BIBA ẸNIRERE SỌRẸ ATI ORIPA RẸ LORI ẸNIKỌỌKAN

Eko ni soki

Melomelo omoniyan ti o ti ileere jade ti o di idakuda lati ara ore ti o yan ni aayo, ore daadaa yio maa gbani ni iyanju daadaa sise, ni idakeji, ore aburu koni gbani ni yanju nkankan ti o ju aburu lo,lati ara idi eyii, ni Islam fi se wa ni ojukokoro yiyan ore ti o je eniire.

Awọn erongba khutuba

-           Rire musulumi kọọkan lori ilana ati iwa isilaamu

-           Wiwani nisọra kuro nibi awọn ẹni buruku, ati pipanilasẹ biba awọn mumini rin.

-           Titẹnpẹlẹ mọ rire awọn ọmọbinrin ati sisamojuto awọn ti wọn nba a sọrẹ

Akoko khutuba: isẹju marundinlogoji

الحمد لله رب العالمين شرع لنا دينا قويما , وهدانا صراطا مستقيما , وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لاشريك له وكفى بالله عليما , وأشهد أن محمدا عبده ورسوله حثّ على صحبة الصالحين صلّى الله عليه وعلى آله وأصحابه وكل من اتّبعه  وسلم تسليما . أما بعد:

Ọpẹ ni fun Ọlọhun ọba, Alaanu julọ, oloore ọfẹ. Mo jẹri pẹ kosi ẹniti ijọsin ododo yẹ, ayafi Ọlọhun nikan, ko lorogun ko lafiwe, bẹẹni mo si jẹri pe Annọbi wa Muhammed ẹrusin Ọlọhun ni, o pawa lasẹ lati sẹsa ọrẹ rere barin bẹẹni o si wawa nisọra nibi ọrẹ buruku ikẹ ati igẹ Ọlọhun ki o maa ba Anọbi wa, awọn ara ile rẹ awọn ẹmẹwa ati gbogbo ẹlẹsin isilaamu lapapọ

Ẹyin mumini ododo, ẹ lọ mọ wipe dajudaju Ọlọhun da ẹda eniyan lẹniti ko nii maa dawa, da jẹun tabi maa sẹmi lohun nikan, bikosepe yoo bukata si ki o ropọ mọ ẹlomiran. Isilaamu si niyi, ẹsin to ba gbogbo adamọ mu ni, kódà, adamọ toba bajẹ isilaamu ni yoo tun un se, idi niyi ti Ọlọhun kofi da annọbi Adamọ loun nikan.

 Ọlọhun sọ pe:

"هو الذى خلقكم من نفس واحدة وخلق منها زوجها ليسكن إليها"

 On ni Ẹniti o da nyin lati inu ẹmi kansoso, O si se aya rẹ lati inu rẹ ki o le ma ba a gbe “suratul A’rafi 189

Nitoripe ọmọniyan ko le dase aye, idi niyi ti isilaamu se se afilọlẹ awọn ijọsin kan ni adijosepọ, bi irun kiki ni janmọọ, kódà ojisẹ Ọlọhun  gbero lati dana sun ile awọn eniyan kan, wọn kii kirun ni janmọọ ninu mọsalasi. Bẹeni o gba arinrinajo niyanju lati wanikúnra.

 Isilaamu seniyan loju ọyin lati sẹsa ọrẹ gidi ti yoo maa ran an leti, bi o ba gbagbe, ti yoo maa salaye ohun ti ko yee fun un. Wọn ni fi ọrẹ rẹ han mi ki n le sọ iru eniyan ti o jẹ’’

Sisẹsa ọrẹ, gbọdọ wa ni ibamu si ilana Isilaamu nipa ẹniti o yẹ ki a base, ati ẹniti koyẹ ki a ba sọrẹ. Ọlọhun sọ pe:

"إنما وليكم الله ورسوله والذين آمنوا الذين يقيمون الصلاة ويؤتون الزكاة وهم راكعون * ومن يتولّ الله ورسوله والذين آمنوا فإن حزب الله هم الغالبون"

"Dajudaju oluranlọwọ yin, olugbojule yin ni Ọlọhun ati ojisẹ Rẹ ati awọn ti o gbagbọ ni ododo awọn, ẹniti nkirun ti wọn si nyan zakat awọn ni olutẹriba. Ẹniti o ba mu Ọlọhun lọrẹ ati ojisẹ Rẹ ati awọn ti o gbagbọ ni ododo, dajudaju awọn ijọ ti Ọlọhun, awon si ni olubori’’ Suratul Maidah 55 - 56

Ọlọhun tun sọ pe:

"لا تجد قوما يؤمنون بالله واليوم الآخر يوآدّون من حآدّ الله ورسوله ولو كانوا آباءهم أو أبناءهم أو إخوانهم أو عشيرتهم"

"Irẹ ko ni ri awọn ẹniyan ti nwọn gba Ọlọhun gbọ lododo ati ọjọ igbẹhin ti nwọn yoo ni ifẹ si ẹniti o tako Ọlọhun ati ojisẹ Rẹ, bi o fẹ bi awọn jẹ awọn baba wọn tabi awọn ọmọ tabi awọn arakunrin wọn tabi awọn ibatan wọn “suratul Mujadalah: 22. Bi ọrọ inu ayah tilẹ jọ bi iro sugbọn asẹ lỌlọhun fipa, gẹgẹ bi afa wa Sinkiti se sọ ọ.Tun wo Suratul Mumtahina: 4 ati Maidah: 54 ati suratul Fathi:29

O se pataki fun irẹ musulumi lati sa fún ọrẹ buruku gẹgẹ bi o o se sa fun kinnun, toripe eeyan koni ba ẹni buruku rin keniyan tun sorire.

Ọlọhun sọ pe:

"ويوم يعضّ الظالم على يديه يقول ياليتني اتخذت مع الرسول سبيلا * يا ويلتى ليتنى لم أتّحذ فلانا خليلا * لقد أضلّني عن الذكر بعد إذ جاءني وكان الشّيطان للإنسان خذولا"

 “Atipe ọjọ ti alabosi ma ge ika rẹ jẹ, ti yoo ma sọpẹ Ye, nbamọni ti emi ko bá ti ba ojisẹ na tọ oju ọna kanna. Ye, ẹ wo egbe abamọ mi o! emi ko ba ti mu lagbaja ni ọrẹ ayo. Dajudaju o si mi lọna kuro nibi iranti na lẹhin igbati o wa ba mi, atipe esu jẹ ẹniti yoo da ọmọ enia da ara rẹ”.suratul furkaani: 27-29.

Ojisẹ Ọlọhun tilẹ ti wani nisọra nipa ọrẹ buruku, bẹni o si sẹwa loju ọyin nipa ọrẹ gidi. O sọ pe: Apejuwe ẹniti mba ọrẹ gidi rin, bii ẹniti nba onilọfinda sọrẹ ti koni pofo ọkan ninu ore mẹta; ninu ki o ra lọfinda, tabi ki ọrẹ rẹ bun un, tabi ki o fimú rẹ ko oorun ti o dara.

Apejuwe ẹniti mba ọrẹ buruku rin dabi ti ẹniti o mba alagbẹdẹ sọrẹ ni ti ko le pofo ọkan ninu aburu meji: ninu ki o fina jo asọ rẹ tabi ki o fimu ko oorun ti ko dàra.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun laise aniani, oore to pọ ni yiyan ọrẹ rere yoo bi fun ẹnikọọkan ati awujọ, bi awujọ ba si ti dara, ọpọ ibukun Ọlọhun naa ni yoo sọ kalẹ sinu awujọ naa. Ọlọhun sọ pẹ:

"ولو أنّ أهل القرى آمنوا واتقوا لفتحنا عليهم بركات من السّماء والأرض ولكن كذّبوا فأخذناهم بما كانوا يكسبون"

“Atipe ti o ba se pe awọn ara ilu na ba gbagbọ lododo ni ti nwọn si paiya ofin [Ọlọhun ] Awa iba sina ibukun fun wọn lati sanma ati ilẹ - sugbọn nwọn pe [ọrọ Ọlọhun] nirọ, nitorinaa, A si mu wọn nitori isẹ ti wọn se’’ suratul a’rafi 96.

Afa Bagawi sọ pe itumo [isinà ibukun] nipe: Ọlọhun yoo maa rojo lati sanma ti irugbin yoo si maa yọ dada, bẹni ọdà kòsì nii dáwọn mọ

Ninu anfani yiyan ọrẹ rere laayo ni pe, Ọlọhun yoo kowọn jọ sinu ọgba alujanna. Ọlọhun sọ pẹ:

"إنّ الذين آمنوا وعملوا الصّالحات كانت لهم الفردوس نزلا"

 Dajudaju awọn ẹniti nwọn gbagbọ lododo, ti nwọn n nsisẹ rere, aarin gbungbun ọgba idẹra na [Alfiridaosa] ti jẹ ibusọ fun wọn’’suratul Kahfi :107

Awọn ẹnirere ti wọn jẹ eniisaajú gbọ agbọye yiyan orẹ ye, wọn si se akolekan to yanju nipa yiyan ọrẹ, latari wipe annabi lo rewọn. Imam Buhari se alaye nipa bi anọbi se se Salimọnu ni ọmọiya Abu Daridai. Ni ọjọ kan Salimanu lọ se abẹwo ọmọ iya rẹ abu Daridai, ko baa nile, sugbọn o ba iyawo rẹ lẹniti ko se ọsọ, loba sọ fun un pe kini o sẹlẹ si ọ? O si dahun pe ọmọ iya kό bukata si aye. Ni Abu Daridai naa ba de, niyawo bá gbe onjẹ fun un. Labu Daridai ba sọ pe iwọ jẹun ni tirẹ, toripe emi gbawẹ; ni Salimanu ba sọ pe: Emi naa koni jẹun ayafi ti o ba jẹ. Loba jẹun. Nigbati ilẹ su, Abu Daridai fẹẹ maa yan nọfila ni Salimanu ba sọ fun un pe: lọ ọ sun, lọ ba lọọ sun, ko pẹ pupọ loba tun taji lati yan nọfilat, Salimọnu tun sọ fun un pe, sun diẹ si, titi ti o fi ku diẹ ki òru parí Salimanu sọ fun un pe, dide ni isinsinyi ki o si yan nọfila, bẹnì o tun sọ fun un pe: dajudaju oluwa rẹ ni awọn ẹtọ kan lori rẹ, bẹni ẹmí ati iyawo rẹ naa ni awọn ẹtọ ati ojuse tiwọn, ti o si gbọdọ san fun wọn, torinaa, tara fun ẹni kọọkan ní ẹtọ ọ rẹ. Nigbati wọn de ọdọ anọbi ti wọn se alaye fun un, anobi sọ pe ododo ni Salimọnu sọ.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ẹ ò warí bi awọn sahabe se nran arawọn lọwọ lorí isẹ rere ati ibẹru Ọlọhun. Bi ọrẹ rere se gbọdọ jẹ si ọrẹ rẹ nu un. Ọrẹ buruku ko lore kankan to le se ọrẹ rẹ, lehin ki o sii lọna ki o si sẹri rẹ kuro nibi ẹsin Ọlọhun.  Ẹ ranti itan Abu Tọlib, ẹ fi sẹ arikọgbọn. Nigbati baba yii npọkaka iku lọwọ, ojisẹ Ọlọhun lọ si ọdọ rẹ, o si ba Abu Jahali ati Abdulahi bun abi Umayyati lọdọ rẹ. Lanọbi ba sọ fun un pe: sọ la illaha illa allahu’’ ki nfi ba ọ fi sẹri pe o se isilaamu lọdọ Ọlọhun, baba naa fẹẹ wi, sugbọn awọn ti ọrẹ mejeji sọ fun un pe se o fẹ filana Abudul Mutọlibi silẹ ni.

Nigbẹhin o ku sori ilana ẹbọ, lojisẹ Ọlọhun ba sọ pe:

" ما كان للنبيّ والّذين آمنوا أن يستغفروا للمشركين ولو كانوا أولي قربى من بعد ما تبيّن لهم أنّهم أصحاب الجحيم"

"N o maa tọrọ idariji ẹsẹ fun ọ, bi Ọlọhun ko ba kọ fun mi lati se bẹẹ ni ayah ba sọ kalẹ pe: kó tọ si annabi ati awọn ti nwọn gbagbọ lododo pe ki nwọn tọrọ aforijin fun awọn ọsẹbọ, bi o fẹ bi nwọn jẹ ẹbi ti o sunmọ wọn, lehin ti o ti han si wọn pe dajudaju awọn [ọsẹbọ] ni ero ina” Suratul Taobah: 113.

Bẹẹni o sọ ayah kalẹ nipa abi Tọlibi pe “irẹ ko le fi ẹniti o ba wu ọ mọna sugbọn Ọlọhun ni o maa nfi ọna mọ ẹniti o ba wu” Ni ipari ẹyin obi ati alagbatọ, ẹ jẹki o di mimọ pe adaranjẹ lẹ jẹ, gbogbo yin ni Ọlọhun yoo si bi leere nipa bi ẹ se da ẹran yin jẹ si. Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Ko si ẹniti Ọlọhun yoo fi se alakoso lori awọn eniyan kan, ti onitọhun yoo wa ku, lẹniti o n sabosi wọn, ayafi ki Ọlọhun se wiwọ alujana leewọ fun un’’. Ninu abosi to tobi lòwà, ki òbí mámọ ibiti ọmọ rẹ  ngbe, ibito nsun, awọn wo lósí nbáárín? O ma se fun iru obi naa, ọmọ rẹ ti nba esu rin.

Ẹyin ọdọ, ẹyin naa ẹ se pẹlẹ, ẹ sẹsà ọrẹ gidi bárìn, sẹ ẹ mọ pe “àgùtàn tí mbájá rìn, yoo jẹgbẹ’’ torinaa, ẹ maa ba awọn ẹnirere, eniọlọhun, oloripipe ẹda rin, awọn ti wọn yoo maa ran yin lọwọ lori ododo, isẹ rere ati ibẹru Ọlọhun.

فاتقوا الله -  عباد الله واهتموا بأولادكم  وراقبوا من يصاحبون  وتذكّروا أنّ كلكم راع وكلكم مسئول عن  رعيته