Apọnle ti Islam se fun Musulumi-binrin

Eko ni soki

Obinrin je eniti won nfi oju re rare, eniyepere nigba aimokan titi ti esin Islam fi de, ti o gbe aponle ti ko ni afiwe fun-un, ti o si laa kuro nibi abosi aimokan, ti o si fi awon etoo re rinle fun-un, o si se obinrin ni dogba pelu okunrin nibi opolopo awon oranyan esin, ati nibi esan ati ijiya, obinrin ko ri igbeaponle funni ati iyi gegebii o se ri ninu awon ofin esin Islam.

Awọn erongba lori Khutuba naa:

 1-     Sise alaye ipo ti obinrin wa ki Islam too de;

2-     Sise alaye ati isafihan sise agbega Islam fun aaye obinrin;

3-     Sise alaye tito ti Islam to obinrin ati ọkunrin pọ si ipo kan naa ni ibi awọn idajọ ẹsin kan;

4-     Sisipaya awọn apọnle ti Islam se fun obinrin.

الحمد لله الذي خلق الإنسان ذكراناً وإناثاً، وفطر كلّ منهم بما يناسبه، فموضوع المرأة ووضعها في الإسلام وعند المسلمين.

أيها المستمعون: إنه لا يمكن معرفة مدى تكريم الإسلام للمرأة إلا بعد معرفة وضعها وحالها في الجاهلية وعند الأمم قبل الإسلام.

Koko khutubah yi jẹ ọrọ kan ti o ti n ja ranyinranyin lati igba ti o ti pẹ titi di asiko yi. Ti wọn si titori rẹ pe Islam ati gbogbo Musulumi ni alailaju ati alaimoye, lalai ni ẹri kankan lori eleyi, ti awọn ọta ẹsin si ti loo gẹgẹ bi ọna lati si awọn eniyan lọna lọ kanrin. Koko ọrọ naa ni: obinrin ati ipo rẹ ni inu Islam ati lọdọ gbogbo Musulumi. Ako lee mọ apọnle ati iyi ti Islam muba obinrin afi ki a kọkọ mọ iha wo ni awọn ijọmiran siwaju Islam ati ni ode oni kọ si obinrin.

Iyaworan bi obinrin tiri ki Islam too de, ninu rẹ nipe ẹrù lasan ni wọn ka obinrin kun tẹlẹ, ti kosi ni ẹtọ ati jogun. Itiju si ni wọn ka bibi obinrin si. Ninu ki wọn paati lai se amojuto rẹ, tabi ki wọn paa ni ipakupa. Wo Al-Quran, suratul-Nahl 16: 58-59.

{وإذا بشر أحدهم بالأنثى ظل وجهه مسودا وهو كظيم. يتوارى من القوم من سوء ما بشر به أيمسكه على هون أم يدسّه في التراب ألا ساء ما يحكمون} [النحل:58-59].

Tun wo:

{وإذا الموءدة سئلت بأي ذنب قتلت} [التكوير:8-9]..

Oburu to bẹẹ debii wipe Ọlọhun se adeun pe Ohun yoo gba ẹsan fun awọn obinrin ti wọn pa wọnyi nijọ agbende.

Wọn a maa jẹ obinrin mogun ni igba aimọkan (Jahiliyah), gẹgẹ bi Bukhari se gba ẹgbawa rẹ lati ọdọ Ibn 'Abbas (رضي الله عنهما) wipe: "Ti ọkunrin kan ba ku nigba aimakan, awọn ara ile rẹ ni wọn lẹtọ si iyawo rẹ, bi o bawu ẹnikan ninu wọn o le fẹẹ, bi o ba si tun wuwọn wọn le fi lọkọ, bi o si wuwọn nigbamiran wọnle mọ fi lọkọ rara, ni Ọlọhun fi sọ wipe:

{يا أيها الذين آمنوا لا يحل لكم أن ترثوا النساء كرها} [النساء 4: 19].

"Ẹyin ti ẹ gbagbọ ni ododo! kolẹtọ funyin ki ẹ jogun obinrin ni tulasi tipatipa). [An-Nisaa 4: 19].

Ọkunrin kan lẹtọ ati fẹ iye iyawo ti o ba wuu lasiko aimọkan, ko si opin fun onka iye ti o le fẹ, bẹẹ ko ni tọju wọn botitọ ati botiyẹ. Sugbọn nigbati Islam de, o fi aala si iye onka iyawo ti ọkunrin le fẹ lẹẹkan naa. O se iyawo mẹrin lẹtọ, ẹwẹ, o tun se ise deede ati dọgbandọgba laarin wọn ni ọranyan lori ọkunrin, ti o si tun jẹ majẹmu ilẹtọ si fifẹ ju iyawo kan lọ. wo surat An-Nisaa 4: 3.

{الرجال قوامون على النساء بما فضل الله بعضهم على بعض وبما أنفقوا من أموالهم} [النساء 4: 34].

Ninurẹ naa nipe ọdunkan gbako ni obinrin yoo fi se  igbale joko ti ọkọ rẹ ba ku, lalaijade rara, Islam se eleyi lewọ, ti o si fi ('idah) osu mẹrin ati ọjọ mẹwa paarọ.

Iye igba ti ọkọ rẹ le kọọ kalẹ ko ni aala lasiko aimọkan, lati lee fi iya jẹ obinrin naa si ni.

Sise afihan awọn ọna ti Islam fi se apọnle fun obinrin:

Iru ipo ti obinrin wa siwaju ki Islam too de niyẹn, sugbọn nigbati Islam de, o gba obinrin silẹ lọwọ abosi, o se apọnle rẹ, koda otun fi awọn ẹtọ rẹ rilẹ pẹlu. Kopin sibẹun, o tun sọọ di akẹgbẹ ọkunrin ni ibi ọpọlọpọ idajọ ni inu ẹsin, jijina si awọn eewọ, nibi gbigba laada ati ofin ijiya, ti wọn koju arawọn lọ nibẹ. Wo suratul-Nahal 16: 97, Al-Ahzaab 33: 35.

Islam gbe ọla fun ọkunrin lori obinrin nibi ijẹ opomulero, ati eto ijogun ara ẹni, ijẹri, owo-ẹmi ati ikọraẹni silẹ fun awọn idi, ninu rẹ nipe ọkunrin lagbara ara ati lakai ju obinrin lọ. wo suratul-Nisaa 3: 7, 34, Baqarah 2: 228, Al-Ahzaab 33: 35.

{الرجال قوامون على النساء بما فضل الله بعضهم على بعض وبما أنفقوا من أموالهم} [النساء 4: 34]. وقال تعالى: {وللرجال عليهن درجة} [البقرة 2: 228]. ففضل الله الرجل على المراة في مقامات، ولأسباب تقتضي تفضيله عليها، كما في الميراث والشهادة والدية والقوامة والطلاق، لأن عند الرجل من الاستعداد الخلقي ما ليس عند المرأة وعليه من المسؤولية في الحياة ما ليس على المرأة.

وجعل الله للمرأة حقا في الميراث فقال سبحانه : {للرجال نصيب مما ترك الوالدان والأقربون وللنساء نصيب مما ترك الوالدان والأقربون مما قل منه أو كثر نصيبا مفروضا} [النساء4 :7].

{من عمل صالحا من ذكر أو أنثى وهو مؤمن فلنحيينه حياة طيبة ولنجزينهم أجرهم بأحسن ما كانوا يعملون} [النحل 16: 97]. وجعل الله لها التملك والتصدق والاعتاق كما للرجل. قال تعالى : {إن المسلمين والمسلمات والمؤمنين والمؤمنات والقانتين والقانتات والصادقين والصادقات والصابرين والصابرات والخاشعين والخاشعات والمتصدقين والمتصدقات والصائمين والصائمات والحافظين فروجهم والحافظات والذاكرين الله كثيرا والذاكرات أعد الله لهم مغفرة وأجرا عظيما} [الأحزاب 33: 35].

Islam fun obinrin ni ẹtọ rẹ pe perepere nibi eto igbeyawo. O fun ni aaye ati sa ẹsa okunrin ti o ba wuu lai jẹẹ nipa, ti o si se fifilọkọ nipa lai tẹẹlọrun leewọ. Ti o si sọ kuro lọwọ awọn alagbeda pẹlu pipa awọn obi tabi alamojuto rẹ ninu awọn mọlẹbi rẹ lasẹ ki wọn tọọ si ọna.

Bi Islam sese ẹtọ ati iwọ obinrin niyi, o fun ni ẹtọ gẹgẹ bi iyawo, tabi alasunmọ, tabi ọmọ iya ni inu ẹsin. Yoo maa se isẹ ile rẹ, ti o si tun lẹtọ ati se isẹ nita labẹ ofin ẹsin Islam ti o ba bukata sii, pẹlu majẹmu iparamọ ati hijab, ati jijin naa si iropọ mọ okunrin lai lẹtọ.

Eleyi ni alaye nisoki nipa apọnle Islam fun obinrin, ti Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) si tun sọ asọsilẹ pe ki a se obinrin daada, ki a se wọn jẹjẹ.

Mo pe gbogbo ẹyin onilaakai, njẹ iyẹpẹrẹ, ẹdinku tabi abuku n bẹ nibi ibalo Islam pẹlu obinrin bi?!

Sise alaye ipo obinrin loni lọdọ awọn awujọ ọlọlaju ti wọn se keferi, lati le se afiwe rẹ pẹlu eto Islam.

Isesi obinrin ni aye ode oni oburu jai ju ti asiko aimọkan lọ. Loni, wọn sọ obinrin di ọja olowo pọọku ti wọn n le sori atẹ ni ihoho, wọn n loo ni awọn aaye ikojọ wọn gẹgẹ bi ẹru ati ọmọ ọdọ, ni inu ile, ni ibi isẹ, ni ile iwosan, ni inu baalu, ni awọn ileetura, wọn fi n se olukọ fun awọn ọkunrin, wọn n lo fun ere itage, sinima ati film lori ẹrọ mohun-maworan, redio ati awọn iwe iroyin olojoojuma, koda wọn fi n se ipolowo ọja lori awọn agolo ọja.

Wọn se abosi fun obinrin, ti wọn si gba ẹtọ rẹ lọwọ rẹ, wọn yọọ kuro ni ile ọkọ, wọn gba isẹ adamọ rẹ lọwọ rẹ, wọn ko jẹ ki o mu oju to itọju ọmọ mọ, bẹẹ ko jẹ aya rere labẹ asẹ ọkọ rẹ mọ, wọn sọọ di ẹni ti o n se wahala ati wa jijẹ ati mimu kiri lọ, bẹẹ ni ẹtọ rẹ ti o se ọranyan fun un lori ọkọ rẹ ni ninu Shari'ah. Wọn bọ asọ iyi ati apọnle lọrun rẹ, wọn wọọ lẹwu abuku ati ẹtẹ, wọn sọọ di irinsẹ igbadun lasan fun awọn ọkunrin.

Nkan ti Ọlọhun se ni ẹtọ awọn see ni eewọn, bẹẹ wọn si se nkan ti O se ni eewọ ni ẹtọ, wọn se fifẹ ju iyawo kan lọ leewọ, sugbọn wọn se sina ni ẹtọ.

Anfaani ti o pọ ni o wa nibi sise fifẹ ju iyawokan lọ, toripe obinrin pọ ju ọkunrin lọ, sibẹsibẹ iyi obinrin ni ki o wa labẹ ọkọ rẹ. Dajudaju abosi nla ni wọn se fun obinrin.

 

الحمد لله، والصّلاة والسّلام على رسول الله، وبعد؛ فيا أيها الناس: اتقوا الله تعالى في نسائكم، فإنكم مستحفظون عليهن، وأي خلل يقعن فيه فأنتم المسؤولون عنه. واعلموا أن الإسلام قد رتب أجرا عظيما على تربية البنات فعن عقبة بن عامر رضي الله عنه قال : سمعت رسول الله صلى الله عليه و سلم يقول : "من كان له ثلاث بنات وصبر عليهن وكساهن من جدته كن له حجابا من النار" أخرجه البخاري في "الأدب" وصححه الألباني.

وعن جابر بن عبد الله قال : قال رسول الله صلى الله عليه و سلم : "من كان له ثلاث بنات يؤويهن، ويكفيهن، ويرحمهن، فقد وجبت له الجنة ألبتة، فقال رجل من بعض القوم واثنتين يا رسول الله؟  قال : واثنتين. أخرجه البخاري في "الأدب".

Sise ikilọ fun gbogbo obinrin ati awọn alamojuto wọn ki wọn ma tẹti si gbogbo ipe ati ariwo anu lati ọdọ awọn ọta ẹsin ti wọn n pepe lọsibi sisi hijab kuro lori obinrin. Ati sise alaye pe Islam pese laada ti o pọ fun titọ obinrin ni ọna Islam.

Mope ẹyin ẹrusin Ọlọhun lododo! ẹbẹru Ọlọhun naa, ki ẹsi mọ wipe wọn o biyin nipa awọn ọmọ yin. O seni ni aanu pupọ bi ọpọ awọn obi se fi ọwọ tẹtẹlẹ mu ọrọ hijab fun awọn ọmọ wọn.

Islam pese laada ti o pọ fun ẹnikẹni ti o ba bi ọmọ obinrin ti o si kọọ ni ẹkọ, ti o fun ni asọ, ti o si pese gbogbo nkan ti o bukata si fun un, Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) sọpe iru ẹni bẹẹ ina Ọlọhun di eewọ fun, ti Ọlọhun yoo si mu wọ Alijanah Rẹ. Ki ẹbẹru Ọlọhun gbogbo ẹyin obi ati alagbatọ, ki ẹ tọ awọn ọmọyin paapa awọn obinrin ni ọna ti yoo seyin ni anfaani laye ati lọrun.

Lati ori pẹpẹ ibani sọrọ (mimbari) yi, mo n ipe awọn obinrin si idunimọ ẹsin wọn ẹsin Islam, ki wọn si ma wipe inu Islam naa ni apọnle ati orire wọn wa. Islam yi ni o gbe ipo obinrin ga, ti o si fun wọn ni ẹtọ wọn. Ki wọn woye si isesi obinrin siwaju ki Islam to de, ati lọdọ awọn awujọ keferi ti wọn sọ obinrin di bebi isere ati ipolowo ọja.

Ki gbogbo obinrin ma wipe ipepe ọlaju, itu obinrin silẹ, ẹtọ obinrin ati bẹẹbẹ ti o nwa lati ẹnu keferi, irọ funfun balau ni iru ipepe naa, ko si oore kankan ni bẹ, ẹyin naa ẹ wo gbogbo awọn ilu Musulumi ti awọn obinrin wọn ti tẹle iru awọn ipe yi, ti wọn si tukun puuru ti wọn tapasi ofin Ọlọhun njẹ wọn tori rẹ ni ilọsiwaju bi, njẹ wọn ni ifọkanbalẹ bi…? Ki a tun wo ilu Musulumi diẹ tosẹku ti wọn duro ti ofin Ọlọhun, bi Ọlọhun se se aanu Rẹ fun wọn, ti wọn n gbe pẹlu alaafia, ifọkanbalẹ ninu ara, ọkan ati awujọ wọn. Al-Quran sọwipe:

{من عمل صالحا من ذكر أو أنثى وهو مؤمن فلنحيينه حياة طيبة ولنجزينهم أجرهم بأحسن ما كانوا يعملون} [النحل : 97].

(Ẹnikẹni ti o ba se isẹ daada lọkunrin nio tabi lobinrin, ti o si gba Ọlọhun gbọ, isẹmi ti o dara ni iru ẹni naa yoo maa gbe, ti a o si sanwọn ni ẹsan isẹ daada wọn) [An-Nahl: 97], tunwo [Al-'Imran: 195]:

{فاستجاب لهم ربهم أني لا أضيع عمل عامل منكم من ذكر أو أنثى بعضكم من بعض} [آل عمران : 195].

Dajudaju aori wipe Islam ni ẹsin ti o pe, ti o fun gbogbo olukaluku ni ẹtọ rẹ, ti o si fi gbogbo nkan si aaye ti o yẹ. Ki gbogbo awọn aafa se alaye ẹsin naa fun awọn eniyan.

الإسلام دين عظيم وشامل، قد أعطى كل ذي حق حقه، فليس فيما أنزل الله سبحانه وتعالى أو جاء به رسوله صلى الله عليه وسلم ظلم ولا تنقص لأحد، بل الإسلام هو الدين الذي أكرم الإنسان، وأعلى مرتبته.

وعلى العلماء الربانيين أن يقوموا ويبينوا للناس حقيقة هذا الدين الشريف، فما أوتي بعض النساء إلا من جهلهن لدينهن وما فيه من المصالح والمكارم.

فاتقوا الله – عباد الله – وتذكروا دائما هادم اللذات، واعلموا أنه لا كرامة لأحد في الدنيا والآخرة إلا بتقوى الله عز وجل.