Eko ni soki

Idaa okun ibi po je alaamori kan ti Olohun fi maa ngbooro arisiki, O si tun je okunfa emigigun, Olohun si maa nfi se ibukun dukia eniyan, idaibipo je apere pipee igbagbo ati didaa Islam eniyan, ni ida miran, ijakun ebi je okunfa ibidandan Olohun ati ijiya re, ati egbee ati iya, ti yio maa pa alubarika re, ti yio si maa jogun ota sise ati ikorira eni.

Awọn erongba khutubah naa:

1-     Alaye Pataki ati paapa dida ẹbi pọ

2-     Alaye  ọla ti o wa ninu dida ẹbi pọ.

3-     Ki a sọra fun jija okun ẹbi.

Pataki ni koko ọrọ dida ẹbi pọ jẹ ; tori pe oun ni Annabi Muhammad (r) sọ wipe: o ma njẹ ki arisiki ẹni pọ si, o si ma nse sababi ki ẹmi ẹni gun pẹlu, o si ma nfa ki ibukun (Albarkah) Ọlọhun wọ inu dukia ẹda. Awọn ẹbi ẹni ni awọn ti wọn sun mọ wa julọ: bi Iya ẹni, baba ẹni, ọmọ ẹni, lọkunrin ati ọmọ ẹni lobinrin; gbogbo ẹni ti  a ba tan papọ lapa baba ẹni tabi lapa Iya ẹni, tabi lapa ọmọ ẹni, lọkunrin tabi ọmọ ẹni lobinrin.

Ọpọlọpọ Hayah Al-kur’an ati Hadiisi Annabi Muhammad (r) lo nsọ Pataki dida ẹbi pọ ati ewu ati ẹsẹ ti o wa ninu jijakun ẹbi, ati ọla ti o wa ninu sise daradara si wọn. Oluwa yin awọn ti wọn nda ẹbi ti Ọlọhun fẹ ki a da papọ:

 فقال : {وَالَّذِينَ يَصِلُونَ مَا أَمَرَ اللّهُ بِهِ أَن يُوصَلَ وَيَخْشَوْنَ رَبَّهُمْ وَيَخَافُونَ سُوءَ الحِسَابِ} [الرعد : 21].

وذم القاطعين ذماً شديداً فقال : {وَالَّذِينَ يَنقُضُونَ عَهْدَ اللّهِ مِن بَعْدِ مِيثَاقِهِ وَيَقْطَعُونَ مَآ أَمَرَ اللّهُ بِهِ أَن يُوصَلَ وَيُفْسِدُونَ فِي الأَرْضِ أُوْلَئِكَ لَهُمُ اللَّعْنَةُ وَلَهُمْ سُوءُ الدَّارِ} [الرعد : 25].

“Atipe awọn ni ẹni ti nwọn so pọ ohun ti Ọlọhun palasẹ pe ki a so pọ, nwa a si maa paya Ọlọhun wọn, nwọn si tun ma nbẹru isiro buruku” Suratur-Ra’d: 21. Ọlọhun si bu awọn ti wọn nja okun ẹbi gidigan: “Atipe awọn ẹni ti ntu adehun ti Ọlọhun lẹhin igba ti wọn see, ti nwọn si ja ohun ti Ọlọhun palasẹ pe ki nwọn sọ pọ, ti nwọn si nse ibajẹ ni ori ilẹ, awọn wọnyi egbe ni fun wọn atipe ti wọn ni ile buburu Suratur-Ra’d” 25.

Ọlọhun si tun leri iya fun awọn ti nwọn nja okun ẹbi ati awọn ti wọn nse ibajẹ lori ilẹ:

{فَهَلْ عَسَيْتُمْ إِن تَوَلَّيْتُمْ أَن تُفْسِدُوا فِي الأرْضِ وَتُقَطِّعُوا أَرْحَامَكُمْ * أُوْلَئِكَ الَّذِينَ لَعَنَهُمُ اللَّهُ فَأَصَمَّهُمْ وَأَعْمَى أَبْصَارَهُمْ} [محمد : 22 – 23].

ووصّى الله تعالى بذوي الأرحام خيراًَ فقال : {وَاتَّقُواْ اللّهَ الَّذِي تَسَاءلُونَ بِهِ وَالأَرْحَامَ إِنَّ اللّهَ كَانَ عَلَيْكُمْ رَقِيبًا} [النساء : 1].

“Njẹ ẹ ha le ma reti pe ti ẹ ba jọga, ki ẹyin wa se ibajẹ lori Ilẹ , ẹ o si tun ja okun ẹbi yin bi? Awọn wọnyi ni Ọlọhun ti sẹbi le, nitorinaa o di wọn leti o si fọ oju wọn. Suratul Muhammad: 22-23”. Ọlọhun si tun sọ asọtẹlẹ fun ọmọniyan pe ki o sẹ daradara si awọn ẹbi rẹ: “… Ki ẹ si bẹru Ọlọhun, ẹni ti ẹ fi mbẹ ara nyin ati okun ẹbi, dajudaju Ọlọhun, jẹ olusọ lori yin.”

وعن أنس بن مالك رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم: (( إن الرحم شجنة [الشجنة : غصن الشجر] متمسكة بالعرش تَكلَّم بلسان ذلْق : اللهم صِلْ من وصلني، واقطع من قطعني، فيقول الله -تبارك وتعالى-: أنا الرحيم الرحمن، وإني شققت للرحم من اسمي، فمن وصلها وصلته، ومن نكثها نكثته" أخرجه البخاري في "الأدب".

Ọlọhun pa asẹ ki a da ẹbi pọ, ti o si nkọ fun awọn ti nja okun ẹbi. Okun ẹbi Iya da gẹgẹ bi ẹtuntun igi ti o fi ara kọ Al-‘arshi ti o si nfi ahọn sọ ọrọ pe: Oluwa se idapọ fun ẹni ti o ba  da mi pọ , ki o si ja danu ẹni ti o ba ja pẹlu mi, ti Ọlọhun ti ọla rẹ ga si sọ wipe : Emi ni Olukẹni laye ati Asakẹ ọrun mo yọ orukọ apo ẹbi Iya lati ara orukọ mi, ẹni ba da ẹbi pọ maa da ẹni na pọ, ẹni ba jamba rẹ emi yo san iru ẹnibẹẹ lẹsan ti ko dara” Bukhari logba Hadiisi yii wa. Ninu Al-Adab.

Dida ẹbi pọ jẹ apẹẹrẹ ipaya Ọlọhun ti o le waye pẹlu ki a maa se ikilọ fun ẹbi ki a si maa fun un ni imọran, ki a maa lo ifẹ pẹlu rẹ, ki a na ọwọ ifẹ  si ẹbi ati ki a se deede pẹlu. Ki a si se ohun ti o jẹ dandan lati se, ati ohun ti a fẹ lati se si ẹbi ẹni bi agbara ba se to. Gẹgẹ bi ki a kọọ lẹkọ, ki a tọọ sọnọ, ki a dari rẹ, ki a paa lasẹ lati se daradara , ki a si kọ fun un lori sise aburu, ki a se ifarada si ohun ti o ba wa lati ọdọ rẹ, ki a si ma se jẹ ki ohun aburu kankan de regberegbe rẹ.

Ki a da ẹbi pọ jẹ sababi gigun ẹmi, ati ki ọpọlọpọ ibukun ba dukia wa. Annabi Muhammad (r) ti kii pa irọ ti o jẹ olododo, ẹni ti a ma ngba lododo sọ bayi ninu Hadiisi ti Bukhari ati Muslim gba wa:

حديث أنس بن مالك أنه قال: "من سره أن يبسط له في رزقه، وينسأ له في أثره، فليصِلْ رَحِمَه" رواه البخاري ومسلم.

 “ẹni ti o ba fẹ ki ọna arisiki ohun fẹ si, ti o si nfẹ ki ẹmi ohun gun bakana, ki iru ẹni bẹẹ da ẹbi rẹ pọ”.

Annabi Muhammad (r) se alaye wipe:

وقد بين النبي صلى الله عليه وسلم أن الوصل الحقيقي هو الذي يكون من الإنسان عندما تقطعه رحمه، أما الذي يصل من وصله فهو مكافئ لذلك المعروف فحسب، وهذا وإن كان من الصلة إلا أن من وصل أقاربه القاطعين له كان أجره أعلى وأعظم، ولهذا قال رسول الله صلى الله عليه وسلم :  "ليس الواصلُ بالمكافئ، ولكن الواصلَ الذي إذا قَطَعت رَحمُه وصلها)) رواه البخاري.

“ẹni ti o nda ẹbi rẹ pọ ni ẹni ti o nse daradara fun ẹbi ti o njina sii, ti ko dapọ mọ ọ. o wa sọ pe:” ki ise ẹni ti o n dapọ mọ ẹbi ni ẹniti nse ẹsan fun ẹni ti o se daradara fun, sugbọn ẹni ti o ndapọ mọ ẹbi ni ẹni ti o n dapọ mọ ẹni ti o nja pẹlu rẹ” Bukhari lo gba Hadiisi yi wa

Isilaamu fẹ, ki a bere ẹbi wa yowu ki ojẹ, koda ẹbi wa ti ojẹ keferi.

فعن أسماء بنت أبي بكر -رضي الله عنها – قالت : قدِمَتْ أمي وهي مشركة في عهد قريش ومدتهم إذ عاهدوا النبي صلى الله عليه وسلم مع أبيها، فاستفتيت النبي صلى الله عليه وسلم فقلت : إن أمي قدمت وهي راغبة - يعني في صلتها - أفأصلها؟ قال:  "نعم ، صِلي أمك" رواه البخاري.

Asmau ọmọ Abubakare bi Anabi Muhammad (r) leere pe:

 “ Iya mi ti o jẹ keferi, njẹ mo le se daradara fun bi? Annabi sọ wipe : Bẹẹni se daradara si iya rẹ” Bukhari lo gba Hadiisi yi wa.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun , njẹ a tẹ le ọrọ Ọlọhun nipa ki a dapọ mọ ẹbi wa bi, njẹ a nyọju si wọn bi? Njẹ a nse daradara si wọn bi? Njẹ a nse amoju kuro bi nipa kudiẹ-kudiẹ wọn bi ati lile ọkan wọn pẹlu wa? A pe iwọ ti o nwa oore aye ati ti ọrun da ẹbi rẹ pọ o; ma se yago kuro fun wọn. Bi a ba nse daada si ẹbi  a o jẹ ere rẹ laye ati lọrun: sise daradara si ẹbi ni apẹẹrẹ pipe igbagbọ ati daradara Isilaamu wa. sisẹ daradara si ẹbi ni o ma nfa ọpọ arisiki ati ibukun , ti o si maa njẹ okunfa ẹmi gigun sise daradara si ẹbi ma njẹ ki a ri iyọnu Ọlọhun.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun; ẹ o gbọ ohun ti awọn ẹni isiwaju daradara sọ ni?

Umar bin khattab sọ wipe:

قال عمر رضي الله عنه : "تعلموا أنسابكم ثم صلوا أرحامكم، والله إنه ليكونن بين الرجل وبين أخيه شيء، ولو يعلم الذي بينه وبينه من داخلة الرحم لأوزعه ذلك عن انتهاكه" [تفسير الطبري 1/ 144].

“ẹ lọ mọ nipa ẹbi yin, ki ẹ si da ẹbi yin pọ, mo fi Ọlọhun bura ti nkankan ba tilẹ wa laarin yin; ti iru ẹni bẹ ba mọ ohun ti sise daradara si ẹbi ko sinu iwọ ki yoo gboya lati faa ya” Tafsir Tabary 1/144.

Attọi sọ wipe :

وقال عطاء بن أبي رباح: "لَدِرهمٌ أضعه في قرابتي أحب إلي من ألفٍ أضعها في فاقة، قال له قائل: يا أبا محمد وإن كان قرابتي مثلي في الغنى؟ قال : وإن كانوا أغنى منك!" [مكارم الأخلاق لابن أبي الدنيا ص 62].

Dirihamu kan ti mo ba na fun ẹbi mi wu mi ju ẹgbẹrun iru rẹ ti mo ba na fun alaini. ẹni kan beere pe: Baba Muhammad ti ẹbi mi ba jẹ ẹni ti o rọrọ gẹgẹ bi ti eni naa? o sisọ pe : koda bi iru ẹni bẹẹ ba rọrọ ju ọ lọ.” Makarimul Akhlaaq- Ibn Abi Duniya  pp. 62.”

Amru bun Dinari sọ bayi:      

وقال عمرو بن دينار: "تعلمُنَّ أنه ما من خطوة بعد الفريضة أعظم أجراً من خطوة إلى ذي رحم"

 “Lọọ mọ wipe : ko si igbesẹ kan ti ẹda le gbe lẹhin isẹ ọranyan ti o le pọ ni laada ti yoo tobi to igbesẹ ti ẹniyan gbe lati fi da ẹbi rẹ pọ ”

Sulaiman bun Musa sọ wipe:

وقال سليمان بن موسى : "قيل لعبد الله بن محيريز : ما حق الرحم؟ قال: تُستقبَلُ إذا أقبلت، وتُتبعُ إذا أدبرت" [المصدر السابق].

“wọn bere lọwọ Abdullahi bin Mihriiz: kini ẹtọ ẹbi ẹni? o sọ wipe: ki a pade rẹ ti o ba da ọju kọ ọ , ki o si tẹ lee  ti ọ ba kọ ẹyin si ọ. Al-Aadabul Sariyah- Bin Muflih .3/269.

 

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, gẹgẹ bi sise daada si ẹbi se ni laada to ; bẹẹni ki a jakun ẹbi naa se buru pẹlu, Annabi Muhammad (r) sọ wipe:

عن جبير بن مطعم ؛ أنه سمع رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول : " لا يدخل الجنة قاطع رحم". رواه البخاري.

“ẹni ti o ba ja okun ẹbi ko ni wọ Al-jannah” Bukhari lo gbaa wa.

ẹni ti o ba jakun ẹbi gẹgẹ bi ẹni ti o njẹ eeru gbigbona ni. “ọkunrin kan bere lọwọ Annabi wipe:

 فعن أبي هريرة رضي الله عنه قال: أتى رجل النبي صلى الله عليه وسلم، فقال : يا رسول الله، إن لي قرابة أصلهم ويقطعوني، وأحسنُ إليهم ويسيئون إليّ، ويجهلون عليّ، وأحلم عنهم؛ قال: "لئن كان كما تقول كأنما تسفُّهم الملَّ، ولا يزال معك من الله ظهير عليهم ما دمتَ على ذلك".

“ mo ni ẹbi ti mo ma mbere wọn ti awọn kii beere mi, mo ma nse daradara si wọn, wọn si ma nse aburu fun mi, wọn hu iwa aimọkan pẹlu, emi si ma nse suru pẹlu wọn? Annabi sọ wipe ti o ba jẹ pe bi o ti se sọ yi ni o se nse pẹlu wọn, gẹgẹ bi igba ti o nfun wọn ni eeru gbigbọna jẹ ni, Ọlọhun yoo yan alaabo ti ọ niwọn igba ti o ba nse gẹgẹ bi o se sọ yii”.

Eleyi ti o tobi julọ ninu jijakun ẹbi ni ki ọmọ se aburu si obi rẹ mejeji ati awọn bẹẹ bẹẹ lọ ninu awọn ẹbi ẹni. Annabi sọ wipe:

يقول رسول الهدى r : "ما من ذنب أحرى أن يعجل اللهُ لصاحبه العقوبة في الدنيا - مع ما يدِّخره له في الآخرة - من قطيعة الرحم والبغي".

“ ko si  ẹsẹ kan ti Ọlọhun le tete  fi iya rẹ jẹ ẹni ti o ba see laye, yatọ fun eyi ti yoo baa fi pamọ lọrun, ti o o tobi to jija okun ẹbi ati ikọja ala”

أيها المسلمون ,إن أصحاب الرحم على  درجات :

الدرجة الأولى : أهل الاستقامة والدين والتقوى، وهؤلاء يوصلون بالأسباب السابقة الذكر، سواء كانت رحمهم عامة أم خاصة.

الثانية: أهل البدع والفسق والفجور وهؤلاء نوعان  

أ. مجاهر ببدعته، وفسقه، وفجوره، داعٍ لذلك. فهؤلاء يهجرون هجراً تاماً، وهجر هؤلاء من أجلِّ القرب عند الله عز وجل، ولا ينبغي أن يجامل في ذلك. وإن كان في مداراتهم واتقائهم درء مفسدة أوجلب منفعة استحب مداراتهم واتقاؤهم حسب الحاجة إلى ذلك، وقد جعل الله لكل شيء قدراً، وقد قال الله عز وجل: "إلا أن تتقوا منهم تقاة"، وقد هشَّ وبشَّ رسولُ الله صلى الله عليه وسلم في وجه عيينة بن حصن، وقد قال عندما استأذن عليه: "بئس أخو العشيرة"، وعندما قيل له في ذلك، قال: "إنا نهشُّ في وجوه قوم وقلوبنا تلعنهم"، أوكما قال.

ب. متسترين ببدعهم وفسقهم. وهؤلاء يعاملون معاملة المسلم مستور الحال، إلا لمن علم حقيقتهم، وحتى في هذه الحال إن كان في معاملتهم والإحسان إليهم درء مفسدة أوجلب منفعة لهم أولغيرهم عوملوا ووصلوا، سيما من أقربائهم

الثالثة : الكفار والمنافقون وهؤلاء نوعان كذلك

أ. محاربون، وهؤلاء يقاطعون ولا يوصلون إلا من باب المداراة واتقاءً لشرهم.

ب. غير محاربين، وهؤلاء يوصلون بالإحسان وبحسن المعاملة ونحو ذلك.

 

·        Awọn ẹbi ẹni pin si ọrisirisi ọna meji:

·        Awọn ti wọn lẹtọ si daradara wa julọ ninu ẹbi wa ni awọn ẹbi ti wọn duro deede lori ẹsin Ọlọhun ti wọn lẹsin ti wọn si npaya Ọlọhun pẹlu.

·        Awọn ti wọn jẹ ẹbi wa, sugbọn ti wọn jẹ poki eniyan, oniwakiwa abi oni Bid’a (adaadalẹ ninu ẹsin) awọn na pin si ọna meji:

·        ọna akọkọ ninu wọn ni awọn ti wọn nse Bid’ah tiwọn lase han, ti wọn se poki ati iwa buburu wọn ni ase- sita; iru awọn ẹni bayi a o ja pẹlu wọn. a ko si nii maa se itanjẹ  pẹlu wọn. Ayafi awọn ti sise itanjẹ pẹlu wọn ba le fa anfani fun musulumi ti a si le fi ti tara wọn yẹ aburu kuro fun musulumi iru ẹnibẹ a le se itanjẹ pẹlu wọn.

Awọn ipin keji ni awọn ti won fi pamọ; a o maa baa awọn eleyi lo papọ gẹgẹ bii ẹni ti iwa palapala rẹ pamọ. Sugbọn ti iwa ti ko tọ wọnyi ba fi han si wa; a o ja pẹlu wọn ayafi ti sise itanjẹ pẹlu wọn ba le fa anfani fun musulumi tabi ti o si le yọ aburu kuro fun musulumi lo sẹku.

Ipin miran ni awọn keferi ati Munafiki; awọn eleyi naa pin si meji, awọn ti wọn ba doju ogun kowa; iru awọn bayi a o ja pẹlu wọn; ayafi sise itanjẹ pẹlu wọn ,awọn ti ko doju ogun kọ wa jẹ awọn ti a o maa se daradara sii, ti a o si tun maa pe wọn si ẹsin ati iduro deede. Bakannaa a o si maa se adura fun wọn lẹhin pe ki Ọlọhun fi ọna mọ wọn. Annabi Muhammad (r) ma nse adura wipe:

فقد كان صلى الله عليه وسلم يدعو لقومه : "اللهم اهدِ قومي فإنهم لا يعلمون"

“Oluwa fi ọna mọ awọn ijọ mi tori pe ọrọ ko yewọn ni.

ẹ se dara si ẹbi yin pẹlu ki ẹ maa bẹwọn wo, ki ẹ maa fun wọn ni ẹbun, ki ẹ si maa tọrẹ fun wọn, ki ẹ se gbogbo rẹ pẹlu aanu, itujuka ati apọnle, ki ẹ si sọra fun ohun ti o le fa jijakun ẹbi, tori pe o le fa adanu laye ati lọrun.

أيها المسلمون : هذا، واعلموا رحمني الله وإياكم أن الله جل جلاله أمرنا بالصلاة على نبيه وقال جل وعلا قولاً كريماً: إن الله وملائكته يصلون على النبي يا أيها الذين آمنوا صلوا عليه وسلموا تسليماً [الأحزاب:56].

اللّهُمَّ أَعِزَّ الإسْلاَمَ وَالْمُسْلِمِينَ، وَدَمِّر أَعَدَاءَكَ أَعَدَاءَ الدِّينِ، وَانْصُرْ عِبَادَكَ الْمُوَحِّدِينَ، اللّهُمَّ عَلَيْكَ بِالْكَفَرَةِ الْفَجَرَةِ فَإِنَّهُمْ لاَ يُعْجِزُونَكَ يَارَبَّ الْعَالَمِينَ

رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الأَخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَدَابَ النَّارِ