ikẹ Ọlọhun maa sọ kalẹ fun eniyan ni pe ki o maa se adura ati ki o si fi ọkan rẹ si ọdọ Ọlọhun.

Ti eniyan ba ti tẹ le awn ofin Oluwa, Oluwa yoo se ikẹ Rẹ fun un ju bi o se ni ero lọ.

Ki Oluwa se halaali ni irọrun fun wa ki o si se eewọ ni inira fun enikọọkan wa. Bakana ki o si se wa ni ọmọ Alujannah.

 

 

فاشكروا الله على نعمه أن رزقكم من الطيّبات وأدّوا شكرها واستعملوها فى الطّاعة يغدق عليكم من واسع فضله. وصلّوا على رسول رب العالمين فقد أمر الله بذلك فى كتابه المبين قال تعالى: "إن الله وملائكته يصلّون على النّبي يا أيّها الذين آمنوا صلّوا عليه وسلّموا تسليما". اللهم صلّ وسلّم على عبدك ورسولك محمد بن عبد الله وارض اللهم عن الخلفاء الرّاشدين أبى بكر وعمر وعثمان وعلي وعن سائر أصحا نبينا محمد وعنّا معهم بمنّك وكرمك يا أرحم الرّاحمين. اللهم أعزّ الإسلام والمسلمين وأذلّ الشّرك والمشركين ودمّر أعداءك أعداء الدّين، اللهم آمنّا فى أوطاننا وسائر بلاد المسلمين. "إنّ الله يأمر بالعدل والإحسان وإيتاء ذي القربى وينهى عن الفحشاء والمنكر والبغي يعظكم لعلكم تذكّرون".

  

            Nitorinaa, ẹyin ẹrusin Ọlọhun, Ẹ dupe fun Ọlọhun lori awọn Idẹra Rẹ, Ọba to n pese ohun to dara fun yin ni jijẹ ati mimu, ki ẹ si maa loo lati fi tẹ le asẹ Ọlọhun, ki o le se ọpọ ikẹ miran fun yin. Bẹẹni ki ẹ maa tọrọ ikẹ ati igẹ fun Anabi Muhammad ni ibamu si asẹ Ọlọhun to sọ pe: « Dajudaju Ọlọhun ati awọn Malaika Rẹ n fi ibukun fun Anabi, ẹyin ti ẹ gbagbo ni ododo, ẹ maa tọrọ ibukun fun un, ki ẹ si kii ni kiki alaafia ». ki Ọlọhun bani sekẹ segẹ Rẹ fun ẹru Rẹ ati ojisẹ Rẹ Muhammad ọmọ Abdullahi, bẹẹni ki o bawa yọnu si awọn arole rẹ ti wọn jẹ afinimona : Abu bakr, Umaru, Usmanu, ati Aliyyu tofi kari awọn Sahabe re to seku, ki O ma yọ awa naa silẹ ninu ikẹ naa. Ọlọhun gbe asọ agbara wọ awa Musulumi ati Isilaamu lọrun. Bẹẹni ki o bawa run awọn ọta Rẹ ti wọn jẹ ọta ẹsin, Ọlọhun jogun ifọkanbale fun wa lorilẹ-ede yii ati awọn ile Isilaamu lapapo. Dajudaju Ọlọhun pawa lasẹ ẹtọ sise ati sise rere ati ki a maa fun awọn ẹbi (ni ẹtọ wọn), O si n kọ fun ni iwa ibajẹ ati iwa buburu ati rukerudo, O n se ikilọ fun un yin ki e le baa gba ikilọ naa ati ki ẹ maa mu adehun Ọlọhun sẹ nigbati ẹnyin ba se e, ati ki ẹ ma si tu ara bubu yin palẹ lẹhin igba ti e ti se e, bẹẹ si ni ẹ ti se Ọlọhun ni ẹlẹri le ara yin lori. Dajudaju Ọlọhun Mọ ohun ti ẹ ba n se ni isẹ ».